“Èmi Wà Pẹ̀lú Yín”
‘Ońṣẹ́ Jèhófà ń bá a lọ láti sọ pé: “ ‘Èmi wà pẹ̀lú yín,’ ni àsọjáde Jèhófà.” ’—HÁGÁÌ 1:13.
1. Ìtàn wo ni Jésù tọ́ka sí tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìgbà tiwa yìí?
ÀKÓKÒ tó ṣe pàtàkì gan-an nínú ìtàn ìran èèyàn là ń gbé yìí. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó ń ṣẹ jẹ́ ká mọ̀ pé a ti wà ní “ọjọ́ Olúwa” láti ọdún 1914. (Ìṣípayá 1:10) Ó ṣeé ṣe kó o ti mọ̀ nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí. Nípa bẹ́ẹ̀, wàá ti mọ̀ pé Jésù fi “àwọn ọjọ́ [tí] Ọmọ ènìyàn” yóò bẹ̀rẹ̀ Ìjọba rẹ̀ wé “àwọn ọjọ́ Nóà” àti “àwọn ọjọ́ Lọ́ọ̀tì.” (Lúùkù 17:26, 28) Bíbélì tipa báyìí fi hàn pé àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Nóà àti ti Lọ́ọ̀tì jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ nígbà tiwa yìí. Ṣùgbọ́n ìṣẹ̀lẹ̀ míì náà tún wà tó bá ìgbà tiwa mu, tó yẹ ká fara balẹ̀ gbé yẹ̀ wò.
2. Iṣẹ́ wo ni Jèhófà gbé lé Hágáì àti Sekaráyà lọ́wọ́?
2 Ẹ jẹ́ ká wo ohun kan tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé àwọn wòlíì méjì kan tí wọ́n jẹ́ Hébérù, ìyẹn Hágáì àti Sekaráyà. Ọ̀rọ̀ wo làwọn wòlíì méjì tó jẹ́ olóòótọ́ yìí sọ tó kan àwọn èèyàn Jèhófà gbọ̀ngbọ̀n nígbà tiwa yìí? Hágáì àti Sekaráyà jẹ́ ‘ońṣẹ́ tí Jèhófà rán’ sáwọn Júù lẹ́yìn tí wọ́n dé láti ìgbèkùn ní Bábílónì. Iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wọn lọ́wọ́ ni pé kí wọ́n fi dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lójú pé Ọlọ́run wà lẹ́yìn wọn lẹ́nu iṣẹ́ tẹ́ńpìlì tí wọ́n ń tún kọ́. (Hágáì 1:13; Sekaráyà 4:8, 9) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwé tí Hágáì àti Sekaráyà kọ kò fi bẹ́ẹ̀ gùn, wọ́n wà lára “gbogbo Ìwé Mímọ́ [tí] Ọlọ́run mí sí, [tó] sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo.”—2 Tímótì 3:16.
Ó Yẹ Ká Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Wọn
3, 4. Kí nìdí tó fi yẹ ká kíyè sí àsọtẹ́lẹ̀ Hágáì àti ti Sekaráyà?
3 Kò sí àní-àní pé ọ̀rọ̀ Hágáì àti Sekaráyà ṣe àwọn Júù ìgbà ayé wọn láǹfààní gan-an, àti pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọn ṣẹ láyé ìgbà náà. Àmọ́, kí ló máa jẹ́ kó dá wa lójú pé ọ̀rọ̀ inú ìwé Hágáì àti Sekaráyà kàn wá lóde òní? Ọ̀rọ̀ inú Hébérù 12:26-29 jẹ́ ká mọ̀ pé ó kàn wá. Nínú ìwé Hébérù yìí, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fa ọ̀rọ̀ inú Hágáì 2:6 yọ, èyí tó sọ nípa bí Ọlọ́run ṣe máa “mi ọ̀run àti ilẹ̀ ayé . . . jìgìjìgì.” Mímì tí Ọlọ́run máa mi ọ̀run àti ayé ni yóò ‘bi ìtẹ́ àwọn ìjọba ṣubú, tí yóò sì pa okun ìjọba àwọn orílẹ̀-èdè rẹ́ ráúráú.’—Hágáì 2:22.
