Iwọ Ha Ni Igbagbọ Bii Ti Elija Bi?
AWUJỌ eniyan lonii foju tín-ín-rín igbagbọ. Awọn amòye rẹ́rìn-ín ẹlẹ́ yà si wíwà Ọlọrun. Agabagebe isin fi Ọlọrun ṣe ẹlẹ́yà. Ayé alaijẹ tẹmi sì ń hùwà siwaju ati siwaju bi ẹni pe Ọlọrun kò tilẹ jámọ́ nǹkan. Yala ẹmi ironu wọnyi dáyà fo ẹnikan, tabi kó irẹwẹsi bá a, tabi kó ẹmi aibikita ràn án, ninu ọran eyikeyii abajade naa jẹ́ ọ̀kan naa: Igbagbọ rẹ̀ yìnrìn. Abajọ ti apọsiteli Pọọlu fi pe aini igbagbọ ni “ẹṣẹ tí ó rọrun lati dì mọ́ wa”!—Heberu 12:1.
Boya idi niyẹn ti Pọọlu fi ṣe isapa akanṣe nipa pipe afiyesi wa si igbesi-aye awọn ọkunrin ati obinrin onigbagbọ lilagbara. (Heberu, ori 11) Iru awọn apẹẹrẹ bẹẹ lè sún wa ṣiṣẹ kí ó sì fokun fun igbagbọ wa. Fun apẹẹrẹ, ẹ jẹ ki a gbé ọ̀ràn ti wolii Elija yẹwo, ni kíkó afiyesi jọ sori kiki apa ibẹrẹ iṣẹ alakooko gigun rẹ̀ ti ó sì kún fun asọtẹlẹ. Ó gbé nigba iṣakoso Ọba Ahabu ati iyawo rẹ̀ abọriṣa, Ayaba Jesebeli, ni akoko kan ti igbagbọ ninu Ọlọrun tootọ ti jó rẹhin, gẹgẹ bii ti isinsinyi.
Ijọba Ẹ̀yà-Mẹ́wàá Oniwapalapala
Irú kan-hùn wo ni wọn jẹ́! Ahabu ni ọba keje ti Ijọba ẹ̀yà-mẹ́wàá Isirẹli. Bi o tilẹ jẹ pe awọn ajoyèṣaájú rẹ̀ mẹfa burú, Ahabu bùrùjà. Kì í ṣe kiki pe ó ń bá ijọsin akọ maluu oniwa palapala ilẹ naa lọ ni ṣugbọn ó fẹ́ Jesebeli ọmọbinrin ọba ajeji, tí ó sì tipa bẹẹ mú iru ijọsin ọlọrun èké Baali ti ó fẹsẹ mulẹ ju eyi ti ilẹ naa tíì mọ̀ rí wọle.—1 Ọba 16:30-33.
Jesebeli ni a ti rì wọnu ijọsin Baali lati igba ọmọ-ọwọ. Baba rẹ̀, Etbaali, alufaa Aṣitoreti (aya Baali) kan, ti pa awọn ẹlomiran lati dé ori ìtẹ́ Sidoni, ijọba ti ó wà ni ariwa Isirẹli gan-an. Jesebeli lo agbara idari lori ọkọ rẹ̀ aláìníwà lati fidi isin Baali mulẹ ni Isirẹli. Kò pẹ́ kò jinna, 450 awọn wolii ọlọrun èké yẹn ati 400 awọn wolii abo-ọlọrun Aṣera ti wà ni ilẹ naa, gbogbo wọn ń jẹun lori tabili ọba. Iru ijọsin wọn ti jẹ́ akóni niriira tó ni oju Ọlọrun tootọ naa, Jehofa! Awọn ami ère olókó gan-n-gan, awọn ààtò ọlọmọyọyọ, awọn kárùwà tẹmpili (ati ọkunrin ati obinrin), ani fifi awọn ọmọde rubọ paapaa—iru iwọnyi ni awọn ohun ọ̀ṣọ́ isin akoni niriira yii. Pẹlu ifọwọsi Ahabu, ó tankalẹ laini idiwọ la ijọba naa já.
