Àkọsílẹ̀ Máàkù
2 Àmọ́ lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, ó tún wá sí Kápánáúmù, ìròyìn sì tàn káàkiri pé ó ti wà nílé.+ 2 Ọ̀pọ̀ èèyàn wá kóra jọ, débi pé kò sí àyè kankan mọ́ nínú ilé, kódà kò sí àyè lẹ́nu ọ̀nà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ọ̀rọ̀ náà fún wọn.+ 3 Wọ́n gbé alárùn rọpárọsẹ̀ kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, àwọn mẹ́rin ló gbé e.+ 4 Àmọ́ wọn ò lè gbé e tààràtà dé ọ̀dọ̀ Jésù torí àwọn èrò, nítorí náà, wọ́n ṣí òrùlé ibi tí Jésù wà, wọ́n dá ihò lu síbẹ̀, wọ́n sì gba ojú ihò náà sọ ibùsùn tí alárùn rọpárọsẹ̀ náà dùbúlẹ̀ sí kalẹ̀. 5 Nígbà tí Jésù rí ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní,+ ó sọ fún alárùn rọpárọsẹ̀ náà pé: “Ọmọ, a dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”+ 6 Àwọn akọ̀wé òfin kan wà níbẹ̀, wọ́n jókòó, wọ́n ń rò ó lọ́kàn pé:+ 7 “Kí ló dé tí ọkùnrin yìí ń sọ̀rọ̀ báyìí? Ọ̀rọ̀ òdì ló ń sọ. Ta ló lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini yàtọ̀ sí Ọlọ́run nìkan?”+ 8 Àmọ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jésù fòye mọ̀ nípasẹ̀ ẹ̀mí rẹ̀ pé ohun tí wọ́n ń rò lọ́kàn nìyẹn, ó wá sọ fún wọn pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń ro àwọn nǹkan yìí lọ́kàn yín?+ 9 Èwo ló rọrùn jù, láti sọ fún alárùn rọpárọsẹ̀ náà pé, ‘A dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́,’ àbí láti sọ pé, ‘Dìde, gbé ibùsùn rẹ, kí o sì máa rìn’? 10 Àmọ́ kí ẹ lè mọ̀ pé Ọmọ èèyàn+ ní àṣẹ láti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ jini láyé—”+ ó sọ fún alárùn rọpárọsẹ̀ náà pé: 11 “Mò ń sọ fún ọ, Dìde, gbé ibùsùn rẹ, kí o sì máa lọ sílé rẹ.” 12 Ló bá dìde, ó gbé ibùsùn rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó sì rìn jáde níwájú gbogbo wọn. Ẹnu ya gbogbo wọn, wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo, wọ́n sọ pé: “A ò rí irú èyí rí.”+
13 Ó tún jáde lọ sétí òkun, gbogbo àwọn èèyàn náà ń rọ́ wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ṣáá, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn. 14 Bó ṣe ń kọjá lọ, ó tajú kán rí Léfì ọmọ Áfíọ́sì tó jókòó sí ọ́fíìsì àwọn agbowó orí, ó sì sọ fún un pé: “Máa tẹ̀ lé mi.” Ló bá dìde, ó sì tẹ̀ lé e.+ 15 Lẹ́yìn náà, nígbà tó ń jẹun* nílé rẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn agbowó orí àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ń bá Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ jẹun,* torí pé ọ̀pọ̀ nínú wọn ló ń tẹ̀ lé e.+ 16 Àmọ́ nígbà tí àwọn akọ̀wé òfin lára àwọn Farisí rí i pé ó ń bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ àti àwọn agbowó orí jẹun, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ṣé ó máa ń bá àwọn agbowó orí àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun ni?” 17 Bí Jésù ṣe gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó sọ fún wọn pé: “Àwọn tó lókun ò nílò oníṣègùn, àmọ́ àwọn tó ń ṣàìsàn nílò rẹ̀. Kì í ṣe àwọn olódodo ni mo wá pè, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.”+
18 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù àti àwọn Farisí máa ń gbààwẹ̀. Torí náà, wọ́n wá, wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kí ló dé tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn àwọn Farisí máa ń gbààwẹ̀ àmọ́ tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ kì í gbààwẹ̀?”+ 19 Jésù sọ fún wọn pé: “Tí ọkọ ìyàwó+ bá ṣì wà lọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó, kò sí ohun tó máa mú kí wọ́n gbààwẹ̀, àbí ó wà? Tí ọkọ ìyàwó bá ṣì wà lọ́dọ̀ wọn, wọn ò lè gbààwẹ̀. 20 Àmọ́ ọjọ́ ń bọ̀, tí a máa mú ọkọ ìyàwó kúrò lọ́dọ̀ wọn,+ wọ́n máa wá gbààwẹ̀ lọ́jọ́ yẹn. 21 Kò sí ẹni tó máa rán ègé aṣọ tí kò tíì sún kì mọ́ ara aṣọ àwọ̀lékè tó ti gbó. Tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, aṣọ tuntun náà máa ya kúrò lára èyí tó ti gbó, ó sì máa ya ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.+ 22 Bákan náà, kò sí ẹni tó máa rọ wáìnì tuntun sínú àpò awọ tó ti gbó. Tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, wáìnì tuntun máa bẹ́ awọ náà, wáìnì náà máa dà nù, awọ náà sì máa bà jẹ́. Àmọ́ inú àpò awọ tuntun ni wọ́n máa ń rọ wáìnì tuntun sí.”
23 Bó ṣe ń gba oko ọkà kọjá ní Sábáàtì, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ya àwọn erín ọkà* jẹ bí wọ́n ṣe ń lọ.+ 24 Àwọn Farisí wá sọ fún un pé: “Wò ó! Kí ló dé tí wọ́n ń ṣe ohun tí kò bófin mu lọ́jọ́ Sábáàtì?” 25 Àmọ́ ó sọ fún wọn pé: “Ṣé ẹ ò tíì ka ohun tí Dáfídì ṣe rí ni, nígbà tó ṣaláìní, tí ebi sì ń pa òun àti àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀?+ 26 Nínú ìtàn Ábíátárì+ olórí àlùfáà, bó ṣe wọ ilé Ọlọ́run, tó sì jẹ àwọn búrẹ́dì tí wọ́n ń gbé síwájú,* èyí tí kò bófin mu fún ẹnikẹ́ni láti jẹ àfi àwọn àlùfáà,+ tó sì tún fún àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀ jẹ lára rẹ̀?” 27 Ó wá sọ fún wọn pé: “A dá Sábáàtì torí èèyàn,+ a ò dá èèyàn torí Sábáàtì. 28 Torí náà, Ọmọ èèyàn ni Olúwa, àní Olúwa Sábáàtì.”+