Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
Ó Gbèjà Àwọn Èèyàn Ọlọ́run
BÍ Ẹ́SÍTÉRÌ ṣe ń sún mọ́ àgbàlá ààfin tó wà ní Ṣúṣánì, kò jẹ́ kí ẹ̀rù ba òun. Ipò náà kò rọrùn rárá. Wọ́n ṣe gbogbo nǹkan tó wà ní ilé náà ní aláwọ̀ mèremère, ìyẹn ògiri oníbíríkì tí wọ́n gbẹ́ àwọn màlúù abìyẹ́ sí, wọ́n tún gbẹ́ àwọn tafàtafà àtàwọn kìnnìún tí wọ́n fi bíríkì dídán ṣe ara rẹ̀ sára ògiri náà, wọ́n ṣe àwọn òpó tó nílà àtàwọn ère gàgàrà síbẹ̀, ibi tí ààfin náà tún wà kàmàmà, ìyẹn nítòsí àwọn Òkè Zagros tí yìnyín bò tó sì dojú kọ omi odò Choaspes tó mọ́ gaara, gbogbo nǹkan yìí ń jẹ́ kí àwọn àlejò tó ń bọ̀ mọ bí agbára ọkùnrin tí obìnrin yìí ń lọ bá ti pọ̀ tó, ẹni tó pe ara rẹ̀ ní “ọba ńlá.” Ọkùnrin yìí tún jẹ́ ọkọ Ẹ́sítérì.
Ọkọ kẹ̀! Ẹ ò rí i pé Ahasuwérúsì yàtọ̀ pátápátá sí irú ọkọ tí ọmọbìnrin Júù tó jẹ́ olóòótọ́ máa fẹ́ fi ṣe ọkọ!a Kò ní irú ìwà tí Ábúrámù ní rárá, ìyẹn ọkùnrin tó fi ìrẹ̀lẹ̀ tẹ̀ lé ìtọ́ni tí Ọlọ́run fún un pé kó fetí sí Sárà aya rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 21:12) Ahasuwérúsì kò mọ nǹkan kan nípa Jèhófà Ọlọ́run tí Ẹ́sítérì ń jọ́sìn tàbí àwọn Òfin rẹ̀. Àmọ́ ó mọ òfin ilẹ̀ Páṣíà dáadáa, títí kan òfin tó ta ko ohun tí Ẹ́sítérì fẹ́ láti ṣe báyìí. Kí ni òfin náà? Òfin yẹn ni pé, wọ́n máa pa ẹnikẹ́ni tó bá wá síwájú ọba Páṣíà láìjẹ́ pé ọba sọ pé kí ẹni náà wá. Ọba kò sọ pé kí Ẹ́sítérì wá, àmọ́ ó ń lọ sọ́dọ̀ ọba. Bí ó ṣe ń sún mọ́ àárín àgbàlá níbi tí ọba ti máa rí i látorí ìtẹ́, ó ṣeé ṣe kó máa rò ó lọ́kàn pé òun fẹ́ lọ kú rèé.—Ẹ́sítérì 4:11; 5:1.
Kí nìdí tó fi fẹ̀mí ara rẹ̀ wewu? Àti pé kí la lè rí kọ́ látinú ìgbàgbọ́ obìnrin tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí? Lákọ̀ọ́kọ́ náà, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa bí Ẹ́sítérì ṣe dé ipò tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí, ìyẹn ipò ayaba ilẹ̀ Páṣíà.
‘Ó Lẹ́wà Ní Ìrísí’
Àwọn òbí Ẹ́sítérì ti kú. A ò fi bẹ́ẹ̀ mọ ohun tó pọ̀ nípa àwọn òbí tó fún un ní orúkọ náà Hádásà, ìyẹn ọ̀rọ̀ Hébérù tó túmọ̀ sí “igi mátílì,” igi yìí máa ń yọ òdòdó funfun tó sì fani mọ́ra. Nígbà táwọn òbí Ẹ́sítérì kú, ọkùnrin onínúure kan tó ń jẹ́ Módékáì tó jẹ́ mọ̀lẹ́bí rẹ̀ ṣàánú rẹ̀, ó sì mú un sọ́dọ̀ bí ọmọ. Èèyàn òbí Ẹ́sítérì ni Módékáì, àmọ́ Módékáì ti dàgbà. Ó mú Ẹ́sítérì wá sílé rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í bójú tó o gẹ́gẹ́ bí ọmọ rẹ̀.—Ẹ́sítérì 2:5-7, 15.