Araadọta-ọkẹ awọn ọmọ Isirẹli gbagbe Jehofa, Ẹlẹdaa ilẹ̀-ayé ati ìyípo omi rẹ̀. Fun wọn Baali ni ó ń fi ojo bukun ilẹ lẹhin igba ọ̀gbẹlẹ̀. Lọdọọdun wọn ń fi ireti gboju wo ‘Olùgun Àwọsánmà Lẹ́ṣin’ yii, ọlọrun ọlọmọyọyọ ati igba ojo ti a fẹnu lasan pe bẹẹ, lati fopin sí sáà akoko ọ̀gbẹlẹ̀. Leralera fun ọpọlọpọ ọdun, ojo rọ̀. Leralera fun ọpọlọpọ ọdun Baali ni wọn buyì fún.
Elija Polongo Ọ̀dá
Boya ó jẹ́ ni opin ìgbà ẹ̀rùn gigun, aláìlójò kan—ní akoko naa gan-an ti awọn eniyan bẹrẹ sii reti pe ki Baali bẹrẹ ojo ti ń mú ìyè wá—ni Elija farahan loju iran.a Ó já lu akọsilẹ Bibeli lojiji bi sísán àrá. Ohun diẹ ni a sọ fun wa nipa ìtàn igbesi-aye rẹ̀, a kò mọ ohunkohun nipa awọn obi rẹ̀. Ṣugbọn lai dabi àrá, Elija kì í ṣe olupolongo bíbọ̀ òjò oníjì. Ó kede fun Ahabu pe: “Bi Oluwa [“Jehofa,” NW] Ọlọrun ti wà, niwaju ẹni ti emi duro, ki yoo sí ìrì tabi òjò ni ọdun wọnyi, ṣugbọn gẹgẹ bi ọrọ mi.”—1 Ọba 17:1.
Foju inu wo ọkunrin yii, ti ó wọ aṣọ ìbílẹ̀ onírun rẹ̀. Ó jẹ́ ọmọ ibilẹ oloke págunpàgun ti Gilead, ti ó ṣeeṣe ki a ti tọ́ dagba laaarin awọn oluṣọ agbo agutan onirẹlẹ. Ó duro ni iwaju ọba Ahabu alagbara, boya ninu ààfin rẹ̀ fífẹ̀ gan-an, pẹlu ile eléhín erin rẹ̀ ti ó lokiki ninu arosọ atọwọdọwọ, awọn ohun ọ̀ṣọ́ apàfiyèsí ati awọn ère ràgàjì. Nibẹ, ninu ilu oníriyẹriyẹ ti a mọdisí ti Samaria, nibi ti ijọsin Jehofa ti di eyi ti a gbagbe patapata, ó sọ fun Ahabu pe ọlọrun rẹ̀ yii, Baali yii, kò lagbara, kò jámọ́ nǹkankan. Elija polongo pe, fun ọdun yii ati awọn ọdun ti ń bọ̀, kò ni sí yálà òjò tabi ìrì!
Nibo ni ó ti ri iru igbagbọ bẹẹ? Ẹ̀rù kò ha bà á bí, ní diduro sibẹ niwaju ọba onigbeeraga, apẹhinda yii? Boya ni. Ní ohun ti o ju ẹgbẹrun ọdun kan lọ lẹhin naa, Jakọbu ọbàkan Jesu mú un dá wa loju pe Elija jẹ́ “eniyan oniru ìwà bi awa.” (Jakobu 5:17) Ṣugbọn ṣakiyesi awọn ọrọ Elija: “Bi Oluwa [“Jehofa,” NW] Ọlọrun ti wà, niwaju ẹni ti emi duro.” Elija fi sọkan pe gẹgẹ bi iranṣẹ Jehofa, oun ń duro niwaju ìtẹ́ giga lọpọlọpọ ju ti Ahabu lọ—ìtẹ́ Oluwa Ọba-Alaṣẹ agbaye! Oun jẹ́ ayanṣaṣoju kan, ikọ̀, fun ìtẹ́ yẹn. Pẹlu iwoye gbigbooro yii, ki ni oun nilati bẹru lati ọdọ Ahabu, ọba eniyan kekere bín-ín-tín kan ti ó ti padanu ojurere Ọlọrun?
