Ẹ́kísódù
8 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Wọlé lọ bá Fáráò, kí o sọ fún un pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Jẹ́ kí àwọn èèyàn mi máa lọ kí wọ́n lè lọ sìn mí.+ 2 Tí o bá kọ̀ jálẹ̀, tí o ò jẹ́ kí wọ́n lọ, màá mú kí àkèré bo gbogbo ilẹ̀ rẹ.+ 3 Àkèré yóò kún inú odò Náílì, wọ́n á jáde wá látinú odò, wọ́n á sì wọnú ilé rẹ àti yàrá rẹ, wọ́n á gun ibùsùn rẹ, wọ́n á wọ ilé àwọn ìránṣẹ́ rẹ, wọ́n á bo àwọn èèyàn rẹ, wọ́n á wọnú àwọn ààrò rẹ àti àwọn ọpọ́n* tí o fi ń po nǹkan.+ 4 Àkèré yóò bo ìwọ, àwọn èèyàn rẹ àti gbogbo ìránṣẹ́ rẹ.”’”
5 Lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Sọ fún Áárónì pé, ‘Na ọ̀pá ọwọ́ rẹ sórí àwọn odò, àwọn ipa odò Náílì àti àwọn irà, kí o sì mú kí àkèré bo ilẹ̀ Íjíbítì.’” 6 Áárónì wá na ọwọ́ rẹ̀ sórí àwọn omi Íjíbítì, àwọn àkèré sì bẹ̀rẹ̀ sí í jáde, wọ́n sì bo ilẹ̀ Íjíbítì. 7 Àmọ́ àwọn àlùfáà onídán fi agbára òkùnkùn wọn ṣe ohun kan náà, àwọn náà mú kí àkèré jáde sórí ilẹ̀ Íjíbítì.+ 8 Fáráò wá pe Mósè àti Áárónì, ó sì sọ pé: “Ẹ bẹ Jèhófà pé kó mú àwọn àkèré náà kúrò lọ́dọ̀ èmi àti àwọn èèyàn mi,+ torí mo fẹ́ yọ̀ǹda àwọn èèyàn náà kí wọ́n máa lọ kí wọ́n lè rúbọ sí Jèhófà.” 9 Mósè sọ fún Fáráò pé: “Mo fún ọ láǹfààní láti sọ ìgbà tí o fẹ́ kí n bẹ̀bẹ̀ pé kí àwọn àkèré náà kúrò lọ́dọ̀ rẹ, ọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn èèyàn rẹ àti nínú àwọn ilé rẹ. Inú odò Náílì nìkan ni wọ́n á ṣẹ́ kù sí.” 10 Ó fèsì pé: “Ní ọ̀la.” Ó wá sọ pé: “Bí o ṣe sọ ló máa rí, kí o lè mọ̀ pé kò sẹ́ni tó dà bíi Jèhófà Ọlọ́run wa.+ 11 Àwọn àkèré náà máa kúrò lọ́dọ̀ rẹ, nínú àwọn ilé rẹ, lọ́dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ àti àwọn èèyàn rẹ. Inú odò Náílì nìkan ni wọ́n á ṣẹ́ kù sí.”+
12 Mósè àti Áárónì wá kúrò lọ́dọ̀ Fáráò, Mósè sì bẹ Jèhófà nítorí àwọn àkèré tó mú kó bo Fáráò.+ 13 Jèhófà sì ṣe ohun tí Mósè béèrè. Àwọn àkèré tó wà nínú ilé, nínú àwọn àgbàlá àti nínú oko sì bẹ̀rẹ̀ sí í kú. 14 Wọ́n wá ń kó wọn jọ pelemọ, òkìtì wọn ò sì lóǹkà, ilẹ̀ náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í rùn. 15 Nígbà tí Fáráò rí i pé ìtura dé, ó tún mú ọkàn rẹ̀ le,+ kò sì fetí sí wọn bí Jèhófà ṣe sọ.