4 Bí Pọ́ọ̀lù ṣe fa ọ̀rọ̀ Hágáì yọ tán ló sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí “ìjọba àwọn orílẹ̀-èdè,” ó sì wá sọ̀rọ̀ nípa bí ìjọba tí kò ṣeé mì, táwọn Kristẹni ẹni àmì òróró yóò gbà ṣe ju Ìjọba èyíkéyìí lọ. (Hébérù 12:27, 28) Èyí jẹ́ ká rí i pé lákòókò tí Pọ́ọ̀lù ń kọ ìwé Hébérù ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni, ohun tó máa ṣẹ lọ́jọ́ iwájú ni àsọtẹ́lẹ̀ Hágáì àti ti Sekaráyà jẹ́. Àṣẹ́kù àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọn yóò bá Jésù ṣe Ìjọba Mèsáyà ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé lónìí. Èyí fi hàn pé àsọtẹ́lẹ̀ Hágáì àti ti Sekaráyà ní láti kan àwa tá à ń gbé lóde òní.
5, 6. Kí làwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ kí Hágáì àti Sekaráyà tó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àsọtẹ́lẹ̀ wọn?
5 Ìwé Ẹ́sírà jẹ́ ká mọ àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ kí Hágáì àti Sekaráyà tó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àsọtẹ́lẹ̀. Lẹ́yìn táwọn Júù padà dé láti ìgbèkùn ní Bábílónì lọ́dún 537 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Gómìnà Serubábélì àti Jóṣúà (tàbí Jéṣúà) tó jẹ́ àlùfáà àgbà bojú tó àwọn tó fi ìpìlẹ̀ tẹ́ńpìlì tuntun lélẹ̀ lọ́dún 536 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. (Ẹ́sírà 3:8-13; 5:1) Bí wọ́n ṣe fi ìpìlẹ̀ tẹ́ńpìlì yìí lélẹ̀ múnú àwọn Júù dùn gan-an, àmọ́ kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni ẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ sí í bà wọ́n. Ẹ́sírà 4:4 sọ pé: “Àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà [ìyẹn àwọn ọ̀tá] ń bá a lọ ní sísọ ọwọ́ àwọn ènìyàn Júdà di aláìlera, wọ́n sì ń sọ ọkàn wọn domi láti má ṣe kọ́lé.” Àwọn ọ̀tá yìí, pàápàá àwọn ará Samáríà, fi onírúurú ẹ̀sùn èké kan àwọn Júù. Àwọn alátakò yìí sì rí sí i pé ọba Páṣíà gbẹ́sẹ̀ lé iṣẹ́ tẹ́ńpìlì tí wọ́n ń kọ́.—Ẹ́sírà 4:10-21.
6 Bí ìrẹ̀wẹ̀sì ṣe bá àwọn Júù lórí iṣẹ́ tẹ́ńpìlì tí wọ́n ń kọ́ nìyẹn. Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í lépa àwọn nǹkan tara wọn. Àmọ́ lọ́dún 520 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ìyẹn ọdún mẹ́rìndínlógún lẹ́yìn tí wọ́n fi ìpìlẹ̀ tẹ́ńpìlì lélẹ̀, Jèhófà yan Hágáì àti Sekaráyà pé kí wọ́n fún àwọn Júù níṣìírí kí wọ́n lè tún bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ kíkọ́ tẹ́ńpìlì náà padà. (Hágáì 1:1; Sekaráyà 1:1) Báwọn ońṣẹ́ Ọlọ́run ṣe ta àwọn Júù jí, tó sì wá dá wọn lójú pé Jèhófà ń bẹ lẹ́yìn wọn, wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lórí tẹ́ńpìlì náà, wọ́n sì kọ́ ọ parí lọ́dún 515 ṣáájú Sànmánì Kristẹni.—Ẹ́sírà 6:14, 15.
