Àkọsílẹ̀ Máàkù
9 Ó tún sọ fún wọn pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín pé àwọn kan wà lára àwọn tó dúró síbí yìí tí kò ní tọ́ ikú wò rárá títí wọ́n á fi kọ́kọ́ rí i tí Ìjọba Ọlọ́run ti dé tagbáratagbára.”+ 2 Ọjọ́ mẹ́fà lẹ́yìn náà, Jésù mú Pétérù, Jémíìsì àti Jòhánù dání lọ sí orí òkè kan tó ga fíofío láwọn nìkan. A sì yí i pa dà di ológo níwájú wọn;+ 3 aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í tàn yinrin, ó di funfun nini ju bí alágbàfọ̀ èyíkéyìí ní ayé ṣe lè sọ ọ́ di funfun. 4 Bákan náà, Èlíjà àti Mósè fara hàn wọ́n, wọ́n sì ń bá Jésù sọ̀rọ̀. 5 Pétérù wá sọ fún Jésù pé: “Rábì, ó dáa bí a ṣe wà níbí. Torí náà, jẹ́ ká pa àgọ́ mẹ́ta, ọ̀kan fún ọ, ọ̀kan fún Mósè àti ọ̀kan fún Èlíjà.” 6 Ní tòótọ́, kò mọ ohun tí ì bá ṣe, torí ẹ̀rù bà wọ́n gan-an. 7 Ìkùukùu* wá kóra jọ, ó ṣíji bò wọ́n, ohùn kan+ sì dún látinú ìkùukùu náà pé: “Èyí ni Ọmọ mi, àyànfẹ́.+ Ẹ fetí sí i.”+ 8 Lójijì, wọ́n wò yí ká, wọn ò sì rí ẹnì kankan pẹ̀lú wọn mọ́, àfi Jésù nìkan.
9 Bí wọ́n ṣe ń sọ̀ kalẹ̀ bọ̀ látorí òkè náà, ó kìlọ̀ fún wọn gidigidi pé kí wọ́n má sọ ohun tí wọ́n rí fún ẹnì kankan,+ títí dìgbà tí Ọmọ èèyàn bá jí dìde.+ 10 Wọ́n fi ọ̀rọ̀ náà sọ́kàn,* àmọ́ wọ́n ń sọ ohun tí àjíǹde náà túmọ̀ sí láàárín ara wọn. 11 Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í bi í pé: “Kí ló dé tí àwọn akọ̀wé òfin fi ń sọ pé Èlíjà + gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ wá?”+ 12 Ó sọ fún wọn pé: “Èlíjà máa kọ́kọ́ wá, ó sì máa mú ohun gbogbo pa dà sí bó ṣe yẹ;+ àmọ́ kí wá nìdí tí a fi kọ ọ́ nípa Ọmọ èèyàn pé ó gbọ́dọ̀ jìyà púpọ̀,+ kí wọ́n sì kàn án lábùkù?+ 13 Ní tòótọ́, mò ń sọ fún yín pé Èlíjà+ ti wá, wọ́n sì ṣe ohun tó wù wọ́n sí i, bí a ṣe kọ ọ́ nípa rẹ̀.”+
14 Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù, wọ́n rí èrò rẹpẹtẹ tó yí wọn ká, àwọn akọ̀wé òfin sì ń bá wọn jiyàn.+ 15 Àmọ́ gbàrà tí gbogbo àwọn èrò náà tajú kán rí i, ó yà wọ́n lẹ́nu, wọ́n sì sáré lọ kí i. 16 Ó wá bi wọ́n pé: “Kí ni ẹ̀ ń bá wọn jiyàn lé lórí?” 17 Ọ̀kan lára àwọn èrò náà dá a lóhùn pé: “Olùkọ́, mo mú ọmọkùnrin mi wá sọ́dọ̀ rẹ torí ó ní ẹ̀mí kan tí kò jẹ́ kó lè sọ̀rọ̀.