Irapada Tí Ó Dọ́gba Rẹ́gífun Gbogbo Eniyan
“Ọmọkunrin eniyan wá, kì í ṣe lati jẹ́ kí á ṣe ìránṣẹ́ fun un, ṣugbọn lati ṣe ìránṣẹ́ ati lati fi ọkàn rẹ̀ ṣe irapada ni pàṣípààrọ̀ fun ọpọlọpọ eniyan.”—MATIU 20:28, NW.
1, 2. (a) Eeṣe ti a fi le sọ pe irapada ni ẹ̀bùn Ọlọrun titobi julọ fun araye? (b) Awọn èrè wo ni o wa ninu ṣiṣayẹwo irapada?
IRAPADA naa jẹ́ ẹ̀bùn Ọlọrun titobi julọ fun aráyé. Nipasẹ “ìtúsílẹ̀ nipa irapada,” awa le rí “idariji awọn ìrékọjá wa” gbà. (Efesu 1:7, NW) O jẹ́ ìpìlẹ̀ ireti ìyè àìnípẹ̀kun, yala ni ọrun tabi lori paradise ilẹ-aye. (Luuku 23:43; Johanu 3:16) Ati nitori rẹ, awọn Kristian le gbadun ìdúró rere niwaju Ọlọrun ani nisinsinyi paapaa.—Iṣipaya 7:14, 15.
2 Nitori naa irapada kii ṣe ohun kan ti ko ṣe kedere tabi jóòótọ́. Bi o ti ní ìpìlẹ̀ ti o bá ofin mu ninu awọn ìlànà atọrunwa, irapada le mu awọn èrè gidi, ti o jẹ́ tootọ wá. Awọn apá-ìhà ẹkọ-igbagbọ yii le “ṣoro íyéni.” (2 Peteru 3:16) Ṣugbọn iwọ yoo ri pe ìsapá naa yẹ lati ṣàyẹ̀wò irapada lọna kínníkínní, nitori pe o fi ìfẹ́ titayọ Ọlọrun fun aráyé han. Lati loye itumọ irapada naa ni lati mọ apá pàtàkì “ọrọ̀ ati ọgbọ́n ati imọ” jijinlẹ ti Ọlọrun.—Roomu 5:8; 11:33.
Awọn Àríyànjiyàn Ti A Nilati Yanjú
3. Bawo ni irapada ṣe di eyi ti o pọndandan, èésìtiṣe ti Ọlọrun ko fi le gbojufo ipo ẹṣẹ aráyé dá?
3 Irapada naa di ohun tí o pọndandan nitori ẹṣẹ ẹda-eniyan akọkọ naa, Adamu, ẹni ti o fi ogún aláìwúlò ti ẹṣẹ, àìsàn, ìbànújẹ́, ati ìrora silẹ fun iru-ọmọ rẹ̀. (Roomu 8:20) Nitori àìpé ti wọn ti jogún, gbogbo awọn àtọmọdọ́mọ Adamu jẹ́ “ọmọ ìbínú,” ti wọn yẹ fun ikú. (Efesu 2:3; Deuteronomi 32:5) Ọlọrun kò lè juwọ́sílẹ̀ fun ero imọlara ti o gba gbẹ̀rẹ́ fun ohun ti kò tọ́ ki o sì wulẹ̀ dariji aráyé laiwẹhin wò. Ọrọ oun tìkáraarẹ̀ fihan pe “ikú ni èrè ẹṣẹ.” (Roomu 6:23) Lati gbojufo ipò ẹṣẹ aráyé dá, Ọlọrun yóò nilati pa awọn ọ̀pá ìdiwọ̀n oun tìkáraarẹ̀ tì, lati sọ idajọ-ododo oun tìkaraarẹ̀ ti o bofin mu di eyi ti ko gbeṣẹ mọ! (Joobu 40:8) Sibẹ, “ododo ati idajọ ni ibi ìtẹ́ [Ọlọrun] ti a ti fidi rẹ̀ múlẹ̀.” (Saamu 89:14, NW) Ìyàbàrá eyikeyii kuro ninu òdodo ni ìhà-ọ̀dọ̀ rẹ̀ yóò wulẹ̀ ru ìwà-àìlófin sókè yóò si jin ipò rẹ̀ gẹgẹbi Ọba-alaṣẹ Àgbáyé lẹsẹ.—Fiwe Oniwaasu 8:11.
