Orí Karùn-ún
Jèhófà Tẹ́ Àwọn Agbéraga
1, 2. Èé ṣe tí iṣẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ tí Aísáyà jẹ́ fáwọn Júù ayé tirẹ̀ fi gbàfiyèsí wa?
IPÒ tí Jerúsálẹ́mù àti Júdà wà tojú sú Aísáyà ló bá yíjú sí Jèhófà Ọlọ́run pé: “Ìwọ ti ṣá àwọn ènìyàn rẹ, ilé Jékọ́bù tì.” (Aísáyà 2:6a) Kí ló fà á tí Ọlọ́run fi kọ àwọn ènìyàn tí òun fúnra rẹ̀ yàn gẹ́gẹ́ bí “àkànṣe dúkìá” sílẹ̀?—Diutarónómì 14:2.
2 Bí Aísáyà ṣe bẹnu àtẹ́ lu àwọn Júù ìgbà tirẹ̀ gbàfiyèsí wa gidigidi. Èé ṣe? Nítorí pé ipò tí Kirisẹ́ńdọ̀mù wà lónìí jọ tàwọn ènìyàn Aísáyà gan-an ni, irú ìdájọ́ kan náà sì ni Jèhófà ṣe. Bí a bá fiyè sí ohun tí Aísáyà kéde, yékéyéké la óò lóye ohun tí Ọlọ́run lòdì sí, yóò sì jẹ́ kí a kọ àwọn ìwà tí Ọlọ́run kò fẹ́. Nígbà náà, ẹ jẹ́ kí a tara ṣàṣà gbé ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Jèhófà tó wà nínú Aísáyà 2:6–4:1 yẹ̀ wò.
Tìrera-tìrera Ni Wọ́n Ń Tẹrí Ba
3. Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni Aísáyà ń jẹ́wọ́ pé àwọn ènìyàn òun ṣẹ̀?
3 Aísáyà ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn rẹ̀ pé: “Wọ́n ti kún fún ohun tí ó ti Ìlà-Oòrùn wá, wọ́n sì jẹ́ pidánpidán bí àwọn Filísínì, àwọn ọmọ ará ilẹ̀ òkèèrè sì pọ̀ gidigidi nínú wọn.” (Aísáyà 2:6b) Nǹkan bí ẹgbẹ̀rin ọdún ṣáájú ìgbà yẹn ni Jèhófà ti pàṣẹ fún àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ má ṣe sọ ara yín di aláìmọ́ nípa èyíkéyìí nínú nǹkan wọ̀nyí, [nípa èyí tí] àwọn orílẹ̀-èdè tí èmi yóò rán kúrò níwájú yín fi sọ ara wọn di aláìmọ́.” (Léfítíkù 18:24) Jèhófà mú kí Báláámù sọ nípa àwọn tóun yàn gẹ́gẹ́ bí àkànṣe dúkìá òun pé: “Láti orí àwọn àpáta ni mo ti rí wọn, láti àwọn òkè kéékèèké ni mo sì ti rí wọn. Wọ́n pàgọ́ síbẹ̀ ní àdádó gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn kan, wọn kò sì ka ara wọn mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè.” (Númérì 23:9, 12) Síbẹ̀síbẹ̀, nígbà tó fi máa dayé Aísáyà, àwọn àyànfẹ́ Jèhófà tí bẹ̀rẹ̀ sí hu ìwàkiwà àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká, wọ́n sì ti “kún fún ohun tí ó ti Ìlà-Oòrùn wá.” Dípò kí wọ́n gba Jèhófà àti ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́, wọ́n di “pidánpidán bí àwọn Filísínì.” Ilẹ̀ náà kò ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ kúrò láàárín àwọn orílẹ̀-èdè rárá ni, kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni “àwọn ọmọ ará ilẹ̀ òkèèrè . . . pọ̀ gidigidi nínú wọn”—ó dájú pé àwọn ará ilẹ̀ òkèèrè wọ̀nyí ló kó ìwàkiwà ran àwọn ènìyàn Ọlọ́run.
