Ẹ́sítà
4 Nígbà tí Módékáì+ gbọ́ gbogbo ohun tí wọ́n ṣe,+ ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó wọ aṣọ ọ̀fọ̀,* ó sì da eérú sórí. Ó wá lọ sí àárín ìlú, ó gbé ohùn sókè, ó sì ń sunkún kíkankíkan. 2 Ó ń lọ títí ó fi dé ẹnubodè ọba, àmọ́ kò wọlé, torí ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ wọ aṣọ ọ̀fọ̀* wọ ẹnubodè ọba. 3 Ọ̀fọ̀ ńlá ṣẹ̀ láàárín àwọn Júù tó wà ní gbogbo ìpínlẹ̀*+ tí ọ̀rọ̀ ọba àti àṣẹ rẹ̀ ti dé, wọ́n ń gbààwẹ̀,+ wọ́n ń sunkún, wọ́n sì ń pohùn réré ẹkún. Ọ̀pọ̀ lára wọn sùn sórí aṣọ ọ̀fọ̀* àti eérú.+ 4 Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́bìnrin Ẹ́sítà àti àwọn ìwẹ̀fà rẹ̀ wọlé wá, tí wọ́n sì sọ fún un, ìdààmú bá ayaba gidigidi. Ó wá fi aṣọ ránṣẹ́ sí Módékáì, pé kó wọ̀ ọ́ dípò aṣọ ọ̀fọ̀* tó wà lọ́rùn rẹ̀, àmọ́ kò gbà á. 5 Ni Ẹ́sítà bá pe Hátákì, ọ̀kan lára àwọn ìwẹ̀fà ọba, ẹni tí ọba yàn láti máa ṣe ìránṣẹ́ fún Ẹ́sítà, ó sì ní kó lọ béèrè lọ́wọ́ Módékáì ohun tí èyí túmọ̀ sí àti ohun tó ń ṣẹlẹ̀.
6 Torí náà, Hátákì lọ bá Módékáì ní gbàgede ìlú tó wà níwájú ẹnubodè ọba. 7 Módékáì sọ gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i fún Hátákì àti iye owó+ tí Hámánì sọ pé òun máa san sínú ibi ìṣúra ọba kí wọ́n lè pa àwọn Júù run.+ 8 Ó tún fún un ní ẹ̀dà ìwé àṣẹ tí wọ́n gbé jáde ní Ṣúṣánì*+ láti pa wọ́n run. Ó ní kó fi han Ẹ́sítà, kó ṣàlàyé rẹ̀ fún un, kó sì sọ fún un+ pé kó lọ bá ọba láti wá ojú rere rẹ̀, kí òun fúnra rẹ̀ sì bá àwọn èèyàn rẹ̀ bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ ọba.
9 Hátákì pa dà, ó sì jíṣẹ́ Módékáì fún Ẹ́sítà. 10 Ẹ́sítà ní kí Hátákì lọ ṣàlàyé fún Módékáì+ pé: 11 “Gbogbo àwọn ìránṣẹ́ ọba àti àwọn èèyàn tó wà ní àwọn ìpínlẹ̀ abẹ́ àṣẹ ọba ló mọ̀ pé, tí ọkùnrin tàbí obìnrin èyíkéyìí bá wọlé lọ bá ọba ní àgbàlá inú+ láìjẹ́ pé ọba pè é, òfin kan ṣoṣo tí wọ́n máa tẹ̀ lé ni pé: Kí wọ́n pa onítọ̀hún; àyàfi tí ọba bá na ọ̀pá àṣẹ wúrà+ sí i ni kò ní kú. Ó sì ti tó ọgbọ̀n (30) ọjọ́ báyìí tí wọn ò tíì pè mí sọ́dọ̀ ọba.”
12 Nígbà tí wọ́n jíṣẹ́ Ẹ́sítà fún Módékáì, 13 ó fún Ẹ́sítà lésì pé: “Má rò pé ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí gbogbo àwọn Júù yòókù kò ní kàn ọ́ torí pé o wà nínú agbo ilé ọba. 14 Tí o bá dákẹ́ ní àkókò yìí, àwọn Júù máa rí ìtura àti ìdáǹdè láti ibòmíì,+ ṣùgbọ́n ìwọ àti ilé bàbá rẹ yóò ṣègbé. Ta ló sì mọ̀ bóyá torí irú àkókò yìí lo fi dé ipò ayaba tí o wà?”+
15 Nígbà náà, Ẹ́sítà fún Módékáì lésì pé: 16 “Lọ, kó gbogbo àwọn Júù tó wà ní Ṣúṣánì* jọ, kí ẹ sì gbààwẹ̀+ nítorí mi. Ẹ má jẹ, ẹ má sì mu fún ọjọ́ mẹ́ta,+ ní òru àti ní ọ̀sán. Èmi àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin mi á sì gbààwẹ̀ bákan náà. Màá wọlé lọ sọ́dọ̀ ọba, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò bá òfin mu, tí mo bá sì máa kú, kí n kú.” 17 Torí náà, Módékáì lọ, ó sì ṣe gbogbo ohun tí Ẹ́sítà sọ pé kó ṣe.