ORÍ 63
Méjì Lára Ìmọ̀ràn Jésù
MÁTÍÙ 18:6-20 MÁÀKÙ 9:38-50 LÚÙKÙ 9:49, 50
BÍ A Ò ṢE NÍ MÚ ÀWỌN MÍÌ KỌSẸ̀
OHUN TÓ YẸ KÁ ṢE TẸ́NÌ KAN BÁ DẸ́SẸ̀
Jésù ṣẹ̀ṣẹ̀ bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa ìwà tó yẹ kí wọ́n máa hù. Ó ní kí wọ́n máa wo ara wọ́n bí ọmọdé, torí pé àwọn ọmọdé kì í gbéra ga tàbí wá ipò ọlá. Torí náà, ó yẹ káwọn ọmọ ẹ̀yìn yẹn ‘gba irú ọmọ kékeré bẹ́ẹ̀ nítorí orúkọ Jésù, kí wọ́n lè tipa bẹ́ẹ̀ gba òun náà.’—Mátíù 18:5.
Kò tíì pẹ́ táwọn àpọ́sítélì bára wọn jiyàn nípa ẹni tó tóbi jù láàárín wọn, torí náà ó ṣeé ṣe kí wọ́n gbà pé àwọn ni Jésù fi ohun tó sọ yìí bá wí. Ohun kan wá ṣẹlẹ̀ tí àpọ́sítélì Jòhánù fẹ́ fi tó Jésù létí, ó ní: “A rí ẹnì kan tó ń fi orúkọ rẹ lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, a sì gbìyànjú láti dá a dúró, torí kì í tẹ̀ lé wa.”—Lúùkù 9:49.
Àbí Jòhánù ń rò pé àwọn àpọ́sítélì nìkan ló láṣẹ láti lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde tàbí láti woni sàn? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ibo ni ọkùnrin Júù yẹn ti wá rí agbára tó fi ń lé ẹ̀mí èṣù jáde? Ó ṣeé ṣe kí Jòhánù ronú pé ọkùnrin yẹn ò lẹ́tọ̀ọ́ láti máa ṣe iṣẹ́ ìyanu torí pé kò dara pọ̀ mọ́ àwọn.
Ó dájú pé ohun tí Jésù sọ máa ya Jòhánù lẹ́nu, ó ní: “Ẹ má gbìyànjú láti dá a dúró, torí kò sí ẹni tó máa fi orúkọ mi ṣe iṣẹ́ agbára kankan tó máa lè yára sọ ohunkóhun tí kò dáa nípa mi. Torí ẹnikẹ́ni tí kò bá ta kò wá, tiwa ló ń ṣe. Ẹnikẹ́ni tó bá fún yín ní ife omi mu torí pé ẹ jẹ́ ti Kristi, lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ó dájú pé kò ní pàdánù èrè rẹ̀.”—Máàkù 9:39-41.
Lásìkò tí Jésù ń sọ̀rọ̀ náà, kò pọn dandan kí ọkùnrin yẹn dara pọ̀ mọ́ wọn kó tó lè fi hàn pé òun jẹ́ ti Kristi. Wọn ò tíì dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀, torí náà ti pé ọkùnrin yẹn kì í tẹ̀ lé wọn káàkiri kò túmọ̀ sí pé ó ta kò wọ́n tàbí pé ìsìn èké ló ń ṣe. Ó hàn gbangba pé ọkùnrin yẹn nígbàgbọ́ nínú Jésù, ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ sì fi hàn pé Ọlọ́run máa san ọkùnrin náà lẹ́san.
Àmọ́ o, ó máa burú gan-an táwọn àpọ́sítélì bá mú ọkùnrin yẹn kọsẹ̀, ì báà jẹ́ lọ́rọ̀ tàbí níṣe. Torí náà, Jésù sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá mú ọ̀kan nínú àwọn ẹni kékeré yìí tó ní ìgbàgbọ́ kọsẹ̀, ó sàn ká so ọlọ mọ́ ọn lọ́rùn, irú èyí tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ máa ń yí, ká sì jù ú sínú òkun.” (Máàkù 9:42) Lẹ́yìn náà, Jésù sọ pé ó sàn káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun pàdánù ọwọ́, ẹsẹ̀ tàbí ojú wọn ju kí wọ́n mú àwọn míì kọsẹ̀. Ó tẹnu mọ́ ọn pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹ̀yà ara yìí wúlò gan-an, ó sàn kéèyàn wọ Ìjọba Ọlọ́run láìsí àwọn ẹ̀yà ara yìí ju kéèyàn ní wọn kó sí bá ara ẹ̀ nínú Gẹ̀hẹ́nà (Àfonífojì Hínómù). Ó ṣeé ṣe káwọn àpọ́sítélì mọ̀ pé àfonífojì tó wà nítòsí Jerúsálẹ́mù yẹn làwọn èèyàn ti máa ń sun àwọn nǹkan ẹ̀gbin, torí náà ó yé wọn pé ìparun ayérayé ló ṣàpẹẹrẹ.