Ṣúṣánì tó jẹ́ olú ìlú Páṣíà ni Módékáì àti Ẹ́sítérì ń gbé nígbà tí wọ́n kó àwọn Júù nígbèkùn, ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n máa fara da inúnibíni nítorí ẹ̀sìn wọn àti nítorí bí wọ́n ṣe ń tẹ̀ lé Òfin àwọn Júù. Àmọ́ kò sí iyè méjì pé Ẹ́sítérì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú mọ̀lẹ́bí rẹ̀ yìí bí ìyẹn ṣe ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run aláàánú tó dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè lọ́wọ́ ìdààmú lọ́pọ̀ ìgbà sẹ́yìn, tó sì tún máa ṣe bẹ́ẹ̀. (Léfítíkù 26:44, 45) Kò sí iyè méjì pé Módékáì àti Ẹ́sítérì ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún ara wọn, wọ́n sì jẹ́ olóòótọ́ sí ara wọn.
Ó jọ pé Módékáì wà lára àwọn òṣìṣẹ́ ọba ní Ṣúṣánì, nítorí pé ó máa ń lọ jókòó lẹ́nu ibodè ìlú náà pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ ọba yòókù. (Ẹ́sítérì 2:19, 21; 3:3) A ò lè sọ ní pàtó nípa bí Ẹ́sítérì ṣe gbé ìgbé ayé rẹ̀ nígbà tó ń dàgbà, àmọ́ ó jọ pé kò burú tá a bá sọ pé ó ń tọ́jú bàbá tó jẹ́ mọ̀lẹ́bí rẹ̀ dáadáa, ó sì ń tọ́jú ilé, ó ṣeé ṣe kí ilé wọn wà lápá ibi tí àwọn tálákà ń gbé, odò ló la àárín ibi tí wọ́n ń gbé àti ibi tí ààfin ọba wà. Ó ṣeé ṣe kó fẹ́ràn láti máa lọ sọ́jà tó wà ní Ṣúṣánì, níbi tí àwọn tó ń ta ohun ọ̀ṣọ́ góòlù, fàdákà àtàwọn ohun ọ̀ṣọ́ míì máa ń pàtẹ sí. Ẹ́sítérì kò lè ronú pé òun náà á máa lo irú àwọn nǹkan ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye yẹn láyé òun, ó ṣe tán kò mọ ohun rere tó máa ṣẹlẹ̀ sí òun lọ́jọ́ iwájú.
Ọba Pààrọ̀ Ayaba
Lọ́jọ́ kan, àwọn èèyàn tó ń gbé ní Ṣúṣánì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro tó wà ní ilé ọba. Ní ọjọ́ tí ọba Ahasuwérúsì se àsè oúnjẹ aládùn àti wáìnì fún àwọn èèyàn pàtàkì-pàtàkì tó gbà lálejò, ọba pinnu láti pe Fáṣítì ayaba, obìnrin arẹwà yìí náà sì ń jẹ àsè pẹ̀lú àwọn obìnrin. Àmọ́ Fáṣítì kọ̀ láti wá. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí mú kí ìtìjú bá ọba, inú sì bí i gan-an, nítorí náà ó ní kí àwọn agbani-nímọ̀ràn mú ìmọ̀ràn wá lórí ìyà tó tọ́ sí Fáṣítì. Kí ni àbájáde rẹ̀? Ọba kéde pé kì í ṣe ayaba mọ́. Nítorí náà, àwọn ìránṣẹ́ ọba bẹ̀rẹ̀ sí í lọ káàkiri ilẹ̀ náà láti wá àwọn wúńdíá tó rẹwà, kí ọba lè yan èyí tó máa jẹ́ ayaba tuntun lára wọn.—Ẹ́sítérì 1:1–2:4.
