Àkọsílẹ̀ Mátíù
8 Lẹ́yìn tó sọ̀ kalẹ̀ látorí òkè náà, èrò rẹpẹtẹ rọ́ tẹ̀ lé e. 2 Wò ó! adẹ́tẹ̀ kan wá, ó sì forí balẹ̀* fún un, ó sọ pé: “Olúwa, tí o bá ṣáà ti fẹ́, o lè jẹ́ kí n mọ́.”+ 3 Torí náà, ó na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fọwọ́ kàn án, ó ní: “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀! Kí o mọ́.”+ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, a wẹ ẹ̀tẹ̀ rẹ̀ mọ́.+ 4 Jésù wá sọ fún un pé: “Rí i pé o ò sọ fún ẹnì kankan,+ àmọ́ lọ, kí o fi ara rẹ han àlùfáà,+ kí o sì mú ẹ̀bùn tí Mósè sọ lọ,+ kó lè jẹ́ ẹ̀rí fún wọn.”
5 Nígbà tó wọ Kápánáúmù, ọ̀gágun kan wá bá a, ó ń bẹ̀ ẹ́,+ 6 ó sì ń sọ pé: “Ọ̀gá, àrùn rọpárọsẹ̀ dá ìránṣẹ́ mi dùbúlẹ̀ sínú ilé, ìyà sì ń jẹ ẹ́ gidigidi.” 7 Ó sọ fún un pé: “Tí mo bá débẹ̀, màá wò ó sàn.” 8 Ọ̀gágun náà fèsì pé: “Ọ̀gá, mi ò yẹ lẹ́ni tí o lè wá sábẹ́ òrùlé rẹ̀, àmọ́ ṣáà ti sọ̀rọ̀, ara ìránṣẹ́ mi á sì yá. 9 Torí èmi náà wà lábẹ́ àṣẹ, mo sì ní àwọn ọmọ ogun tó wà lábẹ́ àṣẹ mi, tí mo bá sọ fún eléyìí pé, ‘Lọ!’ á lọ, tí mo bá sọ fún ẹlòmíì pé, ‘Wá!’ á wá, tí mo bá sì sọ fún ẹrú mi pé, ‘Ṣe báyìí!’ á ṣe é.” 10 Nígbà tí Jésù gbọ́ ohun tó sọ, ó yà á lẹ́nu, ó sì sọ fún àwọn tó ń tẹ̀ lé e pé: “Kí n sọ òótọ́ fún yín, mi ò tíì rí ẹnì kankan ní Ísírẹ́lì tó ní ìgbàgbọ́ tó lágbára tó báyìí.+ 11 Àmọ́ mo sọ fún yín pé ọ̀pọ̀ èèyàn láti ìlà oòrùn àti ìwọ̀ oòrùn máa wá, wọ́n á sì jókòó* sídìí tábìlì pẹ̀lú Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù nínú Ìjọba ọ̀run;+ 12 àmọ́ a máa ju àwọn ọmọ Ìjọba náà sínú òkùnkùn níta. Ibẹ̀ ni wọ́n á ti máa sunkún, tí wọ́n á sì ti máa payín keke.”+ 13 Jésù wá sọ fún ọ̀gágun náà pé: “Máa lọ. Bí o ṣe fi hàn pé o nígbàgbọ́, kó rí bẹ́ẹ̀ fún ọ.”+ Ara ìránṣẹ́ náà sì yá ní wákàtí yẹn.+
14 Nígbà tí Jésù wọ ilé Pétérù, ó rí ìyá ìyàwó rẹ̀+ tí àìsàn ibà dá dùbúlẹ̀.+ 15 Ó sì fọwọ́ kan ọwọ́ obìnrin náà,+ ibà náà sì lọ, obìnrin náà wá dìde, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìránṣẹ́ fún un. 16 Àmọ́ nígbà tó di ìrọ̀lẹ́, àwọn èèyàn mú ọ̀pọ̀ àwọn tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu wá sọ́dọ̀ rẹ̀; ọ̀rọ̀ ló fi lé àwọn ẹ̀mí náà jáde, ó sì wo gbogbo àwọn tó ń jìyà sàn, 17 kí ohun tí a sọ nípasẹ̀ wòlíì Àìsáyà lè ṣẹ, pé: “Òun fúnra rẹ̀ ru àwọn àìsàn wa, ó sì gbé àwọn àrùn wa.”+