Kò dédé ṣẹlẹ pe Jehofa jẹ́ ẹni gidi gan-an fun Elija. Ó daju pe wolii naa ti kiyesi akọsilẹ awọn ibalo Ọlọrun pẹlu awọn eniyan Rẹ̀. Jehofa ti kilọ fun awọn Juu pe oun yoo fiya jẹ wọn pẹlu ọ̀dá ati ìyàn bi wọn bá yipada lati jọsin awọn ọlọrun èké. (Deutaronomi 11:16, 17) Bi ó ti ní igbọkanle pe Jehofa maa ń mú ọrọ rẹ̀ ṣẹ nigba gbogbo, Elija “gbadura gidigidi pe ki òjò ki o maṣe rọ̀.”—Jakobu 5:17.
Ó Fi Igbagbọ Hàn Nipa Titẹle Itọsọna
Bi o ti wu ki o ri, fun akoko yii ná, ipolongo Elija fi í sinu ewu iku. Akoko tó fun ìhà igbagbọ rẹ̀ miiran lati wà lẹnu iṣẹ. Kí ó baa lè walaaye, oun nilati jẹ́ oloootọ ninu titẹle awọn itọni Jehofa pe: “Kuro nihin-in, ki o sì kọju siha ila-oorun, ki o sì fi ara rẹ pamọ nibi odò Keriti, ti ń bẹ niwaju Jọdani. Yoo sì ṣe, iwọ yoo mu ninu odò naa; mo sì ti paṣẹ fun awọn ẹyẹ ìwo lati maa bọ́ ọ nibẹ.”—1 Ọba 17:3, 4.
Elija ṣegbọran lọ́gán. Bi ó bá fẹ́ lati la ọ̀dá ati ìyàn ti ó kọlu ilẹ rẹ̀ já, oun nilati gbarale awọn ipese yoowu ki Jehofa ṣe fun un. Eyi kò rọrun rara. Ó tumọ si fifi araarẹ pamọ, biba a lọ ni gbigbe ni àdádó patapata fun ọpọ oṣu. Ó tumọ si jijẹ ẹran ati akara ti awọn ẹyẹ ìwo gbé wá fun un—awọn ẹyẹ ti ń jẹ oku ẹran ti a kà sí alaimọ ninu Ofin Mose—ati níní igbẹkẹle ninu Jehofa pe iru ẹran bẹẹ kì í ṣe oku ẹran ṣugbọn ẹran ti a ti dú lọna bibojumu ni ibamu pẹlu ofin. Iṣẹ iyanu alakooko gigun yii ni ó jọ bii pe kò rí bẹẹ fun awọn oluṣalaye Bibeli kan debi pe wọn damọran pe ọrọ ti ó kọkọ wà nihin-in ti gbọdọ tumọ si “Arabs” kì í sii ṣe “ravens” (awọn [ẹyẹ] ìwo) rara. Ṣugbọn awọn [ẹyẹ] ìwo ni yiyan ti ó yẹ. Kò sí ẹnikẹni ti ó lè fura pe awọn ẹyẹ rirẹlẹ, alaimọ wọnyi ti wọn ń fò lọ sinu aginju pẹlu awọn ìjàǹjá ounjẹ wọn ń founjẹ bọ́ Elija, ẹni ti Ahabu ati Jesebeli ń wá ninu gbogbo ijọba wọn yika niti gidi!—1 Ọba 18:3, 4, 10.