A lè fojú inú wo bí Módékáì á ṣe máa fi tayọ̀tayọ̀ wo Ẹ́sítérì látìgbàdégbà tí inú rẹ̀ á sì máa dùn tí á máa rò ó pé ọmọ mọ̀lẹ́bí òun tí òun ń tọ́jú mà ti di àrímáleèlọ arẹwà bó ṣe ń dàgbà. Bíbélì sọ pé: “Ọ̀dọ́bìnrin náà sì rẹwà ní wíwò, ó sì lẹ́wà ní ìrísí.” (Ẹ́sítérì 2:7) Ẹwà ojú dára lóòótọ́, àmọ́ ó tún yẹ kéèyàn ní ọgbọ́n àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀. Láìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ó lè mú kéèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í gbéra ga tàbí kéèyàn máa hu àwọn ìwà míì tí kò dára, tí gbogbo ẹwà náà á sì já sí asán. (Òwe 11:22) Ṣé òótọ́ ni? Àmọ́, irú ẹni wo ni ẹwà máa sọ Ẹ́sítérì dà, ṣé ẹwà tó ní máa mú kó wúlò ni àbí ó máa sọ ọ́ dìdàkudà? Bí àkókò ṣe ń lọ a máa mọ̀.
Àwọn ìránṣẹ́ ọba kíyè sí Ẹ́sítérì. Wọ́n sì kó o mọ́ àwọn arẹwà obìnrin lákòókò tí wọ́n ń lọ káàkiri ilẹ̀ náà, bí wọ́n ṣe mú un kúrò lọ́dọ̀ Módékáì tó sì di èrò ààfin ọba lódìkejì odò nìyẹn. (Ẹ́sítérì 2:8) Ó dájú pé kò ní rọrùn rárá nígbà tí àwọn méjèèjì fẹ́ fi ara wọn sílẹ̀, nítorí pé ńṣe làwọn méjèèjì dà bíi bàbá àti ọmọ. Kò sí iyè méjì pé Módékáì kò ní fẹ́ kí ọmọbìnrin tí òun gbà ṣọmọ yìí fẹ́ aláìgbàgbọ́, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ pé kó fẹ́ ọba, àmọ́ ọ̀rọ̀ náà kọjá agbára rẹ̀. Ẹ wo bí Ẹ́sítérì á ti ṣe máa fetí sí ìmọ̀ràn tí Módékáì fún un kí wọ́n tó mú un lọ! Bí wọ́n ṣe ń mú un lọ sí Ṣúṣánì ní ààfin, oríṣiríṣi ìbéèrè ni á máa jà gùdù lọ́kàn rẹ̀. Irú ìgbésí ayé wo ni á máa gbé lọ́hùn ún?
Ó Rí “Ojú Rere Ní Ojú Gbogbo Àwọn Tí Ó Bá Rí I”
Ẹ́sítérì bá ara rẹ̀ nínú ìgbésí ayé tó yàtọ̀ pátápátá sí ohun tó mọ̀ tẹ́lẹ̀. Ó wà lára “àwọn ọ̀dọ́bìnrin púpọ̀” tí wọ́n kó jọ káàkiri Ilẹ̀ Ọba Páṣíà. Kò sí iyè méjì pé, àṣà, èdè àti ìwà àwọn ọ̀dọ́bìnrin tí wọ́n kó jọ yìí máa yàtọ̀ síra gan-an ni. Wọ́n kó àwọn ọ̀dọ́bìnrin náà sábẹ́ àbójútó ìránṣẹ́ ọba kan tó ń jẹ́ Hégáì, gbogbo wọn ni wọ́n máa fún ní ìtọ́jú ẹwà ara, ọdún kan ni wọ́n sì máa fi ṣe é, ó kan fífi òróró tó ń ta sánsán wọ́ra fún wọn. (Ẹ́sítérì 2:8, 12) Ibi tí àwọn ọ̀dọ́bìnrin yìí wà àti ìgbésí ayé tó wà níbẹ̀ lè mú kí ọ̀rọ̀ ìrísí ara gbà wọ́n lọ́kàn pátápátá, tí ìyẹn sì lè mú kí wọ́n máa bára wọn díje kí wọ́n sì máa lépa ohun asán. Ipa wo láwọn nǹkan yìí ní lórí Ẹ́sítérì?