Jésù wá kìlọ̀ fún wọn pé: “Ẹ rí i pé ẹ ò kẹ́gàn ọ̀kan nínú àwọn ẹni kékeré yìí, torí mò ń sọ fún yín pé ìgbà gbogbo ni àwọn áńgẹ́lì wọn ní ọ̀run máa ń wo ojú Baba mi.” Báwo ni “àwọn ẹni kékeré” yìí ṣe ṣeyebíye tó lójú Jèhófà? Jésù ṣàkàwé ẹ̀ pẹ̀lú ọkùnrin kan tó ní ọgọ́rùn-ún (100) àgùntàn àmọ́ tí ọ̀kan nínú wọn sọ nù. Ọkùnrin yẹn fi àwọn àgùntàn mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún (99) yòókù sílẹ̀ síbì kan, ó sì wá èyí tó sọ nù lọ, lẹ́yìn tó rí i, Jésù sọ pé inú ẹ̀ dùn gan-an lórí ẹyọ kan tó rí yẹn ju bínú ẹ̀ ṣe dùn lórí àwọn tó kù. Ó wá fi kún un pé: “Kò wu Baba mi tó wà ní ọ̀run pé kí ọ̀kan péré nínú àwọn ẹni kékeré yìí ṣègbé.”—Mátíù 18:10, 14.
Jésù wá gba àwọn àpọ́sítélì náà níyànjú lórí ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń bá ara wọn fà nípa ẹni tó tóbi jù, ó ní: “Ẹ ní iyọ̀ nínú ara yín, kí ẹ sì jẹ́ kí àlàáfíà wà láàárín yín.” (Máàkù 9:50) Iyọ̀ máa ń mú kí oúnjẹ dùn ni, torí náà táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù bá dà bí iyọ̀, ọ̀rọ̀ ẹnu wọn máa dùn, á mú kó rọrùn fáwọn míì láti gba ọ̀rọ̀ wọn, kí àlàáfíà sì jọba dípò kí wọ́n máa jiyàn, torí ìyẹn ò ní jẹ́ kí ìṣọ̀kan wà láàárín wọn.—Kólósè 4:6.
Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ṣá o, ohun tó lágbára lè wáyé láàárín wọn, torí náà Jésù sọ bí wọ́n ṣe lè yanjú ẹ̀. Ó ní: “Tí arákùnrin rẹ bá ṣẹ̀, lọ sọ ẹ̀bi rẹ̀ fún un láàárín ìwọ àti òun nìkan. Tó bá fetí sí ọ, o ti jèrè arákùnrin rẹ.” Tí kò bá gbà ńkọ́? Jésù rọ̀ wọ́n pé: “Mú ẹnì kan tàbí méjì dání, kó lè jẹ́ pé nípa ẹ̀rí ẹni méjì tàbí mẹ́ta, a ó fìdí gbogbo ọ̀rọ̀ múlẹ̀.” Tọ́rọ̀ kò bá lójú lẹ́yìn ìyẹn, Jésù ní kí wọ́n sọ̀rọ̀ náà fún “ìjọ,” ìyẹn fún àwọn alàgbà láti bá wọn dá sí i. Kí ni kí wọ́n wá ṣe tí ẹlẹ́ṣẹ̀ náà bá fàáké kọ́rí? Jésù sọ pé kí wọ́n kà á sí “èèyàn àwọn orílẹ̀-èdè àti agbowó orí,” tí àwọn Júù kì í bá kẹ́gbẹ́.—Mátíù 18:15-17.
Ó ṣe pàtàkì káwọn alábòójútó máa lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí wọ́n bá ń bójú tó ọ̀rọ̀ nínú ìjọ. Tí wọ́n bá rí i pé ẹnì kan jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án tí wọ́n sì bá a wí, a jẹ́ pé ìdájọ́ wọn jẹ́ èyí “tí a ti dè ní ọ̀run.” Àmọ́ tí wọ́n bá dá ẹnì kan láre, a jẹ́ pé ìdájọ́ wọn jẹ́ èyí “tí a ti tú ní ọ̀run.” Ìlànà yìí máa wúlò gan-an nígbà tí wọ́n bá dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀. Jésù sọ ohun kan tó ń fini lọ́kàn bálẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ ìgbẹ́jọ́, ó ní: “Ibi tí ẹni méjì tàbí mẹ́ta bá kóra jọ sí ní orúkọ mi, mo wà níbẹ̀ láàárín wọn.”—Mátíù 18:18-20.