16 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Sọ fún Áárónì pé, ‘Na ọ̀pá rẹ, kí o lu erùpẹ̀, yóò sì di kòkòrò abìyẹ́ tó ń mùjẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì.’” 17 Wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀. Áárónì na ọ̀pá ọwọ́ rẹ̀ jáde, ó sì fi lu erùpẹ̀, àwọn kòkòrò náà wá bo èèyàn àti ẹranko. Gbogbo erùpẹ̀ di kòkòrò abìyẹ́ tó ń mùjẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì.+ 18 Àwọn àlùfáà onídán náà gbìyànjú láti ṣe ohun kan náà, wọ́n fẹ́ fi agbára òkùnkùn wọn mú kòkòrò jáde,+ àmọ́ wọn ò rí i ṣe. Àwọn kòkòrò náà bo èèyàn àti ẹranko. 19 Torí náà, àwọn àlùfáà onídán sọ fún Fáráò pé: “Ìka Ọlọ́run nìyí!”+ Àmọ́ ọkàn Fáráò ṣì le, kò sì fetí sí wọn bí Jèhófà ṣe sọ.
20 Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Dìde ní àárọ̀ kùtù, kí o lọ dúró de Fáráò. Wò ó! Ó ń jáde bọ̀ wá sí odò! Kí o sọ fún un pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Jẹ́ kí àwọn èèyàn mi máa lọ kí wọ́n lè lọ sìn mí. 21 Àmọ́ tí o ò bá jẹ́ kí àwọn èèyàn mi lọ, màá mú kí eṣinṣin mùjẹ̀mùjẹ̀ bo ìwọ, àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn èèyàn rẹ, wọ́n á sì wọnú àwọn ilé rẹ; eṣinṣin mùjẹ̀mùjẹ̀ yóò kún àwọn ilé Íjíbítì, wọ́n á sì bo ilẹ̀ tí wọ́n* dúró sí. 22 Ní ọjọ́ yẹn, ó dájú pé màá ya ilẹ̀ Góṣénì sọ́tọ̀, níbi tí àwọn èèyàn mi ń gbé. Eṣinṣin mùjẹ̀mùjẹ̀ kankan ò ní sí níbẹ̀;+ èyí á sì jẹ́ kí o mọ̀ pé èmi Jèhófà wà ní ilẹ̀ yìí.+ 23 Màá fi ìyàtọ̀ sáàárín àwọn èèyàn mi àti àwọn èèyàn rẹ. Iṣẹ́ àmì yìí máa ṣẹlẹ̀ lọ́la.”’”
24 Jèhófà sì ṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ eṣinṣin mùjẹ̀mùjẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ya bo ilé Fáráò àti ilé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì.+ Àwọn eṣinṣin náà run ilẹ̀ náà.+ 25 Níkẹyìn, Fáráò pe Mósè àti Áárónì, ó sì sọ pé: “Ẹ lọ, kí ẹ rúbọ sí Ọlọ́run yín ní ilẹ̀ yìí.” 26 Àmọ́ Mósè sọ pé: “Kò tọ́ ká ṣe bẹ́ẹ̀, torí àwọn ará Íjíbítì máa kórìíra ohun tí a fẹ́ fi rúbọ sí Jèhófà Ọlọ́run wa.+ Tí a bá fi ohun tí àwọn ará Íjíbítì kórìíra rúbọ níṣojú wọn, ṣé wọn ò ní sọ wá lókùúta? 27 A máa rin ìrìn àjò ọjọ́ mẹ́ta lọ sí aginjù, ibẹ̀ la sì ti máa rúbọ sí Jèhófà Ọlọ́run wa bó ṣe ní ká ṣe gẹ́lẹ́.”+
28 Ni Fáráò bá sọ pé: “Màá jẹ́ kí ẹ lọ rúbọ sí Jèhófà Ọlọ́run yín nínú aginjù. Àmọ́, ẹ má lọ jìnnà o. Ẹ bá mi bẹ̀ ẹ́.”+ 29 Mósè wá sọ pé: “Màá kúrò lọ́dọ̀ rẹ báyìí, màá bá ọ bẹ Jèhófà, àwọn eṣinṣin mùjẹ̀mùjẹ̀ náà yóò sì kúrò lọ́dọ̀ Fáráò, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́la. Àmọ́ kí Fáráò má ṣe tún tàn wá* mọ́, kó má sọ pé òun ò ní gbà kí àwọn èèyàn náà lọ rúbọ sí Jèhófà.”+ 30 Mósè wá kúrò lọ́dọ̀ Fáráò, ó sì bẹ Jèhófà.+ 31 Jèhófà ṣe ohun tí Mósè sọ, àwọn eṣinṣin mùjẹ̀mùjẹ̀ náà sì kúrò lọ́dọ̀ Fáráò, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti àwọn èèyàn rẹ̀ láìku ẹyọ kan. 32 Àmọ́ Fáráò tún mú kí ọkàn rẹ̀ le, kò sì jẹ́ kí àwọn èèyàn náà lọ.