Ìfihàn Èyí Tí Jòhánù Rí
5 Mo sì rí àkájọ ìwé kan lọ́wọ́ ọ̀tún Ẹni tó jókòó lórí ìtẹ́ náà,+ tí wọ́n kọ̀wé sí tojú tẹ̀yìn,* tí wọ́n sì fi èdìdì méje dì pinpin. 2 Mo sì rí áńgẹ́lì alágbára kan tó ń fi ohùn tó rinlẹ̀ kéde pé: “Ta ló yẹ kó ṣí àkájọ ìwé náà, kó sì tú àwọn èdìdì rẹ̀?” 3 Àmọ́ kò sí ẹnikẹ́ni ní ọ̀run tàbí ní ayé tàbí lábẹ́ ilẹ̀ tó lè ṣí àkájọ ìwé náà tàbí wo inú rẹ̀. 4 Mo bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún gidigidi torí a ò rí ẹnì kankan tó yẹ láti ṣí àkájọ ìwé náà tàbí wo inú rẹ̀. 5 Àmọ́ ọ̀kan lára àwọn àgbààgbà náà sọ fún mi pé: “Má sunkún mọ́. Wò ó! Kìnnìún ẹ̀yà Júdà,+ gbòǹgbò+ Dáfídì,+ ti ṣẹ́gun+ kó lè ṣí àkájọ ìwé náà àti èdìdì méje rẹ̀.”
6 Mo sì rí ọ̀dọ́ àgùntàn+ kan tó rí bí èyí tí wọ́n ti pa,+ ó dúró ní àárín ìtẹ́ náà àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà àti ní àárín àwọn àgbààgbà náà,+ ó ní ìwo méje àti ojú méje, àwọn ojú náà sì túmọ̀ sí ẹ̀mí méje ti Ọlọ́run+ tí a ti rán jáde sí gbogbo ayé. 7 Ó wá síwájú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó sì gba àkájọ ìwé náà lọ́wọ́ ọ̀tún Ẹni tó jókòó lórí ìtẹ́.+ 8 Nígbà tó gbà á, àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin àti àwọn àgbààgbà mẹ́rìnlélógún + (24) náà wólẹ̀ níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní háàpù kan lọ́wọ́ àti abọ́ wúrà tí tùràrí kún inú rẹ̀. (Tùràrí náà túmọ̀ sí àdúrà àwọn ẹni mímọ́.)+ 9 Wọ́n sì ń kọ orin tuntun+ kan pé: “Ìwọ ló yẹ kó gba àkájọ ìwé náà, kí o sì ṣí àwọn èdìdì rẹ̀, torí pé wọ́n pa ọ́, o sì fi ẹ̀jẹ̀ rẹ ra àwọn èèyàn fún Ọlọ́run+ látinú gbogbo ẹ̀yà àti ahọ́n* àti èèyàn àti orílẹ̀-èdè,+ 10 o mú kí wọ́n di ìjọba kan+ àti àlùfáà fún Ọlọ́run wa,+ wọ́n sì máa ṣàkóso bí ọba+ lé ayé lórí.”
11 Mo rí ọ̀pọ̀ áńgẹ́lì, mo sì gbọ́ ohùn wọn, wọ́n wà yí ká ìtẹ́ náà àti àwọn ẹ̀dá alààyè àti àwọn àgbààgbà náà, iye wọn jẹ́ ẹgbẹẹgbàárùn-ún lọ́nà ẹgbẹẹgbàárùn-ún* àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún,+ 12 wọ́n ń ké jáde pé: “Ọ̀dọ́ Àgùntàn tí wọ́n pa+ ló yẹ láti gba agbára àti ọrọ̀ àti ọgbọ́n àti okun àti ọlá àti ògo àti ìbùkún.”+
13 Mo gbọ́ tí gbogbo ẹ̀dá tó wà ní ọ̀run àti ayé àti lábẹ́ ilẹ̀+ àti lórí òkun àti gbogbo ohun tó wà nínú wọn, ń sọ pé: “Kí ìbùkún àti ọlá+ àti ògo àti agbára jẹ́ ti Ẹni tó jókòó sórí ìtẹ́ náà+ àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà+ títí láé àti láéláé.”+ 14 Àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà ń sọ pé: “Àmín!” àwọn àgbààgbà náà wólẹ̀, wọ́n sì jọ́sìn.