4. Dípò kí ọrọ̀ àti ohun ìjà alágbára tí àwọn Júù ní mú kí wọ́n fọpẹ́ fún Jèhófà, ipa wo ló ní lórí wọn?
4 Bí Aísáyà ṣe kíyè sí ọrọ̀ ajé Júdà tó ń búrẹ́kẹ, àti ohun ìjà alágbára tí wọ́n ní nígbà náà, lábẹ́ Ùsáyà Ọba, ó ní: “Ilẹ̀ wọn sì kún fún fàdákà àti wúrà, ìṣúra wọn kò sì lópin. Ilẹ̀ wọn sì kún fún ẹṣin, kẹ̀kẹ́ ẹṣin wọn kò sì lópin.” (Aísáyà 2:7) Ǹjẹ́ àwọn èèyàn wọ̀nyẹn dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ọrọ̀ àti ohun ìjà alágbára tí wọ́n ní? (2 Kíróníkà 26:1, 6-15) Rárá o! Kàkà bẹ́ẹ̀, ọrọ̀ yẹn gan-an ni wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé, wọ́n sì wá kẹ̀yìn sí Jèhófà Ọlọ́run, Ẹni tó pèsè rẹ̀. Kí ni àbájáde rẹ̀? “Ilẹ̀ wọn sì kún fún àwọn ọlọ́run tí kò ní láárí. Iṣẹ́ ọwọ́ ara ẹni sì ni wọ́n ń tẹrí ba fún, èyí tí ìka ara ẹni ṣe. Ará ayé sì tẹrí ba, ènìyàn sì di rírẹ̀sílẹ̀, ìwọ kò sì lè dárí jì wọ́n rárá.” (Aísáyà 2:8, 9) Wọ́n kẹ̀yìn sí Ọlọ́run alààyè, wọ́n wá ń tẹrí ba fáwọn ère aláìlẹ́mìí.
5. Èé ṣe tí títẹríba fún àwọn òrìṣà kò fi jẹ́ àmì ìrẹ̀lẹ̀?
5 Títẹríba lè jẹ́ àmì ìrẹ̀lẹ̀. Àmọ́, asán ni títẹríba fáwọn nǹkan aláìlẹ́mìí jẹ́, ńṣe ló ń mú kí abọ̀rìṣà náà di “rírẹ̀sílẹ̀,” kó dẹni yẹ̀yẹ́. Báwo ni Jèhófà ṣe wá lè dárí irú ẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀ jini? Kí ni àwọn abọ̀rìṣà wọ̀nyí yóò ṣe nígbà tí Jèhófà bá pè wọ́n wá jẹ́jọ́?
‘Ojú Ìrera Yóò Di Rírẹ̀sílẹ̀’
6, 7. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ sí àwọn agbéraga lọ́jọ́ ìdájọ́ Jèhófà? (b) Orí kí ni àti ta ni ìbínú Jèhófà dé sí, èé sì ti ṣe?
6 Aísáyà ń bọ́rọ̀ lọ pé: “Wọ inú àpáta, kí o sì fi ara rẹ pa mọ́ sínú ekuru nítorí ìbẹ̀rùbojo fún Jèhófà, àti kúrò lójú ìlọ́lájù rẹ̀ gígọntíọ.” (Aísáyà 2:10) Ṣùgbọ́n kò ní sí àpáta tó tóbi tó láti dáàbò bò wọ́n, kò sóhun tó nípọn tó láti fi wọ́n pa mọ́ kúrò lójú Jèhófà, Olódùmarè. Nígbà tó bá gbé ìdájọ́ rẹ̀ dé, “ojú ìrera ará ayé yóò di rírẹ̀sílẹ̀, ìgafíofío àwọn ènìyàn yóò sì tẹrí ba; Jèhófà nìkan ṣoṣo sì ni a óò gbé ga ní ọjọ́ yẹn.”—Aísáyà 2:11.
7 “Ọjọ́ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun” ń bọ̀. Yóò jẹ́ àkókò tí ìbínú Ọlọ́run yóò dé sórí “gbogbo kédárì ti Lẹ́bánónì tí ó ga fíofío, tí a sì gbé ga àti lórí gbogbo igi ràgàjì Báṣánì; àti lórí gbogbo òkè ńlá gíga fíofío àti lórí gbogbo òkè kéékèèké tí a gbé ga; àti lórí gbogbo ilé gogoro tí ó ga àti lórí gbogbo ògiri olódi; àti lórí gbogbo ọkọ̀ òkun Táṣíṣì àti lórí gbogbo ọkọ̀ ojú omi fífani-lọ́kàn-mọ́ra.” (Aísáyà 2:12-16) Bẹ́ẹ̀ ni o, gbogbo àjọ tí ènìyàn dá sílẹ̀ láti lè máa fi yangàn, àti gbogbo àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run ni yóò gbàfiyèsí lọ́jọ́ ìrunú Jèhófà. Nípa báyìí, “ìrera ará ayé yóò . . . tẹrí ba, ìgafíofío àwọn ènìyàn yóò sì di rírẹ̀sílẹ̀; Jèhófà nìkan ṣoṣo sì ni a óò gbé ga ní ọjọ́ yẹn.”—Aísáyà 2:17.