Kò sí ẹni tí ọ̀rọ̀ Ẹ́sítérì máa gbà lọ́kàn láyé yìí tó Módékáì. Bíbélì sọ pé, ojoojúmọ́ ló máa ń lọ sí ìtòsí ilé táwọn obìnrin náà wà bó bá ti lè ṣeé ṣe tó, kó bàa lè mọ bí nǹkan ṣe ń lọ sí fún Ẹ́sítérì. (Ẹ́sítérì 2:11) Kò sí àní-àní pé inú rẹ̀ máa dùn bó ṣe máa ń gbọ́ nípa Ẹ́sítérì, bóyá nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ ilé tí wọ́n fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú Ẹ́sítérì àti Módékáì. Kí nìdí tí ọ̀rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀?
Inú Hégáì dùn sí Ẹ́sítérì débi pé, ó ṣe ojú rere tó pọ̀ gan-an sí i, ó fún un ní ìránṣẹ́bìnrin méje àti ibi tó dára gan-an nínú ilé àwọn obìnrin náà. Àkọsílẹ̀ náà tiẹ̀ sọ pé: “Ní gbogbo àkókò yìí, Ẹ́sítérì ń bá a lọ ní jíjèrè ojú rere ní ojú gbogbo àwọn tí ó bá rí i.” (Ẹ́sítérì 2:9, 15) Ǹjẹ́ ẹwà nìkan ló mú káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ Ẹ́sítérì tó báyìí? Rárá, nǹkan tó jù bẹ́ẹ̀ lọ ló fà á.
Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé: “Ẹ́sítérì kò tíì sọ nípa àwọn ènìyàn rẹ̀ tàbí nípa àwọn ìbátan rẹ̀, nítorí Módékáì fúnra rẹ̀ ti gbé àṣẹ kalẹ̀ fún un pé kí ó má sọ.” (Ẹ́sítérì 2:10) Módékáì ti sọ fún ọmọbìnrin yìí pé kò gbọ́dọ̀ sọ fún ẹnikẹ́ni pé Júù ni òun, Módékáì ti rí i pé àwọn aláṣẹ Páṣíà kò fẹ́ràn àwọn èèyàn òun. Àbẹ́ ò rí i pé inú rẹ̀ máa dùn gan-an pé, bí Ẹ́sítérì kò tiẹ̀ sí lọ́dọ̀ òun mọ́, síbẹ̀ ó ṣì jẹ́ ọmọ tó gbọ́n tó sì jẹ́ onígbọràn!
Bákan náà lónìí, àwọn ọmọ lè múnú àwọn òbí àtàwọn alágbàtọ́ wọn dùn. Nígbà tí wọn kò bá tiẹ̀ sí lọ́dọ̀ àwọn òbí wọn pàápàá, kí wọ́n tiẹ̀ máa gbé láàárín àwọn oníwà pálapàla, àwọn tí kò láròjinlẹ̀ tàbí àwọn oníjàgídíjàgan, wọn kò ní kẹ́gbẹ́kẹ́gbẹ́, ohun tí wọ́n mọ̀ pé ó tọ́ ni wọ́n á máa ṣe. Tí wọ́n bá ṣe bí Ẹ́sítérì ti ṣe, wọ́n á tipa bẹ́ẹ̀ máa mú ọkàn Bàbá wọn ọ̀run yọ̀.—Òwe 27:11.
Nígbà tó kan Ẹ́sítérì láti lọ rí ọba, wọ́n fún un láyè láti mú ohunkóhun tó lè nílò, bóyá àwọn nǹkan tó lè lò láti túbọ̀ gbé ẹwà rẹ̀ yọ. Àmọ́ ṣá o, ó tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Hégáì, kò sì béèrè kọjá ohun tí wọ́n fún un. (Ẹ́sítérì 2:15) Ó ṣeé ṣe kó ti mọ̀ pé, èèyàn kò lè torí ẹwà nìkan rí ojú rere ọba, nítorí pé, ìmọ̀wọ̀n ara ẹni àti ìrẹ̀lẹ̀ jẹ́ ohun tó ṣọ̀wọ́n gan-an ní ààfin náà. Ṣé òótọ́ ni èrò rẹ̀?