18 Nígbà tí Jésù rí èrò tó yí i ká, ó pàṣẹ pé kí wọ́n kúrò lọ sí òdìkejì.+ 19 Akọ̀wé òfin kan wá bá a, ó sì sọ fún un pé: “Olùkọ́, màá tẹ̀ lé ọ lọ ibikíbi tí o bá lọ.”+ 20 Àmọ́ Jésù sọ fún un pé: “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ní ìtẹ́, àmọ́ Ọmọ èèyàn kò ní ibì kankan tó máa gbé orí rẹ̀ lé.”+ 21 Ẹlòmíì nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn wá sọ fún un pé: “Olúwa, gbà mí láyè kí n kọ́kọ́ lọ sìnkú bàbá mi.”+ 22 Jésù sọ fún un pé: “Máa tẹ̀ lé mi, jẹ́ kí àwọn òkú máa sin òkú wọn.”+
23 Nígbà tó wọ ọkọ̀ ojú omi, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tẹ̀ lé e.+ 24 Wò ó! ìjì líle bẹ̀rẹ̀ sí í jà lórí òkun, débi pé ìgbì òkun ń bo ọkọ̀ náà; àmọ́ ó ń sùn.+ 25 Ni wọ́n bá wá jí i, wọ́n sọ pé: “Olúwa, gbà wá, a ti fẹ́ ṣègbé!” 26 Ṣùgbọ́n ó sọ fún wọn pé: “Kí ló dé tí ẹ̀rù ń bà yín* tó báyìí, ẹ̀yin tí ìgbàgbọ́ yín kéré?”+ Ó wá dìde, ó sì bá ìjì àti òkun wí, ni gbogbo ẹ̀ bá pa rọ́rọ́.+ 27 Ẹnu ya àwọn ọkùnrin náà, wọ́n sì sọ pé: “Irú èèyàn wo nìyí? Ìjì àti òkun pàápàá ń gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu.”
28 Nígbà tó dé òdìkejì, ní agbègbè àwọn ará Gádárà, àwọn ọkùnrin méjì tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu, tí wọ́n ń jáde bọ̀ láti àárín àwọn ibojì* pàdé rẹ̀.+ Wọ́n burú gan-an débi pé kò sẹ́ni tó láyà láti gba ọ̀nà yẹn kọjá. 29 Wò ó! wọ́n kígbe pé: “Kí ló pa wá pọ̀, Ọmọ Ọlọ́run?+ Ṣé o wá síbí láti fìyà jẹ wá+ kí àkókò tó tó ni?”+ 30 Ọ̀wọ́ àwọn ẹlẹ́dẹ̀ tó pọ̀ ń jẹun+ níbì kan tó jìnnà sọ́dọ̀ wọn. 31 Àwọn ẹ̀mí èṣù náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ̀ ẹ́ pé: “Tí o bá lé wa jáde, jẹ́ ká wọnú ọ̀wọ́ àwọn ẹlẹ́dẹ̀ yẹn.”+ 32 Ó wá sọ fún wọn pé: “Ẹ lọ!” Ni wọ́n bá jáde, wọ́n sì wọnú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ náà, wò ó! gbogbo ọ̀wọ́ ẹran náà rọ́ kọjá ní etí òkè* sínú òkun, wọ́n sì kú sínú omi. 33 Àwọn darandaran bá sá lọ, nígbà tí wọ́n dé inú ìlú, wọ́n ròyìn gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀, títí kan ọ̀rọ̀ àwọn ọkùnrin tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu náà. 34 Wò ó! gbogbo ìlú jáde wá pàdé Jésù, nígbà tí wọ́n sì rí i, wọ́n rọ̀ ọ́ pé kó kúrò ní agbègbè wọn.+