8. Báwo ni ọjọ́ ìdájọ́ tí àsọtẹ́lẹ̀ sọ ṣe dé sórí Jerúsálẹ́mù lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa?
8 Ọdún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa lọjọ́ ìdájọ́ tí àsọtẹ́lẹ̀ yẹn sọ dé sórí àwọn Júù, nígbà tí Nebukadinésárì ọba Bábílónì pa Jerúsálẹ́mù run. Níṣojú àwọn èèyàn ibẹ̀ ni iná ṣe ń sọ làù látinú ìlú wọn ọ̀wọ́n, tí wọ́n wó àwọn ilé ńláńlá ibẹ̀ palẹ̀, tí wọ́n sì bi odi rẹ̀ gìrìwò ṣubú. Wọ́n fọ́ tẹ́ńpìlì Jèhófà túútúú. Dúkìá wọn àti kẹ̀kẹ́ ogun wọn kò já mọ́ nǹkan kan ní “ọjọ́ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun.” Àwọn ère wọn wá ńkọ́? Ohun tí Aísáyà wí gan-an ló ṣẹlẹ̀: “Àní àwọn ọlọ́run tí kò ní láárí yóò kọjá lọ pátápátá.” (Aísáyà 2:18) Wọ́n kó àwọn Júù—títí kan àwọn ọmọ aládé àti alágbára—lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì. Àádọ́rin ọdún ni Jerúsálẹ́mù yóò fi wà ní ahoro.
9. Ọ̀nà wo ni ipò Kirisẹ́ńdọ̀mù fi jọ ti Jerúsálẹ́mù àti ti Júdà ọjọ́ Aísáyà?
9 Ipò Kirisẹ́ńdọ̀mù mà kúkú jọ ti Júdà àti ti Jerúsálẹ́mù ayé Aísáyà o! Kùrùkẹrẹ Kirisẹ́ńdọ̀mù pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè ayé yìí ti pọ̀ jù. Tìtara-tìtara ló ń ṣètìlẹyìn fún àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, ó sì kó ère àti àwọn ìṣe tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu kún ilé rẹ̀ fọ́fọ́. Onífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì làwọn ọmọ ìjọ rẹ̀, agbára ohun ìjà sì ni wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé. Wọn kò ha sì ń ka àwọn àlùfáà wọn sí ọlọ́lá jù lọ, tí wọ́n ń sọ wọ́n di olóyè àti ẹni ọ̀wọ̀? Ìgbéraga Kirisẹ́ńdọ̀mù yóò wọlẹ̀ dájúdájú. Ṣùgbọ́n ìgbà wo ni?
“Ọjọ́ Jèhófà” Tó Rọ̀ Dẹ̀dẹ̀
10. “Ọjọ́ Jèhófà” wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti Pétérù tọ́ka sí?
10 Ìwé Mímọ́ tọ́ka sí “ọjọ́ Jèhófà” kan tí yóò tún ṣe pàtàkì gan-an ju ọjọ́ ìdájọ́ tó dé bá Jerúsálẹ́mù àti Júdà àtijọ́. Lábẹ́ ìmísí, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi hàn pé “ọjọ́ Jèhófà” tí ń bọ̀ yóò dé nígbà wíwà níhìn-ín Jésù Kristi Ọba tí ń bẹ lórí ìtẹ́. (2 Tẹsalóníkà 2:1, 2) Pétérù sọ pé ọjọ́ yẹn yóò dé nígbà ìgbékalẹ̀ ‘ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun nínú èyí tí òdodo yóò máa gbé.’ (2 Pétérù 3:10-13) Ọjọ́ yẹn ni Jèhófà yóò ṣèdájọ́ gbogbo ètò àwọn nǹkan búburú yìí, títí kan Kirisẹ́ńdọ̀mù.
11. (a) Ta ni yóò “lè dúró lábẹ́” “ọjọ́ Jèhófà” tí ń bọ̀? (b) Báwo ni a ṣe lè fi Jèhófà ṣe ibi ìsádi wa?
11 Wòlíì Jóẹ́lì sọ pé: “Págà fún ọjọ́ náà; nítorí ọjọ́ Jèhófà sún mọ́lé, yóò sì dé gẹ́gẹ́ bí ìfiṣèjẹ láti ọ̀dọ̀ Ẹni tí í ṣe Olódùmarè!” Lójú bí “ọjọ́” náà ṣe rọ̀ dẹ̀dẹ̀ yìí, ǹjẹ́ kò yẹ kí ọ̀ràn ààbò lákòókò yẹn jẹ gbogbo ènìyàn lógún? Jóẹ́lì béèrè pé: ‘Ta ni ó lè dúró lábẹ́ rẹ̀?’ Ó wá dáhùn pé: “Jèhófà yóò jẹ́ ibi ìsádi fún àwọn ènìyàn rẹ̀.” (Jóẹ́lì 1:15; 2:11; 3:16) Ṣé Jèhófà Ọlọ́run yóò wá jẹ́ ibi ìsádi fún àwọn agbéraga tó gbẹ́kẹ̀ wọn lé ọrọ̀, ohun ìjà alágbára, àti àwọn ọlọ́run àtọwọ́dá? Ká má rí i! Ọlọ́run kọ àwọn ènìyàn tó jẹ́ àyànfẹ́ rẹ̀ pàápàá sílẹ̀ nígbà tí wọ́n ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Ó mà wá ṣe pàtàkì gan-an o, pé kí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run “wá òdodo,” kí wọ́n “wá ọkàn-tútù,” kí wọ́n sì gbé ipò tí wọ́n fi ìjọsìn Jèhófà sí láyé wọn yẹ̀ wò gidigidi!—Sefanáyà 2:2, 3.
