Àìsáyà
2 Rárá, àwọn àṣìṣe yín ti pín ẹ̀yin àti Ọlọ́run yín níyà.+
Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín ti mú kó fi ojú rẹ̀ pa mọ́ fún yín,
Ó sì kọ̀ láti gbọ́ yín.+
Ètè yín ń parọ́,+ ahọ́n yín sì ń sọ àìṣòdodo kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́.
Ohun tí kò sí rárá* ni wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé,+ wọ́n sì ń sọ ohun tí kò ní láárí.
Wọ́n lóyún wàhálà, wọ́n sì bí ohun tó ń pani lára.+
Ẹnikẹ́ni tó bá jẹ ẹyin wọn máa kú,
Ẹyin tí wọ́n sì tẹ̀ fọ́ mú ejò paramọ́lẹ̀ jáde.
Iṣẹ́ wọn léwu,
Ìwà ipá ló sì kún ọwọ́ wọn.+
Ohun burúkú ni wọ́n ń rò;
Ìparun àti ìyà wà ní àwọn ọ̀nà wọn.+
Wọ́n mú kí àwọn ọ̀nà wọn wọ́;
Ìkankan nínú àwọn tó ń rìn níbẹ̀ kò ní mọ àlàáfíà.+
9 Ìdí nìyẹn tí ìdájọ́ òdodo fi jìnnà sí wa,
Tí òdodo kò sì lé wa bá.
À ń retí ìmọ́lẹ̀ ṣáá, àmọ́ wò ó! òkùnkùn ló ṣú;
À ń retí ìmọ́lẹ̀ tó tàn yòò, àmọ́ a ò yéé rìn nínú ìṣúdùdù.+
A kọsẹ̀ ní ọ̀sán gangan bíi pé a wà nínú òkùnkùn alẹ́;
Ṣe la dà bí òkú láàárín àwọn alágbára.
11 Gbogbo wa ń kùn ṣáá bíi bíárì,
A sì ń ṣọ̀fọ̀, à ń ké kúùkúù bí àdàbà.
À ń retí ìdájọ́ òdodo, àmọ́ kò sí;
À ń retí ìgbàlà, àmọ́ ó jìnnà gan-an sí wa.
Torí àwọn ọ̀tẹ̀ wa wà pẹ̀lú wa;
A mọ àwọn àṣìṣe wa dáadáa.+
13 A ti ṣẹ̀, a sì ti sẹ́ Jèhófà;
A ti kẹ̀yìn sí Ọlọ́run wa,
A ti sọ̀rọ̀ nípa ìnilára àti ọ̀tẹ̀;+
A ti lóyún irọ́, a sì ti sọ̀rọ̀ èké kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ látinú ọkàn.+
14 Wọ́n ti rọ́ ìdájọ́ òdodo sẹ́yìn,+
Òdodo sì dúró sí ọ̀nà jíjìn;+
Nítorí pé òtítọ́* ti kọsẹ̀ ní ojúde ìlú,
Ohun tó tọ́ kò sì rí ọ̀nà wọlé.
16 Ó rí i pé kò sí èèyàn kankan,
Ó sì yà á lẹ́nu pé ẹnì kankan ò bá wọn bẹ̀bẹ̀,
Torí náà, apá rẹ̀ mú ìgbàlà wá,*
Òdodo rẹ̀ sì tì í lẹ́yìn.
18 Ó máa san wọ́n lẹ́san ohun tí wọ́n ṣe:+
Ó máa bínú sí àwọn elénìní rẹ̀, ó máa fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ jẹ àwọn ọ̀tá rẹ̀.+
Ó sì máa san ohun tó yẹ àwọn erékùṣù fún wọn.
19 Wọ́n máa bẹ̀rù orúkọ Jèhófà láti ìwọ̀ oòrùn
Àti ògo rẹ̀ láti ìlà oòrùn,
Torí ó máa wọlé wá bí odò tó ń yára ṣàn,
Tí ẹ̀mí Jèhófà ń gbé lọ.
20 “Olùtúnrà+ máa wá sí Síónì,+
Sọ́dọ̀ àwọn ti Jékọ́bù, àwọn tó yí pa dà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀,”+ ni Jèhófà wí.
21 “Ní tèmi, májẹ̀mú tí mo bá wọn dá nìyí,”+ ni Jèhófà wí. “Ẹ̀mí mi tó wà lára rẹ àti àwọn ọ̀rọ̀ mi tí mo fi sí ẹnu rẹ kò ní kúrò ní ẹnu rẹ, ní ẹnu àwọn ọmọ* rẹ tàbí ní ẹnu àwọn ọmọ ọmọ rẹ,”* ni Jèhófà wí, “láti ìsinsìnyí lọ àti títí láé.”