Àwọn Ọba Kìíní
17 Nígbà náà, Èlíjà*+ ará Tíṣíbè, tó ń gbé ní Gílíádì+ sọ fún Áhábù pé: “Bí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì tí mò ń sìn* ti wà láàyè, kò ní sí òjò tàbí ìrì ní àwọn ọdún tó ń bọ̀, àfi nípa ọ̀rọ̀ mi!”+
2 Jèhófà bá a sọ̀rọ̀, ó ní: 3 “Kúrò ní ibí yìí, kí o forí lé ìlà oòrùn, kí o sì fara pa mọ́ sí Àfonífojì Kérítì, tó wà ní ìlà oòrùn Jọ́dánì. 4 Kí o máa mu omi láti inú odò tó wà níbẹ̀, màá sì pàṣẹ fún àwọn ẹyẹ ìwò pé kí wọ́n máa gbé oúnjẹ wá fún ọ níbẹ̀.”+ 5 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó lọ, ó sì ṣe ohun tí Jèhófà sọ; ó lọ sí Àfonífojì Kérítì tó wà ní ìlà oòrùn Jọ́dánì, ó sì dúró síbẹ̀. 6 Àwọn ẹyẹ ìwò ń gbé búrẹ́dì àti ẹran wá fún un ní àárọ̀, wọ́n tún ń gbé búrẹ́dì àti ẹran wá fún un ní ìrọ̀lẹ́, ó sì ń mu omi láti inú odò náà.+ 7 Àmọ́ lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan, odò náà gbẹ+ torí pé òjò ò rọ̀ ní ilẹ̀ náà.
8 Jèhófà bá a sọ̀rọ̀, ó ní: 9 “Dìde, lọ sí Sáréfátì, ti Sídónì, kí o sì máa gbé ibẹ̀. Wò ó! Màá pàṣẹ fún opó kan níbẹ̀, pé kí ó máa gbé oúnjẹ wá fún ọ.”+ 10 Torí náà, ó dìde, ó sì lọ sí Sáréfátì. Nígbà tó dé ẹnu ọ̀nà ìlú náà, opó kan wà níbẹ̀ tó ń ṣa igi jọ. Torí náà, ó pè é, ó sì sọ pé: “Jọ̀wọ́, bá mi fi ife bu omi díẹ̀ wá kí n mu.”+ 11 Bí ó ṣe ń lọ bù ú wá, ó pè é, ó sì sọ pé: “Jọ̀wọ́, bá mi mú búrẹ́dì díẹ̀ bọ̀.” 12 Obìnrin náà wá sọ pé: “Bí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti wà láàyè, mi ò ní búrẹ́dì kankan, àfi ẹ̀kúnwọ́ ìyẹ̀fun nínú ìkòkò àti òróró díẹ̀ nínú ìṣà kékeré.+ Ńṣe ni mò ń ṣa igi díẹ̀ jọ, kí n lè wọlé lọ ṣe nǹkan díẹ̀ fún èmi àti ọmọ mi. Lẹ́yìn tí a bá ti jẹ ẹ́ tán, a ò ní nǹkan míì, ikú ló kàn.”
13 Ni Èlíjà bá sọ fún un pé: “Má bẹ̀rù. Wọlé lọ, kí o sì ṣe bí o ṣe sọ. Àmọ́ kọ́kọ́ bá mi fi ohun tó wà nílẹ̀ ṣe búrẹ́dì ribiti kékeré kan, kí o sì gbé e wá fún mi. Lẹ́yìn náà, o lè wá ṣe nǹkan kan fún ìwọ àti ọmọ rẹ. 14 Nítorí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: ‘Ìyẹ̀fun kò ní tán nínú ìkòkò náà, òróró ò sì ní gbẹ nínú ìṣà kékeré náà títí di ọjọ́ tí Jèhófà yóò rọ òjò sórí ilẹ̀.’”+ 15 Nítorí náà, ó lọ, ó sì ṣe ohun tí Èlíjà sọ, ọ̀pọ̀ ọjọ́ ni obìnrin náà àti agbo ilé rẹ̀ pẹ̀lú Èlíjà fi rí oúnjẹ jẹ.+ 16 Ìyẹ̀fun kò tán nínú ìkòkò náà, òróró kò sì gbẹ nínú ìṣà kékeré náà, bí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà gbẹnu Èlíjà sọ.
17 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, ọmọ obìnrin tí ó ni ilé náà ṣàìsàn, àìsàn tó ṣe é sì le débi pé kò lè mí mọ́.+ 18 Ni ó bá sọ fún Èlíjà pé: “Kí ni mo ṣe fún ọ,* ìwọ èèyàn Ọlọ́run tòótọ́? Ṣé o wá rán mi létí ẹ̀ṣẹ̀ tí mo dá, kí o sì pa mí lọ́mọ ni?”+ 19 Àmọ́, ó sọ fún un pé: “Gbé ọmọ rẹ fún mi.” Nígbà náà, ó gbà á lọ́wọ́ rẹ̀, ó gbé e lọ sí yàrá orí òrùlé, níbi tó ń gbé, ó sì tẹ́ ẹ sórí ibùsùn rẹ̀.+ 20 Ó ké pe Jèhófà pé: “Jèhófà Ọlọ́run mi,+ ṣé wàá tún mú àjálù bá opó tí mò ń gbé lọ́dọ̀ rẹ̀ ni, tí o fi jẹ́ kí ọmọ rẹ̀ kú?” 21 Lẹ́yìn náà, ó nà sórí ọmọ náà ní ìgbà mẹ́ta, ó sì ké pe Jèhófà pé: “Jèhófà Ọlọ́run mi, jọ̀wọ́, mú kí ẹ̀mí* ọmọ yìí sọ jí.” 22 Jèhófà gbọ́ ẹ̀bẹ̀ Èlíjà,+ ẹ̀mí* ọmọ náà sọ jí, ó sì yè.+ 23 Èlíjà gbé ọmọ náà, ó gbé e sọ̀ kalẹ̀ láti yàrá orí òrùlé wá sínú ilé, ó sì gbé e fún ìyá rẹ̀; Èlíjà wá sọ pé: “Wò ó, ọmọ rẹ yè.”+ 24 Obìnrin náà wá sọ fún Èlíjà pé: “Mo ti wá mọ̀ báyìí pé èèyàn Ọlọ́run+ ni ọ́ lóòótọ́ àti pé ọ̀rọ̀ Jèhófà tó wà lẹ́nu rẹ jẹ́ òótọ́.”