Jóòbù
13 “Àní ojú mi ti rí gbogbo èyí,
Etí mi ti gbọ́, ó sì ti yé mi.
2 Ohun tí ẹ mọ̀ ni èmi náà mọ̀;
Mi ò kéré sí yín.
3 Ní tèmi, màá kúkú bá Olódùmarè fúnra rẹ̀ sọ̀rọ̀;
Ọlọ́run ni mo fẹ́ ro ẹjọ́ mi fún.+
4 Ẹ̀ ń fi irọ́ bà mí lórúkọ jẹ́;
Oníṣègùn tí kò wúlò ni gbogbo yín.+
5 Ká ní ẹ lè dákẹ́ láìsọ nǹkan kan ni,
Ìyẹn ì bá fi hàn pé ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n!+
6 Ẹ jọ̀ọ́, ẹ tẹ́tí gbọ́ àlàyé mi,
Kí ẹ sì fiyè sí àrọwà ètè mi.
7 Ṣé ẹ máa sọ̀rọ̀ tí kò tọ́ láti gbèjà Ọlọ́run,
Ṣé ẹ fẹ́ sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn láti gbè é lẹ́yìn?
8 Ṣé ẹ máa gbè sẹ́yìn rẹ̀,*
Ṣé ẹ fẹ́ máa gbèjà Ọlọ́run tòótọ́ ni?
9 Tó bá yẹ̀ yín wò, ṣé ibi tó dáa ló máa já sí?+
Àbí ẹ máa tàn án jẹ bí ẹ ṣe máa tan ẹni kíkú?
10 Tí ẹ bá gbìyànjú láti ṣe ojúsàájú níkọ̀kọ̀,+
Ó dájú pé ó máa bá yín wí.
11 Ṣé iyì rẹ̀ pàápàá kò ní kó jìnnìjìnnì bá yín,
Ṣé ẹ̀rù rẹ̀ kò sì ní bà yín?
12 Àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n* yín jẹ́ òwe tó dà bí eérú;
Àwọn ohun tí ẹ fi ń gbèjà ara yín* ò lágbára, wọ́n dà bí ohun tí wọ́n fi amọ̀ ṣe.
13 Ẹ dákẹ́ níwájú mi, kí n lè sọ̀rọ̀.
Kí ohunkóhun tó bá wá fẹ́ ṣẹlẹ̀ sí mi ṣẹlẹ̀!
17 Ẹ fetí sílẹ̀ dáadáa sí ọ̀rọ̀ mi;
Ẹ fiyè sí ohun tí mo fẹ́ sọ.
18 Ẹ wò ó, mo ti múra ẹjọ́ mi sílẹ̀ báyìí;
Mo mọ̀ pé èmi ni mo jàre.
19 Ta ló máa bá mi fà á?
Màá kú tí mo bá dákẹ́!*
20 Ohun méjì péré ni kí o ṣe fún mi, ìwọ Ọlọ́run,*
Kí n má bàa fi ara mi pa mọ́ níwájú rẹ:
21 Gbé ọwọ́ rẹ tó wúwo jìnnà réré sí mi,
Má sì jẹ́ kí ẹ̀rù rẹ kó jìnnìjìnnì bá mi.+
22 Nínú kí o pè, kí n sì dá ọ lóhùn,
Tàbí kí o jẹ́ kí n sọ̀rọ̀, kí o sì dá mi lóhùn.
23 Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ̀, kí sì ni àṣìṣe mi?
Jẹ́ kí n mọ ìṣìnà mi àti ẹ̀ṣẹ̀ mi.
25 Ṣé o máa fẹ́ dẹ́rù ba ewé tí afẹ́fẹ́ ń gbé kiri ni,
Àbí o fẹ́ máa sáré lé àgékù pòròpórò tó ti gbẹ?
26 Torí ò ń fẹ̀sùn tó le kàn mí, o sì ń kọ ọ́ sílẹ̀ ṣáá,
O sì mú kí n jìyà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí mo dá nígbà tí mo ṣì kéré.
27 O ti ẹsẹ̀ mi mọ́ inú àbà,
Ò ń ṣọ́ gbogbo ọ̀nà mi lójú méjèèjì,
O sì ń wá ipasẹ̀ mi jáde lọ́kọ̀ọ̀kan.