Àìsáyà
10 Àwọn tó ń gbé ìlànà tó ń pani lára kalẹ̀ gbé,+
Àwọn tó ń ṣe òfin tó ń nini lára ṣáá,
2 Láti fi ẹ̀tọ́ àwọn aláìní dù wọ́n lábẹ́ òfin,
Láti fi ìdájọ́ òdodo du àwọn tó rẹlẹ̀ láàárín àwọn èèyàn mi,+
Wọ́n ń kó àwọn opó nífà bí ẹrù ogun
4 Kò sí ohun tó ṣẹ́ kù ju pé kí ẹ bẹ̀rẹ̀ sáàárín àwọn ẹlẹ́wọ̀n
Tàbí kí ẹ ṣubú láàárín àwọn tí wọ́n pa.
Pẹ̀lú gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò tíì yí pa dà,
Àmọ́ ó ṣì na ọwọ́ rẹ̀ jáde láti lù wọ́n.+
6 Màá rán an sí orílẹ̀-èdè apẹ̀yìndà,+
Sí àwọn èèyàn tó múnú bí mi;
Màá pàṣẹ fún un pé kó kó nǹkan púpọ̀ àti ẹrù ogun tó pọ̀,
Kó sì tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ bí ẹrẹ̀ lójú ọ̀nà.+
7 Àmọ́ kò ní fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀,
Kò sì ní gbèrò lọ́kàn rẹ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀;
Torí ó wà lọ́kàn rẹ̀ láti pani run,
Láti pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè rẹ́, tí kì í ṣe díẹ̀.
9 Ṣebí bíi Kákémíṣì+ gẹ́lẹ́ ni Kálínò+ rí?
Ṣebí bíi Damásíkù+ ni Samáríà+ rí?
10 Ọwọ́ mi tẹ ìjọba àwọn ọlọ́run tí kò ní láárí,
Àwọn tí ère gbígbẹ́ wọn pọ̀ ju ti Jerúsálẹ́mù àti Samáríà lọ!+
11 Ǹjẹ́ kì í ṣe ohun tí mo ṣe sí Samáríà àti àwọn ọlọ́run rẹ̀ tí kò ní láárí gẹ́lẹ́
Ni màá ṣe sí Jerúsálẹ́mù àti àwọn òrìṣà rẹ̀?’+
12 “Tí Jèhófà bá ti parí gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ lórí Òkè Síónì àti ní Jerúsálẹ́mù, Ó* máa fìyà jẹ ọba Ásíríà torí àfojúdi ọkàn rẹ̀ àti ojú rẹ̀ gíga tó fi ń woni pẹ̀lú ìgbéraga.+ 13 Torí ó sọ pé,
‘Agbára ọwọ́ mi ni màá fi ṣe èyí
Àti ọgbọ́n mi, torí mo gbọ́n.
14 Bí èèyàn tó fẹ́ tọwọ́ bọ ìtẹ́ ẹyẹ,
Ọwọ́ mi máa tẹ àwọn ohun àmúṣọrọ̀ àwọn èèyàn;
Bí ẹni tó sì ń kó ẹyin tí wọ́n pa tì jọ,
Ni màá kó gbogbo ayé jọ!
Kò sẹ́ni tó máa gbọn ìyẹ́ rẹ̀, tó máa la ẹnu tàbí tó máa ké ṣíoṣío.’”
15 Ṣé àáké máa gbé ara rẹ̀ ga ju ẹni tó ń fi gé nǹkan?
Ṣé ayùn máa gbé ara rẹ̀ ga ju ẹni tó ń fi rẹ́ nǹkan?
Ṣé ọ̀pá+ lè fi ẹni tó gbé e sókè?
Àbí ọ̀pá lè gbé ẹni tí wọn ò fi igi ṣe sókè?
16 Torí náà, Olúwa tòótọ́, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun
Máa mú kí àwọn èèyàn rẹ̀ tó sanra rù,+
Ó sì máa dá iná tó ń jó lala sábẹ́ ògo rẹ̀.+
17 Ìmọ́lẹ̀ Ísírẹ́lì+ máa di iná,+
Ẹni Mímọ́ rẹ̀ sì máa di ọwọ́ iná;
Ó máa jó àwọn èpò àtàwọn igi ẹlẹ́gùn-ún rẹ̀ run ní ọjọ́ kan.
18 Ó máa mú ògo igbó rẹ̀ àti ọgbà eléso rẹ̀ kúrò pátápátá;*
Ó máa dà bí ìgbà tí ẹni tó ń ṣàìsàn ń kú lọ.+
19 Iye igi tó kù nínú igbó rẹ̀
Máa kéré gan-an débi pé ọmọdékùnrin máa lè kọ iye wọn sílẹ̀.
20 Ní ọjọ́ yẹn, àwọn tó ṣẹ́ kù ní Ísírẹ́lì
Àti àwọn tó yè bọ́ ní ilé Jékọ́bù
Kò tún ní gbára lé ẹni tó lù wọ́n;+
Àmọ́ wọ́n máa fi òtítọ́ gbára lé Jèhófà,
Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.
23 Àní, ìparun ráúráú tí Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun pinnu,
Máa ṣẹlẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ náà.+
24 Torí náà, ohun tí Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí: “Ẹ̀yin èèyàn mi tó ń gbé ní Síónì, ẹ má bẹ̀rù nítorí ará Ásíríà tó ti máa ń fi ọ̀pá lù yín,+ tó sì máa ń gbé ọ̀pá rẹ̀ sókè sí yín bíi ti Íjíbítì.+ 25 Torí kò ní pẹ́ rárá tí ìbáwí náà fi máa dópin; ìbínú mi máa mú kí n pa wọ́n run.+ 26 Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun máa yọ pàṣán kan sí i,+ bó ṣe ṣe nígbà tó ṣẹ́gun Mídíánì lẹ́gbẹ̀ẹ́ àpáta Órébù.+ Ọ̀pá rẹ̀ máa wà lórí òkun, ó sì máa nà á sókè bó ṣe ṣe sí Íjíbítì.+
27 Ní ọjọ́ yẹn, ẹrù rẹ̀ máa kúrò ní èjìká rẹ+
Àti àjàgà rẹ̀ kúrò ní ọrùn rẹ,+
Àjàgà náà sì máa ṣẹ́+ torí òróró.”
29 Wọ́n ti kọjá níbi tó ṣeé fẹsẹ̀ gbà nínú odò;
Gébà+ ni wọ́n sùn mọ́jú;
30 Kígbe kí o sì pariwo, ìwọ ọmọbìnrin Gálímù!
Fiyè sílẹ̀, ìwọ Láíṣà!
O gbé, ìwọ Ánátótì!+
31 Mádíménà ti sá lọ.
Àwọn tó ń gbé Gébímù ti wá ibì kan fara pa mọ́ sí.
32 Lónìí yìí gan-an, ó máa dúró ní Nóbù.+
Ó mi ẹ̀ṣẹ́ rẹ̀ sí òkè ọmọbìnrin Síónì,
Òkè kékeré Jerúsálẹ́mù.
33 Wò ó! Olúwa tòótọ́, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun,
Ń gé àwọn ẹ̀ka lulẹ̀, bí wọ́n ṣe ń fọ́ yángá sì bani lẹ́rù;+
Ó ń gé àwọn igi tó ga jù lulẹ̀,
Ó sì ń rẹ àwọn tó ta yọ wálẹ̀.
34 Ó ń fi irinṣẹ́ onírin* ṣá igbó tó díjú balẹ̀,
Lẹ́bánónì sì máa ti ọwọ́ alágbára kan ṣubú.