Àwọn Ọba Kìíní
4 Ọba Sólómọ́nì ṣàkóso lórí gbogbo Ísírẹ́lì.+ 2 Àwọn ìjòyè* rẹ̀ nìyí: Asaráyà ọmọ Sádókù+ ni àlùfáà; 3 Élíhóréfì àti Áhíjà, àwọn ọmọ Ṣíṣà ni akọ̀wé;+ Jèhóṣáfátì+ ọmọ Áhílúdù ni akọ̀wé ìrántí; 4 Bẹnáyà+ ọmọ Jèhóádà ló ń bójú tó àwọn ọmọ ogun; Sádókù àti Ábíátárì+ sì jẹ́ àlùfáà; 5 Asaráyà ọmọ Nátánì+ ni olórí àwọn alábòójútó; Sábúdù ọmọ Nátánì jẹ́ àlùfáà àti ọ̀rẹ́ ọba;+ 6 Áhíṣà ló ń bójú tó agbo ilé; Ádónírámù+ ọmọ Ábídà ni olórí àwọn tí ọba ní kí ó máa ṣiṣẹ́ fún òun.+
7 Sólómọ́nì ní àwọn alábòójútó méjìlá (12) tó ń bójú tó gbogbo Ísírẹ́lì, wọ́n sì ń pèsè oúnjẹ fún ọba àti agbo ilé rẹ̀. Ojúṣe ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ni láti pèsè oúnjẹ ní oṣù kan lọ́dún.+ 8 Àwọn alábòójútó náà ni: Ọmọ Húrì tó ń bójú tó agbègbè olókè Éfúrémù; 9 ọmọ Dékérì tó ń bójú tó Mákásì, Ṣáálíbímù,+ Bẹti-ṣémẹ́ṣì àti Eloni-bẹti-hánánì; 10 ọmọ Hésédì tó ń bójú tó Árúbótì (tirẹ̀ ni Sókọ̀ àti gbogbo ilẹ̀ Héfà); 11 ọmọ Ábínádábù tó ń bójú tó gbogbo gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Dórì (ó fi Táfátì, ọmọ Sólómọ́nì ṣe aya); 12 Béánà ọmọ Áhílúdù tó ń bójú tó Táánákì, Mẹ́gídò+ àti gbogbo Bẹti-ṣéánì+ tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Sárétánì nísàlẹ̀ Jésírẹ́lì, láti Bẹti-ṣéánì sí Ebẹli-méhólà títí dé agbègbè Jókíméámù;+ 13 ọmọ Gébérì tó ń bójú tó Ramoti-gílíádì+ (tirẹ̀ ni àwọn abúlé àgọ́ Jáírì+ ọmọ Mánásè, tó wà ní Gílíádì;+ òun ló tún ni agbègbè Ágóbù,+ tó wà ní Báṣánì:+ ọgọ́ta [60] ìlú tó tóbi, tó sì ní ògiri àti ọ̀pá ìdábùú bàbà); 14 Áhínádábù ọmọ Ídò tó ń bójú tó Máhánáímù;+ 15 Áhímáásì tó ń bójú tó Náfútálì (ó fi Básémátì, tó tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ Sólómọ́nì, ṣe aya); 16 Béánà ọmọ Húṣáì, tó ń bójú tó Áṣérì àti Béálótì; 17 Jèhóṣáfátì ọmọ Párúà tó ń bójú tó Ísákà; 18 Ṣíméì+ ọmọ Ílà tó ń bójú tó Bẹ́ńjámínì;+ 19 Gébérì ọmọ Úráì tó ń bójú tó ilẹ̀ Gílíádì,+ ilẹ̀ Síhónì+ ọba àwọn Ámórì àti ti Ógù+ ọba Báṣánì. Alábòójútó kan tún wà tó ń bójú tó gbogbo àwọn alábòójútó yòókù ní ilẹ̀ náà.