4. Ìṣọ̀tẹ̀ Satani gbe awọn ibeere wo dide?
4 Ọlọrun tun nilati yanju awọn ọran àríyànjiyàn miiran tí ìṣọ̀tẹ̀ Satani gbedide, àríyànjiyàn tí ó ṣe pàtàkì jinna rékọjá ipo iṣoro ẹda-eniyan. Satani ṣókùnkùn dudu bo orukọ Ọlọrun nipa kika Ọlọrun si onírọ́ ati òǹrorò apàṣẹwàá kan ẹniti o fi ìmọ̀ ati òmìnira du awọn ẹda rẹ. (Jẹnẹsisi 3:1-5) Siwaju si, nipa dida bi ẹni fi ori ète Ọlọrun ti fifi awọn ẹda-eniyan olododo kún ori ilẹ-aye ṣánpọ́n, Satani mú ki Ọlọrun farahan gẹgẹbi akùnà. (Jẹnẹsisi 1:28; Aisaya 55:10, 11) Satani tun gbójúgbóyà ara rẹ lati fọ̀rọ̀kẹ́lẹ́ ba awọn adúróṣinṣin iranṣẹ Ọlọrun jẹ́, ni fifẹsun kàn pe wọn nṣiṣẹsin In kiki nitori awọn ète-ìsúniṣe onimọtara-ẹni-nikan. Satani fọ́nnu pe bi a ba fi wọn sabẹ ikimọlẹ, ẹnikẹni ninu wọn ki yóò wa ni aduroṣinṣin ti Ọlọrun titilọ!—Joobu 1:9-11.
5. Eeṣe ti Ọlọrun ko fi le ṣaika awọn ìpèníjà Satani sí?
5 Awọn ipenija wọnyi ni a ko lè ṣàìkàsí. Bi a ba fi wọn silẹ laidahun, ìgbọ́kànle ati ìtìlẹ́hin fun ipo ìṣàkóso Ọlọrun yoo yìnrìn dànù nikẹhin. (Owe 14:28) Bi ofin ati aṣẹ ko ba gbeṣẹ mọ, ìdàrúdàpọ̀ nlanla ki yóò ha wà jákèjádò àgbáyé? Ọlọrun tipa bayi gbe e kari ara rẹ̀ ati awọn ọ̀nà ododo rẹ̀ lati dá ipò ọba-alaṣẹ rẹ láre. Oun gbe e kari awọn iranṣẹ rẹ̀ olùṣòtítọ́ ki wọn lè fi iduroṣinṣin wọn ti ko ṣeé já hàn. Eyi tumọsi biba ipo buburu iran eniyan ẹlẹṣẹ lò ní ọna ti o fi awọn àríyànjiyàn pataki julọ naa siwaju. Oun sọ fun Israẹli lẹhin naa pe: “Emi, àní emi ni ẹni ti npa àìṣedéédéé rẹ rẹ́ nitori ti emi tikalaraami”—Aisaya 43:25.