7. Kí ló ń ṣẹlẹ̀ lóde òní tó bá ti ìgbà ayé wòlíì Hágáì àti Sekaráyà mu?
7 Ǹjẹ́ o mọ bí gbogbo èyí ṣe kàn wá? A ṣì níṣẹ́ tó pọ̀ láti ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù “ìhìn rere ìjọba” Ọlọ́run. (Mátíù 24:14) Lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kìíní, ètò Ọlọ́run tẹnu mọ́ ọn gan-an pé ó yẹ ká máa ṣe iṣẹ́ yẹn. Gẹ́gẹ́ báwọn Júù ṣe rí ìdáǹdè kúrò ní ìgbèkùn ní Bábílónì ìgbàanì náà ni Jèhófà ṣe mú káwọn èèyàn rẹ̀ òde òní rí ìdáǹdè kúrò nínú ìgbèkùn Bábílónì Ńlá, ìyẹn àpapọ̀ ìsìn èké àgbáyé. Àwọn ẹni àmì òróró Ọlọ́run tẹra mọ́ iṣẹ́ wíwàásù àti kíkọ́ni, wọ́n sì ń darí àwọn èèyàn sí ìjọsìn tòótọ́. Iṣẹ́ náà ń bá a lọ títí dòní, àní lọ́nà tó gbòòrò sí i pàápàá. Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà tiẹ̀ wà lára àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ náà. Àkókò tó yẹ ká káràmáásìkí iṣẹ́ náà nìyí, torí òpin ètò nǹkan burúkú yìí ti dé tán! A gbọ́dọ̀ máa ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́ yìí nìṣó títí Jèhófà yóò fi dá sí ọ̀ràn ìràn ènìyàn nígbà “ìpọ́njú ńlá.” (Mátíù 24:21) Ìyẹn ni Jèhófà yóò fi palẹ̀ ìwà ibi mọ́ láyé tí ìjọsìn tòótọ́ yóò sì wá gbilẹ̀ kárí ayé.
8. Kí nìdí tá a fi lè sọ dájúdájú pé Ọlọ́run ń tì wá lẹ́yìn bá a ṣe ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù?
8 Gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ Hágáì àti ti Sekaráyà ṣe fi hàn, kò sí àní-àní pé Jèhófà ń tì wá lẹ́yìn, ó sì ń bù kún wa bá a ṣe ń fi tinútinú ṣe iṣẹ́ náà. Pẹ̀lú gbogbo ipá táwọn kan ti sà láti rí i pé wọ́n tẹ àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run rì tàbí wọ́n fòfin de iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́, kò tíì sí ìjọba èyíkéyìí tó lè dí ìtẹ̀síwájú iṣẹ́ ìwàásù lọ́wọ́. Ẹ wo bí ìtìlẹyìn Jèhófà ṣe ń mú kí iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ń ṣe gbèrú látìgbà tí Ogun Àgbáyé Kìíní ti parí títí di báyìí. Àmọ́, iṣẹ́ ṣì pọ̀ gan-an láti ṣe o.
9. Àwọn nǹkan wo ló ṣẹlẹ̀ láyé ìgbàanì tó yẹ ká kíyè sí, kí nìdí tó sì fi yẹ ká kíyè sí wọn?
9 Báwo ni ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́ látinú ìwé Hágáì àti Sekaráyà ṣe lè fún wa níṣìírí ká bàa lè túbọ̀ tẹra mọ́ iṣẹ́ wíwàásù àti kíkọ́ni tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́? Ó dára, ẹ jẹ́ ká wo àwọn ẹ̀kọ́ tá a lè rí kọ́ látinú ìwé Bíbélì méjèèjì yìí ná. Bí àpẹẹrẹ, wo àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ kan tó jẹ mọ́ iṣẹ́ kíkọ́ tẹ́ńpìlì táwọn Júù tí Ọlọ́run mú padà bọ̀ sípò ń ṣe. A ti kọ́kọ́ mẹ́nu kàn án tẹ́lẹ̀ pé àwọn Júù tó padà sí Jerúsálẹ́mù láti Bábílónì dáwọ́ iṣẹ́ tẹ́ńpìlì tí wọ́n ń ṣe dúró. Bí wọ́n ṣe fi ìpìlẹ̀ tẹ́ńpìlì lélẹ̀ tán ni wọ́n dẹwọ́ iṣẹ́. Èrò tí kò tọ̀nà wo ló mú káwọn Júù ṣe bẹ́ẹ̀? Ẹ̀kọ́ wo ni èyí sì kọ́ wa?
Bí A Ṣe Lè Ní Èrò Tó Tọ̀nà
10. Èrò tí kò tọ̀nà wo làwọn Júù ní, kí ni ìyẹn sì yọrí sí?
