Hábákúkù
1 Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run sọ fún wòlíì Hábákúkù* nínú ìran pé kó kéde nìyí:
2 Jèhófà, báwo ló ṣe máa pẹ́ tó tí màá fi ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́ àmọ́ tí o kò gbọ́?+
Báwo ló ṣe máa pẹ́ tó tí màá fi ké pè ọ́ pé kí o gbà mí lọ́wọ́ ìwà ipá àmọ́ tí o kò dá sí i?*+
3 Kí nìdí tí o fi ń jẹ́ kí ohun búburú ṣẹlẹ̀ níṣojú mi?
Kí sì nìdí tí o fi fàyè gba ìnilára?
Kí nìdí tí ìparun àti ìwà ipá fi ń ṣẹlẹ̀ níṣojú mi?
Kí sì nìdí tí ìjà àti aáwọ̀ fi wà káàkiri?
4 Òfin kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ mọ́,
Kò sì sí ìdájọ́ òdodo rárá.
Torí àwọn ẹni ibi yí olódodo ká;
Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń yí ìdájọ́ po.+
5 “Ẹ wo àwọn orílẹ̀-èdè kí ẹ sì kíyè sí i!
Kí ẹnu yà yín bí ẹ ṣe ń wò wọ́n, kí ó sì jọ yín lójú;
Torí ohun kan máa ṣẹlẹ̀ lásìkò yín,
Tí ẹ ò ní gbà gbọ́ tí wọ́n bá tiẹ̀ sọ ọ́ fún yín.+
Wọ́n yára bolẹ̀ káàkiri ayé
Láti gba àwọn ilé tí kì í ṣe tiwọn.+
7 Wọ́n ń dẹ́rù bani, wọ́n sì ń kóni láyà jẹ.
Wọ́n ń gbé ìdájọ́ àti àṣẹ* tiwọn kalẹ̀.+
Àwọn ẹṣin ogun wọn ń bẹ́ gìjàgìjà;
Ọ̀nà jíjìn làwọn ẹṣin wọn ti wá.
Wọ́n já ṣòòrò wálẹ̀ bí ẹyẹ idì tó fẹ́ yára gbé oúnjẹ.+
9 Torí wọ́n fẹ́ hùwà ipá ni wọ́n ṣe wá.+
Gbogbo wọn kọjú síbì kan náà bí afẹ́fẹ́ tó ń fẹ́ bọ̀ láti ìlà oòrùn,+
Wọ́n sì ń kó àwọn èèyàn lẹ́rú bí ẹni ń kó iyanrìn.
Wọ́n ń fi gbogbo ibi olódi rẹ́rìn-ín;+
Wọ́n fi iyẹ̀pẹ̀ mọ òkìtì, wọ́n sì gbà á.
12 Jèhófà, ṣebí láti ayérayé ni ìwọ ti wà?+
Ọlọ́run mi, Ẹni Mímọ́ mi, ìwọ kì í kú.*+
Kí ló wá dé tí o fi fàyè gba àwọn ọ̀dàlẹ̀,+
Tí o sì dákẹ́ títí ẹni burúkú fi gbé ẹni tó jẹ́ olódodo jù ú lọ mì?+
14 Kí nìdí tí o fi jẹ́ kí àwọn èèyàn dà bí ẹja inú òkun,
Bí àwọn ohun tó ń rákò, tí wọn ò ní olórí?
15 Ó* fi ìwọ̀ kó gbogbo wọn sókè.
Ó fi àwọ̀n rẹ̀ kó wọn,
Ó sì fi àwọ̀n ìpẹja rẹ̀ kó wọn jọ.
Ìdí nìyẹn tí inú rẹ̀ fi ń dùn ṣìnkìn.+
16 Ìdí nìyẹn tó fi ń rúbọ sí àwọ̀n rẹ̀,
Tó sì ń rú ẹbọ* sí àwọ̀n ìpẹja rẹ̀;
Torí wọ́n ń mú kí nǹkan ṣẹnuure fún un,*
Oúnjẹ tó dára jù ló sì ń jẹ.
17 Ṣé gbogbo ìgbà ni yóò máa kó nǹkan jáde nínú àwọ̀n rẹ̀ ni?*
Ṣé bí á ṣe máa pa àwọn orílẹ̀-èdè lọ láì ṣàánú wọn nìyí?+