Irapada: Ìbora Kan
6. Ki ni diẹ lara awọn ede-isọrọ ti a lo ninu Bibeli lati ṣapejuwe ọna Ọlọrun fun gbigba araye là?
6 Ni Saamu 92:5, a kà pe: “Oluwa [“Jehofa,” NW], iṣẹ rẹ ti tobi to! Ìrò inu rẹ jinlẹ̀ gidigidi.” Nitori naa o nbeere isapa fun wa lati loye ohun ti Ọlọrun ti ṣe fun aráyé ni kíkún. (Fiwe Saamu 36:5, 6.) A layọ pe, Bibeli ràn wa lọwọ lati loye awọn ọran nipa lilo iye awọn ede-isọrọ ti o ṣapejuwe tabi ṣàkàwé awọn iṣẹ títóbilọ́lá Ọlọrun lati inú onírúurú ọna igbawoye. Bibeli sọrọ nipa irapada niti rírà, ìlàjà, ìpẹ̀tù, ìtúnràpadà, ati ètùtù. (Saamu 49:8; Daniẹli 9:24; Galatia 3:13; Kolose 1:20; Heberu 2:17, NW) Ṣugbọn boya ọrọ ti o ṣapejuwe awọn ọran lọna didarajulọ ni eyi ti Jesu funraarẹ lò ni Matiu 20:28 (NW): “Ọmọkunrin eniyan wa, kìí ṣe lati jẹ ki a ṣe iranṣẹ fun un, ṣugbọn lati ṣe iranṣẹ ati lati fi ọkan rẹ ṣe irapada [Giriiki, lyʹtron] ni pàṣípààrọ̀ fun ọpọlọpọ eniyan.”
7, 8. (a) Ki ni a kẹkọọ lati inu awọn ọrọ Giriiki ati Heberu fun irapada? (b) Ṣàkàwé bi irapada ti ni iṣerẹgi ninu.
7 Ki ni irapada kan jẹ́? Ọrọ Giriiki naa lyʹtron wá lati inu ọrọ-iṣe ti o tumọ si “lati túsílẹ̀.” A lò ó lati ṣapejuwe owo ti a san ni pàṣípààrọ̀ fun titu ẹni ti a mu loju ogun silẹ. Bi o ti wu ki o ri, ninu iwe mimọ lede Heberu, ọrọ naa fun irapada, koʹpher, wá lati inu ọrọ-iṣe ti o tumọsi lati “fibò” tabi “fitẹ́.” Fun apẹẹrẹ, Ọlọrun sọ fun Noa lati fi ọ̀dà bo (ka·pharʹ) áàkì naa. (Jẹnẹsisi 6:14, NW) Nigba naa, lati inu ọna igbawoye yii, lati ràpadà tabi lati ṣètùtù fun ẹṣẹ tumọsi lati bo ẹṣẹ.—Saamu 65:3.
8 Iwe naa Theological Dictionary of the New Testament ṣakiyesi pe koʹpher “maa nduro fun alabaadọgba nigba gbogbo,” tabi iṣerẹgi. Nipa bayii, ìbóra (kap·poʹreth) áàkì majẹmu naa ṣerẹgi ni irisi pẹlu áàkì naa funraarẹ. Bakan naa, ni ṣíṣètùtù fun ẹṣẹ, tabi rirapada, ìdájọ́-òdodo atọrunwa beere fun “ẹmi fun ẹmi, oju fun oju, ehín fun ehín, ọwọ́ fun ọwọ́, ẹsẹ̀ fun ẹsẹ̀.” (Deuteronomi 19:21) Ṣugbọn nigbamiran, idajọ ododo ni a le múṣẹ bi a ba pese alabaadọgba dipo ìjìyà lilekoko. Lati ṣàkàwé: Ẹkisodu 21:28-32 sọ nipa akọmaluu ti o ba kàn eniyan pa. Bi oni-nnkan ba mọ nipa ìhùwàsí akọmaluu naa ṣugbọn ti ko gbe igbesẹ iṣọra ti o tọ́, oun ni a le mu ki o kaju, tabi san ẹmi oun tikaraarẹ pada fun ẹmi ẹni ti a kàn pa naa! Sibẹ ki ni bi oni-nnkan naa ba wulẹ jẹbi lapakan? Oun yoo nilo koʹpher, ohun kan lati bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Awọn onidaajọ ti a yànsípò le bu irapada, tabi owo ìtanràn fun un, gẹgẹbi iye-owo ìtúnràpadà kan.