“Sí Asín àti sí Àdán”
12, 13. Èé ṣe tó fi bá a mu pé kí àwọn abọ̀rìṣà ju àwọn òrìṣà wọn “sí asín àti sí àdán” lọ́jọ́ Jèhófà?
12 Irú ojú wo ni àwọn abọ̀rìṣà yóò fi wo àwọn òrìṣà wọn lọ́jọ́ ńlá Jèhófà? Aísáyà dáhùn pé: “Àwọn ènìyàn yóò sì wọ inú hòrò àpáta àti inú ihò ekuru nítorí ìbẹ̀rùbojo fún Jèhófà àti kúrò nínú ìlọ́lájù rẹ̀ gígọntíọ, nígbà tí ó bá dìde kí ilẹ̀ ayé lè gbọ̀n rìrì. Ní ọjọ́ yẹn, ará ayé yóò ju àwọn ọlọ́run fàdákà tí kò ní láárí àti àwọn ọlọ́run wúrà tí kò ní láárí . . . sí asín àti sí àdán, kí ó lè wọ inú ihò àwọn àpáta àti pàlàpálá àwọn àpáta gàǹgà, nítorí ìbẹ̀rùbojo fún Jèhófà àti kúrò nínú ìlọ́lájù rẹ̀ gígọntíọ, nígbà tí ó bá dìde kí ilẹ̀ ayé lè gbọ̀n rìrì. Fún ire ara yín, ẹ fà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ ará ayé, ẹni tí èémí rẹ̀ wà ní ihò imú rẹ̀, nítorí ìdí wo ni a ó fi ka òun fúnra rẹ̀ sí?”—Aísáyà 2:19-22.
13 Inú ihò ilẹ̀ lasín ń gbé, àwọn àdán sì ń rọ̀ sínú àwọn hòrò ibi ahoro tó ṣókùnkùn. Ẹ̀wẹ̀, òórùn burúkú ló máa ń wà nínú ibi tí àwọn àdán púpọ̀ bá so rọ̀ sí, tí ìgbẹ́ wọn a sì ga gèlètè síbẹ̀. Irú ibẹ̀ gan-an ló yẹ láti ju àwọn òrìṣà sí. Ibi òkùnkùn àti àìmọ́ nìkan ló yẹ wọ́n. Inú ihò àti pàlàpálá àpáta làwọn èèyàn yẹn yóò lọ sá pa mọ́ sí ní tiwọn, lọ́jọ́ ìdájọ́ Jèhófà. Nípa báyìí, ohun kan náà tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn òrìṣà náà ni yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí ń bọ wọ́n. Bí Aísáyà ṣe wí lóòótọ́, àwọn òrìṣà aláìlẹ́mìí kò gba àwọn tí ń bọ wọ́n, kò sì gba Jerúsálẹ́mù sílẹ̀ lọ́wọ́ Nebukadinésárì lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa.
14. Kí ni àwọn èèyàn tó gbé ìrònú wọn ka nǹkan ti ayé yóò ṣe lọ́jọ́ ìdájọ́ Jèhófà tí ń bọ̀ wá sórí ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé?
14 Kí làwọn èèyàn máa ṣe lọ́jọ́ ìdájọ́ Jèhófà tí ń bọ̀ wá sórí Kirisẹ́ńdọ̀mù àti gbogbo apá yòókù nínú ètò ìsìn èké àgbáyé? Ó jọ pé bí àwọn èèyàn ṣe ń rí i pé ipò àwọn nǹkan túbọ̀ ń burú sí i kárí ayé, ọ̀pọ̀ jù lọ ni yóò wá rí i pé òrìṣà àwọn kò wúlò. Wọ́n lè wá bẹ̀rẹ̀ sí wá ibi ìsádi àti ààbò nínú àwọn àjọ tó jẹ́ ti ayé, tí kò jẹ mọ́ ti ẹ̀sìn, bóyá títí kan Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè tí í ṣe “ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò” inú Ìṣípayá orí kẹtàdínlógún. “Ìwo mẹ́wàá” ẹranko ìṣàpẹẹrẹ yìí ni yóò pa Bábílónì Ńlá, ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé, tí Kirisẹ́ńdọ̀mù jẹ́ apá pàtàkì nínú rẹ̀, run.—Ìṣípayá 17:3, 8-12, 16, 17.
