Jóṣúà
5 Gbàrà tí gbogbo ọba àwọn Ámórì,+ tí wọ́n wà lápá ìwọ̀ oòrùn* Jọ́dánì àti gbogbo ọba àwọn ọmọ Kénáánì,+ tí wọ́n wà létí òkun gbọ́ pé Jèhófà ti mú kí omi Jọ́dánì gbẹ níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì títí wọ́n fi sọdá, ọkàn wọn domi,*+ kò sì sí ẹni tó ní ìgboyà mọ́* torí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+
2 Ìgbà yẹn ni Jèhófà sọ fún Jóṣúà pé: “Fi akọ òkúta ṣe àwọn ọ̀bẹ fún ara rẹ, kí o sì tún dádọ̀dọ́*+ àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì lẹ́ẹ̀kejì.” 3 Jóṣúà wá fi akọ òkúta ṣe àwọn ọ̀bẹ, ó sì dádọ̀dọ́ àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì ní Gibeati-háárálótì.*+ 4 Ìdí tí Jóṣúà fi dádọ̀dọ́ wọn ni pé: Gbogbo ọkùnrin tó wà nínú àwọn èèyàn náà, tí wọ́n kúrò ní Íjíbítì, gbogbo ọkùnrin ogun,* ti kú sínú aginjù lẹ́nu ìrìn àjò wọn lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní Íjíbítì.+ 5 Gbogbo àwọn tó kúrò ní Íjíbítì ló dádọ̀dọ́, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn tí wọ́n bí ní aginjù lẹ́nu ìrìn àjò wọn lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní Íjíbítì kò tíì dádọ̀dọ́. 6 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti fi ogójì (40) ọdún+ rìn ní aginjù, títí gbogbo orílẹ̀-èdè náà fi kú, ìyẹn àwọn ọkùnrin ogun tó kúrò ní Íjíbítì, tí wọn ò fetí sí ohùn Jèhófà.+ Jèhófà búra fún wọn pé òun kò ní jẹ́ kí wọ́n rí ilẹ̀+ tí Jèhófà búra fún àwọn baba ńlá wọn pé òun máa fún wa,+ ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn.+ 7 Ó fi àwọn ọmọ wọn rọ́pò wọn.+ Àwọn yìí ni Jóṣúà dádọ̀dọ́ wọn; aláìdádọ̀dọ́ ni wọ́n torí pé wọn ò tíì dádọ̀dọ́ lẹ́nu ìrìn àjò wọn.
8 Nígbà tí wọ́n dádọ̀dọ́ gbogbo orílẹ̀-èdè náà tán, wọ́n dúró síbi tí wọ́n pàgọ́ sí títí ara wọn fi jinná.
9 Jèhófà wá sọ fún Jóṣúà pé: “Mo yí ẹ̀gàn Íjíbítì kúrò lórí yín lónìí.” Wọ́n wá ń pe ibẹ̀ ní Gílígálì*+ títí di òní yìí.
10 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣì dúró sí Gílígálì tí wọ́n pàgọ́ sí, wọ́n ṣe Ìrékọjá ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹrìnlá oṣù,+ ní aṣálẹ̀ tó tẹ́jú ní Jẹ́ríkò. 11 Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ èso ilẹ̀ náà ní ọjọ́ tó tẹ̀ lé Ìrékọjá, wọ́n jẹ búrẹ́dì aláìwú+ àti àyangbẹ ọkà lọ́jọ́ yẹn kan náà. 12 Mánà ò rọ̀ fún wọn ní ọjọ́ tó tẹ̀ lé ọjọ́ tí wọ́n jẹ lára èso ilẹ̀ náà; àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò rí mánà kó mọ́,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ èso ilẹ̀ Kénáánì ní ọdún yẹn.+
13 Nígbà tí Jóṣúà wà nítòsí Jẹ́ríkò, ó gbójú sókè, ó sì rí ọkùnrin kan+ tó dúró níwájú rẹ̀, tó fa idà yọ.+ Jóṣúà lọ bá a, ó sì bi í pé: “Ṣé tiwa lò ń ṣe ni, àbí tàwọn ọ̀tá wa?” 14 Ó fèsì pé: “Rárá o, mo wá gẹ́gẹ́ bí olórí* àwọn ọmọ ogun Jèhófà.”+ Ni Jóṣúà bá dojú bolẹ̀, ó sì wólẹ̀, ó sọ fún un pé: “Kí ni olúwa mi fẹ́ sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀?” 15 Olórí àwọn ọmọ ogun Jèhófà wá sọ fún Jóṣúà pé: “Bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ, torí ilẹ̀ mímọ́ ni ibi tí o dúró sí.” Jóṣúà sì ṣe bẹ́ẹ̀ lójú ẹsẹ̀.+