9. Bawo ni ipo ti o ni akọbi Israẹli ninu ṣe ṣakawe ìṣewẹ́kú ti a beere fun ninu iye-owo ìtúnràpadà kan?
9 Ede-isọrọ Heberu miiran ti o tanmọ́ “rirapada” ni pa·dhahʹ, ọrọ-iṣe kan ti o pilẹ tumọsi “túnràpadà.” Numeri 3:39-51 ṣàkàwé bi iye-owo ìtúnràpadà naa ti nilati ṣe wẹ́kú tó. Ni yiyọ akọbi awọn ọmọ Israẹli kuro ninu ewu iku ni Ìrékọjá 1513 B.C.E., wọn di ti Ọlọrun. Oun si ti le tipa bayii beere fun gbogbo ọmọkunrin akọbi awọn ọmọ Israẹli lati ṣiṣẹsin oun ninu tẹmpili. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ọlọrun gba “iye-owo ìtúnràpadà” kan (pidh·yohmʹ, ọrọ orukọ ti a fayọ lati inu pa·dah’) ni pípàṣẹ pe: “Ki iwọ ki o gba awọn ọmọ Lefi fun mi . . . ni ipo gbogbo awọn akọbi ninu ọmọ Israẹli.” Ṣugbọn ìfidípò naa nilati ṣe wẹ́kú. A ka iye eniyan ẹ̀yà Lefi: 22,000 ọkunrin. Tẹle e, a ka iye eniyan gbogbo akọbi ọmọ Israẹli: 22,273 ọkunrin. Kiki nipa sisan “iye-owo irapada” kan tabi ṣékélì marun-un fun ẹnikọọkan ni a tó lè tún 273 akọbi ti o lé silẹ ràpadà, ki a dá wọn silẹ kuro ninu iṣẹ-isin tẹmpili.
Irapada Tí Ó Ṣérẹ́gí
10. Eeṣe ti awọn ìrúbọ ẹran ko fi lè to lati bo awọn ẹṣẹ aráyé?
10 Awọn ọ̀rọ̀ ti a ṣẹṣẹ mẹnukan tan yii ṣapejuwe pe irapada kan gbọdọ jẹ alabaadọgba eyi ti o dípò, tabi ki o kájú rẹ̀. Ẹbọ ẹran tí awọn ẹni igbagbọ bẹrẹ lati ori Abeli siwaju fi rubọ ko le bo ẹṣẹ eniyan niti gidi, niwọnbi awọn eniyan ti galọla ju awọn ẹranko ẹhànnà aláìlè ronu. (Saamu 8:4-8) Nipa bayii Pọọlu le kọwe pe “Ko ṣeeṣe fun ẹ̀jẹ̀ akọmaluu ati ti ewurẹ lati mu ẹṣẹ kuro.” Iru awọn ẹbọ bẹẹ wulẹ lè ṣiṣẹ gẹgẹ bi bibo ẹ̀ṣẹ̀ lọna iṣapẹẹrẹ, tabi lọna aworan ni ifojusọna fun irapada naa ti nbọ.—Heberu 10:1-4.
11, 12. (a) Eeṣe ti ẹgbẹẹgbẹrun lọna àràádọ́ta ọkẹ awọn eniyan ko fi nilati ku iku ìrúbọ lati bo ipo ẹṣẹ aráyé? (b) Ẹnikan ṣoṣo wo ni o le ṣiṣẹ gẹgẹbi “irapada ṣiṣerẹgi kan,” ki si ni ète ti iku rẹ ṣiṣẹ fun?