15. Báwo ni yóò ṣe jẹ́ pé Jèhófà nìkan “ni a óò gbé ga” lọ́jọ́ ìdájọ́ rẹ̀?
15 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwo mẹ́wàá ìṣàpẹẹrẹ wọ̀nyẹn ló máa fọwọ́ ara wọn pa Bábílónì Ńlá run, tí wọn yóò sì sun ún, ní tòdodo, ìdájọ́ Jèhófà ló dé sórí rẹ̀. Ìṣípayá 18:8 sọ nípa Bábílónì Ńlá pé: “Ìdí nìyẹn tí àwọn ìyọnu àjàkálẹ̀ rẹ̀, ikú àti ọ̀fọ̀ àti ìyàn, yóò fi dé ní ọjọ́ kan ṣoṣo, a ó sì fi iná sun ún pátápátá, nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run, ẹni tí ó ṣèdájọ́ rẹ̀, jẹ́ alágbára.” Nítorí náà, Jèhófà Ọlọ́run, Olódùmarè, ni ìyìn yẹ, fún dídá tó dá aráyé nídè kúrò lábẹ́ ìsìn èké tó jẹ gàba lé wọn lórí. Gẹ́gẹ́ bí Aísáyà ṣe sọ, “Jèhófà nìkan ṣoṣo . . . ni a óò gbé ga ní ọjọ́ yẹn. Nítorí ọjọ́ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ni.”—Aísáyà 2:11b, 12a.
‘Àwọn Aṣáájú Ń Mú Kí O Rìn Gbéregbère’
16. (a) Kí ló para pọ̀ jẹ́ “ìtìlẹyìn àti amóhundúró” fún àwùjọ ènìyàn? (b) Báwo ni ìyà yóò ṣe jẹ àwọn ènìyàn Aísáyà nítorí ìmúkúrò ohun tó jẹ́ “ìtìlẹyìn àti amóhundúró” fún àwùjọ wọn?
16 Kí àwùjọ ènìyàn tó lè tòrò, ó ní láti ní “ìtìlẹyìn àti amóhundúró,” ìyẹn ni, àwọn ohun kòṣeémánìí bí oúnjẹ àti omi, àti ní pàtàkì, ó ní láti ní àwọn aṣáájú tó ṣeé fọkàn tán, tó lè tọ́ àwọn ènìyàn sọ́nà, kí wọ́n sì mú kí àwùjọ wà létòlétò. Àmọ́ o, Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa Ísírẹ́lì àtijọ́ pé: “Wò ó! Olúwa tòótọ́, Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, yóò mú ìtìlẹyìn àti amóhundúró kúrò ní Jerúsálẹ́mù àti Júdà, gbogbo ìtìlẹyìn oúnjẹ àti gbogbo ìtìlẹyìn omi, alágbára ńlá àti jagunjagun, onídàájọ́ àti wòlíì, woṣẹ́woṣẹ́ àti àgbàlagbà, olórí àádọ́ta àti ẹni tí a bọ̀wọ̀ fún gidigidi àti agbani-nímọ̀ràn àti ògbógi nínú idán pípa, àti ọ̀jáfáfá atujú.” (Aísáyà 3:1-3) Ọmọdékùnrin lásán-làsàn yóò di ọmọ aládé, ìkùgbù ni yóò sì máa fi ṣàkóso. Kì í ṣe pé àwọn alákòóso yóò máa tẹ àwọn èèyàn lórí ba nìkan, ṣùgbọ́n “àwọn ènìyàn náà yóò . . . máa fi ìkà gbo ẹnì kìíní-kejì mọ́lẹ̀ ní ti tòótọ́ . . . Wọn yóò fi ipá rọ́ lura, ọmọdékùnrin lu àgbà ọkùnrin, àti ẹni tí a kò fi bẹ́ẹ̀ kà sí lu ẹni tí a bọlá fún.” (Aísáyà 3:4, 5) Àwọn ọmọdé yóò “fipá rọ́” lu àwọn àgbà wọn, láìbọ̀wọ̀ fún wọn. Ayé yóò bàjẹ́ débi pé ẹnì kan yóò máa sọ fún ẹnì kejì rẹ̀ tí kò tóótun láti ṣàkóso pé: “Ìwọ ní aṣọ àlàbora. Apàṣẹwàá ni ó yẹ kí o jẹ́ fún wa, kí àgbájọ ènìyàn tí a bì ṣubú yìí sì wà lábẹ́ ọwọ́ rẹ.” (Aísáyà 3:6) Ṣùgbọ́n àwọn tí wọ́n ké sí yẹn yóò kọ̀, wọ́n ó sọ pé apá àwọn ò ká iṣẹ́ wíwo ọgbẹ́ ilẹ̀ yẹn sàn rárá, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ò ní ọrọ̀ tí wọn ó fi ṣe ojúṣe yẹn. Wọn ó sọ pé: “Èmi kì yóò di olùwẹ ọgbẹ́; kò sì sí oúnjẹ tàbí aṣọ àlàbora nínú ilé mi. Kí ẹ má fi mí ṣe apàṣẹwàá lé àwọn ènìyàn lórí.”—Aísáyà 3:7.