10 Àwọn Júù tí Ọlọ́run mú padà bọ̀ sípò ń sọ pé: “Àkókò kò tíì tó.” (Hágáì 1:2) Nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lórí kíkọ́ tẹ́ńpìlì, tí wọ́n fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ lọ́dún 536 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, wọn kò sọ pé “àkókò kò tíì tó.” Ṣùgbọ́n kò pẹ́ tí wọ́n fi jẹ́ kí àtakò àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká àti ìdíwọ́ látọ̀dọ̀ ìjọba mú kí wọ́n dẹwọ́ iṣẹ́. Àwọn Júù wá gbájú mọ́ iṣẹ́ ilé tara wọn àti ìgbádùn ara wọn. Nígbà tí Jèhófà wo bí wọ́n ṣe pa tẹ́ńpìlì tì tí wọ́n ń fi ojúlówó igi dárà sí ilé tiwọn, ó bi wọ́n pé: “Àkókò ha nìyí fún ẹ̀yin láti máa gbé nínú àwọn ilé yín tí a fi igi pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ ṣe ọ̀ṣọ́ sí, nígbà tí ilé yìí wà ní ipò ahoro?”—Hágáì 1:4.
11. Kí nìdí tí Jèhófà fi bá àwọn Júù ìgbà ayé Hágáì wí?
11 Àwọn nǹkan mìíràn làwọn Júù yìí kà sí pàtàkì ju tẹ́ńpìlì tí wọ́n ń kọ́ lọ. Dípò tí wọn ì bá fi fi iṣẹ́ àtúnkọ́ tẹ́ńpìlì tí Jèhófà fẹ́ kí wọ́n ṣe ṣáájú, ọ̀rọ̀ ara wọn àti ilé wọn ni wọ́n gbájú mọ́. Wọ́n wá pa iṣẹ́ ilé ìjọsìn Ọlọ́run tì. Jèhófà sì sọ ọ̀rọ̀ tó wà nínú Hágáì 1:5 láti fi gba àwọn Júù níyànjú pé kí wọ́n ‘fi ọkàn wọn sí àwọn ọ̀nà wọn.’ Ohun tí Jèhófà ń fi ìyẹn sọ ni pé kí wọ́n fara balẹ̀ ronú nípa ohun tí wọ́n ń ṣe, kí wọ́n sì wo irú àkóbá tí àìfi iṣẹ́ kíkọ́ tẹ́ńpìlì sípò àkọ́kọ́ ń ṣe fún wọn.
12, 13. Báwo ni Hágáì 1:6 ṣe ṣàpèjúwe ipò táwọn Júù wà, kí sì ni ìtumọ̀ ẹsẹ yẹn?
12 Wàá rí i pé báwọn Júù ṣe jẹ́ kí ohun tí kò yẹ gba iwájú lọ́kàn wọn ṣàkóbá fún wọn. Wo bí Hágáì 1:6 ṣe sọ irú ojú tí Ọlọ́run fi wo ohun tí wọ́n ṣe, ó ní: “Ẹ ti fún irúgbìn púpọ̀, ṣùgbọ́n díẹ̀ ni ẹ ń mú wọlé. Ẹ ń jẹun, ṣùgbọ́n kì í ṣe ní àjẹyó. Ẹ ń mutí, ṣùgbọ́n kì í ṣe dórí mímu àmuyó. Ẹ ń wọṣọ, ṣùgbọ́n kò sí ẹnikẹ́ni tí ó móoru; ẹni tí ó sì ń fi ara rẹ̀ háyà ń fi ara rẹ̀ háyà fún àpò tí ó ní àwọn ihò.”
