Hágáì
1 Ní ọdún kejì tí Ọba Dáríúsì ń ṣàkóso, ní oṣù kẹfà, ní ọjọ́ kìíní oṣù náà, Jèhófà rán wòlíì Hágáì*+ pé kó sọ fún Serubábélì+ ọmọ Ṣéálítíẹ́lì, gómìnà Júdà àti Jóṣúà ọmọ Jèhósádákì, àlùfáà àgbà pé:
2 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí, ‘Àwọn èèyàn yìí sọ pé: “Kò tíì tó àkókò láti kọ́ ilé* Jèhófà.”’”*+
3 Jèhófà tún rán wòlíì Hágáì+ pé: 4 “Ṣé àsìkò yìí ló yẹ kí ẹ máa gbé inú àwọn ilé yín tí ẹ fi pákó ṣe lọ́ṣọ̀ọ́, nígbà tí ilé yìí ti di àwókù?+ 5 Ní báyìí, ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí, ‘Ẹ kíyè sí* àwọn ohun tí ẹ̀ ń ṣe. 6 Ẹ ti fún irúgbìn tó pọ̀, àmọ́ irè oko díẹ̀ ni ẹ kó.+ Ẹ̀ ń jẹun, àmọ́ ẹ ò yó. Ẹ̀ ń mu, àmọ́ kò tẹ́ yín lọ́rùn. Ẹ̀ ń wọṣọ, àmọ́ ara ẹnì kankan yín ò móoru. Inú ajádìí àpò ni ẹni tí wọ́n gbà síṣẹ́ ń kó owó iṣẹ́ rẹ̀ sí.’”
7 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí, ‘Ẹ kíyè sí* àwọn ohun tí ẹ̀ ń ṣe.’
8 “‘Ẹ gun orí òkè lọ, kí ẹ sì gbé igi gẹdú wá.+ Kí ẹ sì kọ́ ilé náà,+ kí inú mi lè dùn sí i, kí a sì lè yìn mí lógo,’+ ni Jèhófà wí.”
9 “‘Ohun tó pọ̀ ni ẹ̀ ń retí, àmọ́ díẹ̀ ni ẹ̀ ń rí gbà; nígbà tí ẹ sì mú un wá sínú ilé, mo fẹ́ ẹ dà nù.+ Kí nìdí?’ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí. ‘Torí ilé mi ti di àwókù, kálukú yín sì ń sá kiri kó lè bójú tó ilé tirẹ̀.+ 10 Torí náà, ọ̀run ò sẹ ìrì, ilẹ̀ ò sì mú èso jáde. 11 Mo sì mú kí ọ̀dá wà lórí ayé, lórí àwọn òkè, lórí ọkà, lórí wáìnì tuntun, lórí òróró, lórí ohun tó ń hù lórí ilẹ̀, lórí èèyàn àti ẹran ọ̀sìn àti gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín.’”
12 Serubábélì+ ọmọ Ṣéálítíẹ́lì+ àti Jóṣúà ọmọ Jèhósádákì,+ àlùfáà àgbà àti gbogbo àwọn tó ṣẹ́ kù nínú àwọn èèyàn náà fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run wọn àti sí ọ̀rọ̀ wòlíì Hágáì, torí Jèhófà Ọlọ́run wọn ló rán an; àwọn èèyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ̀rù Jèhófà.
13 Hágáì ìránṣẹ́ Jèhófà wá jíṣẹ́ fún àwọn èèyàn bí Jèhófà ṣe rán an pé: “‘Mo wà pẹ̀lú yín,’+ ni Jèhófà wí.”
14 Torí náà, Jèhófà ru ẹ̀mí+ Serubábélì ọmọ Ṣéálítíẹ́lì, gómìnà Júdà+ sókè, ó tún ru ẹ̀mí Jóṣúà+ ọmọ Jèhósádákì, àlùfáà àgbà sókè àti ẹ̀mí gbogbo àwọn tó ṣẹ́ kù nínú àwọn èèyàn náà; wọ́n wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àtúnkọ́ ilé Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun tó jẹ́ Ọlọ́run wọn.+ 15 Èyí jẹ́ ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹfà ní ọdún kejì tí Ọba Dáríúsì ń ṣàkóso.+