Ìwé Kejì sí Àwọn Ará Kọ́ríńtì
9 Ní ti iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó wà fún àwọn ẹni mímọ́,+ kò pọn dandan kí n kọ̀wé sí yín, 2 torí mo mọ bó ṣe ń yá yín lára, mo sì fi ń yangàn lójú àwọn ará Makedóníà, pé ó ti pé ọdún kan báyìí tí Ákáyà ti múra tán, ìtara yín sì ti mú kí èyí tó pọ̀ jù nínú wọn gbára dì. 3 Àmọ́ mò ń rán àwọn arákùnrin náà sí yín, kí gbogbo bí a ṣe ń fi yín yangàn má bàa já sí asán nínú ọ̀ràn yìí, kí ẹ sì lè múra tán lóòótọ́, bí mo ṣe sọ pé ẹ máa ṣe. 4 Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, tí àwọn ará Makedóníà bá bá mi wá, tí wọ́n sì rí i pé ẹ ò múra sílẹ̀, ìtìjú á bá wa, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ẹ̀yin, torí pé a fọkàn tán yín. 5 Nítorí náà, mo wò ó pé ó ṣe pàtàkì láti fún àwọn arákùnrin náà ní ìṣírí pé kí wọ́n wá sọ́dọ̀ yín ṣáájú àkókò, kí wọ́n sì múra ọ̀pọ̀ ẹ̀bùn tí ẹ ti ṣèlérí sílẹ̀, kí èyí lè wà nílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ àtinúwá, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun tí èèyàn fipá gbà.
6 Àmọ́ ní ti èyí, ẹni tó bá ń fúnrúgbìn díẹ̀ máa kórè díẹ̀, ẹni tó bá sì ń fúnrúgbìn yanturu máa kórè yanturu.+ 7 Kí kálukú ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu nínú ọkàn rẹ̀, kì í ṣe pẹ̀lú lílọ́ra tàbí lábẹ́ àfipáṣe,*+ nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ẹni tó ń fúnni pẹ̀lú ìdùnnú.+
8 Yàtọ̀ síyẹn, Ọlọ́run lè mú kí gbogbo inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ pọ̀ gidigidi fún yín, kí ẹ lè máa ní ànító ohun gbogbo nígbà gbogbo, kí ẹ sì tún ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ fún iṣẹ́ rere gbogbo.+ 9 (Bó ṣe wà lákọsílẹ̀ pé: “Ó ti pín nǹkan fún àwọn èèyàn káàkiri,* ó ti fún àwọn aláìní. Òdodo rẹ̀ wà títí láé.”+ 10 Ẹni tó ń pèsè irúgbìn lọ́pọ̀ yanturu fún afúnrúgbìn àti oúnjẹ fún jíjẹ máa pèsè irúgbìn, ó máa sọ ọ́ di púpọ̀ fún yín láti gbìn, á sì mú èso òdodo yín pọ̀ sí i.) 11 Ọlọ́run ti bù kún yín ní gbogbo ọ̀nà, kí ẹ lè máa fúnni lóríṣiríṣi ọ̀nà, èyí sì ń mú ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run; 12 nítorí iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí ẹ̀ ń ṣe fún àwọn èèyàn kì í ṣe láti fún àwọn ẹni mímọ́ ní ohun tí wọ́n nílò nìkan,+ ó tún máa mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run. 13 Ohun tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìrànwọ́ yìí ń ṣe jẹ́ ẹ̀rí, èyí sì ń mú kí wọ́n máa yin Ọlọ́run lógo torí pé ẹ̀ ń ṣègbọràn sí ìhìn rere nípa Kristi, bí ẹ ṣe kéde fún àwọn èèyàn, tí ẹ sì jẹ́ ọ̀làwọ́ nínú ọrẹ tí ẹ̀ ń ṣe fún wọn àti fún gbogbo èèyàn.+ 14 Wọ́n fi ìfẹ́ hàn sí yín bí wọ́n ṣe ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ fún yín, torí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run títayọ tó wà lórí yín.
15 Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nítorí ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ rẹ̀ tí kò ṣeé ṣàpèjúwe.