17. (a) Ọ̀nà wo ni àwọn ẹ̀ṣẹ̀ Jerúsálẹ́mù àti ti Júdà fi dà “bí ti Sódómù”? (b) Ta ni Aísáyà di ẹ̀bi ipò tí àwọn ènìyàn rẹ̀ wà rù?
17 Aísáyà ń bọ́rọ̀ lọ pé: “Jerúsálẹ́mù ti kọsẹ̀, Júdà alára sì ti ṣubú, nítorí pé ahọ́n wọn àti ìbánilò wọn wà ní ìlòdìsí Jèhófà, ní híhùwà ọ̀tẹ̀ ní ojú ògo rẹ̀. Àní ìrísí ojú wọn ń jẹ́rìí lòdì sí wọn ní ti gidi, ó sì ń sọ nípa ẹ̀ṣẹ̀ wọn, bí ti Sódómù. Kò fi í pa mọ́. Ègbé ni fún ọkàn wọn! Nítorí pé wọ́n ti pín ìyọnu àjálù fún ara wọn.” (Aísáyà 3:8, 9) Àtọ̀rọ̀ àtìṣe làwọn ènìyàn Ọlọ́run fi ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run tòótọ́. Àní ìrísí àìnítìjú àti àìronúpìwàdà tó hàn lójú wọn gan-an ń fi ẹ̀ṣẹ̀ wọn hàn, ẹ̀ṣẹ̀ tó ríni lára bíi ti Sódómù gẹ́lẹ́. Lóòótọ́ ni Jèhófà Ọlọ́run ti bá wọn dá májẹ̀mú, síbẹ̀ kò ní tìtorí wọn yí ọ̀pá ìdiwọ̀n rẹ̀ padà. “Yóò dára fún olódodo, nítorí pé wọn yóò jẹ èso ìbánilò wọn. Ègbé ni fún ẹni burúkú!—Ìyọnu àjálù; nítorí pé ìlòsíni tí ọwọ́ òun fúnra rẹ̀ fi báni lò ni a ó fi bá a lò! Ní ti àwọn ènìyàn mi, àwọn apínṣẹ́fúnni rẹ̀ ń báni lò lọ́nà mímúná, àní obìnrin sì ni ó ń ṣàkóso lé e lórí ní ti tòótọ́. Ẹ̀yin ènìyàn mi, àwọn tí ń ṣamọ̀nà rẹ lọ ń mú kí o rìn gbéregbère, wọ́n sì ti da ipa àwọn ọ̀nà rẹ rú.”—Aísáyà 3:10-12.
18. (a) Ìdájọ́ wo ni Jèhófà kéde sórí àwọn àgbàlagbà àti àwọn ọmọ aládé ayé Aísáyà? (b) Ẹ̀kọ́ wo ni ìdájọ́ tí Jèhófà ṣe fún àwọn àgbàlagbà àti àwọn ọmọ aládé kọ́ wa?
18 Jèhófà “ṣe ìdájọ́” àwọn àgbàlagbà àti ọmọ aládé Júdà, ó sì “wọnú ìdájọ́” pé: “Ẹ̀yin fúnra yín sì ti sun ọgbà àjàrà kanlẹ̀. Ohun tí a fi ìjanilólè gbà lọ́wọ́ ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ wà nínú ilé yín. Kí ni ẹ ní lọ́kàn, ní ti pé ẹ tẹ àwọn ènìyàn mi rẹ́, àti pé ojú àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ ni ẹ fi ń gbolẹ̀?” (Aísáyà 3:13-15) Dípò kí àwọn aṣáájú máa wá ire àwọn èèyàn wọn, ìwà bìrìbìrì ni wọ́n ń hù. Wọ́n ń ṣi agbára wọn lò nípa dídi agbàlọ́wọ́mérìí, tó ń du àwọn tálákà àti aláìní ní ẹ̀tọ́ wọn. Àmọ́, àwọn aṣáájú wọ̀nyí ní láti jẹ́jọ́ níwájú Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun fún títẹ̀ tí wọ́n ń tẹ ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ lórí ba. Ìkìlọ̀ ńlá mà lèyí jẹ́ fáwọn tó wà nípò ẹrù iṣẹ́ lónìí o! Ǹjẹ́ kí wọ́n máa ṣọ́ra nígbà gbogbo kí wọ́n má ṣe ṣi agbára wọn lò.