11 Irapada ti a fi ojiji rẹ han ṣaaju yii nilati jẹ alabaadọgba Adamu gan-an, niwọnbi idajọ ìjìyà iku tí Ọlọrun ṣe fun Adamu lọna ti o ba idajọ ododo mu ti yọrisi idalẹbi iku fun iran eniyan. ‘Ninu Adamu gbogbo eniyan nku,’ ni 1 Kọrinti 15:22 wi. Nitori naa, ko pọndandan fun ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọna àràádọ́ta ọ̀kẹ́ eniyan lẹnikọọkan lati ku iku irubọ lati ṣerẹgi pẹlu ọmọ Adamu kọọkan. “Nipasẹ ọkunrin kan [Adamu] ẹṣẹ wọnu aye ati iku nipasẹ ẹṣẹ.” (Roomu 5:12, NW) Ati “niwọnbi iku ti jẹ nipasẹ ọkunrin kan,” ìtúnràpadà araye tun le wa “nipasẹ ọkunrin kan.”—1 Kọrinti 15:21.
12 Ẹni ti o le jẹ irapada naa nilati jẹ eniyan ẹlẹran ara ati ẹ̀jẹ̀ pipe—alabaadọgba rẹ́gí Adamu. (Roomu 5:14) Ẹda ẹmi kan tabi “Ọlọrun-eniyan” kan ko le mu ìwọ̀n idajọ ododo duro déédéé. Kiki eniyan pipe, ẹnikan ti ko si labẹ ìdájọ́ iku Adamu, ni o le pese “irapada ṣíṣerẹ́gí kan,” ọkan ti o ṣerẹ́gí lọna pipe pẹlu Adamu. (1 Timoti 2:6)a Nipa fífínúfíndọ̀ fi ẹmi rẹ rubọ, “Adamu ìkẹhìn” yii le san owó ọ̀yà fun ẹ̀ṣẹ̀ “Adamu ọkunrin iṣaaju.”—1 Kọrinti 15:45; Roomu 6:23.
13, 14. (a) Njẹ Adamu ati Efa ha jèrè lati inu irapada naa bi? Ṣàlàyé. (b) Bawo ni awọn atọmọdọmọ Adamu ṣe jàǹfààní lati inu irapada naa? Ṣàkàwé.
13 Bi o ti wu ki o ri, yala Adamu tabi Efa, ko jere ninu irapada naa. Ofin Mose ni ìlànà yi ninu: “Ki ẹyin ki o maṣe gba ohun ìràsílẹ̀ [“irapada,” NW] fun apaniyan ti o jẹbi iku.” (Numeri 35:31) Adamu ni a ko tanjẹ, nitori naa ẹṣẹ rẹ jẹ àfínnúfíndọ̀ṣe, àmọ̀-ọ́nmọ̀ dá. (1 Timoti 2:14) O tumọsi pípa awọn iru-ọmọ rẹ, nitori pe wọn jogun àìpé rẹ nisinsinyi, ti wọn tipa bayii bọ́ sabẹ ìdájọ́ iku. Ni kedere, Adamu yẹ ki o kú, nitori gẹgẹbi ọkunrin pipe kan, oun ti fínnúfíndọ̀ yàn lati ṣàìgbọràn si ofin Ọlọrun. Yóò lòdìsí awọn ilana ododo Jehofa bi oun ba lo irapada nititori Adamu. Bi o ti wu ki o ri, sisan iye ti ẹṣẹ Adamu beere fun ko sọ idajọ iku lori iru-ọmọ Adamu dòfo! (Roomu 5:16) Ni itumọ ti ofin, agbara iṣeparun ẹṣẹ ni a fòpin sí lati orisun rẹ gan-an. Olurapada naa ‘tọ́ iku wo fun olukuluku eniyan,’ ni riru awọn abajade ẹṣẹ fun gbogbo awọn ọmọ Adamu.—Heberu 2:9; 2 Kọrinti 5:21; 1 Peteru 2:24.