Àkọsílẹ̀ náà dáhùn pé: “Ọba sì wá nífẹ̀ẹ́ Ẹ́sítérì ju gbogbo àwọn obìnrin yòókù lọ, bẹ́ẹ̀ ni ó sì jèrè ojú rere àti inú-rere-onífẹ̀ẹ́ púpọ̀ sí i níwájú rẹ̀ ju gbogbo àwọn wúńdíá yòókù. Ó sì tẹ̀ síwájú láti fi ìwérí ayaba sí i ní orí, ó sì fi í ṣe ayaba dípò Fáṣítì.” (Ẹ́sítérì 2:17) Ó dájú pé kò ní rọrùn fún ọmọbìnrin Júù tó ní ìrẹ̀lẹ̀ yìí láti mú ara rẹ̀ bá ìyípadà tó dé bá a yìí mu, ìyẹn ni pé ní báyìí òun ni ayaba tuntun, ìyàwó ọba tó lágbára jù lọ láyé ní àkókò yẹn! Ǹjẹ́ Ẹ́sítérì jẹ́ kí èyí kó sí òun lórí kó wá máa gbéra ga?
Rárá o! Ẹ́sítérì ń bá a nìṣó láti jẹ́ onígbọràn sí Módékáì tó gbà á ṣọmọ. Kò sọ fún ẹnikẹ́ni pé òun bá àwọn Júù tan. Síwájú sí i, nígbà tí Módékáì gbọ́ nípa bí àwọn kan ṣe ń gbèrò láti ṣekú pa Ahasuwérúsì, gbàrà tí Módékáì fi ọ̀rọ̀ náà tó Ẹ́sítérì létí, ńṣe ló ṣègbọràn ó sì lọ sọ ewu tí Módékáì rí fún ọba, àṣírí àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà sì tú. (Ẹ́sítérì 2:20-23) Ẹ́sítérì fi hàn pé òun ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, bó ṣe ṣe ìyẹn ni pé, ó ní ọ̀wọ̀, ó sì jẹ́ onígbọràn. Àwọn èèyàn kò ka jíjẹ́ onígbọràn sí nǹkan pàtàkì láyé òde òní, àìgbọràn àti ìṣọ̀tẹ̀ ló gbayé kan. Àmọ́ àwọn èèyàn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ tòótọ́ ka jíjẹ́ onígbọràn sí ohun iyebíye gẹ́gẹ́ bí Ẹ́sítérì ti ṣe.
Ẹ́sítérì Dojú Kọ Àdánwò Ìgbàgbọ́
Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Hámánì di ẹni ńlá láàfin Ahasuwérúsì. Ọba yan Hámánì sí ipò olórí ìjọba, ó fi ṣe olórí agbani-nímọ̀ràn rẹ̀, tí ìyẹn sì wá mú kó wà nípò kejì ní ilẹ̀ ọba náà. Ọba tiẹ̀ tún pàṣẹ pé, gbogbo ẹni tó bá rí olóyè pàtàkì yìí ní láti tẹrí ba fún un. (Ẹ́sítérì 3:1-4) Ìṣòro ni àṣẹ yẹn jẹ́ fún Módékáì. Ó mọ̀ pé ó yẹ kí òun ṣègbọràn sí ọba, àmọ́ kò gbọ́dọ̀ ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run nítorí òfin ọba. Ṣẹ́ ẹ rí i, “ọmọ Ágágì” ni Hámánì. Èyí fi hàn pé ọmọ ìran Ágágì tó jẹ́ ọba Ámálékì tí Sámúẹ́lì wòlíì Ọlọ́run pa ni ọ̀gbẹ́ni yìí. (1 Sámúẹ́lì 15:33) Àwọn ọmọ Ámálékì yìí burú débi pé, wọ́n sọ ara wọn di ọ̀tá Jèhófà àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Èyí sì mú káwọn ọmọ Ámálékì jẹ́ ẹni ìparun lójú Ọlọ́run.b (Diutarónómì 25:19) Báwo ni Júù kan tó jẹ́ olóòótọ́ á ṣe máa tẹrí ba fún olóyè kan tó jẹ́ ọmọ Ámálékì? Módékáì kò ní ṣe bẹ́ẹ̀ láé. Ó dúró lórí ìpinnu rẹ̀ pé òun kò ní tẹrí ba fún un. Títí dòní, àwọn ọkùnrin àtobìnrin tó ní ìgbàgbọ́ kò kọ ohun tí ì bá ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀mí wọn nítorí àtiṣe ohun tí ìlànà Ọlọ́run sọ pé: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.”—Ìṣe 5:29.
