Ìsíkíẹ́lì
38 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 2 “Ọmọ èèyàn, dojú kọ Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù,+ olórí ìjòyè* Méṣékì àti Túbálì,+ kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí i.+ 3 Sọ pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Èmi yóò bá ọ jà, ìwọ Gọ́ọ̀gù, olórí ìjòyè* Méṣékì àti Túbálì. 4 Èmi yóò yí ojú rẹ pa dà, màá fi ìwọ̀ kọ́ ọ lẹ́nu,+ èmi yóò sì mú ìwọ àti gbogbo ọmọ ogun rẹ jáde,+ àwọn ẹṣin àti àwọn tó ń gẹṣin tí gbogbo wọn wọṣọ iyì, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn pẹ̀lú àwọn apata ńlá àti asà,* gbogbo wọn ní idà; 5 Páṣíà, Etiópíà àti Pútì+ wà pẹ̀lú wọn, gbogbo wọn ní asà* àti akoto;* 6 Gómérì àti gbogbo ọmọ ogun rẹ̀, ilé Tógámà+ láti ibi tó jìnnà jù ní àríwá, pẹ̀lú gbogbo ọmọ ogun rẹ̀; ọ̀pọ̀ èèyàn wà pẹ̀lú rẹ.+
7 “‘“Ẹ dira ogun, kí ẹ múra sílẹ̀, ìwọ àti gbogbo ọmọ ogun rẹ tí wọ́n kóra jọ sọ́dọ̀ rẹ, ìwọ lo sì máa ṣe ọ̀gágun* wọn.
8 “‘“Wàá gbàfiyèsí* lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọjọ́. Ní àwọn ọdún tó kẹ́yìn, ìwọ yóò gbógun ja àwọn èèyàn tó ti bọ́ lọ́wọ́ idà, àwọn tó kóra jọ láti inú ọ̀pọ̀ èèyàn sórí àwọn òkè Ísírẹ́lì, tó ti di ahoro tipẹ́. Àárín àwọn èèyàn ni àwọn tó ń gbé ilẹ̀ yìí ti jáde, ààbò sì wà lórí gbogbo wọn.+ 9 Ìwọ yóò ya bò wọ́n bí ìjì, wàá sì bo ilẹ̀ náà bí ìkùukùu,* ìwọ àti gbogbo ọmọ ogun rẹ àti ọ̀pọ̀ èèyàn tó wà pẹ̀lú rẹ.”’
10 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Ní ọjọ́ yẹn, wàá gbèrò àwọn nǹkan lọ́kàn rẹ, wàá sì gbìmọ̀ ibi. 11 O máa sọ pé: “Èmi yóò gbógun ja ilẹ̀ tí àwọn agbègbè rẹ̀ ṣí sílẹ̀.*+ Èmi yóò wá bá àwọn tó ń gbé láìséwu jà, àwọn tí kò sẹ́nì kankan tó ń yọ wọ́n lẹ́nu, gbogbo wọn ń gbé agbègbè tí kò ní ògiri, ọ̀pá ìdábùú tàbí àwọn ẹnubodè.” 12 Ó máa jẹ́ torí kó lè rí ẹrù tó pọ̀, kó sì kó o, láti gbógun ti àwọn ibi tó ti di ahoro àmọ́ tí wọ́n ti wá ń gbé ibẹ̀+ àti láti gbógun ti àwọn èèyàn tí wọ́n tún kó jọ láti àárín àwọn orílẹ̀-èdè,+ tí wọ́n ń kó ọrọ̀ àti dúkìá jọ,+ àwọn tó ń gbé ní àárín ayé.
13 “‘Ṣébà+ àti Dédánì,+ àwọn oníṣòwò Táṣíṣì + àti gbogbo ọmọ ogun* rẹ̀ yóò sọ fún ọ pé: “Ṣé kí o lè rí ẹrù tó pọ̀ kí o sì kó o lo ṣe fẹ́ gbógun jà wọ́n? Ṣé kí o lè kó fàdákà àti wúrà lo ṣe kó àwọn ọmọ ogun rẹ jọ, kí o lè kó ọrọ̀ àti dúkìá, kí o sì rí ẹrù rẹpẹtẹ kó?”’
14 “Torí náà, ọmọ èèyàn, sọ tẹ́lẹ̀, kí o sì sọ fún Gọ́ọ̀gù pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Ní ọjọ́ yẹn, tí àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì bá ń gbé láìséwu, ṣé o ò ní mọ̀?+ 15 O máa wá láti àyè rẹ, láti ibi tó jìnnà jù ní àríwá,+ ìwọ àti ọ̀pọ̀ èèyàn pẹ̀lú rẹ, tí gbogbo wọn gun ẹṣin, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn, àwọn ọmọ ogun tó pọ̀ gan-an.+ 16 Ìwọ yóò wá gbéjà ko àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì bí ìgbà tí ìkùukùu* bo ilẹ̀. Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, èmi yóò mú kí o wá gbéjà ko ilẹ̀ mi,+ kí àwọn orílẹ̀-èdè lè mọ̀ mí, kí wọ́n sì mọ̀ pé ẹni mímọ́ ni mí nígbà tí wọ́n bá rí ohun tí mo ṣe sí ọ, ìwọ Gọ́ọ̀gù.”’+
17 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Ṣebí ìwọ náà ni ẹni tí mo sọ̀rọ̀ rẹ̀ nígbà àtijọ́ nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ mi, àwọn wòlíì Ísírẹ́lì tí wọ́n sọ tẹ́lẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún pé wọ́n á mú ọ wá láti bá wọn jà?’
18 “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ pé, ‘Ní ọjọ́ yẹn, ní ọjọ́ tí Gọ́ọ̀gù bá wá gbógun ja ilẹ̀ Ísírẹ́lì, inú á bí mi gidigidi.+ 19 Ìtara àti ìbínú mi tó ń jó bí iná ni màá fi sọ̀rọ̀. Ní ọjọ́ yẹn, ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára gan-an yóò ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì. 20 Àwọn ẹja inú òkun, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run, àwọn ẹran inú igbó, gbogbo ẹran tó ń fàyà fà àti gbogbo èèyàn tó wà láyé yóò gbọ̀n rìrì nítorí mi, àwọn òkè yóò wó lulẹ̀,+ àwọn òkè tó dà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ yóò ṣubú lulẹ̀, gbogbo ògiri yóò sì wó lulẹ̀.’
21 “‘Èmi yóò mú kí idà kan dojú kọ ọ́ lórí gbogbo òkè mi,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí. ‘Kálukú yóò fi idà rẹ̀ bá arákùnrin rẹ̀ jà.+ 22 Èmi yóò fi àjàkálẹ̀ àrùn+ àti ikú dá a lẹ́jọ́; èmi yóò mú kí òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá, òkúta yìnyín,+ iná+ àti imí ọjọ́+ rọ̀ lé òun àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lórí àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn tó wà pẹ̀lú rẹ̀.+ 23 Ó dájú pé màá gbé ara mi ga, màá jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ẹni mímọ́ ni mí, màá sì jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè mọ irú ẹni tí mo jẹ́; wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’