Sí Àwọn Hébérù
9 Ní tirẹ̀, májẹ̀mú ti tẹ́lẹ̀ ní àwọn ohun tí òfin béèrè, fún iṣẹ́ ìsìn mímọ́ àti ibi mímọ́+ rẹ̀ ní ayé. 2 Torí wọ́n kọ́ apá àkọ́kọ́ nínú àgọ́, níbi tí ọ̀pá fìtílà,+ tábìlì àti àwọn búrẹ́dì tí wọ́n ń gbé síwájú*+ wà; a sì ń pè é ní Ibi Mímọ́.+ 3 Àmọ́ lẹ́yìn aṣọ ìdábùú kejì,+ apá kan wà tí à ń pè ní Ibi Mímọ́ Jù Lọ.+ 4 Àwo tùràrí oníwúrà+ àti àpótí májẹ̀mú + tí wọ́n fi wúrà bò látòkè délẹ̀+ wà níbẹ̀, inú rẹ̀ ni ìṣà wúrà tí wọ́n kó mánà+ sí wà pẹ̀lú ọ̀pá Áárónì tó yọ òdòdó+ àti àwọn wàláà+ májẹ̀mú; 5 àwọn kérúbù ológo tí wọ́n ṣíji bo ìbòrí ìpẹ̀tù*+ sì wà lórí rẹ̀. Àmọ́ àkókò kọ́ nìyí láti máa sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn nǹkan yìí.
6 Lẹ́yìn tí wọ́n kọ́ àwọn nǹkan yìí lọ́nà yìí, àwọn àlùfáà máa ń wọ apá àkọ́kọ́ nínú àgọ́ náà déédéé kí wọ́n lè ṣe àwọn iṣẹ́ ìsìn mímọ́;+ 7 àmọ́ àlùfáà àgbà nìkan ló máa ń wọ apá kejì lẹ́ẹ̀kan lọ́dún,+ kì í wọ ibẹ̀ láìsí ẹ̀jẹ̀,+ èyí tó fi máa ń rúbọ fún ara rẹ̀+ àti fún ẹ̀ṣẹ̀ táwọn èèyàn+ dá láìmọ̀ọ́mọ̀. 8 Ẹ̀mí mímọ́ tipasẹ̀ èyí fi hàn kedere pé a ò tíì fi ọ̀nà tó wọnú ibi mímọ́ hàn nígbà tí àgọ́ àkọ́kọ́ ṣì wà.+ 9 Àgọ́ yìí jẹ́ àpèjúwe fún àkókò yìí,+ a sì ń fi àwọn ọrẹ àti ẹbọ rúbọ ní ìbámu pẹ̀lú ètò yìí.+ Àmọ́ àwọn yìí ò lè mú kí ẹni tó ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ pátápátá.+ 10 Kìkì ohun tí wọ́n dá lé lórí ni oúnjẹ, ohun mímu àti oríṣiríṣi ìwẹ̀* tí òfin sọ.+ Wọ́n jẹ́ àwọn ohun tí òfin béèrè ní ti ara,+ a sì sọ ọ́ di dandan títí di àkókò tí a yàn láti mú àwọn nǹkan tọ́.