14 Lati ṣakawe: Ronu ile-iṣẹ nla kan ti o ni ọgọrọọrun awọn ẹni àgbàsíṣẹ́. Alabojuto ile iṣẹ kan ti o jẹ alaiṣootọ mu iṣẹ ìṣòwò naa wọ gbèsè; ile iṣẹ naa ni a ti pa. Nisinsinyi ọgọrọọrun awọn eniyan kò ni iṣẹ lọwọ wọn ko si le san gbese ti wọn ti jẹ. Awọn olùbáṣègbéyàwó wọn, awọn ọmọ wọn, ati gbogbo awọn ti wọn jẹ ni gbèsè paapaa njiya nitori iwa-ibajẹ ọkunrin kan yẹn! Ṣugbọn ọlọ́rọ̀ onínúure kan de ẹni ti o san gbese ile iṣẹ naa ti o si tun ile iṣẹ naa ṣí pada. Ifagile gbese kan yẹn, ẹ̀wẹ̀, mu ìtura kikun wa fun ọpọlọpọ awọn ẹni àgbàsíṣẹ́, awọn idile wọn, ati awọn ti wọn jẹ ni gbese. Ṣugbọn njẹ oluṣabojuto ipilẹṣẹ yoo ha ṣajọpin ninu aásìkí titun naa? Bẹẹkọ, oun wa ninu ẹwọn o si ti padanu iṣẹ rẹ̀ titi lọ gbére! Lọna ti o farajọra, ìfagilé gbese Adamu mu èrè wa fun àràádọ́ta ọkẹ awọn atọmọdọmọ rẹ̀—ṣugbọn kii ṣe fun Adamu.
Ta Ni Ẹni Ti O Pese Irapada Náà?
15. Ta ni o lè pese irapada fun aráyé, èésìtiṣe?
15 Onisaamu naa kédàárò pe: “Ko si ẹnikankan ninu wọn ani ti o le tun arakunrin kan ra pada lọnakọna: tabi ki o fi irapada fun Ọlọrun nitori rẹ; (iye-owo irapada ọkan wọn si ṣeyebiye tobẹẹ ti o fi dawọ duro titilae).” The New English Bible wipe iye-owo irapada naa “ju agbara rẹ lọ lati san titi lae.” (Saamu 49:7, 8) Nigba naa, ta ni yoo pese irapada naa? Jehofa nikanṣoṣo ni o le pese “Ọdọ agutan” pipe naa “ti o ko ẹṣẹ aye lọ.” (Johanu 1:29) Ọlọrun ko ran awọn angẹli kan lati gba araye silẹ. Oun ṣe irubọ gigalọla julọ ti rírán Ọmọkunrin bibi-kanṣoṣo rẹ, “ẹni naa ti oun ni inudidun si lọna akanṣe.”—Owe 8:30, NW; Johanu 3:16.
16. (a) Bawo ni Ọmọkunrin Ọlọrun ṣe di ẹni ti a bi ni ẹda-eniyan pipe? (b) Ki ni a le pe Jesu ní itumọ ti ofin?
16 Nipa lilọwọ tìfẹ́-inú tìfẹ́-inú ninu ìṣètò atọrunwa naa, Ọmọkunrin Ọlọrun “sọ ara rẹ dofo” ni irisi ti ọrun. (Filipi 2:7) Jehofa ta atare ipa iwalaaye ati akopọ animọ akọbi Ọmokunrin rẹ ti ọrun sinu ile ọlẹ̀ wundia Júù kan ti a npe ni Maria. Lẹhin naa ẹmi mimọ ‘ṣiji bò ó,’ ni mímú un daju pe ọmọ ti ndagba ninu ile ọlẹ̀ rẹ̀ yoo jẹ mimọ ti o bọ lọwọ ẹṣẹ patapata. (Luuku 1:35; 1 Peteru 2:22) Gẹgẹbi eniyan kan, a o maa pe e ni Jesu. Ṣugbọn ni itumọ ti ofin, a le pe e ni ‘Adamu keji naa,’ nitori oun ṣerẹgi lọna pipe pẹlu Adamu. (1 Kọrinti 15:45, 47) Nipa bayii, Jesu le fi ara rẹ rubọ gẹgẹbi ‘ọdọ agutan ti ko ni abuku, ti ko si ni abawọn,’ irapada fun araye ẹlẹṣẹ.—1 Peteru 1:18, 19.
