Sáàmù
Sí olùdarí; ti Jédútúnì.* Orin Dáfídì.
62 Ní tòótọ́, mo* dúró jẹ́ẹ́ de Ọlọ́run.
Ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìgbàlà mi ti wá.+
3 Ìgbà wo lẹ máa kọ lu ọkùnrin kan dà kí ẹ lè pa á?+
Gbogbo yín léwu bí ògiri tó dagun, ògiri olókùúta tó ti fẹ́ wó.*
4 Nítorí wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ láti taari rẹ̀ kúrò ní ipò gíga tó wà;*
Wọ́n fẹ́ràn láti máa parọ́.
Wọ́n ń fi ẹnu wọn súre, àmọ́ nínú wọn lọ́hùn-ún, wọ́n ń gégùn-ún.+ (Sélà)
6 Ní tòótọ́, òun ni àpáta mi àti ìgbàlà mi, ibi ààbò mi;
Mìmì kan ò ní mì mí.+
7 Ọwọ́ Ọlọ́run ni ìgbàlà mi àti ògo mi wà.
Ọlọ́run ni àpáta lílágbára àti ibi ààbò mi.+
8 Ẹ gbẹ́kẹ̀ lé e ní gbogbo ìgbà.
Ẹ tú ọkàn yín jáde níwájú rẹ̀.+
Ọlọ́run jẹ́ ibi ààbò fún wa.+ (Sélà)
9 Èémí lásán ni àwọn ọmọ èèyàn,
Ẹ̀tàn ni àwọn ọmọ aráyé.+
Tí a bá gbé gbogbo wọn lórí òṣùwọ̀n, wọ́n fúyẹ́ ju èémí lásán.+
10 Ẹ má rò pé lílọ́ni lọ́wọ́ gbà máa mú kí ẹ ṣàṣeyọrí,
Ẹ má sì rò pé olè jíjà máa ṣe yín láǹfààní.
Tí ọrọ̀ yín bá ń pọ̀ sí i, ẹ má ṣe gbọ́kàn lé e.+
11 Ọlọ́run sọ̀rọ̀, mo sì gbọ́ lẹ́ẹ̀mejì:
Pé agbára jẹ́ ti Ọlọ́run.+