Àìsáyà
Ẹ pohùn réré ẹkún, ẹ̀yin ọkọ̀ òkun Táṣíṣì!+
Torí a ti run èbúté; kò ṣeé wọ̀.
A ti ṣi í payá fún wọn láti ilẹ̀ Kítímù.+
2 Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ilẹ̀ etíkun.
Àwọn oníṣòwò láti Sídónì,+ tó ń sọdá òkun ti kún inú rẹ.
3 Ọkà* Ṣíhórì*+ gba orí omi púpọ̀,
Ìkórè Náílì, owó tó ń wọlé fún un,
Tó ń mú èrè wá fún àwọn orílẹ̀-èdè.+
4 Kí ojú tì ọ́, ìwọ Sídónì, ìwọ ibi ààbò òkun,
Torí òkun ti sọ pé:
“Mi ò ní ìrora ìrọbí, mi ò sì tíì bímọ,
Bẹ́ẹ̀ ni mi ò tọ́ àwọn ọ̀dọ́kùnrin tàbí ọ̀dọ́bìnrin* dàgbà.”+
5 Bí ìgbà tí wọ́n gbọ́ ìròyìn nípa Íjíbítì,+
Àwọn èèyàn máa jẹ̀rora torí ìròyìn tí wọ́n gbọ́ nípa Tírè.+
6 Ẹ sọdá sí Táṣíṣì!
Ẹ pohùn réré ẹkún, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ilẹ̀ etíkun!
7 Ṣé ìlú yín tó ń yọ̀ látọjọ́ tó ti pẹ́ nìyí, láti ìgbà àtijọ́ rẹ̀?
Ẹsẹ̀ rẹ̀ máa ń gbé e lọ sí àwọn ilẹ̀ tó jìn kó lè gbé ibẹ̀.
8 Ta ló pinnu èyí sí Tírè,
Ẹni tó ń déni ládé,
Tí àwọn oníṣòwò rẹ̀ jẹ́ ìjòyè,
Tí wọ́n ń bọlá fún àwọn ọlọ́jà rẹ̀ ní gbogbo ayé?+
9 Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun fúnra rẹ̀ ti pinnu èyí,
Láti tẹ́ńbẹ́lú bó ṣe ń fi gbogbo ẹwà rẹ̀ yangàn,
Láti rẹ gbogbo àwọn tí wọ́n ń bọlá fún ní ayé sílẹ̀.+
10 Sọdá ilẹ̀ rẹ bí odò Náílì, ìwọ ọmọbìnrin Táṣíṣì.
Kò sí ibi tí wọ́n ti ń ṣe ọkọ̀ òkun* mọ́.+
11 Ó ti na ọwọ́ rẹ̀ sórí òkun;
Ó ti mi àwọn ìjọba jìgìjìgì.
Jèhófà ti pàṣẹ pé kí wọ́n pa àwọn ibi ààbò Foníṣíà run.+
Dìde, sọdá sí Kítímù.+
O ò ní ní ìsinmi níbẹ̀ pàápàá.”
13 Wò ó! Ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà.+
Àwọn èèyàn náà nìyí, kì í ṣe Ásíríà,+
Wọ́n sọ ọ́ di ibi tí àwọn tó ń lọ sínú aṣálẹ̀ máa ń lọ.
Wọ́n ti kọ́ àwọn ilé gogoro láti dó tì í;
Wọ́n ti ya àwọn ilé gogoro rẹ̀ lulẹ̀,+
Wọ́n ti sọ ọ́ di ibi tó rún wómúwómú.
14 Ẹ pohùn réré ẹkún, ẹ̀yin ọkọ̀ òkun Táṣíṣì,
Torí ibi ààbò yín ti pa run.+
15 Ní ọjọ́ yẹn, wọ́n máa gbàgbé Tírè fún àádọ́rin (70) ọdún,+ bí ayé ìgbà* ọba kan. Lópin àádọ́rin (70) ọdún, ó máa ṣẹlẹ̀ sí Tírè bí orin aṣẹ́wó kan tó sọ pé:
16 “Mú háàpù, lọ yí ká ìlú, ìwọ aṣẹ́wó tí wọ́n ti gbàgbé.
Ta háàpù rẹ dáadáa;
Kọ orin tó pọ̀,
Kí wọ́n lè rántí rẹ.”
17 Ní òpin àádọ́rin (70) ọdún, Jèhófà máa rántí Tírè, ó máa pa dà sídìí ọrọ̀ rẹ̀, á sì máa bá gbogbo ìjọba ayé tó wà lórí ilẹ̀ ayé ṣe ìṣekúṣe. 18 Àmọ́ èrè rẹ̀ àti ọrọ̀ rẹ̀ máa di ohun mímọ́ fún Jèhófà. Kò ní kó o pa mọ́ tàbí kó tò ó jọ, torí pé ọrọ̀ rẹ̀ máa di ti àwọn tó ń gbé iwájú Jèhófà, kí wọ́n lè jẹun ní àjẹyó, kí wọ́n sì wọ aṣọ aláràbarà.+