19. Ìtẹ̀lóríba àti inúnibíni wo ni Kirisẹ́ńdọ̀mù ti ń ṣe?
19 Kirisẹ́ńdọ̀mù—pàápàá àwùjọ àlùfáà àtàwọn sàràkí-sàràkí inú rẹ̀—ti fọ̀nà èrú gba ọ̀pọ̀ nǹkan tó yẹ kó jẹ́ tàwọn mẹ̀kúnnù, àwọn ẹni tó ti ń tẹ̀ lórí ba bọ̀ láìṣíwọ́ títí di ìsinsìnyí. Ó tún ń lu àwọn ènìyàn Ọlọ́run, ó ń ṣenúnibíni sí wọn, ó ń fojú wọn rí màbo, ó sì tún kẹ́gàn ńlá bá orúkọ Jèhófà. Bó bá tákòókò lójú Jèhófà, ìdájọ́ rẹ̀ yóò dé sí i lórí.
“Àpá Àmì Dípò Ẹwà Ojú”
20. Èé ṣe tí Jèhófà fi bẹnu àtẹ́ lu “àwọn ọmọbìnrin Síónì”?
20 Lẹ́yìn tí Jèhófà bẹnu àtẹ́ lu ìwà àìtọ́ àwọn aṣáájú tán, ó yíjú sí àwọn obìnrin Síónì, tàbí Jerúsálẹ́mù. Ó dájú pé oge ṣíṣe ló sún “àwọn ọmọbìnrin Síónì” débi lílo “ẹ̀gbà ẹsẹ̀” tó ń dún woroworo. Àwọn obìnrin yẹn a máa kasẹ̀ rìn, wọn a “rin ìrìn oge,” wọn a máa rera. Èwo ló wá burú nínú ìyẹn? Ìwà àwọn obìnrin yẹn ni. Jèhófà sọ pé: “Àwọn ọmọbìnrin Síónì ti di onírera, tí wọ́n sì ń rìn pẹ̀lú ọ̀fun nínà síwájú, tí wọ́n sì ń sejú.” (Aísáyà 3:16) Wọn kò ru ìwà ìrera yẹn là.
21. Ipa wo ni ìdájọ́ Jèhófà lórí Jerúsálẹ́mù ní lórí àwọn obìnrin Júù?
21 Nípa bẹ́ẹ̀, nígbà tí ìdájọ́ Jèhófà bá dé sórí ilẹ̀ náà, gbogbo nǹkan wọ̀nyí pátá làwọn onírera “ọmọbìnrin Síónì” yóò pàdánù—títí kan ẹwà tí wọ́n fi ń yangàn pàápàá. Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Jèhófà pẹ̀lú yóò mú kí àtàrí àwọn ọmọbìnrin Síónì ní ẹ̀yi ní tòótọ́, Jèhófà yóò sì tú iwájú orí wọn gan-an sí borokoto. Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà yóò mú ẹwà àwọn ẹ̀gbà ọrùn ẹsẹ̀ kúrò àti ọ̀já ìwérí àti àwọn ohun ọ̀ṣọ́ onírìísí òṣùpá, àwọn yẹtí jọlọjọlọ àti júfù àti ìbòjú, àwọn ìwérí àti ẹ̀gbà ẹsẹ̀ àti ọ̀já ìgbàyà àti ‘àwọn ilé ọkàn’ [bóyá orùba lọ́fínńdà] àti àwọn karawun àfiṣọ̀ṣọ́ tí ń kùn bí oyin [tàbí, ońdè], òrùka ọwọ́ àti òrùka imú, aṣọ ìgúnwà àti àwọ̀lékè àti aṣọ ìlékè àti àpò, àti dígí ọwọ́ àti ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ àti láwàní àti ìbòjú ńlá.” (Aísáyà 3:17-23; wó àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW.) Àyípadà burúkú gbáà lèyí o!
22. Kí ni àwọn obìnrin Jerúsálẹ́mù tún pàdánù yàtọ̀ sí ohun ọ̀ṣọ́ wọn?
22 Ìhìn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ń bá a lọ pé: “Dípò òróró básámù, kìkì òórùn dídìkàsì ni yóò wà; àti dípò ìgbànú, ìjàrá ni yóò wà; àti dípò ìṣètò irun lọ́nà rèǹtèrente, orí pípá ni yóò wà; àti dípò ẹ̀wù olówó ńlá, sísán aṣọ àpò ìdọ̀họ ni yóò wà; àpá àmì dípò ẹwà ojú.” (Aísáyà 3:24) Àwọn agbéraga obìnrin Jerúsálẹ́mù kúrò nípò ọlá, wọ́n di òtòṣì lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa. Wọ́n pàdánù òmìnira wọn, wọ́n sì gba “àpá àmì” ìsìnrú.
