Àìsáyà
37 Gbàrà tí Ọba Hẹsikáyà gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, ó fa ẹ̀wù rẹ̀ ya, ó fi aṣọ ọ̀fọ̀* bora, ó sì lọ sínú ilé Jèhófà.+ 2 Lẹ́yìn náà, ó rán Élíákímù, ẹni tó ń bójú tó agbo ilé* àti Ṣébínà akọ̀wé pẹ̀lú àwọn àgbààgbà nínú àwọn àlùfáà, wọ́n fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora, ó sì rán wọn sí wòlíì Àìsáyà,+ ọmọ Émọ́ọ̀sì. 3 Wọ́n sọ fún un pé: “Ohun tí Hẹsikáyà sọ nìyí, ‘Ọjọ́ òní jẹ́ ọjọ́ wàhálà àti ti ìbáwí* àti ti ìtìjú; nítorí a dà bí aboyún tó fẹ́ bímọ,* àmọ́ tí kò ní okun láti bí i.+ 4 Bóyá Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa gbọ́ ọ̀rọ̀ Rábúṣákè tí olúwa rẹ̀ ọba Ásíríà rán láti pẹ̀gàn Ọlọ́run alààyè,+ tí á sì pè é wá jíhìn nítorí àwọn ọ̀rọ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti gbọ́. Torí náà, gbàdúrà+ nítorí àṣẹ́kù tó yè bọ́ yìí.’”+
5 Nítorí náà, àwọn ìránṣẹ́ Ọba Hẹsikáyà lọ sọ́dọ̀ Àìsáyà,+ 6 Àìsáyà sì sọ fún wọn pé: “Ẹ sọ fún olúwa yín pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Má bẹ̀rù+ nítorí àwọn ọ̀rọ̀ tí o gbọ́, àwọn ọ̀rọ̀ tí àwọn ẹmẹ̀wà* ọba Ásíríà+ fi pẹ̀gàn mi. 7 Wò ó, màá fi ohun kan sí i lọ́kàn,* ó máa gbọ́ ìròyìn kan, á sì pa dà sí ilẹ̀ rẹ̀;+ màá sì jẹ́ kí wọ́n fi idà pa á ní ilẹ̀ òun fúnra rẹ̀.”’”+
8 Lẹ́yìn tí Rábúṣákè gbọ́ pé ọba Ásíríà ti kúrò ní Lákíṣì, ó pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì rí i tó ń bá Líbínà jà.+ 9 Ọba wá gbọ́ tí wọ́n sọ nípa Tíhákà ọba Etiópíà pé: “Ó ti jáde láti wá bá ọ jà.” Nígbà tó gbọ́, ó tún rán àwọn òjíṣẹ́ sí Hẹsikáyà+ pé: 10 “Ẹ sọ fún Hẹsikáyà ọba Júdà pé, ‘Má ṣe jẹ́ kí Ọlọ́run rẹ tí o gbẹ́kẹ̀ lé tàn ọ́ jẹ pé: “A kò ní fi Jerúsálẹ́mù lé ọba Ásíríà lọ́wọ́.”+ 11 Wò ó! O ti gbọ́ ohun tí àwọn ọba Ásíríà ṣe sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, bí wọ́n ṣe pa wọ́n run.+ Ṣé o rò pé ìwọ lè bọ́ lọ́wọ́ wa ni? 12 Ǹjẹ́ àwọn ọlọ́run àwọn orílẹ̀-èdè tí àwọn baba ńlá mi pa run gbà wọ́n?+ Ibo ni Gósánì, Háránì,+ Réséfù àti àwọn èèyàn Édẹ́nì tó wà ní Tẹli-ásárì wà? 13 Ibo ni ọba Hámátì, ọba Áápádì, ọba àwọn ìlú Séfáfáímù,+ ọba Hénà àti ọba Ífà wà?’”
14 Hẹsikáyà gba àwọn lẹ́tà náà lọ́wọ́ àwọn òjíṣẹ́ náà, ó sì kà wọ́n. Lẹ́yìn náà, Hẹsikáyà lọ sí ilé Jèhófà, ó sì tẹ́ wọn* síwájú Jèhófà.+ 15 Hẹsikáyà wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà sí Jèhófà,+ ó sọ pé: 16 “Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun,+ Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí o jókòó sórí ìtẹ́ lókè* àwọn kérúbù, ìwọ nìkan ni Ọlọ́run tòótọ́ lórí gbogbo ìjọba ayé. Ìwọ lo dá ọ̀run àti ayé. 17 Fetí sílẹ̀, Jèhófà, kí o sì gbọ́!+ La ojú rẹ, Jèhófà, kí o sì rí i!+ Kí o gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí Senakérúbù fi ránṣẹ́ láti pẹ̀gàn Ọlọ́run alààyè.+ 18 Jèhófà, òótọ́ ni pé àwọn ọba Ásíríà ti pa gbogbo ilẹ̀ run,+ títí kan ilẹ̀ wọn. 19 Wọ́n sì ti ju àwọn ọlọ́run wọn sínú iná,+ nítorí wọn kì í ṣe ọlọ́run, iṣẹ́ ọwọ́ èèyàn ni wọ́n,+ wọ́n jẹ́ igi àti òkúta. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi lè pa wọ́n run. 20 Àmọ́ ní báyìí, ìwọ Jèhófà Ọlọ́run wa, gbà wá lọ́wọ́ rẹ̀, kí gbogbo ìjọba ayé lè mọ̀ pé ìwọ Jèhófà nìkan ṣoṣo ni Ọlọ́run.”+
21 Àìsáyà ọmọ Émọ́ọ̀sì wá ránṣẹ́ sí Hẹsikáyà pé: “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Torí pé o gbàdúrà sí mi nítorí Senakérúbù ọba Ásíríà,+ 22 ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ nípa rẹ̀ nìyí:
“Wúńdíá ọmọbìnrin Síónì pẹ̀gàn rẹ, ó ti fi ọ́ ṣẹ̀sín.
Ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù mi orí rẹ̀ sí ọ.
23 Ta lo pẹ̀gàn,+ tí o sì sọ̀rọ̀ òdì sí?
Ta lo gbé ohùn rẹ sókè sí,+
Tí o sì gbé ojú rẹ ga sí?
Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì mà ni!+
24 O tipasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ pẹ̀gàn Jèhófà,+ o sọ pé,
‘Pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn kẹ̀kẹ́ ogun mi,
Màá gun ibi gíga àwọn òkè,+
Ibi tó jìnnà jù lọ ní Lẹ́bánónì.
Ṣe ni màá gé àwọn igi kédárì rẹ̀ tó ga fíofío lulẹ̀, àwọn ààyò igi júnípà rẹ̀.
Màá wọ ibi tó ga jù tó máa ń sá sí, igbó kìjikìji rẹ̀.
25 Màá gbẹ́ kànga, màá sì mu omi;
Màá fi àtẹ́lẹsẹ̀ mi mú kí àwọn odò* Íjíbítì gbẹ.’
26 Ṣé o ò tíì gbọ́ ni? Tipẹ́tipẹ́ ni mo ti pinnu rẹ̀.*
Láti ọ̀pọ̀ ọjọ́ sẹ́yìn ni mo ti ṣètò rẹ̀.*+
Ní báyìí, màá ṣe é.+
Wàá sọ àwọn ìlú olódi di àwókù.+
27 Àwọn tó ń gbé inú wọn á di aláìlágbára;
Jìnnìjìnnì á bá wọn, ojú á sì tì wọ́n.
Wọ́n á rọ bí ewéko pápá àti bí koríko tútù ṣe máa ń rọ,
Bíi koríko orí òrùlé tí atẹ́gùn ìlà oòrùn ti jó gbẹ.
28 Àmọ́, mo mọ ìgbà tí o bá jókòó, ìgbà tí o bá jáde àti ìgbà tí o bá wọlé+
Àti ìgbà tí inú rẹ bá ru sí mi,+
29 Torí bí inú rẹ ṣe ń ru sí mi+ àti bí o ṣe ń ké ramúramù ti dé etí mi.+
Torí náà, màá fi ìwọ̀ mi kọ́ imú rẹ, màá fi ìjánu+ mi sáàárín ètè rẹ,
Ọ̀nà tí o gbà wá ni màá sì mú ọ gbà pa dà.”
30 “‘Ohun tó máa jẹ́ àmì fún ọ* nìyí: Lọ́dún yìí, ẹ ó jẹ ohun tó lalẹ̀ hù;* ní ọdún kejì, ọkà tó hù látinú ìyẹn ni ẹ ó jẹ; àmọ́ ní ọdún kẹta, ẹ ó fúnrúgbìn, ẹ ó sì kórè, ẹ ó gbin àwọn ọgbà àjàrà, ẹ ó sì jẹ èso wọn.+ 31 Ìyókù àwọn ará ilé Júdà tó sá àsálà+ máa ta gbòǹgbò nísàlẹ̀, wọ́n á sì so èso lókè. 32 Nítorí àṣẹ́kù kan máa jáde wá láti Jerúsálẹ́mù, àwọn tó là á já sì máa jáde wá láti Òkè Síónì.+ Ìtara Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun máa ṣe èyí.+
33 “‘Torí náà, ohun tí Jèhófà sọ nípa ọba Ásíríà+ nìyí:
“Kò ní wọ inú ìlú yìí,+
Bẹ́ẹ̀ ni kò ní ta ọfà sí ibẹ̀,
Tàbí kó fi apata dojú kọ ọ́,
Bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní mọ òkìtì láti dó tì í.”’+
34 ‘Ọ̀nà tó gbà wá ló máa gbà pa dà;
Kò ní wọ inú ìlú yìí,’ ni Jèhófà wí.
36 Áńgẹ́lì Jèhófà wá jáde lọ, ó sì pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀rún márùn-ún (185,000) ọkùnrin nínú ibùdó àwọn ará Ásíríà. Nígbà tí àwọn èèyàn jí láàárọ̀ kùtù, wọ́n rí òkú nílẹ̀ bẹẹrẹbẹ.+ 37 Torí náà, Senakérúbù ọba Ásíríà kúrò níbẹ̀, ó pa dà sí Nínéfè,+ ó sì ń gbé ibẹ̀.+ 38 Bó ṣe ń forí balẹ̀ ní ilé* Nísírọ́kì ọlọ́run rẹ̀, àwọn ọmọ rẹ̀, Adiramélékì àti Ṣárésà fi idà pa á,+ wọ́n sì sá lọ sí ilẹ̀ Árárátì.+ Esari-hádónì+ ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.