Inú bí Hámánì gan-an. Àmọ́ kì í ṣe Módékáì nìkan ló wù ú láti ṣekú pa. Ó tún fẹ́ pa gbogbo àwọn èèyàn Módékáì pẹ̀lú! Hámánì sọ ọ̀rọ̀ àwọn Júù fún ọba láìdáa. Kò dárúkọ wọn, ohun tó sì ń dọ́gbọ́n sọ ni pé, aláìjámọ́ nǹkankan ni wọ́n, pé wọ́n jẹ́ èèyàn “tí a tú ká, tí a sì yà sọ́tọ̀ láàárín àwọn ènìyàn.” Ohun tó burú jù tó sọ nípa wọn ni pé, wọn kì í ṣègbọràn sí àṣẹ ọba, nítorí náà ọlọ̀tẹ̀ paraku ni wọ́n. Ó sọ pé òun máa fún ọba ní owó ńlá láti fi bójú tó pípa àwọn Júù kúrò ní ilẹ̀ ọba náà.c Ahasuwérúsì fún Hámánì ní òǹtẹ̀ ọba pé kó fi lu ohunkóhun tó bá fẹ́ ṣe ní òǹtẹ̀.—Ẹ́sítérì 3:5-10.
Ká tó pajú pẹ́, àwọn tó gun ẹṣin ti ń sáré lọ káàkiri ilẹ̀ ọba náà, wọ́n ti ń jíṣẹ́ fún àwọn èèyàn pé kí wọ́n pa àwọn Júù. Ẹ fojú inú wo bí ọ̀rọ̀ náà ṣe máa rí lára àwọn àṣẹ́kù Júù tó kúrò ní ìgbèkùn Bábílónì nígbà tí wọ́n gbọ́ ní Jerúsálẹ́mù, ìyẹn ibi tí wọ́n ti ń sapá láti ṣàtúnkọ́ ìlú tí kò ní ògiri ààbò. Nígbà tí Módékáì gbọ́ ìròyìn tó ń dẹ́rù báni náà, ó ṣeé ṣe kí ó ronú nípa àwọn àṣẹ́kù yìí àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ títí kan àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ tó wà ní Ṣúṣánì. Ìbànújẹ́ bá a, nítorí náà ó fa aṣọ ara rẹ̀ ya, ó wọ aṣọ àpò ìdọ̀họ, ó kó eérú sórí, ó sì wá ń sunkún láàárín ìlú náà. Àmọ́ ní ti Hámánì, ó jókòó pẹ̀lú ọba, ó ń mú ọtí, ìbànújẹ́ tó dá sílẹ̀ láàárín àwọn Júù àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn tó wà ní Ṣúṣánì kò tiẹ̀ kàn án rárá.—Ẹ́sítérì 3:12–4:1.
Módékáì mọ̀ pé ó yẹ kí òun wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ náà. Àmọ́ kí ló máa ṣe? Ẹ́sítérì gbọ́ nípa ìbànújẹ́ tó bá Módékáì, ó sì fi aṣọ ránṣẹ́ sí i, ó sì tù ú nínú, àmọ́ Módékáì kò gba ìtùnú. Ó ṣeé ṣe kí Módékáì ti máa ṣe kàyéfì tipẹ́ nípa ìdí tí Jèhófà Ọlọ́run òun fi yọ̀ǹda pé kí wọ́n mú Ẹ́sítérì ọmọ òun ọ̀wọ́n kúrò lọ́dọ̀ òun, tí ó sì wá di ayaba fún ọba tó jẹ́ abọ̀rìṣà. Ó jọ pé ìdí tí ọ̀ràn fi rí bẹ́ẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí í yé e wàyí. Módékáì ránṣẹ́ sí Ẹ́sítérì ayaba, ó ní kó bá ọba sọ̀rọ̀ pé kó paná ọ̀rọ̀ náà, pé kí Ẹ́sítérì gbèjà “àwọn ènìyàn rẹ̀.”—Ẹ́sítérì 4:4-8.