20 Júdà àti Ísírẹ́lì pọ̀ bí iyanrìn etí òkun;+ wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n sì ń yọ̀.+
21 Sólómọ́nì ṣàkóso gbogbo àwọn ìjọba láti Odò*+ dé ilẹ̀ àwọn Filísínì àti títí dé ààlà Íjíbítì. Wọ́n ń mú ìṣákọ́lẹ̀* wá, wọ́n sì ń sin Sólómọ́nì ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.+
22 Oúnjẹ Sólómọ́nì ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọgbọ̀n (30) òṣùwọ̀n kọ́ọ̀* ìyẹ̀fun kíkúnná àti ọgọ́ta (60) òṣùwọ̀n kọ́ọ̀ ìyẹ̀fun, 23 màlúù àbọ́sanra mẹ́wàá, ogún (20) màlúù láti ibi ìjẹko àti ọgọ́rùn-ún (100) àgùntàn, yàtọ̀ sí àwọn akọ àgbọ̀nrín mélòó kan, àwọn egbin, àwọn èsúwó àti àwọn ẹ̀lúlùú tí ó sanra. 24 Ó ń bójú tó gbogbo ohun tó wà lápá Odò+ níbí,* láti Tífísà dé Gásà,+ títí kan gbogbo àwọn ọba tó wà lápá Odò níbí; ó sì ní àlàáfíà ní gbogbo agbègbè tó yí i ká.+ 25 Júdà àti Ísírẹ́lì ń gbé lábẹ́ ààbò ní gbogbo ọjọ́ ayé Sólómọ́nì, kálukú lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, láti Dánì títí dé Bíá-ṣébà.
26 Sólómọ́nì ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rin (4,000)* ilé ẹṣin fún àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ àti ẹgbẹ̀rún méjìlá (12,000) ẹṣin.*+
27 Àwọn alábòójútó yìí ń pèsè oúnjẹ fún Ọba Sólómọ́nì àti gbogbo àwọn tó ń jẹun ní tábìlì Ọba Sólómọ́nì. Kálukú ní oṣù tirẹ̀ tó ń pèsè oúnjẹ, á sì rí i dájú pé gbogbo ohun tí wọ́n nílò ló wà.+ 28 Wọ́n á tún mú ọkà bálì àti pòròpórò wá níbikíbi tí a bá ti nílò rẹ̀ fún àwọn ẹṣin títí kan àwọn ẹṣin tó ń fa kẹ̀kẹ́ ẹṣin, bí iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún kálukú wọn bá ṣe gbà.
29 Ọlọ́run fún Sólómọ́nì ní ọgbọ́n àti òye tó pọ̀ gan-an àti ìjìnlẹ̀ òye tó pọ̀* bí iyanrìn etí òkun.+ 30 Ọgbọ́n Sólómọ́nì pọ̀ ju ọgbọ́n gbogbo àwọn ará Ìlà Oòrùn àti gbogbo ọgbọ́n Íjíbítì.+ 31 Ó gbọ́n ju èèyàn èyíkéyìí lọ, ó gbọ́n ju Étánì+ tó jẹ́ Ẹ́síráhì àti Hémánì,+ Kálíkólì+ àti Dáádà, àwọn ọmọ Máhólì; òkìkí rẹ̀ sì kàn ní gbogbo orílẹ̀-èdè tó yí i ká.+ 32 Ó kọ* ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) òwe,+ àwọn orin rẹ̀+ sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan ó lé márùn-ún (1,005). 33 Ó máa ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn igi, látorí kédárì tó wà ní Lẹ́bánónì dórí hísópù+ tó ń hù lára ògiri; ó máa ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹranko,+ àwọn ẹyẹ,*+ àwọn ohun tó ń rákò*+ àti àwọn ẹja. 34 Àwọn èèyàn ń wá láti gbogbo orílẹ̀-èdè kí wọ́n lè gbọ́ ọgbọ́n Sólómọ́nì, títí kan àwọn ọba láti ibi gbogbo láyé tí wọ́n ti gbọ́ nípa ọgbọ́n rẹ̀.+