Bi ọ̀dá naa ti ń baa lọ fun akoko gigun jù, Elija ni ó ṣeeṣe ki o ti mú aniyan dagba lori ipese omi rẹ̀ ninu afonifoji ọ̀gbàrá Keriti. Ọpọjulọ awọn afonifoji ọ̀gbàrá Isirẹli gbẹ ni akoko ọ̀dá, ati “lẹhin ọjọ wọnni,” eyi pẹlu gbẹ. Iwọ ha lè finuro imọlara Elija bi omi naa ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ti dinku di eyi tí ń ṣàn térétéré ti agbajọ omi naa sì ń lọ silẹ lojoojumọ? Dajudaju oun ti gbọdọ ṣe kayefi ohun ti yoo ṣẹlẹ nigba ti omi naa bá gbẹ tan. Laika eyiini si, Elija fi tootọtootọ duro sibẹ. Ayafi ìgbà ti odo naa gbẹ ni Jehofa tó fun un ni ọ̀wọ́ awọn itọni rẹ̀ ti ó kan. Lọ si Sarefati, ni a sọ fun wolii naa. Nibẹ ni oun yoo ti ri ounjẹ agbẹ́mìíró ni ile opó kan.—1 Ọba 17:7-9.
Sarefati! Apakan ilu nla Sidoni ni ilu yẹn jẹ́, nibi ti Jesebeli ti wá ati nibi ti baba oun funraarẹ ti ṣakoso gẹgẹ bi ọba! Yoo ha ṣaláìléwu bi? Elija ti lè ṣe kayefi. Ṣugbọn ‘ó dide, ó sì lọ.’—1 Ọba 17:10.
Jehofa Pese Ounjẹ Agbẹ́mìíró ati Ìyè
Igbọran rẹ̀ ni a san èrè fun laipẹ. Ó pade opó kan gẹgẹ bi a ti sọtẹlẹ, ó sì rí iru igbagbọ naa gan-an ti kò sí tobẹẹ laaarin awọn ará ilu ninu rẹ̀. Opó alaini yii ní kiki iyẹfun ati òróró ti ó pọ̀ tó lati ṣe ounjẹ ẹẹkanṣoṣo sii fun araarẹ ati ọmọkunrin rẹ̀ ọ̀dọ́. Sibẹ, ninu aini gidigidi rẹ̀ paapaa, ó muratan lati ṣe akara fun Elija lakọọkọ, ni gbigbẹkẹle ileri rẹ̀ pe Jehofa yoo pa ipese ikoko òróró ati ikoko ìyẹ̀fun rẹ̀ mọ́ niwọn ìgbà ti aini bá wà. Abajọ ti Jesu fi pe apẹẹrẹ iṣotitọ opó yii wá sọkan nigba ti ó ń bu ẹnu àtẹ́ lu awọn ọmọ Isirẹli alainigbagbọ ni ọjọ tirẹ!—1 Ọba 17:13-16; Luuku 4:25, 26.
Bi o ti wu ki o ri, laika ti iṣẹ iyanu yii sí, igbagbọ opó naa ati ti Elija ni yoo dojukọ idanwo mimuna laipẹ. Ọmọkunrin rẹ̀ kú lojiji. Bi ibanujẹ ti bò ó mọlẹ, opó naa wulẹ nilati gbagbọ pe àjálù apanilẹkun yii ni nǹkan ṣe pẹlu Elija, “eniyan Ọlọrun.” Ó ṣe kayefi boya a ń fiya jẹ oun fun awọn ẹṣẹ atijọ kan. Ṣugbọn Elija gba ọmọkunrin rẹ̀ alailẹmii kuro ni apa rẹ̀ ó sì gbé e lọ si iyàrá òkè kan. Ó mọ pe Jehofa lè pese ju ounjẹ agbẹ́mìíró lọ. Jehofa ni orisun ìyè funraarẹ! Nitori naa Elija gbadura tọkantọkan ati leralera fun ẹmi ọmọ naa lati pada.
Elija kọ́ ni ẹni akọkọ lati ni iru igbagbọ bẹẹ ninu ajinde, ṣugbọn ninu akọsilẹ Bibeli, oun ni ẹni akọkọ ti a lo lati ṣe ọ̀kan. Ọmọkunrin naa ‘wá si ìyè’! Ayọ iya rẹ̀ gbọdọ ti jẹ́ iran kan ti o dun lati rí gẹgẹ bi Elija ti mú ọmọkunrin rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá pẹlu awọn ọrọ diẹ naa pe: “Wò ó, ọmọ rẹ yè.” Ó lè jẹ́ pe pẹlu omije loju, ni oun wi pe: “Nisinsinyi nipa eyi ni emi mọ pe, eniyan Ọlọrun ni iwọ ń ṣe, ati pe, ọrọ Oluwa ni ẹnu rẹ, otitọ ni.”—1 Ọba 17:17-24.