13 Àwọn Júù wà lórí ilẹ̀ tí Ọlọ́run fún wọn lóòótọ́, ṣùgbọ́n ilẹ̀ náà ò méso jáde bí wọ́n ṣe fẹ́. Ìdí ni pé Jèhófà fawọ́ ìbùkún rẹ̀ sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ wọn gẹ́gẹ́ bí ìkìlọ̀ tó ti ṣe fún wọn tẹ́lẹ̀. (Diutarónómì 28:38-48) Àwọn Júù yìí ń fúnrúgbìn, àmọ́ ohun tí wọ́n ń kórè ò tó nǹkan nítorí pé Ọlọ́run ò tì wọ́n lẹ́yìn, èyí ò sì jẹ́ kí wọ́n rí oúnjẹ jẹ tó. Níwọ̀n bí Ọlọ́run ò ti fìbùkún sí ohun tí wọ́n ń ṣe, wọn ò tẹ́ni tó ń wọṣọ tó máa mú ara wọn móoru. Ńṣe ló tiẹ̀ wá dà bíi pé àpò tó luhò ni wọ́n ń kó owó tí wọ́n pa sí, èyí tó jẹ́ àdánù ńlá fáwọn òṣìṣẹ́ tó ń gbowó iṣẹ́. Kí wá ni ìtumọ̀ gbólóhùn náà: “Ẹ ń mutí, ṣùgbọ́n kì í ṣe dórí mímu àmuyó”? Kò lè túmọ̀ sí pé mímu tí wọ́n bá ń mutí para ló máa fi hàn pé Ọlọ́run ń bù kún wọn torí pé Ọlọ́run lòdì sí ìmutípara. (1 Sámúẹ́lì 25:36; Òwe 23:29-35) Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni gbólóhùn yìí túbọ̀ ń fi hàn pé Ọlọ́run fawọ́ ìbùkún rẹ̀ sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ àwọn Júù. Bí wọ́n bá pọn ọtí wáìnì, ìwọ̀nba díẹ̀ ni wọ́n máa rí. Kò ní pọ̀ tó èyí tí ọtí á fi lè pa wọ́n. Bí Bibeli Mimọ ṣe sọ ọ́ ni pé: “Ẹnyin nmu, ṣugbọn kò tẹ yin lọrun.”
14, 15. Ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n wo ni Hágáì 1:6 kọ́ wa?
14 Kì í ṣe ẹ̀kọ́ nípa bá a ṣe lè dárà sí ilé wa ni ìtàn àwọn Júù yìí ń kọ́ wa. Tipẹ́tipẹ́ ṣáájú káwọn ará Bábílónì tó kó wọn nígbèkùn ni wòlíì Ámósì ti bẹnu àtẹ́ lu àwọn ọlọ́rọ̀ Ísírẹ́lì nítorí “àwọn ilé eyín erin” tí wọ́n ń kọ́ àti bí wọ́n ṣe “ń dùbúlẹ̀ sórí àga ìrọ̀gbọ̀kú tí a fi eyín erin ṣe.” (Ámósì 3:15; 6:4) Àwọn ilé aláràbarà wọ̀nyẹn àtàwọn ohun ọ̀ṣọ́ ilé wọn kò pẹ́ lọ títí. Àwọn ọ̀tá tó ṣẹ́gun wọn ló kó nǹkan wọ̀nyẹn lọ. Síbẹ̀, lẹ́yìn táwọn èèyàn Ọlọ́run ti wà nígbèkùn fún àádọ́rin ọdún, púpọ̀ lára wọn kò fi ohun tó ṣẹlẹ̀ níṣàájú kọ́gbọ́n. Ṣé a ó fi wọ́n kọ́gbọ́n ní tiwa? Á dára kí kálukú wa bi ara rẹ̀ pé: ‘Kí n sòótọ́, báwo ni ọ̀rọ̀ ilé tàbí ibùgbé mi àti ṣíṣe ohun ọ̀ṣọ́ síbẹ̀ ṣe gbà mí lọ́kàn tó? Ọwọ́ wo ni mo fi mú ọ̀rọ̀ lílọ kàwé sí i kí n lè dépò ńlá, èyí tó jẹ́ pé ó lè gba ọ̀pọ̀ àkókò fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, débi pé mi ò ní rí àkókò tó jọjú lò fún ìjọsìn Ọlọ́run?’—Lúùkù 12:20, 21; 1 Tímótì 6:17-19.