“Ṣe Ni A Ó Gbá A Dànù”
23. Kí ni Jèhófà kéde nípa Jerúsálẹ́mù?
23 Jèhófà wá dojú ọ̀rọ̀ kọ ìlú ńlá Jerúsálẹ́mù, ó kéde pé: “Àwọn ọkùnrin rẹ yóò ti ipa idà ṣubú, agbára ńlá rẹ yóò sì ti ipa ogun ṣubú. Ó dájú pé àwọn ẹnu ọ̀nà rẹ̀ yóò ṣọ̀fọ̀, wọn yóò sì kárísọ, ṣe ni a ó sì gbá a dànù. Òun yóò jókòó sí ilẹ̀ pẹ̀pẹ̀.” (Aísáyà 3:25, 26) Ojú ogun làwọn ọkùnrin Jerúsálẹ́mù yóò kú sí, àti àwọn alágbára rẹ̀ pàápàá. Ṣe ni wọ́n máa wó ìlú náà palẹ̀ bẹẹrẹ. “Àwọn ẹnu ọ̀nà rẹ̀ yóò ṣọ̀fọ̀,” tí “wọn yóò sì kárísọ” lákòókò náà. Ṣe ni wọ́n máa “gbá” Jerúsálẹ́mù “dànù,” wọn yóò sì sọ ọ́ dahoro.
24. Ọ̀ràn ńlá wo ni pípa tí idà pa àwọn ọkùnrin dànù dá sílẹ̀ fáwọn obìnrin Jerúsálẹ́mù?
24 Pípa tí idà pa àwọn ọkùnrin dànù máa dá ọ̀ràn ńláǹlà sílẹ̀ fáwọn obìnrin Jerúsálẹ́mù. Nígbà tí Aísáyà ń kásẹ̀ apá ìwé àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ yìí nílẹ̀, ó sàsọtẹ́lẹ̀ pé: “Obìnrin méje yóò sì rá ọkùnrin kan mú ní ọjọ́ yẹn ní ti tòótọ́, wọn yóò sì wí pé: ‘Oúnjẹ tiwa ni àwa yóò máa jẹ, aṣọ àlàbora tiwa sì ni àwa yóò máa wọ̀; kìkì pé kí a máa fi orúkọ rẹ pè wá, láti mú ẹ̀gàn wa kúrò.’” (Aísáyà 4:1) Ọkọ máa wọ́n lóde débi pé obìnrin mélòó kan yóò dìrọ̀ mọ́ ọkùnrin kan ṣoṣo kí wọ́n sáà lè máa forúkọ rẹ̀ pè wọ́n, ìyẹn ni pé káráyé kà wọ́n sí aya rẹ̀, kí ìtìjú àìlọ́kọ lè kúrò lára wọn. Ọkọ ni Òfin Mósè sọ pé kó pèsè ohun ìgbẹ́mìíró àti aṣọ fún aya rẹ̀. (Ẹ́kísódù 21:10) Àmọ́, àwọn obìnrin wọ̀nyẹn gbà pé kí ọkùnrin yìí bọ́ nínú ojúṣe tí òfin wí yẹn, wọ́n gbà láti ‘máa jẹ oúnjẹ tiwọn kí wọ́n sì máa wọ aṣọ àlàbora tiwọn.’ Ọ̀ràn mà kúkú ti wá le dójú ẹ̀ fáwọn “ọmọbìnrin Síónì” tó jẹ́ onírera tẹ́lẹ̀ rí o!
25. Kí ló ń bẹ níwájú fún àwọn agbéraga?
25 Jèhófà tẹ́ àwọn agbéraga. Lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa, ó mú kí ìrera àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ “tẹrí ba” lóòótọ́, ó sì mú kí “ìgafíofío” wọn di “rírẹ̀sílẹ̀.” Ǹjẹ́ kí àwọn Kristẹni tòótọ́ má gbàgbé láé pé “Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn onírera, ṣùgbọ́n ó fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.”—Jákọ́bù 4:6.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 50]
Àwọn òrìṣà, ọrọ̀, àti jíjẹ́ akin lójú ogun kò gba Jerúsálẹ́mù sílẹ̀ lọ́jọ́ ìdájọ́ Jèhófà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 55]
Ní “ọjọ́ Jèhófà,” ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé yóò pa run