Jóṣúà
4 Gbàrà tí gbogbo orílẹ̀-èdè náà sọdá Jọ́dánì tán, Jèhófà sọ fún Jóṣúà pé: 2 “Mú ọkùnrin méjìlá (12) láàárín àwọn èèyàn náà, ọkùnrin kan látinú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan,+ 3 kí o sì pàṣẹ fún wọn pé: ‘Ẹ gbé òkúta méjìlá (12) ní àárín Jọ́dánì, níbi tí ẹsẹ̀ àwọn àlùfáà tó dúró sójú kan wà,+ kí ẹ gbé àwọn òkúta náà dání, kí ẹ sì tò wọ́n síbi tí ẹ máa sùn mọ́jú.’”+
4 Jóṣúà wá pe ọkùnrin méjìlá (12) tó yàn látinú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ọkùnrin kan látinú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, 5 Jóṣúà sì sọ fún wọn pé: “Ẹ kọjá síwájú Àpótí Jèhófà Ọlọ́run yín, sí àárín Jọ́dánì, kí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín sì gbé òkúta kan sí èjìká rẹ̀, kó jẹ́ iye ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, 6 kí èyí jẹ́ àmì fún yín. Tí àwọn ọmọ* yín bá bi yín lọ́jọ́ iwájú pé, ‘Kí ni ẹ̀ ń fi àwọn òkúta yìí ṣe?’+ 7 kí ẹ sọ fún wọn pé: ‘Torí omi odò Jọ́dánì tó dáwọ́ dúró níwájú àpótí+ májẹ̀mú Jèhófà ni. Nígbà tí wọ́n gbé àpótí náà sọdá odò Jọ́dánì, omi odò Jọ́dánì dáwọ́ dúró. Àwọn òkúta yìí máa jẹ́ ohun ìrántí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì títí lọ.’”+
8 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ohun tí Jóṣúà sọ gẹ́lẹ́. Wọ́n gbé òkúta méjìlá (12) ní àárín Jọ́dánì, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Jóṣúà, iye òkúta náà jẹ́ iye ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Wọ́n kó o lọ síbi tí wọ́n fẹ́ sùn mọ́jú, wọ́n sì tò ó síbẹ̀.
9 Jóṣúà tún to òkúta méjìlá (12) sí àárín Jọ́dánì níbi tí àwọn àlùfáà tí wọ́n gbé àpótí májẹ̀mú náà dúró sí,+ àwọn òkúta náà sì wà níbẹ̀ títí dòní.
10 Àwọn àlùfáà tó gbé Àpótí náà dúró sí àárín Jọ́dánì títí àwọn èèyàn náà fi parí gbogbo ohun tí Jèhófà pa láṣẹ pé kí Jóṣúà sọ fún wọn, bíi gbogbo ohun tí Mósè pa láṣẹ fún Jóṣúà. Ní gbogbo ìgbà yẹn, àwọn èèyàn náà ń yára sọdá. 11 Gbàrà tí gbogbo àwọn èèyàn náà sọdá tán, Àpótí Jèhófà àti àwọn àlùfáà sọdá níṣojú àwọn èèyàn náà.+ 12 Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, àwọn ọmọ Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè sọdá ṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yòókù, wọ́n tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti jagun,+ bí Mósè ṣe pa á láṣẹ fún wọn.+ 13 Nǹkan bí ọ̀kẹ́ méjì (40,000) ọmọ ogun tó dira ogun ló sọdá níwájú Jèhófà sí aṣálẹ̀ tó tẹ́jú ní Jẹ́ríkò.
14 Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà gbé Jóṣúà ga níṣojú gbogbo Ísírẹ́lì,+ wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún un gan-an* ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, bí wọ́n ṣe bọ̀wọ̀ fún Mósè gidigidi.+
15 Jèhófà wá sọ fún Jóṣúà pé: 16 “Pàṣẹ fún àwọn àlùfáà tó gbé àpótí+ Ẹ̀rí pé kí wọ́n jáde nínú odò Jọ́dánì.” 17 Ni Jóṣúà bá pàṣẹ fún àwọn àlùfáà náà pé: “Ẹ jáde nínú odò Jọ́dánì.” 18 Nígbà tí àwọn àlùfáà tó gbé àpótí+ májẹ̀mú Jèhófà jáde ní àárín Jọ́dánì, tí àtẹ́lẹsẹ̀ àwọn àlùfáà náà sì kan orí ilẹ̀, omi odò Jọ́dánì tún bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàn, ó sì kún bo bèbè rẹ̀+ bó ṣe wà tẹ́lẹ̀.
19 Ní ọjọ́ kẹwàá oṣù kìíní, àwọn èèyàn náà kúrò ní Jọ́dánì, wọ́n sì pàgọ́ sí Gílígálì+ ní ààlà Jẹ́ríkò lápá ìlà oòrùn.
20 Ní ti òkúta méjìlá (12) tí wọ́n kó jáde látinú Jọ́dánì, Jóṣúà tò ó sí Gílígálì.+ 21 Ó wá sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Lọ́jọ́ iwájú, tí àwọn ọmọ yín bá béèrè lọ́wọ́ àwọn bàbá wọn pé, ‘Kí ni àwọn òkúta yìí wà fún?’+ 22 kí ẹ ṣàlàyé fún àwọn ọmọ yín pé: ‘Orí ilẹ̀ gbígbẹ ni Ísírẹ́lì gbà sọdá Jọ́dánì+ 23 nígbà tí Jèhófà Ọlọ́run yín mú kí omi Jọ́dánì gbẹ níwájú wọn títí wọ́n fi sọdá, bí Jèhófà Ọlọ́run yín ṣe ṣe sí Òkun Pupa nígbà tó mú kó gbẹ níwájú wa títí a fi sọdá.+ 24 Ó ṣe èyí, kí gbogbo aráyé lè mọ bí ọwọ́ Jèhófà ṣe lágbára tó,+ kí ẹ sì lè máa bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run yín nígbà gbogbo.’”