Àkọsílẹ̀ Máàkù
8 Nígbà yẹn, èrò rẹpẹtẹ tún wà, tí wọn ò ní ohunkóhun tí wọ́n máa jẹ. Torí náà, ó pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn, ó sì sọ fún wọn pé: 2 “Àánú àwọn èèyàn yìí ń ṣe mí,+ torí ọjọ́ kẹta nìyí tí wọ́n ti wà lọ́dọ̀ mi, tí wọn ò sì ní ohunkóhun tí wọ́n máa jẹ.+ 3 Tí n bá ní kí wọ́n máa lọ sílé láìjẹun,* okun wọn máa tán lójú ọ̀nà, ibi tó jìnnà sì ni àwọn kan lára wọn ti wá.” 4 Àmọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ dá a lóhùn pé: “Ibo lèèyàn ti máa rí oúnjẹ tó máa tó bọ́ àwọn èèyàn yìí ní àdádó yìí?” 5 Ó wá bi wọ́n pé: “Búrẹ́dì mélòó lẹ ní?” Wọ́n sọ pé: “Méje.”+ 6 Ó sọ fún àwọn èrò náà pé kí wọ́n jókòó sílẹ̀.* Ó wá mú búrẹ́dì méje náà, ó dúpẹ́, ó bù ú, ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n pín in, wọ́n sì pín in fún àwọn èrò náà.+ 7 Wọ́n tún ní ẹja wẹ́wẹ́ díẹ̀, lẹ́yìn tó súre sí i, ó ní kí wọ́n pín ìyẹn náà. 8 Wọ́n sì jẹ, wọ́n yó, ohun tó ṣẹ́ kù tí wọ́n kó jọ sì kún apẹ̀rẹ̀ ńlá* méje.+ 9 Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rin (4,000) ọkùnrin ló wà níbẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó ní kí wọ́n máa lọ.
10 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, òun àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wọ ọkọ̀ ojú omi, wọ́n sì wá sí agbègbè Dámánútà.+ 11 Àwọn Farisí wá bá a níbẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá a jiyàn, wọ́n ní kó fún àwọn ní àmì kan láti ọ̀run, kí wọ́n lè dán an wò.+ 12 Torí náà, ẹ̀dùn ọkàn bá a gidigidi nínú ẹ̀mí rẹ̀, ó sì sọ pé: “Kí ló dé tí ìran yìí ń wá àmì?+ Lóòótọ́ ni mo sọ, a ò ní fún ìran yìí ní àmì kankan.”+ 13 Ló bá fi wọ́n sílẹ̀, ó sì tún wọ ọkọ̀ lọ sí èbúté tó wà ní òdìkejì.
14 Àmọ́, wọn ò rántí mú búrẹ́dì dání, wọn ò sì ní nǹkan kan pẹ̀lú wọn nínú ọkọ̀ ojú omi, àfi búrẹ́dì kan ṣoṣo.+ 15 Ó wá kìlọ̀ fún wọn lọ́nà tó ṣe kedere pé: “Ẹ la ojú yín sílẹ̀; kí ẹ ṣọ́ra fún ìwúkàrà àwọn Farisí àti ìwúkàrà Hẹ́rọ́dù.”+ 16 Ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í bára wọn jiyàn torí pé wọn ò ní búrẹ́dì kankan. 17 Ó kíyè sí i, ó sì sọ fún wọn pé: “Kí ló dé tí ẹ fi ń jiyàn torí pé ẹ ò ní búrẹ́dì? Ṣé ẹ ò tíì fòye mọ̀, kó sì yé yín ni? Ṣé ọkàn yín ò tíì ní òye ni? 18 ‘Ẹ ní ojú, síbẹ̀ ṣé ẹ ò ríran ni; àti pé ẹ ní etí, síbẹ̀ ṣé ẹ ò gbọ́ ni?’ Ṣé ẹ ò rántí ni, 19 nígbà tí mo bu búrẹ́dì márùn-ún+ fún ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ọkùnrin, ẹ̀kún apẹ̀rẹ̀ mélòó lẹ kó jọ látinú ohun tó ṣẹ́ kù?” Wọ́n dáhùn pé: “Méjìlá (12).”+ 20 “Nígbà tí mo bu búrẹ́dì méje fún ẹgbẹ̀rún mẹ́rin (4,000) ọkùnrin, ẹ̀kún apẹ̀rẹ̀ ńlá* mélòó lẹ kó jọ látinú ohun tó ṣẹ́ kù?” Wọ́n sọ fún un pé: “Méje.”+ 21 Ó wá sọ fún wọn pé: “Ṣé kò tíì yé yín náà ni?”
