Àìsáyà
3 Wò ó! Olúwa tòótọ́, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun,
Ó ń mú gbogbo ìtìlẹ́yìn àtàwọn ohun tí wọ́n nílò ní Jerúsálẹ́mù àti Júdà kúrò,
Gbogbo ìtìlẹ́yìn oúnjẹ àti omi,+
2 Akíkanjú ọkùnrin àti jagunjagun,
Adájọ́ àti wòlíì,+ woṣẹ́woṣẹ́ àtàwọn àgbààgbà,
3 Olórí àádọ́ta (50),+ èèyàn pàtàkì àti agbani-nímọ̀ràn,
Onídán tó gbówọ́ àti atujú tó gbóná.+
4 Àwọn ọmọdékùnrin ni màá fi ṣe olórí wọn,
Àwọn aláìnípinnu* ló sì máa ṣàkóso wọn.
Ọmọdékùnrin máa lu àgbà ọkùnrin,
Ẹni tí wọn ò fi bẹ́ẹ̀ kà sí sì máa fojú di ẹni táwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún.+
6 Kálukú máa mú arákùnrin rẹ̀ nínú ilé bàbá rẹ̀, á sì sọ pé:
“O ní aṣọ àwọ̀lékè, wá ṣe olórí wa.
Jẹ́ kí àwókù ibi tí a ṣẹ́gun yìí wà níkàáwọ́ rẹ.”
7 Àmọ́ ó máa kọ̀ jálẹ̀ ní ọjọ́ yẹn pé:
“Mi ò ní wẹ ọgbẹ́ rẹ;*
Mi ò ní oúnjẹ tàbí aṣọ nínú ilé mi.
Ẹ má fi mí ṣe olórí àwọn èèyàn náà.”
Wọ́n* gbé, torí wọ́n ń mú àjálù wá sórí ara wọn!
11 Ẹni burúkú gbé!
Àjálù máa dé bá a,
Torí ohun tó fi ọwọ́ ara rẹ̀ ṣe ni wọ́n máa ṣe fún un!
12 Ní ti àwọn èèyàn mi, àwọn tó ń kó wọn ṣiṣẹ́ ń fìyà jẹ wọ́n,
Àwọn obìnrin sì ń jọba lé wọn lórí.
Ẹ̀yin èèyàn mi, àwọn olórí yín ń mú kí ẹ rìn gbéregbère,
Wọ́n sì ń da ọ̀nà rú mọ́ yín lójú.+
13 Jèhófà dúró sí àyè rẹ̀ láti fẹ̀sùn kàn wọ́n;
Ó dìde dúró láti ṣèdájọ́ àwọn èèyàn.
14 Jèhófà máa dá àwọn àgbààgbà àtàwọn olórí àwọn èèyàn rẹ̀ lẹ́jọ́.
“Ẹ ti dáná sun ọgbà àjàrà.
Ohun tí ẹ jí lọ́dọ̀ aláìní sì wà nínú àwọn ilé yín.+
15 Kí ló kì yín láyà tí ẹ fi ń tẹ àwọn èèyàn mi rẹ́,
Tí ẹ sì ń fi ojú àwọn aláìní gbolẹ̀?”+ ni Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.
16 Jèhófà sọ pé: “Torí pé àwọn ọmọbìnrin Síónì ń gbéra ga,
Tí wọ́n ń gbé orí wọn sókè* bí wọ́n ṣe ń rìn,
Tí wọ́n ń sejú, tí wọ́n sì ń ṣakọ lọ,
Wọ́n ń mú kí ẹ̀gbà ẹsẹ̀ wọn máa dún woroworo,
17 Jèhófà tún máa fi èépá kọ lu àwọn ọmọbìnrin Síónì ní orí,
Jèhófà sì máa mú kí iwájú orí wọn pá.+
18 Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà ò ní mú kí àwọn ẹ̀gbà ọwọ́ àti ẹsẹ̀ wọn rẹwà mọ́,
Àwọn aṣọ ìwérí àtàwọn ohun ọ̀ṣọ́ tó rí bí òṣùpá,+
19 Àwọn yẹtí,* àwọn ẹ̀gbà ọwọ́ àti ìbòjú,
20 Àwọn ìwérí, àwọn ẹ̀gbà ẹsẹ̀ àtàwọn ọ̀já ìgbàyà,*
Àwọn ìgò lọ́fínńdà* àtàwọn oògùn,*
21 Àwọn òrùka ọwọ́ àti òrùka imú,
22 Àwọn aṣọ oyè, àwọn aṣọ àwọ̀lékè, àwọn aṣọ ìlékè àtàwọn àpò,
23 Àwọn dígí ọwọ́+ àtàwọn aṣọ ọ̀gbọ̀,*
Àwọn láwàní àtàwọn ìbòjú.