Ó dájú pé ẹ̀rù máa ba Ẹ́sítérì gan-an nígbà tó gbọ́ nǹkan tí Módékáì ní kó ṣe. Àdánwò ìgbàgbọ́ tó le jù lọ ló dé bá a yìí. Ohun tó fi dá Módékáì lóhùn fi hàn pé ẹ̀rù bà á gan-an. Ó rán Módékáì létí òfin ọba. Òfin náà ni pé, kí wọ́n pa ẹni tó bá wá síwájú ọba láìjẹ́ pé ọba ní kó wá. Àyàfi bí ọba bá na ọ̀pá aládé wúrà sí ẹni náà ni wọn kò ní pa á. Ǹjẹ́ ìdí kankan wà fún Ẹ́sítérì láti ronú pé ọba máa fi àánú hàn sí òun, àgàgà tá a bá ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Fáṣítì nígbà tó kọ̀ láti lọ sọ́dọ̀ ọba nígbà tí ọba ní kó wá? Ó sọ fún Módékáì pé, ọba kò tíì pe òun láti ọgbọ̀n ọjọ́ sẹ́yìn! Bí ọba kò ṣe pe Ẹ́sítérì yìí mú kí ó máa ní èrò pé bóyá ọba tó máa ń ṣe èyí tó wù ú yìí kò nífẹ̀ẹ́ òun mọ́.d—Ẹ́sítérì 4:9-11.
Módékáì dá Ẹ́sítérì lóhùn lọ́nà tó ṣe ṣàkó kí ó lè fún ìgbàgbọ́ rẹ̀ lókun. Ó sọ fún un pé tí kò bá gbé ìgbésẹ̀ láti ṣèrànwọ́, àwọn Júù á rí ìgbàlà láti ibòmíì. Àmọ́ ǹjẹ́ Ẹ́sítérì á yè bọ́ nígbà tí inúnibíni yìí bá le ju bó ṣe wà yẹn lọ? Módékáì fi hàn níbí yìí pé òun ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Jèhófà, ẹni tí kò ní jẹ́ kí wọ́n pa gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀ run, nítorí tó bá ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, ìyẹn kò ní jẹ́ kí Jèhófà lè mú ìlérí tó ṣe fún wọn ṣẹ. (Jóṣúà 23:14) Nítorí náà, Módékáì bi Ẹ́sítérì pé: “Ta sì ni ó mọ̀ bóyá nítorí irú àkókò yìí ni ìwọ fi dé ipò ọlá ayaba?” (Ẹ́sítérì 4:12-14) Módékáì ní ìgbẹ́kẹ̀lé pátápátá nínú Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀. Ǹjẹ́ àwa náà ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà?—Òwe 3:5, 6.
Ìgbàgbọ́ Tó Lágbára Ju Ìbẹ̀rù Ikú Lọ
Ní báyìí, ó kù sọ́wọ́ Ẹ́sítérì láti pinnu. Ó sọ fún Módékáì pé kí ó kó àwọn Júù jọ, kí wọ́n gbààwẹ̀ pẹ̀lú òun fún ọjọ́ mẹ́ta, lẹ́yìn náà, ó fi gbólóhùn táwọn èèyàn mọ̀ gan-an tó fi ìgbàgbọ́ àti ìgboyà tó ní hàn parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Bí ó bá ṣe pé èmi yóò ṣègbé, èmi yóò ṣègbé.” (Ẹ́sítérì 4:15-17) Ó dájú pé ó máa gbàdúrà gan-an ní ọjọ́ mẹ́ta yìí ju ti ìgbàkigbà rí lọ ní ìgbésí ayé rẹ̀. Àmọ́ níkẹyìn, ọjọ́ tó fẹ́ lọ sọ́dọ̀ ọba pé. Ó wọ aṣọ tó dára jù lọ lára àwọn aṣọ rẹ̀, ó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kí ìrísí rẹ̀ lè wu ọba. Lẹ́yìn náà, ó bọ́ sọ́nà.
Bí a ṣe sọ ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, Ẹ́sítérì forí lé ààfin ọba. A lè fojú inú wo àníyàn tó máa gbà á lọ́kàn, tí á sì máa gbàdúrà kíkankíkan. Ó wọ àgbàlá náà, níbi tó ti lè rí Ahasuwérúsì lórí ìtẹ́ rẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó gbìyànjú láti wo ojú rẹ̀ kó lè mọ ohun tó ń rò. Irun orí ọba wé wálẹ̀, wọ́n gé irùngbọ̀n rẹ̀, ó sì wá yọ igun mẹ́ta. Ńṣe ló dà bíi pé kó ti sọ ọ̀rọ̀ tó bá wá kíákíá. Àmọ́ kò pẹ́ tí ọkọ rẹ̀ fi rí i. Ó dájú pé ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún ọba láti rí i, àmọ́ kò sọ ọ̀rọ̀ tó le. Ó na ọ̀pá aládé wúrà sí i!—Ẹ́sítérì 5:1, 2.