15 Ó yẹ kí ohun tá a kà nínú Hágáì 1:6 jẹ́ ká rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an ká rí ìbùkún Ọlọ́run gbà ní ìgbésí ayé wa. Ọlọ́run ò fìbùkún síṣẹ́ àwọn Júù ayé ìgbàanì, ìyẹn sì ṣe àkóbá púpọ̀ fún wọn. Lónìí pẹ̀lú, yálà a ní ọ̀pọ̀ dúkìá tàbí a ò ní, ohun tó dájú ni pé bí a kò bá rí ìbùkún Jèhófà gbà, ìyẹn yóò ṣàkóbá púpọ̀ fún àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run. (Mátíù 25:34-40; 2 Kọ́ríńtì 9:8-12) Àmọ́, báwo la ṣe lè rí ìbùkún Ọlọ́run gbà?
Jèhófà Ń Fi Ẹ̀mí Rẹ̀ Ṣèrànwọ́
16-18. Kí ni ọ̀rọ̀ inú Sekaráyà 4:6 túmọ̀ sí fáwọn Júù ayé ìgbàanì?
16 Ọlọ́run mí sí Sekaráyà tó jẹ́ wòlíì bíi ti Hágáì pé kó sọ ọ̀nà tí Jèhófà gbà fún àwọn olùfọkànsìn ayé ìgbàanì níṣìírí àti ọ̀nà tó gbà bù kún wọn. Èyí á sì jẹ́ kó o rí ọ̀nà tó máa gbà bù kún ìwọ náà. Ó sọ pé: “‘Kì í ṣe nípasẹ̀ ẹgbẹ́ ológun, tàbí nípasẹ̀ agbára, bí kò ṣe nípasẹ̀ ẹ̀mí mi,’ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí.” (Sekaráyà 4:6) Ó ṣeé ṣe kó o ti máa gbọ́ ẹsẹ Bíbélì yìí lọ́pọ̀ ìgbà, àmọ́ kí ló túmọ̀ sí fáwọn Júù ìgbà ayé Hágáì àti Sekaráyà, báwo ló sì ṣe kàn ọ́?
17 Rántí pé iṣẹ́ kékeré kọ́ lọ̀rọ̀ Hágáì àti ti Sekaráyà ṣe lára àwọn Júù ìgbà ayé wọn. Ohun táwọn wòlíì méjèèjì yìí sọ ta àwọn Júù olóòótọ́ jí. Oṣù kẹfà ọdún 520 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni Hágáì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àsọtẹ́lẹ̀, Sekaráyà sì bẹ̀rẹ̀ tirẹ̀ ní oṣù kẹjọ ọdún yẹn kan náà. (Sekaráyà 1:1) Hágáì 2:18 jẹ́ ká mọ̀ pé oṣù kẹsàn-án ni wọ́n padà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní pẹrẹu lórí ìpìlẹ̀ tẹ́ńpìlì náà. Àsọtẹ́lẹ̀ wọn ló mú kí orí àwọn Júù yá gágá sí iṣẹ́ náà, tí wọ́n sì ṣe ohun tí Jèhófà wí pẹ̀lú ìdánilójú pé ó ń bẹ lẹ́yìn àwọn. Èyí jẹ́ ká rí i pé ọ̀rọ̀ bí Ọlọ́run ṣe ń tì wọ́n lẹ́yìn ni Sekaráyà 4:6 ń sọ.
18 Nígbà táwọn Júù padà sí ìlú wọn lọ́dún 537 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, wọn ò ní ẹgbẹ́ ológun. Síbẹ̀, Jèhófà dáàbò bò wọ́n, ó sì ṣamọ̀nà wọn délé láti Bábílónì. Ẹ̀mí rẹ̀ ló darí wọn nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lórí tẹ́ńpìlì láìpẹ́ sígbà tí wọ́n ti ìgbèkùn dé. Bí wọ́n bá sì tún bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ yẹn tọkàntọkàn, Jèhófà yóò fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ tì wọ́n lẹ́yìn.