11 Àmọ́, nígbà tí Kristi dé bí àlùfáà àgbà àwọn ohun rere tó ti ṣẹlẹ̀, ó gba inú àgọ́ tó tóbi jù, tó sì jẹ́ pípé jù, tí wọn ò fi ọwọ́ ṣe, ìyẹn tí kì í ṣe ti ẹ̀dá yìí. 12 Kì í ṣe ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ àti ti àwọn akọ ọmọ màlúù ló gbé wọnú ibi mímọ́, àmọ́ ẹ̀jẹ̀ òun fúnra rẹ̀ ni,+ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún ní ṣe é mọ́ láé, ó sì gba ìtúsílẹ̀* àìnípẹ̀kun fún wa.+ 13 Torí tí ẹ̀jẹ̀ àwọn ewúrẹ́ àti ti àwọn akọ màlúù+ àti eérú ọmọ màlúù* tí wọ́n fi wọ́n àwọn tó ti di aláìmọ́ bá sọ wọ́n di mímọ́ kó lè wẹ ẹran ara mọ́,+ 14 ǹjẹ́ ẹ̀jẹ̀ Kristi,+ ẹni tó tipasẹ̀ ẹ̀mí àìnípẹ̀kun fi ara rẹ̀ rúbọ sí Ọlọ́run láìní àbààwọ́n kò ní ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ láti wẹ ẹ̀rí ọkàn wa mọ́ kúrò nínú àwọn òkú iṣẹ́,+ ká lè máa ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún Ọlọ́run alààyè?+
15 Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ alárinà májẹ̀mú tuntun,+ kí àwọn tí a ti pè lè gba ìlérí ogún àìnípẹ̀kun, torí ẹnì kan ti kú fún wọn, kí wọ́n lè rí ìtúsílẹ̀ nípasẹ̀ ìràpadà+ kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó wà lábẹ́ májẹ̀mú ti tẹ́lẹ̀.+ 16 Torí tí a bá dá májẹ̀mú, ẹ̀rí gbọ́dọ̀ wà pé èèyàn tó dá májẹ̀mú náà ti kú, 17 ìdí ni pé ikú máa ń fìdí májẹ̀mú múlẹ̀, torí pé kò tíì lè bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tí èèyàn tó dá májẹ̀mú náà bá ṣì wà láàyè. 18 Tó bá rí bẹ́ẹ̀, májẹ̀mú ti tẹ́lẹ̀ náà kò lè ṣiṣẹ́* láìsí ẹ̀jẹ̀. 19 Torí lẹ́yìn tí Mósè sọ gbogbo àṣẹ inú Òfin náà fún gbogbo èèyàn, ó mú ẹ̀jẹ̀ àwọn akọ ọmọ màlúù àti ti àwọn ewúrẹ́, pẹ̀lú omi, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti ewéko hísópù, ó sì fi wọ́n ìwé* náà àti gbogbo àwọn èèyàn náà, 20 ó sọ pé: “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú tí Ọlọ́run pa láṣẹ pé kí ẹ pa mọ́.”+ 21 Bákan náà, ó fi ẹ̀jẹ̀ náà wọ́n àgọ́ àti gbogbo ohun tí wọ́n ń lò fún iṣẹ́ ìsìn mímọ́.*+ 22 Àní bí Òfin ṣe sọ, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo nǹkan ni wọ́n ń fi ẹ̀jẹ̀ wẹ̀ mọ́,+ ìdáríjì kankan ò sì lè wáyé àfi tí a bá tú ẹ̀jẹ̀ jáde.+
23 Torí náà, ó pọn dandan pé ká wẹ àwọn ohun tó ṣàpẹẹrẹ+ àwọn ohun ti ọ̀run mọ́ láwọn ọ̀nà yìí,+ àmọ́ àwọn ẹbọ tó dáa ju èyí lọ fíìfíì ló yẹ àwọn ohun ti ọ̀run. 24 Torí Kristi ò wọnú ibi mímọ́ tí wọ́n fi ọwọ́ ṣe,+ tó jẹ́ àpẹẹrẹ ohun gidi,+ àmọ́ ọ̀run gangan ló wọ̀ lọ,+ tó fi jẹ́ pé ó ń fara hàn báyìí níwájú* Ọlọ́run nítorí wa.+ 25 Kò ṣe èyí láti máa fi ara rẹ̀ rúbọ léraléra bí ìgbà tí àlùfáà àgbà máa ń wọ ibi mímọ́ lọ́dọọdún+ pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ tí kì í ṣe tiẹ̀. 26 Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ì bá máa jìyà léraléra látìgbà ìpìlẹ̀ ayé. Àmọ́ ní báyìí, ó ti fi ara rẹ̀ hàn kedere ní ìparí àwọn ètò àwọn nǹkan,* lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún ní ṣe é mọ́ láé, ó fi ara rẹ̀ rúbọ kó lè mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò.+ 27 Bó ṣe jẹ́ pé ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni èèyàn máa ń kú, tí kò sì ní kú mọ́ láé, àmọ́ lẹ́yìn èyí, ó máa gba ìdájọ́, 28 bákan náà ló ṣe jẹ́ pé a fi Kristi rúbọ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún ní ṣe é mọ́ láé, kó lè ru ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀;+ tó bá sì fara hàn lẹ́ẹ̀kejì, kò ní jẹ́ torí ẹ̀ṣẹ̀,* àwọn tó ń fi taratara wá a fún ìgbàlà wọn sì máa rí i.+