+ 18 Ní ibikíbi tó bá ti mú un, ṣe ló máa ń gbé e ṣánlẹ̀, á sì máa yọ ìfófòó lẹ́nu, á máa wa eyín pọ̀, kò sì ní lókun mọ́. Mo ní kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ lé e jáde, àmọ́ wọn ò rí i ṣe.” 19 Ó dá wọn lóhùn pé: “Ìran aláìnígbàgbọ́,+ títí dìgbà wo ni màá fi wà pẹ̀lú yín? Títí dìgbà wo ni màá fi máa fara dà á fún yín? Ẹ mú un wá sọ́dọ̀ mi.”+ 20 Wọ́n bá mú ọmọ náà wá sọ́dọ̀ rẹ̀, àmọ́ gbàrà tó rí i, ṣe ni ẹ̀mí náà mú kí gìrì mú ọmọ náà lójijì. Lẹ́yìn tó ṣubú lulẹ̀, ó ń yí kiri, ó sì ń yọ ìfófòó lẹ́nu. 21 Jésù wá bi bàbá ọmọ náà pé: “Ó tó ìgbà wo tí nǹkan yìí ti ń ṣe ọmọ yìí?” Ó ní: “Láti kékeré ni, 22 ó máa ń gbé e jù sínú iná àti sínú omi lọ́pọ̀ ìgbà kó lè pa á. Àmọ́ tí o bá lè ṣe ohunkóhun sí i, ṣàánú wa, kí o sì ràn wá lọ́wọ́.” 23 Jésù sọ fún un pé: “Kì í ṣe ọ̀rọ̀, ‘Tí o bá lè’! Ó dájú pé ohun gbogbo ṣeé ṣe fún ẹni tó bá ní ìgbàgbọ́.”+ 24 Ojú ẹsẹ̀ ni bàbá ọmọ náà kígbe pé: “Mo ní ìgbàgbọ́! Ràn mí lọ́wọ́ níbi tí mo ti nílò ìgbàgbọ́!”+
25 Jésù rí i pé èrò rẹpẹtẹ ń yára bọ̀ wá sọ́dọ̀ wọn, ó wá bá ẹ̀mí àìmọ́ náà wí, ó sọ fún un pé: “Ìwọ ẹ̀mí tí kò jẹ́ kó lè sọ̀rọ̀, tó sì di í létí, mo pàṣẹ fún ọ, jáde kúrò lára rẹ̀, o ò sì gbọ́dọ̀ wọ inú rẹ̀ mọ́!”+ 26 Lẹ́yìn tí ọmọ náà kígbe, tí gìrì náà sì gbé e léraléra, ó jáde, ọmọ náà sì dà bí ẹni tó ti kú, débi pé ọ̀pọ̀ èèyàn ń sọ pé: “Ó ti kú!” 27 Àmọ́ Jésù di ọwọ́ rẹ̀ mú, ó gbé e dìde, ó sì dìde. 28 Torí náà, lẹ́yìn tó wọ ilé kan, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bi í lóun nìkan pé: “Kí ló dé tí a ò fi lè lé e jáde?”+ 29 Ó sọ fún wọn pé: “Àdúrà nìkan ló lè lé irú èyí jáde.”
30 Wọ́n kúrò níbẹ̀, wọ́n sì gba Gálílì kọjá, àmọ́ kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀ nípa rẹ̀. 31 Torí ó ń kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì ń sọ fún wọn pé: “A máa fi Ọmọ èèyàn lé àwọn èèyàn lọ́wọ́, wọ́n sì máa pa á,+ àmọ́ bí wọ́n tiẹ̀ pa á, ọjọ́ mẹ́ta lẹ́yìn náà ló máa dìde.”+ 32 Àmọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò yé wọn, ẹ̀rù sì ń bà wọ́n láti bi í léèrè.
