ORÍ 36
Ọ̀gágun Kan Fi Hàn Pé Òun Nígbàgbọ́ Tó Lágbára
JÉSÙ WO ẸRÚ Ọ̀GÁGUN KAN SÀN
ỌLỌ́RUN MÁA BÙ KÚN ÀWỌN TÓ BÁ NÍGBÀGBỌ́
Lẹ́yìn tí Jésù parí Ìwàásù orí Òkè, ó lọ sí Kápánáúmù. Nígbà tó dé ibẹ̀, àwọn àgbààgbà Júù kan wá bá a. Ọ̀gágun Róòmù kan tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì ló rán wọn sí Jésù.
Ẹrú ọ̀gágun náà tó fẹ́ràn gan-an ló ń ṣàìsàn tó le, ó sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀gágun náà kì í ṣe Júù, ó fẹ́ kí Jésù ran òun lọ́wọ́. Àwọn Júù tó wá bá Jésù sọ fún un pé ẹrú náà “dùbúlẹ̀ sínú ilé, ìyà sì ń jẹ ẹ́ gidigidi,” èyí fi hàn pé ó ṣeé ṣe kó máa jẹ̀rora gan-an. (Mátíù 8:6) Wọ́n wá sọ fún Jésù pé ó yẹ kó ran ọkùnrin náà lọ́wọ́, wọ́n ní: “Ó nífẹ̀ẹ́ orílẹ̀-èdè wa, òun ló sì kọ́ sínágọ́gù wa.”—Lúùkù 7:4, 5.
Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn ni Jésù tẹ̀ lé àwọ́n àgbààgbà yìí lọ sílé ọ̀gágun náà. Nígbà tó kù díẹ̀ kí wọ́n dé ilé yẹn, ọ̀gágun náà ní káwọn ọ̀rẹ́ òun sọ fún Jésù pé: “Ọ̀gá, má ṣèyọnu, torí mi ò yẹ lẹ́ni tí o lè wá sábẹ́ òrùlé rẹ̀. Ìdí nìyẹn tí mi ò fi ka ara mi sí ẹni tó yẹ láti wá sọ́dọ̀ rẹ.” (Lúùkù 7:6, 7) Ẹ ò rí i pé ọkùnrin náà lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ gan-an, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó wà nípò àṣẹ! Ìwà ọkùnrin náà yàtọ̀ pátápátá sí tàwọn ará Róòmù tó máa ń hùwà ìkà sáwọn ẹrú wọn.—Mátíù 8:9.
Ó dájú pé ọ̀gágun náà mọ̀ pé àwọn Júù kì í da nǹkan pọ̀ pẹ̀lú àwọn tí kì í ṣe Júù. (Ìṣe 10:28) Torí náà, ó ní káwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lọ sọ fún Jésù pé: “Sọ̀rọ̀, kí o sì jẹ́ kí ara ìránṣẹ́ mi yá.”—Lúùkù 7:7.
Ohun tí ọkùnrin náà sọ ya Jésù lẹ́nu gan-an, Jésù wá sọ pé: “Mò ń sọ fún yín pé, mi ò tíì rí ẹnì kankan ní Ísírẹ́lì pàápàá tó ní ìgbàgbọ́ tó lágbára tó báyìí.” (Lúùkù 7:9) Nígbà táwọn ọ̀rẹ́ ọ̀gágun náà fi máa délé, wọ́n rí i pé ara ẹrú tó ń ṣàìsàn náà ti yá.
Lẹ́yìn tí Jésù wo ẹrú náà sàn, ó lo àǹfààní yẹn láti jẹ́ káwọn tó wà níbẹ̀ mọ̀ pé tí àwọn tí kì í ṣe Júù bá nígbàgbọ́, wọ́n máa rí ìbùkún Ọlọ́run. Ó sọ pé: “Ọ̀pọ̀ èèyàn láti ìlà oòrùn àti ìwọ̀ oòrùn máa wá, wọ́n á sì jókòó sídìí tábìlì pẹ̀lú Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù nínú Ìjọba ọ̀run.” Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ sáwọn Júù tí kò nígbàgbọ́? Jésù sọ pé wọ́n máa jù wọ́n “sínú òkùnkùn níta. Ibẹ̀ ni wọ́n á ti máa sunkún, tí wọ́n á sì ti máa payín keke.”—Mátíù 8:11, 12.
Èyí fi hàn pé Ọlọ́run máa kọ àwọn Júù tí kò tẹ́wọ́ gba àǹfààní tó fún wọn láti wà lára àwọn tó máa bá Kristi jọba. Ó sì máa gba àwọn tí kì í ṣe Júù wọlé bíi pé wọ́n jókòó sídìí tábìlì rẹ̀ “nínú Ìjọba ọ̀run.”