Àwọn Ọba Kìíní
6 Ní ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé ọgọ́rin (480) ọdún lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ ní ọdún kẹrin lẹ́yìn tí Sólómọ́nì di ọba lórí Ísírẹ́lì, ní oṣù Sífì*+ (ìyẹn, oṣù kejì), ó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ilé Jèhófà.*+ 2 Ilé tí Ọba Sólómọ́nì kọ́ fún Jèhófà jẹ́ ọgọ́ta (60) ìgbọ̀nwọ́* ní gígùn, ogún (20) ìgbọ̀nwọ́ ní fífẹ̀ àti ọgbọ̀n (30) ìgbọ̀nwọ́ ní gíga.+ 3 Ibi àbáwọlé*+ tó wà níwájú tẹ́ńpìlì* náà jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn,* ó sì bá fífẹ̀ ilé náà mu.* Ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ló fi yọ síta lára iwájú ilé náà.
4 Ó ṣe àwọn fèrèsé* tí férémù wọn fẹ̀ lápá kan tó sì kéré lódìkejì*+ sí ilé náà. 5 Ó tún mọ ògiri kan ti ògiri ilé náà; ògiri náà yí àwọn ògiri ilé náà ká, ìyẹn ti tẹ́ńpìlì* àti ti yàrá inú lọ́hùn-ún,+ ó sì ṣe àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ sínú rẹ̀ yí ká.+ 6 Àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ tó wà ní ìsàlẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní fífẹ̀, ti àárín jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà ní fífẹ̀, ti ìkẹta tó sì wà lókè jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méje ní fífẹ̀, nítorí ó gé àwọn ibì kan sínú lára* ilé náà yí ká, kí ohunkóhun má bàa wọnú ògiri ilé náà.+
7 Àwọn òkúta tí wọ́n ti gbẹ́ sílẹ̀+ ni wọ́n fi kọ́ ilé náà, tí a kò fi gbọ́ ìró òòlù, àáké tàbí ohun èlò irin kankan nínú ilé náà nígbà tí wọ́n ń kọ́ ọ lọ́wọ́. 8 Ẹnu ọ̀nà tó wọ yàrá ẹ̀gbẹ́ tó wà ní ìsàlẹ̀ wà lápá gúúsù* ilé náà,+ àtẹ̀gùn tó yí po ni wọ́n ń gbà gòkè lọ sí yàrá àárín àti láti yàrá àárín dé yàrá kẹta tó wà lókè. 9 Ó kọ́ ilé náà títí ó fi parí rẹ̀,+ ó fi igi kédárì ṣe igi àjà àti pákó+ tó fi bo ilé náà. 10 Ó kọ́ àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ yí ilé náà ká,+ gíga ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, àwọn gẹdú igi kédárì ni ó sì fi mú wọn mọ́ ara ilé náà.
11 Ní àkókò yìí, Jèhófà bá Sólómọ́nì sọ̀rọ̀, ó ní: 12 “Ní ti ilé tí ò ń kọ́ yìí, tí o bá rìn nínú àwọn òfin mi, tí o pa àwọn ìdájọ́ mi mọ́, tí o pa gbogbo àṣẹ mi mọ́, tí o sì ń rìn nínú wọn,+ èmi náà á mú ìlérí tí mo ṣe fún Dáfídì bàbá rẹ ṣẹ,+ 13 èmi yóò máa gbé láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ mi ò sì ní fi àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì+ sílẹ̀.”
14 Sólómọ́nì ń bá iṣẹ́ ilé kíkọ́ náà lọ kí ó lè parí rẹ̀. 15 Ó fi àwọn pátákó kédárì bo* àwọn ògiri inú ilé náà. Ó fi àwọn ẹ̀là gẹdú bo ògiri inú, láti ìsàlẹ̀ ilé náà títí dé àwọn igi ìrólé tó wà ní àjà, ó sì fi àwọn pátákó júnípà+ bo ilẹ̀ ilé náà. 16 Ó fi pátákó kédárì ṣe apá kan tí ó jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́ sí ẹ̀yìn ilé náà, láti ìsàlẹ̀ ilé náà títí dé àwọn igi ìrólé, ó sì kọ́ Ibi Mímọ́ Jù Lọ+ sínú rẹ̀,* èyí ni yàrá inú lọ́hùn-ún.+ 17 Ogójì (40) ìgbọ̀nwọ́ sì ni apá tó kù níwájú ilé náà, èyí ni tẹ́ńpìlì.*+ 18 Àwọn akèrègbè+ àti ìtànná òdòdó+ ni wọ́n gbẹ́ sára igi kédárì tí ó wà nínú ilé náà. Gbogbo rẹ̀ jẹ́ igi kédárì; kò sí òkúta kankan tí a rí.
