Sáàmù
Másíkílì.* Ti Étánì+ tó jẹ́ Ẹ́síráhì.
89 Títí ayé ni èmi yóò máa kọ orin nípa bí Jèhófà ṣe ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn.
Màá fi ẹnu mi sọ nípa òtítọ́ rẹ̀ fún gbogbo ìran.
2 Nítorí mo sọ pé: “Ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ yóò dúró* títí láé,+
O ti mú kí òtítọ́ rẹ fìdí múlẹ̀ ṣinṣin ní ọ̀run.”
5 Àwọn ọ̀run ń yin àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ, Jèhófà,
Àní, wọ́n ń yin òtítọ́ rẹ nínú ìjọ àwọn ẹni mímọ́.
6 Ta ló wà ní ọ̀run tí a lè fi wé Jèhófà?+
Èwo nínú àwọn ọmọ Ọlọ́run+ ló dà bíi Jèhófà?
7 Ọlọ́run yẹ lẹ́ni tí à ń bẹ̀rù nínú ìgbìmọ̀* àwọn ẹni mímọ́;+
Ó jẹ́ atóbilọ́lá àti ẹni tí ẹ̀rù rẹ̀ ń bani lójú gbogbo àwọn tó yí i ká.+
8 Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun,
Ta ló lágbára bí rẹ, ìwọ Jáà?+
10 O ti ṣẹ́gun Ráhábù+ pátápátá bí ẹni tí wọ́n pa.+
O ti fi apá rẹ tó lágbára tú àwọn ọ̀tá rẹ ká.+
11 Tìrẹ ni ọ̀run, tìrẹ sì ni ayé;+
Ilẹ̀ tó ń méso jáde àti ohun tó kún inú rẹ̀,+ ìwọ lo fìdí wọn múlẹ̀.
15 Aláyọ̀ ni àwọn tó ń fi ìdùnnú yìn ọ́.+
Jèhófà, inú ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ ni wọ́n ti ń rìn.
16 Orúkọ rẹ ń mú inú wọn dùn láti àárọ̀ ṣúlẹ̀,
A sì gbé wọn ga nínú òdodo rẹ.
18 Apata wa jẹ́ ti Jèhófà,
Ọba wa sì jẹ́ ti Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.+
19 Ní àkókò yẹn, o bá àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ sọ̀rọ̀ nínú ìran, o ní:
21 Ọwọ́ mi yóò tì í lẹ́yìn,+
Apá mi yóò sì fún un lókun.
26 Yóò ké pè mí pé: ‘Ìwọ ni Bàbá mi,
Ọlọ́run mi àti Àpáta ìgbàlà mi.’+
30 Tí àwọn ọmọ rẹ̀ bá pa òfin mi tì,
Tí wọn ò sì tẹ̀ lé àwọn àṣẹ* mi,
31 Tí wọ́n bá rú òfin mi,
Tí wọn ò sì pa àwọn àṣẹ mi mọ́,
32 Nígbà náà, màá fi ọ̀pá nà wọ́n nítorí àìgbọ́ràn* wọn,+
Màá sì fi ẹgba nà wọ́n nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
35 Mo ti búra nínú ìjẹ́mímọ́ mi, lẹ́ẹ̀kan láìtún ṣe é mọ́;
Mi ò ní parọ́ fún Dáfídì.+
37 Yóò fìdí múlẹ̀ títí láé bí òṣùpá
Bí ẹlẹ́rìí tó ṣeé gbára lé ní ojú ọ̀run.” (Sélà)
38 Àmọ́ ìwọ fúnra rẹ ti tá a nù, o sì ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀;+
O ti bínú gidigidi sí ẹni àmì òróró rẹ.
39 O ti pa májẹ̀mú rẹ tì, èyí tí o bá ìránṣẹ́ rẹ dá;
O ti sọ adé* rẹ̀ di aláìmọ́ bí o ṣe jù ú sílẹ̀.
40 O ti wó gbogbo àwọn ògiri* olókùúta rẹ̀ lulẹ̀;
O ti sọ àwọn ibi olódi rẹ̀ di àwókù.
41 Gbogbo àwọn tó kọjá ló kó ẹrù rẹ̀ lọ;
Ó ti di ẹni ẹ̀gàn lọ́dọ̀ àwọn aládùúgbò rẹ̀.+
43 Bákan náà, o ò jẹ́ kí idà rẹ̀ wúlò,
O ò sì jẹ́ kó rọ́wọ́ mú lójú ogun.
44 O ti mú kí ọlá ńlá rẹ̀ pa rẹ́,
O sì ti wó ìtẹ́ rẹ̀ mọ́lẹ̀.
45 O ti gé ìgbà ọ̀dọ́ rẹ̀ kúrú;
O ti fi ìtìjú wọ̀ ọ́ láṣọ. (Sélà)
46 Jèhófà, ìgbà wo lo máa fi ara rẹ pa mọ́ dà? Ṣé títí láé ni?+
Ṣé ìbínú ńlá rẹ yóò máa jó lọ bí iná ni?
47 Rántí bí ọjọ́ ayé mi ṣe kúrú tó!+
Ṣé lásán lo dá gbogbo èèyàn ni?
48 Ta ló wà láàyè tí kò ní kú?+
Ṣé ó lè gba ara* rẹ̀ lọ́wọ́ agbára Isà Òkú ni?* (Sélà)
49 Jèhófà, ibo ni ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ti ìgbà àtijọ́ wà,
Èyí tí o búra nípa rẹ̀ fún Dáfídì nínú òtítọ́ rẹ?+
50 Jèhófà, rántí ẹ̀gàn tí wọ́n kó bá ìránṣẹ́ rẹ;
Bí mo ṣe fara da ẹ̀gàn gbogbo èèyàn;*
51 Jèhófà, rántí bí àwọn ọ̀tá rẹ ṣé ń sọ̀kò ọ̀rọ̀;
Bí wọ́n ṣe pẹ̀gàn gbogbo ìṣísẹ̀ ẹni àmì òróró rẹ.
52 Ìyìn ni fún Jèhófà títí láé. Àmín àti Àmín.+