19. Alágbára wo ló ń ṣèdíwọ́, àmọ́ tí ẹ̀mí Ọlọ́run borí rẹ̀?
19 Ìran mẹ́jọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Sekaráyà rí, tí Jèhófà fi mú kó dá a lójú pé òun yóò wà pẹ̀lú àwọn èèyàn òun tí wọ́n bá ń fi tọkàntọkàn bá iṣẹ́ tẹ́ńpìlì kíkọ́ náà lọ títí dé ìparí rẹ̀. Ìran kẹrin, èyí tó wà ní orí kẹta ìwé Sekaráyà, fi hàn pé Sátánì ń jin gbogbo ìsapá táwọn Júù ń ṣe láti parí kíkọ́ tẹ́ńpìlì náà lẹ́sẹ̀. (Sekaráyà 3:1) Ó dájú pé kò ní dùn mọ́ Sátánì nínú láti rí i pé Jóṣúà Àlùfáà Àgbà ń ṣe iṣẹ́ àlùfáà fáwọn èèyàn nínú tẹ́ńpìlì tuntun. Àmọ́ bó tilẹ̀ jẹ́ pé Èṣù ò jáwọ́ nínú ìdíwọ́ tó ń ṣe fáwọn Júù lẹ́nu iṣẹ́ tẹ́ńpìlì tí wọ́n ń kọ́, ẹ̀mí Jèhófà ṣe bẹbẹ fáwọn Júù débi pé gbogbo ohun ìdènà kúrò lọ́nà, ẹ̀mí yẹn sì tún fún wọn lágbára tí wọ́n fi kọ́ tẹ́ńpìlì náà parí.
20. Báwo ni ẹ̀mí mímọ́ ṣe ṣèrànwọ́ fáwọn Júù tí wọ́n fi lè parí iṣẹ́ tí Ọlọ́run ní kí wọ́n ṣe?
20 Àwọn òṣìṣẹ́ ọba dojú àtakò kọ àwọn Júù, wọ́n rí sí i pé ọba gbẹ́sẹ̀ lé iṣẹ́ tẹ́ńpìlì náà. Ìyẹn wá dà bí òkè ìṣòro níwájú àwọn Júù. Ṣùgbọ́n, Jèhófà ṣèlérí pé òun yóò bi ohun tó dà bí “òkè ńlá” yìí wó, yóò sì di “ilẹ̀ títẹ́jú pẹrẹsẹ.” (Sekaráyà 4:7) Ohun tó sì ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn! Dáríúsì Ọba Kìíní ṣèwádìí ó sì rí ìwé kan tí Kírúsì kọ láti fi yọ̀ǹda pé káwọn Júù tún tẹ́ńpìlì náà kọ́. Dáríúsì wá fagi lé òfin tí wọ́n fi de iṣẹ́ wọn, ó sì ní kí wọ́n mú owó fáwọn Júù látinú ìṣúra ọba, kí wọ́n fi bójú tó ìnáwó iṣẹ́ tẹ́ńpìlì. Àyípadà yìí mà ga o! Ǹjẹ́ ẹ̀mí Ọlọ́run ló darí ọba yìí? Ó dájú pé òun ni. Wọ́n kọ́ tẹ́ńpìlì náà parí lọ́dún 515 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ìyẹn ọdún kẹfà tí Dáríúsì Kìíní di ọba.—Ẹ́sírà 6:1, 15.
21. (a) Láyé ìgbàanì, báwo ni Ọlọ́run ṣe “mi gbogbo orílẹ̀-èdè jìgìjìgì,” báwo sì ni “àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra” inú wọn ṣe jáde wá? (b) Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe ṣẹ lóde òní?