Ọba fetí sí ohun tí Ẹ́sítérì fẹ́ sọ. Bí Ẹ́sítérì ṣè ṣojú fún Ọlọ́run rẹ̀ tó sì gbèjà àwọn èèyàn rẹ̀ nìyẹn, ó sì tipa báyìí fi àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ tó lágbára lélẹ̀ fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run láti ìgbà yẹn wá. Àmọ́ iṣẹ́ tí Ẹ́sítérì fẹ́ ṣe ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni. Báwo ló ṣe máa yí ọba lérò pa dà pé ẹni ibi ni Hámánì tó jẹ́ agbani-nímọ̀ràn tí ọba fẹ́ràn gan-an? Kí ni Ẹ́sítérì máa ṣe láti dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè? A máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí lọ́jọ́ iwájú.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọ̀pọ̀ ló gbà pé Ahasuwérúsì ni Sásítà Kìíní tó ṣàkóso Ilẹ̀ Ọba Páṣíà ní ìbẹ̀rẹ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún karùn-ún ṣáájú Sànmánì Kristẹni.
b Ìgbà ayé Hesekáyà Ọba ni wọ́n pa “àṣẹ́kù” àwọn ọmọ Ámálékì, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Hámánì wà lára àwọn tó ṣẹ́ kù nígbà yẹn.—1 Kíróníkà 4:43.
c Hámánì sọ pé òun á fún ọba ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá [10,000] tálẹ́ńtì fàdákà, lóde òní iye yìí tó ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù owó dọ́là. Tó bá jẹ́ pé Ahasuwérúsì ni Sásítà Kìíní lóòótọ́, owó tí Hámánì sọ yìí ti ní láti fà á lọ́kàn mọ́ra. Nítorí pé Sásítà pàdánù ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ owó nígbà tó bá ilẹ̀ Gíríìsì jà, ó sì ṣeé ṣe kí ìyẹn jẹ́ ṣáájú kó tó fẹ́ Ẹ́sítérì.
d Sásítà Kìíní jẹ́ ẹni tó máa ń ṣe èyí tó wù ú, ó sì tètè máa ń bínú. Òpìtàn ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì tó ń jẹ́ Herodotus ṣàkọsílẹ̀ àwọn àpẹẹrẹ kan látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Sásítà bá ilẹ̀ Gíríìsì jà. Ọba pàṣẹ pé kí wọ́n fi ọkọ̀ ojú omi ṣe afárá lọ sí ibi tí wọ́n ń pè ní Hellespont. Nígbà tí ìjì ba afárá náà jẹ́, Sásítà pàṣẹ pé kí wọ́n lọ bẹ́ orí àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ tó ṣe afárá náà, ó tiẹ̀ tún ní kí àwọn ọkùnrin rẹ̀ “fìyà jẹ” àwọn èèyàn tó ń gbé Hellespont, ìyà náà ni pé kí wọ́n gbọ́n omi tó wà ní àgbègbè náà kúrò, bí wọ́n sì ti ń gbọ́n omi náà lọ́wọ́ kí wọ́n ka ọ̀rọ̀ èébú lé wọ́n lórí. Lákòókò ogun yìí kan náà, nígbà tí ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan lọ bẹ̀bẹ̀ pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí ọmọkùnrin òun dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun, ńṣe ni Sásítà ní kí wọ́n gé ọmọ náà sí méjì kí wọ́n gbé e síta kó lè jẹ́ ìkìlọ̀ fún àwọn míì.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Ohun tó pọ̀ ló mú kí Módékáì máa dunnú nítorí ọmọbìnrin tó gbà ṣọmọ yìí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Ẹ́sítérì mọ̀ pé ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ọgbọ́n ṣe pàtàkì gan-an ju ìrísí ara lọ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22, 23]
Ẹ́sítérì fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wewu kó lè dáàbò bo àwọn èèyàn Ọlọ́run