Sáàmù
Sí olùdarí. Ti àwọn ọmọ Kórà.+ Orin.
49 Ẹ gbọ́, gbogbo ẹ̀yin èèyàn.
3 Ẹnu mi yóò sọ̀rọ̀ ọgbọ́n,
Àṣàrò ọkàn mi+ yóò sì fi òye hàn.
4 Màá fiyè sí òwe;
Màá fi háàpù pa àlọ́ mi.
6 Àwọn tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé ọrọ̀ wọn,+
Tí wọ́n sì ń fi ọrọ̀ rẹpẹtẹ wọn fọ́nnu,+
7 Kò sí ìkankan nínú wọn tó lè ra arákùnrin kan pa dà
Tàbí tí ó lè fún Ọlọ́run ní ìràpadà nítorí rẹ̀,+
8 (Iye owó ìràpadà ẹ̀mí* wọn ṣe iyebíye
Débi pé ó kọjá ohun tí ọwọ́ wọn lè tẹ̀);
10 Gbogbo èèyàn ló mọ̀ pé àwọn ọlọ́gbọ́n pàápàá ń kú;
Àwọn òmùgọ̀ àti àwọn aláìnírònú ń ṣègbé pa pọ̀,+
Wọ́n á sì fi ọrọ̀ wọn sílẹ̀ fún àwọn ẹlòmíì.+
11 Ohun tó ń wù wọ́n lọ́kàn ni pé kí ilé wọn wà títí láé,
Kí àgọ́ wọn wà láti ìran dé ìran.
Wọ́n ti fi orúkọ wọn pe àwọn ilẹ̀ wọn.
13 Bí ọ̀nà àwọn òmùgọ̀ ṣe rí nìyí+
Àti ti àwọn tó ń tẹ̀ lé wọn, tí inú wọn ń dùn sí ọ̀rọ̀ asán tí wọ́n ń sọ. (Sélà)
14 A ti yàn wọ́n bí àgùntàn láti lọ sí Isà Òkú.*
Ikú yóò ṣe olùṣọ́ àgùntàn wọn;
Àwọn adúróṣinṣin yóò ṣàkóso wọn+ ní òwúrọ̀.
16 Má bẹ̀rù nítorí pé ẹnì kan di ọlọ́rọ̀,
Nítorí pé ògo ilé rẹ̀ ń pọ̀ sí i,
17 Nítorí tí ó bá kú, kò lè mú ohunkóhun lọ;+
Ògo rẹ̀ kò ní bá a sọ̀ kalẹ̀ lọ.+
18 Nítorí nígbà ayé rẹ̀, ó ń yin ara* rẹ̀.+
(Aráyé máa ń yin èèyàn nígbà tó bá láásìkí.)+
19 Àmọ́ nígbẹ̀yìn, yóò dara pọ̀ mọ́ ìran àwọn baba ńlá rẹ̀.
Wọn kò ní rí ìmọ́lẹ̀ mọ́ láé.
20 Ẹni tí kò bá lóye èyí, bí a tilẹ̀ dá a lọ́lá,+
Kò sàn ju àwọn ẹranko tó ń ṣègbé.