17. (a) Ta ni a san irapada naa fun, èésìtise? (b) Niwọnbi Ọlọrun ti pese ti o si tun gba irapada naa, eeṣe ti a fi ṣe pàṣípààrọ̀ naa rárá?
17 Ṣugbọn, ta ni a o san irapada naa fun? Fun ọpọ ọgọrun-un ọdun, awọn ẹlẹkọọ isin Kristẹndọm ti jiyan pe a san án fun Satani Eṣu. Otitọ naa ni pe araye ni a ti “tà sabẹ” ẹṣẹ o si ti tipa bayii bọ́ sábẹ́ idari Satani. (Roomu 7:14, NW; 1 Johanu 5:19) Sibẹ, Jehofa ni “olugbẹsan” fun ìwà buburu kii ṣe Satani. (1 Tẹsalonika 4:6) Nitori naa, gẹgẹbi Saamu 49:7 ti wi ni kedere, irapada naa ni a nilati san “fun Ọlọrun.” Jehofa mu ki irapada naa wa larọọwọto, ṣugbọn lẹhin ti a ti fi Ọ̀dọ́ agutan Ọlọrun rubọ, itoye irapada rẹ ni a gbọdọ san fun Ọlọrun. (Fiwe Jẹnẹsisi 22:7, 8, 11-13; Heberu 11:17.) Eyi ko din irapada na ku si pàṣípààrọ̀ alainidii, ti a ṣe bi àṣà lasan, gẹgẹbi pe a mu owo jade lati inu apo kan a si fi sinu omiran. Irapada naa ko ni pàṣípààrọ̀ aṣeefojuri ninu gẹgẹ bi ìdúnàádúrà lọna ofin. Nipa fifi dandan le e pe irapada kan ni a gbọdọ san—ani ti o tilẹ na an ni ohun nlanla—Jehofa tubọ mu itoropinpin rẹ̀ didurogbọnyin mọ ìlànà ododo daju.—Jakọbu 1:17.
“O Pari!”
18, 19. Eeṣe ti o fi pọndandan fun Jesu lati jiya?
18 Ni igba ìrúwé 33 C.E., o ti tó akoko fun sisan irapada naa. Jesu Kristi ni a faṣẹ ọba mu lori awọn ẹsun eke, a da a lẹjọ ẹbi, a si kan mọ opo-igi ifiya-iku-jẹni. Oun gbadura ẹbẹ si Ọlọrun pẹlu “ẹkun rara ati omije” nitori irora mimuna ati irẹnisilẹ tẹgantẹgan ti o ni ninu. (Heberu 5:7) O ha pọndandan fun Jesu lati jiya bayii bi? Bẹẹni, nitori nipa diduro gẹgẹbi “mímọ́, alailẹtan, alailẹgbin, ti a ya sọtọ kuro lara awọn ẹlẹṣẹ,” taara titi de opin, Jesu yanju àríyànjiyàn ti iwa titọ awọn iranṣẹ Ọlọrun lẹẹkan fáàbàdà.—Heberu 7:26, NW.
19 Ijiya Kristi tun ṣeranwọ lati sọ ọ́ di pipe fun iṣẹ́ rẹ̀ gẹgẹbi Alufaa Agba fun araye. Gẹgẹ bi iru ẹni bẹẹ, oun ki yóò jẹ olùṣàkóso aláìlẹ́mìí ọ̀rẹ́, olùdágunlá ti nrinkinkin mọ ilana lọna ti ko lọgbọn ninu. “Nitori niwọnbi oun ti jiya nipa idanwo, o le ràn awọn ti a ndanwo lọwọ.” (Heberu 2:10, 18; 4:15) Pẹlu èémí rẹ̀ ikẹhin, Jesu le kigbe jade gẹgẹbi aṣẹgun pe: “O pari!” (Johanu 19:30) Kii ṣe kiki pe oun ti fi ẹri iwatitọ tirẹ funraarẹ hàn nikan ni ṣugbọn oun ti ṣaṣeyọrisirere ninu fifi ipilẹ fun igbala araye lelẹ—ati eyi ti o ṣe pataki julọ, ìdáláre ipo ọba-alaṣẹ Jehofa!