21 Nínú Hágáì 2:5, wòlíì Hágáì rán àwọn Júù létí májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá wọn dá lẹ́bàá Òkè Sínáì, nígbà tí “gbogbo òkè ńlá náà . . . ń wárìrì gidigidi.” (Ẹ́kísódù 19:18) Jèhófà fẹ́ ṣe ohun tó tún máa fa ìwárìrì nígbà ayé Hágáì àti Sekaráyà gẹ́gẹ́ bí Hágáì 2:6, 7 ṣe fi hàn lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Ńṣe ni nǹkan máa dà rú ní gbogbo ilẹ̀ tí Páṣíà ń ṣàkóso lé lórí, àmọ́ iṣẹ́ táwọn Júù ń ṣe lórí tẹ́ńpìlì yóò máa tẹ̀ síwájú títí tí yóò fi parí. “Àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra tí ń bẹ nínú gbogbo orílẹ̀-èdè,” ìyẹn àwọn tí kì í ṣe Júù, yóò wá bẹ̀rẹ̀ sí í yin Ọlọ́run lógo pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn Júù nínú tẹ́ńpìlì náà. Ohun kan náà ti ṣẹlẹ̀ lọ́nà tó ga ju ìwọ̀nyí lọ ní àkókò tiwa yìí. Ohun náà ni pé Ọlọ́run ti lo iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe láti fi ‘mi gbogbo orílẹ̀-èdè jìgìjìgì,’ “àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra tí ń bẹ nínú gbogbo orílẹ̀-èdè” sì ti ń wọlé wá láti máa bá àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró jọ́sìn Ọlọ́run pọ̀. Ní báyìí, ńṣe làwọn ẹni àmì òróró àtàwọn àgùntàn mìíràn yìí jọ ń fi ògo kún inú ilé Jèhófà. Ìgbàgbọ́ táwọn olùjọ́sìn tòótọ́ wọ̀nyí ní nínú Ọlọ́run ló mú kí wọ́n máa dúró de àkókò tí Jèhófà máa ‘mi ọ̀run àti ilẹ̀ ayé jìgìjìgì’ lọ́nà mìíràn. Ńṣe ni Jèhófà yóò fi mímì yẹn bi okun tàbí agbára ìjọba àwọn orílẹ̀-èdè ṣubú, tí yóò sì pa wọ́n rẹ́ ráúráú.—Hágáì 2:22.
22. Báwo ni Jèhófà ṣe ‘ń mi àwọn orílẹ̀-èdè jìgìjìgì,’ kí ni ìyẹn ti yọrí sí, kí ló sì máa tó ṣẹlẹ̀?
22 Àwọn nǹkan wọ̀nyí mú wa rántí ìrọ́kẹ̀kẹ̀ kan tó ti wáyé láàárín àwọn ohun tí “ọ̀run àti ilẹ̀ ayé àti òkun àti ilẹ̀ gbígbẹ” dúró fún. Ọ̀kan ni ti Sátánì Èṣù àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ tí Jésù fi sọ̀kò sí àgbègbè ilẹ̀ ayé. (Ìṣípayá 12:7-12) Bákan náà, ó dájú pé iṣẹ́ ìwàásù táwọn ẹni àmì òróró ń múpò iwájú nínú rẹ̀ ti mi àwọn èèyàn tó jẹ́ ara ètò àwọn nǹkan yìí jìgìjìgì. (Ìṣípayá 11:18) Pẹ̀lú bí gbogbo èyí ṣe ń ṣẹlẹ̀, ńṣe ni “ogunlọ́gọ̀ ńlá” èèyàn tí wọ́n jẹ́ ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra látinú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ń jáde wá láti dara pọ̀ mọ́ Ísírẹ́lì tẹ̀mí láti máa sin Jèhófà. (Ìṣípayá 7:9, 10) Àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí ń bá àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ṣiṣẹ́ pọ̀, wọ́n jọ ń wàásù ìhìn rere pé Ọlọ́run yóò fi ogun Amágẹ́dọ́nì mi àwọn orílẹ̀-èdè jìgìjìgì láìpẹ́. Lẹ́yìn ìyẹn, aráyé yóò lè máa ṣe ìjọsìn tòótọ́ bó ṣe yẹ kó rí gan-an kárí ayé.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Ìgbà wo ni Hágáì àti Sekaráyà ṣe iṣẹ́ wòlíì, kí làwọn ohun tó sì ń ṣẹlẹ̀ nígbà náà?
• Báwo lo ṣe lè fi ọ̀rọ̀ Hágáì àti ti Sekaráyà sílò?
• Kí nìdí tí Sekaráyà 4:6 fi jẹ́ ọ̀rọ̀ ìṣírí fún ọ?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Ìwé Hágáì àti ti Sekaráyà mú kó dá wa lójú pé Ọlọ́run ń bẹ lẹ́yìn wa
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
“Àkókò ha nìyí fún ẹ̀yin láti máa gbé nínú àwọn ilé yín tí a fi igi pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ ṣe ọ̀ṣọ́ sí, nígbà tí ilé yìí wà ní ipò ahoro?”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Àwọn èèyàn Jèhófà ń kópa nínú iṣẹ́ wíwàásù fún ‘àwọn ẹni fífani-lọ́kàn-mọ́ra látinú àwọn orílẹ̀-èdè’