33 Lẹ́yìn náà, wọ́n dé sí Kápánáúmù. Nígbà tó wà nínú ilé, ó bi wọ́n léèrè pé: “Kí lẹ̀ ń jiyàn lé lórí lójú ọ̀nà?”+ 34 Wọn ò sọ̀rọ̀, torí wọ́n ń jiyàn láàárín ara wọn lójú ọ̀nà nípa ẹni tó tóbi jù. 35 Torí náà, ó jókòó, ó pe àwọn Méjìlá náà, ó sì sọ fún wọn pé: “Tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ jẹ́ ẹni àkọ́kọ́, òun ló gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni ìkẹyìn àti ìránṣẹ́ gbogbo yín.”+ 36 Ó wá mú ọmọ kékeré kan, ó mú un dúró ní àárín wọn; ó fi ọwọ́ gbá a mọ́ra, ó sì sọ fún wọn pé: 37 “Ẹnikẹ́ni tó bá gba irú ọmọ kékeré+ yìí nítorí orúkọ mi gba èmi náà; ẹnikẹ́ni tó bá sì gbà mí, kì í ṣe èmi nìkan ló gbà, àmọ́ ó tún gba Ẹni tó rán mi.”+
38 Jòhánù sọ fún un pé: “Olùkọ́, a rí ẹnì kan tó ń fi orúkọ rẹ lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, a sì gbìyànjú láti dá a dúró, torí kì í tẹ̀ lé wa.”+ 39 Àmọ́ Jésù sọ pé: “Ẹ má gbìyànjú láti dá a dúró, torí kò sí ẹni tó máa fi orúkọ mi ṣe iṣẹ́ agbára kankan tó máa lè yára sọ ohunkóhun tí kò dáa nípa mi. 40 Torí ẹnikẹ́ni tí kò bá ta kò wá, tiwa ló ń ṣe.+ 41 Ẹnikẹ́ni tó bá fún yín ní ife omi mu torí pé ẹ jẹ́ ti Kristi,+ lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ó dájú pé kò ní pàdánù èrè rẹ̀.+ 42 Àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá mú ọ̀kan nínú àwọn ẹni kékeré yìí tó ní ìgbàgbọ́ kọsẹ̀, ó sàn ká so ọlọ mọ́ ọn lọ́rùn, irú èyí tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ máa ń yí, ká sì jù ú sínú òkun.+
43 “Tí ọwọ́ rẹ bá mú ọ kọsẹ̀ pẹ́nrẹ́n, gé e kúrò. Ó sàn fún ọ láti jogún ìyè ní aláàbọ̀ ara ju kí o wọnú Gẹ̀hẹ́nà* pẹ̀lú ọwọ́ méjèèjì, sínú iná tí kò ṣeé pa.+ 44* —— 45 Tí ẹsẹ̀ rẹ bá sì mú ọ kọsẹ̀, gé e kúrò. Ó sàn fún ọ láti jogún ìyè ní arọ ju kí a jù ọ́ sínú Gẹ̀hẹ́nà*+ pẹ̀lú ẹsẹ̀ méjèèjì. 46* —— 47 Tí ojú rẹ bá sì mú ọ kọsẹ̀, sọ ọ́ nù.+ Ó sàn fún ọ láti wọ Ìjọba Ọlọ́run ní olójú kan ju kí a jù ọ́ sínú Gẹ̀hẹ́nà*+ pẹ̀lú ojú méjèèjì, 48 níbi tí ìdin kì í ti í kú, tí a kì í sì í pa iná.+
49 “Nítorí a gbọ́dọ̀ fi iná dun kálukú bí iyọ̀.+ 50 Iyọ̀ dáa, àmọ́ tí iyọ̀ bá sọ adùn rẹ̀ nù pẹ́nrẹ́n, kí lẹ máa fi mú òun fúnra rẹ̀ dùn?+ Ẹ ní iyọ̀ nínú ara yín,+ kí ẹ sì jẹ́ kí àlàáfíà wà láàárín yín.”+