22 Nígbà náà, wọ́n gúnlẹ̀ sí Bẹtisáídà. Ibẹ̀ làwọn èèyàn ti mú ọkùnrin afọ́jú kan wá bá a, wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ pé kó fọwọ́ kàn án.+ 23 Ó wá fa ọkùnrin afọ́jú náà lọ́wọ́ jáde sẹ́yìn abúlé náà. Lẹ́yìn tó tutọ́ sí ojú rẹ̀,+ ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e, ó sì bi í pé: “Ṣé o rí nǹkan kan?” 24 Ọkùnrin náà gbójú sókè, ó sọ pé: “Mo rí àwọn èèyàn, àmọ́ wọ́n dà bí igi tó ń rìn káàkiri.” 25 Ló bá tún gbé ọwọ́ rẹ̀ lé ojú ọkùnrin náà, ọkùnrin náà wá ríran dáadáa. Ojú rẹ̀ tún bẹ̀rẹ̀ sí í ríran, ó sì ń rí gbogbo nǹkan kedere. 26 Torí náà, ó ní kó máa lọ sílé, ó sọ fún un pé: “Má wọ inú abúlé.”
27 Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wá lọ sí àwọn abúlé Kesaríà Fílípì, ó sì ń bi àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lójú ọ̀nà pé: “Ta ni àwọn èèyàn ń sọ pé mo jẹ́?”+ 28 Wọ́n sọ fún un pé: “Jòhánù Arinibọmi,+ àmọ́ àwọn míì ń sọ pé Èlíjà,+ àwọn míì sì ń sọ pé ọ̀kan lára àwọn wòlíì.” 29 Ó wá bi wọ́n pé: “Ẹ̀yin ńkọ́, ta lẹ̀ ń sọ pé mo jẹ́?” Pétérù dá a lóhùn pé: “Ìwọ ni Kristi náà.”+ 30 Ó wá kìlọ̀ fún wọn gidigidi pé kí wọ́n má sọ fún ẹnì kankan nípa òun.+ 31 Bákan náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn pé Ọmọ èèyàn gbọ́dọ̀ jìyà púpọ̀, àwọn àgbààgbà, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin máa kọ̀ ọ́, wọ́n máa pa á,+ ọjọ́ mẹ́ta lẹ́yìn náà ló sì máa dìde.+ 32 Àní, gbangba ló ti ń sọ ọ̀rọ̀ yẹn. Àmọ́ Pétérù mú un lọ sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá a wí.+ 33 Ló bá yíjú pa dà, ó wo àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì bá Pétérù wí, ó ní: “Dẹ̀yìn lẹ́yìn mi,* Sátánì! torí èrò èèyàn lò ń rò, kì í ṣe ti Ọlọ́run.”+
34 Lẹ́yìn náà, ó pe àwọn èrò àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ́dọ̀, ó sì sọ fún wọn pé: “Tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ máa tẹ̀ lé mi, kó sẹ́ ara rẹ̀, kó gbé òpó igi oró* rẹ̀, kó sì máa tẹ̀ lé mi.+ 35 Torí ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ gba ẹ̀mí* rẹ̀ là máa pàdánù rẹ̀, àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá pàdánù ẹ̀mí* rẹ̀ nítorí mi àti nítorí ìhìn rere máa gbà á là.+ 36 Lóòótọ́, àǹfààní wo ni èèyàn máa rí tó bá jèrè gbogbo ayé, tó sì wá pàdánù ẹ̀mí* rẹ̀?+ 37 Ká sòótọ́, kí ni èèyàn máa fi dípò ẹ̀mí* rẹ̀?+ 38 Torí ẹnikẹ́ni tó bá tijú èmi àti àwọn ọ̀rọ̀ mi nínú ìran alágbèrè* àti ẹlẹ́ṣẹ̀ yìí, Ọmọ èèyàn náà máa tijú rẹ̀+ nígbà tó bá dé nínú ògo Baba rẹ̀ pẹ̀lú àwọn áńgẹ́lì mímọ́.”+