Àìsáyà
16 Ẹ fi àgbò ránṣẹ́ sí alákòóso ilẹ̀ náà,
Láti Sẹ́ẹ́là gba aginjù
Lọ sórí òkè ọmọbìnrin Síónì.
2 Bí ẹyẹ tí wọ́n lé kúrò nínú ìtẹ́ rẹ̀ +
Ni àwọn ọmọbìnrin Móábù máa rí níbi tó ṣeé fẹsẹ̀ gbà nínú odò Áánónì.+
3 “Ẹ gbani nímọ̀ràn, ẹ tẹ̀ lé ìpinnu náà.
Jẹ́ kí òjìji rẹ ní ọ̀sán gangan dà bí òru.
Fi àwọn tí wọ́n fọ́n ká pa mọ́, má sì dalẹ̀ àwọn tó ń sá lọ.
4 Kí àwọn èèyàn mi tó fọ́n ká máa gbé inú rẹ, ìwọ Móábù.
Di ibi ààbò fún wọn torí ẹni tó ń pani run.+
Òpin máa dé bá aninilára,
Ìparun náà máa dópin,
Àwọn tó ń tẹ ẹlòmíì mọ́lẹ̀ sì máa pa rẹ́ ní ayé.
5 Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ máa wá mú kí ìtẹ́ kan fìdí múlẹ̀ gbọn-in.
Ẹni tó jókòó sórí rẹ̀ nínú àgọ́ Dáfídì máa jẹ́ olóòótọ́;+
Ó máa dá ẹjọ́ bó ṣe tọ́, ó sì máa yára ṣe òdodo.”+
6 A ti gbọ́ bí Móábù ṣe ń gbéra ga, ó ń gbéra ga gan-an;+
Bó ṣe ń gbéra ga, tó ń yangàn, tó sì ń bínú;+
Àmọ́ pàbó ni ọ̀rọ̀ asán rẹ̀ máa já sí.
Àwọn tí wọ́n lù máa dárò torí ìṣù àjàrà gbígbẹ ti Kiri-hárésétì.+
8 Torí àwọn ilẹ̀ onípele Hẹ́ṣíbónì+ ti gbẹ,
Àjàrà Síbúmà,+
Àwọn alákòóso àwọn orílẹ̀-èdè ti tẹ àwọn ẹ̀ka rẹ̀ tó pupa fòò* mọ́lẹ̀;
Wọ́n ti lọ títí dé Jásérì;+
Wọ́n ti tàn dé aginjù.
Àwọn ọ̀mùnú rẹ̀ ti tàn kálẹ̀, wọ́n sì ti lọ títí dé òkun.
9 Ìdí nìyẹn tí màá fi sunkún torí àjàrà Síbúmà bí mo ṣe ń sunkún torí Jásérì.
Màá fi omijé mi rin ọ́ gbingbin, ìwọ Hẹ́ṣíbónì àti Éléálè,+
Torí pé igbe tí wọ́n ń ké torí èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn rẹ àti ìkórè rẹ ti dópin.*
10 A ti mú ayọ̀ àti ìdùnnú kúrò nínú ọgbà eléso,
Kò sì sí orin ayọ̀ tàbí ariwo nínú àwọn ọgbà àjàrà.+
Ẹni tó ń fẹsẹ̀ tẹ àjàrà kò tẹ̀ ẹ́ mọ́ ní àwọn ibi ìfúntí láti ṣe wáìnì,
Torí mo ti mú kí ariwo náà dáwọ́ dúró.+
11 Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé inú mi lọ́hùn-ún ń ru sókè torí Móábù,+
Bí ìgbà tí wọ́n ń ta háàpù,
Àti inú mi lọ́hùn-ún torí Kiri-hárésétì.+
12 Kódà, tí Móábù bá tán ara rẹ̀ lókun lórí ibi gíga, tó sì lọ gbàdúrà nínú ibi mímọ́ rẹ̀, kò ní rí nǹkan kan ṣe.+
13 Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà ti sọ nípa Móábù nìyí. 14 Ní báyìí, Jèhófà sọ pé: “Láàárín ọdún mẹ́ta, bí iye ọdún alágbàṣe,* onírúurú rúkèrúdò ni wọ́n máa fi dójú ti ògo Móábù, àwọn tó máa ṣẹ́ kù máa kéré gan-an, wọn ò sì ní já mọ́ nǹkan kan.”+