Míkà
6 Ẹ jọ̀ọ́, ẹ gbọ́ ohun tí Jèhófà ń sọ.
Ẹ dìde, ẹ gbé ẹjọ́ yín lọ síwájú àwọn òkè,
Kí àwọn òkè kéékèèké sì gbọ́ ohùn yín.+
2 Ẹ gbọ́ ẹjọ́ Jèhófà, ẹ̀yin òkè
Àti ẹ̀yin ìpìlẹ̀ ayé tó fìdí múlẹ̀,+
Torí Jèhófà fẹ́ pe àwọn èèyàn rẹ̀ lẹ́jọ́;
Yóò sì bá Ísírẹ́lì ro ẹjọ́ pé:+
3 “Ẹ̀yin èèyàn mi, kí ni mo ṣe fún yín?
Kí ni mo ṣe tí ọ̀rọ̀ mi fi sú yín?+
Ẹ sọ ohun tí mo ṣe.
4 Mo mú yín kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì,+
Mo rà yín pa dà lóko ẹrú;+
Mo rán Mósè, Áárónì àti Míríámù sí yín.+
5 Ẹ̀yin èèyàn mi, ẹ jọ̀ọ́, ẹ rántí ohun tí Bálákì ọba Móábù gbèrò+
Àti ohun tí Báláámù ọmọ Béórì fi dá a lóhùn.+
6 Kí ni màá mú wá síwájú Jèhófà?
Kí sì ni màá mú wá tí mo bá wá tẹrí ba fún Ọlọ́run lókè?
Ṣé odindi ẹbọ sísun ni màá gbé wá síwájú rẹ̀,
Àwọn ọmọ màlúù ọlọ́dún kan?+
7 Ṣé inú Jèhófà máa dùn sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àgbò,
Sí ẹgbẹẹgbàárùn-ún ìṣàn òróró?+
8 Ó ti sọ ohun tó dára fún ọ, ìwọ ọmọ aráyé.
Kí sì ni Jèhófà fẹ́ kí o ṣe?*
9 Àwọn èèyàn ìlú náà gbọ́ ohùn Jèhófà;
Àwọn tó ní ọgbọ́n tó gbéṣẹ́ yóò bẹ̀rù orúkọ rẹ.
Ẹ fiyè sí ọ̀pá náà àti ẹni tó yàn án.+
10 Ṣé àwọn ìṣúra tí wọ́n fi ìwà ìkà kó jọ ṣì wà nílé ẹni burúkú
Àti òṣùwọ̀n eéfà* tí kò péye tó ń ríni lára?
13 “Torí náà, màá lù ọ́, màá sì ṣe ọ́ léṣe;+
Màá sọ ọ́ di ahoro torí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.
14 Wàá jẹun àmọ́ o ò ní yó,
Inú rẹ máa ṣófo.+
Tí o bá tiẹ̀ rí nǹkan kó, o ò ní lè kó o lọ,
Tí o bá sì rí i kó lọ, màá fi í fún idà.
15 Wàá fún irúgbìn, àmọ́ o ò ní ká a.
Wàá tẹ ólífì, àmọ́ o ò ní lo òróró rẹ̀;
Wàá ṣe wáìnì tuntun, àmọ́ o ò ní rí wáìnì mu.+
16 Torí ò ń tẹ̀ lé òfin Ómírì àti gbogbo ohun tí wọ́n ṣe ní ilé Áhábù,+
O sì ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn wọn.