19 Ó ṣètò yàrá inú lọ́hùn-ún+ ilé náà kí ó lè gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà síbẹ̀.+ 20 Gígùn yàrá inú lọ́hùn-ún náà jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́, fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́, gíga rẹ̀ sì jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́;+ ó sì fi ògidì wúrà bò ó; ó fi igi kédárì bo pẹpẹ náà.+ 21 Sólómọ́nì fi ògidì wúrà+ bo inú ilé náà, ó na ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi wúrà ṣe sí iwájú yàrá inú lọ́hùn-ún,+ èyí tí wọ́n fi wúrà bò. 22 Ó fi wúrà bo gbogbo ilé náà títí wọ́n fi parí rẹ̀ látòkèdélẹ̀; ó tún fi wúrà bo gbogbo pẹpẹ+ tí ó wà nítòsí yàrá inú lọ́hùn-ún.
23 Nínú yàrá inú lọ́hùn-ún náà, ó fi igi ahóyaya* ṣe kérúbù méjì+ síbẹ̀, gíga ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá.+ 24 Ìyẹ́ apá kan kérúbù náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, ìyẹ́ apá kejì sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún. Ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ni ó jẹ́ láti ṣóńṣó orí ìyẹ́ apá kan dé ṣóńṣó orí ìyẹ́ apá kejì. 25 Kérúbù kejì náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá. Àwọn kérúbù méjèèjì rí bákan náà, wọn ò sì tóbi ju ara wọn. 26 Gíga kérúbù àkọ́kọ́ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá bíi ti kérúbù kejì. 27 Lẹ́yìn náà, ó gbé àwọn kérúbù náà+ sínú yàrá inú lọ́hùn-ún.* Ìyẹ́ apá àwọn kérúbù náà nà jáde tí ó fi jẹ́ pé ìyẹ́ apá kérúbù àkọ́kọ́ kan ògiri kìíní, ìyẹ́ apá kérúbù kejì sì kan ògiri kejì, ìyẹ́ apá àwọn méjèèjì wá kanra ní àárín ilé náà. 28 Ó sì fi wúrà bo àwọn kérúbù náà.
29 Ó gbẹ́ àwòrán àwọn kérúbù,+ igi ọ̀pẹ+ àti ìtànná òdòdó+ sára gbogbo ògiri yàrá méjèèjì* tó wà nínú ilé náà yí ká. 30 Ó fi wúrà bo ilẹ̀ yàrá méjèèjì tó wà nínú ilé náà. 31 Ó fi igi ahóyaya ṣe ilẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà yàrá inú lọ́hùn-ún, ó tún fi ṣe àwọn òpó ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ àti àwọn òpó ilẹ̀kùn, ó jẹ́ ìdá márùn-ún* ògiri náà. 32 Igi ahóyaya ni wọ́n fi ṣe àwọn ilẹ̀kùn méjèèjì, ó gbẹ́ àwọn kérúbù, igi ọ̀pẹ àti ìtànná òdòdó sára wọn, ó sì fi wúrà bò wọ́n; ó fi òòlù tẹ wúrà náà mọ́ àwọn kérúbù àti àwọn igi ọ̀pẹ náà lára. 33 Bẹ́ẹ̀ náà ni ó ṣe fi igi ahóyaya ṣe férémù ilẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà tẹ́ńpìlì,* igun rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sì dọ́gba.* 34 Ó fi igi júnípà ṣe ilẹ̀kùn méjì. Ilẹ̀kùn àkọ́kọ́ ní awẹ́ méjì tó ṣeé pa dé, ilẹ̀kùn kejì sì ní awẹ́ méjì tó ṣeé pa dé.+ 35 Ó gbẹ́ àwọn kérúbù, igi ọ̀pẹ àti ìtànná òdòdó, ó sì fi wúrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ bo gbogbo wọn.
36 Ó fi òkúta gbígbẹ́ kọ́ ipele mẹ́ta ògiri àgbàlá inú,+ lẹ́yìn náà wọ́n gbé ipele kan ìtì igi kédárì+ lé e.
37 Ní ọdún kẹrin, oṣù Sífì,* wọ́n fi ìpìlẹ̀ ilé Jèhófà lélẹ̀;+ 38 ní ọdún kọkànlá, oṣù Búlì* (ìyẹn, oṣù kẹjọ), wọ́n parí gbogbo iṣẹ́ ilé náà bó ṣe wà nínú àwòrán ilé kíkọ́ rẹ̀.+ Torí náà, ọdún méje ni ó fi kọ́ ọ.