20, 21. (a) Eeṣe ti a fi ji Kristi dide kuro ninu oku? (b) Eeṣe ti a fi ‘sọ’ Jesu Kristi ‘di ààyè ninu ẹmi’?
20 Ṣugbọn, ni ọna wo ni a o gba fi irapada naa silo nitootọ gan-an fun araye ẹlẹṣẹ? Nigba wo? Bawo? awọn ọran wọnyi ni a ko fi silẹ fun èèṣì. Ni ọjọ kẹta lẹhin iku Kristi, Jehofa ji i dide kuro ninu oku. (Iṣe 3:15; 10:40) Nipa igbesẹ ṣiṣe pataki pupọ yii, otitọ kan ti ọgọrọọrun awọn ẹlẹri ti ọran ṣoju wọn rí daju, kii ṣe kiki pe Jehofa san ere fun iṣẹ-isin iṣotitọ Ọmọkunrin rẹ nikan ni ṣugbọn o fun un ni àǹfààní lati pari iṣẹ itunrapada rẹ̀.—Roomu 1:4; 1 Kọrinti 15:3-8.
21 Jesu “ni a sọ di ààyè ninu ẹmi,” ara oku rẹ̀ ti ilẹ-aye ni a palẹmọ kuro lọna ti a ko fihan. (1 Peteru 3:18; Saamu 16:10; Iṣe 2:27) Gẹgẹbi ẹda-ẹmi kan, Jesu Kristi ti a ji dide le pada si ọrun nisinsinyi gẹgẹbi aṣẹgun. Iru ayọ nla ti o kọyọyọ wo ni o ti gbọdọ wà ni ọrun ni akoko iṣẹlẹ yẹn! (Fiwe Joobu 38:7.) Jesu ko pada lọ kiki lati gbadun ìkíkáàbọ̀ rẹ̀. Oun dé lati ṣe iṣẹ miiran, eyi ti o ni mimu ki gbogbo iran eniyan jèrè lati inu irapada rẹ̀ ninu. (Fiwe Johanu 5:17, 20, 21.) Gan-an bi oun ṣe ṣaṣepari eyi ati ohun ti o tumọsi fun araye ni a o jiroro ninu ọrọ-ẹkọ ti o tẹle e.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọrọ Giriiki ti a lò nihin-in, an·tiʹly·tron, ko farahan nibomiran ninu Bibeli. O tan mọ́ ọrọ ti Jesu lo fun irapada (lyʹtron) ni Maaku 10:45. Bi o ti wu ki o ri, The New International Dictionary of New Testament Theology tọka jade pe an·tiʹly·tron ‘tẹnumọ erongba ti pàṣípààrọ̀.’ Lọna ti o tọ́, New World Translation ṣetumọ rẹ si “irapada ṣíṣerẹ́gí.”
Awọn Ibeere Atunyẹwo
◻ Awọn àríyànjiyàn wo ni wọn ṣe pataki ani ju ìgbàlà aráyé lọ?
◻ Ki ni o tumọsi lati “ra” awọn ẹlẹṣẹ “pada”?
◻ Ta ni Jesu nilati ba ṣerẹgi, eesitiṣe?
◻ Ta ni o pese irapada naa, ta ni a sì san án fun?
◻ Eeṣe ti o fi pọndandan pe ki a ji Kristi dide kuro ninu oku gẹgẹbi ẹmi?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Awọn irubọ ẹran ko to lati bo awọn ẹṣẹ eniyan; wọn ṣapẹẹrẹ ẹbọ titobiju ti nbọ