Ẹ́sítà
3 Lẹ́yìn èyí, Ọba Ahasuérúsì gbé Hámánì+ ọmọ Hamédátà ọmọ Ágágì+ ga, ó sì gbé ìtẹ́ rẹ̀ ga ju ti gbogbo àwọn ìjòyè yòókù tí wọ́n jọ wà.+ 2 Gbogbo àwọn ìránṣẹ́ ọba tó wà ní ẹnubodè ọba máa ń tẹrí ba fún Hámánì, wọ́n sì ń wólẹ̀ fún un, nítorí ohun tí ọba pàṣẹ pé kí wọ́n máa ṣe fún un nìyẹn. Àmọ́ Módékáì kọ̀, kò tẹrí ba fún un, kò sì wólẹ̀. 3 Torí náà, àwọn ìránṣẹ́ ọba tó wà ní ẹnubodè ọba béèrè lọ́wọ́ Módékáì pé: “Kí ló dé tí o kò fi pa àṣẹ ọba mọ́?” 4 Ojoojúmọ́ ni wọ́n ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, àmọ́ kì í fetí sí wọn. Wọ́n wá sọ fún Hámánì láti mọ̀ bóyá ohun tí Módékáì ń ṣe bójú mu;+ torí ó ti sọ fún wọn pé Júù ni òun.+
5 Nígbà tí Hámánì rí i pé Módékáì kọ̀, kò tẹrí ba fún òun, tí kò sì wólẹ̀, Hámánì gbaná jẹ.+ 6 Àmọ́ kò tẹ́ ẹ lọ́rùn láti pa* Módékáì nìkan, torí wọ́n ti sọ fún un nípa àwọn èèyàn Módékáì. Nítorí náà, Hámánì bẹ̀rẹ̀ sí í wá bó ṣe máa pa gbogbo àwọn Júù tó wà ní gbogbo ilẹ̀ ìjọba Ahasuérúsì run, ìyẹn gbogbo àwọn èèyàn Módékáì.
7 Ní oṣù kìíní, ìyẹn oṣù Nísàn,* ọdún+ kejìlá Ọba Ahasuérúsì, wọ́n ṣẹ́ Púrì,+ (ìyẹn Kèké) níwájú Hámánì láti mọ ọjọ́ àti oṣù, ó sì bọ́ sí oṣù kejìlá, oṣù Ádárì.*+ 8 Hámánì wá sọ fún Ọba Ahasuérúsì pé: “Àwọn èèyàn kan wà káàkiri tí wọ́n ń dá tiwọn ṣe láàárín àwọn èèyàn+ tó wà ní gbogbo ìpínlẹ̀* tó wà lábẹ́ àkóso rẹ,+ òfin wọn yàtọ̀ sí ti gbogbo àwọn èèyàn yòókù; wọn kì í sì í pa òfin ọba mọ́, wọ́n á pa ọba lára tí a bá fi wọ́n sílẹ̀ bẹ́ẹ̀. 9 Tó bá dáa lójú ọba, kí ó pa àṣẹ kan, kí wọ́n sì kọ ọ́ sílẹ̀ pé kí a pa wọ́n run. Màá fún àwọn òṣìṣẹ́ ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) tálẹ́ńtì* fàdákà pé kí wọ́n kó o sínú ibi ìṣúra ọba.”*
10 Ọba wá bọ́ òrùka àṣẹ+ ọwọ́ rẹ̀, ó sì fún Hámánì + ọmọ Hamédátà ọmọ Ágágì,+ ẹni tó jẹ́ ọ̀tá àwọn Júù. 11 Ọba sọ fún Hámánì pé: “A fún ọ ní fàdákà àti àwọn èèyàn náà, ohun tó bá wù ọ́ ni kí o ṣe sí wọn.” 12 Wọ́n wá pe àwọn akọ̀wé ọba+ ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kìíní. Wọ́n kọ+ gbogbo àṣẹ tí Hámánì pa fún àwọn baálẹ̀ ọba, àwọn gómìnà tó ń ṣàkóso àwọn ìpínlẹ̀* àti àwọn olórí àwùjọ èèyàn lóríṣiríṣi, wọ́n kọ ọ́ sí ìpínlẹ̀* kọ̀ọ̀kan ní ọ̀nà ìgbàkọ̀wé tirẹ̀ àti sí àwùjọ àwọn èèyàn kọ̀ọ̀kan ní èdè wọn. Wọ́n kọ ọ́ ní orúkọ Ọba Ahasuérúsì, wọ́n sì fi òrùka àṣẹ ọba gbé èdìdì lé e.+
13 Wọ́n fi àwọn lẹ́tà náà rán àwọn asáréjíṣẹ́ sí gbogbo ìpínlẹ̀ tó wà lábẹ́ àṣẹ ọba, láti fi pàṣẹ pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn Júù, kí wọ́n run wọ́n, kí wọ́n sì pa wọ́n rẹ́, lọ́mọdé lágbà, àwọn ọmọ kéékèèké àti àwọn obìnrin, lọ́jọ́ kan náà, ìyẹn lọ́jọ́ kẹtàlá oṣù kejìlá, oṣù Ádárì,+ kí wọ́n sì gba àwọn ohun ìní wọn.+ 14 Kí wọ́n fi ẹ̀dà lẹ́tà náà ṣe òfin fún ìpínlẹ̀* kọ̀ọ̀kan, kí wọ́n sì kéde rẹ̀ fún gbogbo èèyàn, kí wọ́n lè múra sílẹ̀ de ọjọ́ náà. 15 Àwọn asáréjíṣẹ́ náà jáde lọ kíákíá+ bí ọba ṣe pa á láṣẹ; wọ́n gbé òfin náà jáde ní Ṣúṣánì*+ ilé ńlá.* Ọba àti Hámánì wá jókòó láti mutí, àmọ́ ìlú Ṣúṣánì* wà nínú ìdàrúdàpọ̀.