“Ọlọrun Mi Ni Jehofa”
Ó ti wọni lọkan tó, ó sì ti ba a mu tó, pe orukọ Elija tumọ si “Ọlọrun Mi Ni Jehofa”! Ni akoko ọ̀dá ati ìyàn, Jehofa fun un ni jijẹ ati mimu; ni akoko idarudapọ nipa ohun ti ó tọ́, Jehofa fun un ni itọsọna yiyekooro; ni akoko iku kan, Jehofa lò ó lati mu ìyè padabọsipo. Ó sì dabi ẹni pe ni gbogbo igba ti a pe Elija lati lo igbagbọ rẹ̀ ninu Ọlọrun—nipa níní igbẹkẹle ninu Rẹ̀ lati pese, nipa titẹle awọn idari Rẹ̀, nipa gbigbarale E lati sọ orukọ Rẹ̀ di mímọ́—oun ni a san èrè fun pẹlu idi pupọ sii sibẹsibẹ lati ni igbagbọ ninu Jehofa. Ọna ìgbàbánilò yii ń baa lọ lati jẹ otitọ bi oun ti ń baa lọ lati tẹwọgba awọn iṣẹ ayanfunni lilekoko ti ó sì banilẹru paapaa lati ọdọ Ọlọrun rẹ̀, Jehofa; niti tootọ, diẹ lara awọn iṣẹ iyanu agbafiyesi julọ rẹ̀ ṣì wà niwaju fun un.—Wo 1 Ọba, ori 18.
Lọpọlọpọ ni o ri bakan naa fun awọn iranṣẹ Jehofa lonii. A lè má tipasẹ iṣẹ iyanu founjẹ bọ́ wa tabi ki a lò wá lati jí ẹnikan dide; eyi kì í ṣe sanmani fun iru iṣẹ iyanu bẹẹ. Bi o ti wu ki o ri, Jehofa funraarẹ kò tii yipada ni iwọn kan lati ọjọ Elija.—1 Kọrinti 13:8; Jakobu 1:17.
Awa pẹlu lè gba awọn iṣẹ ayanfunni ti ń bani lẹru kan, awọn ipinlẹ lilekoko ti ń janilaya lati mú ihin-iṣẹ ti Ọlọrun fi funni dé. Awa pẹlu lè dojukọ inunibini. Ebi tilẹ lè pa wá paapaa. Ṣugbọn fun awọn ẹnikọọkan ti wọn jẹ́ oluṣotitọ ati fun eto-ajọ rẹ̀ lodindi, Jehofa ti fihan leralera pe oun ń dari oun ṣì ń daabo bo awọn iranṣẹ oun. Ó sì ń fun wọn ni agbara lati maa baa lọ pẹlu iṣẹ eyikeyii ti ó bá yàn fun wọn. Ó sì ń ràn wọ́n lọwọ sibẹ lati farada awọn adanwo eyikeyii ti ó lè wa sori wọn ninu ayé oniyọnu yii.—Saamu 55:22.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ati Jesu ati Jakọbu sọ pe òjò kò rọ̀ ni ilẹ naa fun “ọdun mẹta oun oṣu mẹfa.” Sibẹ, Elija ni a sọ pe ó farahan niwaju Ahabu lati fopin si ọ̀dá naa ‘ni ọdun kẹta’—boya ni kíkà á lati ọjọ ti o ti kede ọ̀dá naa. Nipa bayii, ó gbọdọ ti jẹ́ lẹhin igba ọgbẹlẹ gigun, aláìlójò kan nigba ti ó kọkọ duro niwaju Ahabu.—Luuku 4:25; Jakobu 5:17; 1 Ọba 18:1.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Iwọ, bi Elija, ha ni igbagbọ pe Jehofa yoo bojuto aini awọn iranṣẹ rẹ̀ bi?