Hósíà
2 Àmọ́, ọkàn wọn ò sọ fún wọn pé màá rántí gbogbo ìwà ìkà wọn.+
Ní báyìí, ohun tí wọ́n ṣe ti hàn síta;
Wọ́n wà ní iwájú mi.
3 Wọ́n ń fi ìwà ìkà wọn mú inú ọba dùn,
Wọ́n sì ń fi ẹ̀tàn wọn mú inú àwọn ìjòyè dùn.
4 Alágbèrè ni gbogbo wọn,
Ara wọn ń gbóná bí iná ààrò ẹni tó ń ṣe búrẹ́dì,
Tí kò nílò láti kò ó mọ́ látìgbà tó ti po ìyẹ̀fun títí á fi wú.
5 Lọ́jọ́ àjọyọ̀ ọba wa, àwọn ìjòyè ń ṣàìsàn,
Wáìnì ti mú kí wọ́n bínú.+
Ọba ti tẹ́wọ́ gba àwọn afiniṣẹ̀sín.
6 Nítorí wọ́n wá pẹ̀lú ìfẹ́ ọkàn wọn tó ń jó bí iná ààrò.*
Ẹni tó ń ṣe búrẹ́dì fi gbogbo òru sùn;
Ní òwúrọ̀, iná ààrò náà ti ń jó fòfò.
7 Gbogbo wọn gbóná bí ààrò,
Wọ́n sì jẹ àwọn alákòóso* wọn run.
8 Éfúrémù ti dara pọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè.+
Éfúrémù dà bí àkàrà tí a kò yí ẹ̀yìn rẹ̀ pa dà.
9 Àwọn àjèjì ti gba okun rẹ̀ tán,+ ṣùgbọ́n kò mọ̀.
Irun orí rẹ̀ ti di funfun, síbẹ̀ kò kíyè sí i.
10 Ìwà Ísírẹ́lì ti jẹ́rìí sí i pé ó gbéra ga,+
Síbẹ̀ wọn kò pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run wọn,+
Bẹ́ẹ̀ ni wọn kò wá a pẹ̀lú adúrú ohun tí wọ́n ṣe yìí.
11 Éfúrémù dà bí àdàbà tó gọ̀, tí kò ní làákàyè.*+
Wọ́n ti ké pe Íjíbítì;+ wọ́n ti lọ sí Ásíríà.+
12 Ibikíbi tí wọn ì báà lọ, màá fi àwọ̀n mi mú wọn.
Màá mú wọn wálẹ̀ bí ẹyẹ ojú ọ̀run.
Màá bá wọn wí lọ́nà tí mo gbà kìlọ̀ fún àpéjọ wọn.+
13 Wọ́n gbé! Torí wọ́n sá kúrò lọ́dọ̀ mi.
Ìparun á bá wọn, torí wọ́n ti ṣẹ̀ mí!
Mo ṣe tán láti rà wọ́n pa dà, àmọ́ wọ́n pa irọ́ mọ́ mi.+
14 Wọn ò ké pè mí látinú ọkàn wọn fún ìrànlọ́wọ́,+
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń sunkún ṣáá lórí ibùsùn wọn.
Torí ọkà wọn àti wáìnì tuntun wọn, wọ́n ń fi nǹkan ya ara wọn;
Wọ́n kẹ̀yìn sí mi.
15 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo bá wọn wí tí mo sì fún wọn lókun,
Wọ́n kẹ̀yìn sí mi, wọ́n sì ń gbèrò ibi.
Idà ni yóò pa àwọn olórí wọn nítorí ahọ́n wọn mú.
Torí èyí, wọ́n á di ẹni ẹ̀sín ní ilẹ̀ Íjíbítì.”+