Jẹ́nẹ́sísì
40 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, olórí agbọ́tí+ ọba Íjíbítì àti olórí alásè* ṣẹ ọba Íjíbítì tó jẹ́ olúwa wọn. 2 Fáráò wá bínú sí àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ méjèèjì, ìyẹn olórí agbọ́tí àti olórí alásè,+ 3 ó sì jù wọ́n sí ẹ̀wọ̀n ní ilé olórí ẹ̀ṣọ́,+ níbi tí Jósẹ́fù ti ń ṣẹ̀wọ̀n.+ 4 Olórí ẹ̀ṣọ́ wá yan Jósẹ́fù pé kó wà pẹ̀lú wọn, kó sì máa bójú tó wọn.+ Wọ́n sì wà lẹ́wọ̀n fúngbà díẹ̀.*
5 Agbọ́tí àti alásè ọba Íjíbítì tí wọ́n wà lẹ́wọ̀n lá àlá ní alẹ́ ọjọ́ kan náà, àlá tí kálukú wọn lá sì ní ìtumọ̀ tirẹ̀. 6 Ní àárọ̀ ọjọ́ kejì, nígbà tí Jósẹ́fù wọlé, ó rí i pé inú wọn ò dùn. 7 Ó wá bi àwọn òṣìṣẹ́ Fáráò tí wọ́n jọ wà lẹ́wọ̀n ní ilé ọ̀gá rẹ̀ pé: “Kí ló dé tí ẹ fajú ro lónìí?” 8 Wọ́n fèsì pé: “Kálukú wa lá àlá, àmọ́ kò sẹ́ni tó máa túmọ̀ rẹ̀ fún wa.” Jósẹ́fù sọ fún wọn pé: “Ṣebí Ọlọ́run+ ló ni ìtúmọ̀? Ẹ jọ̀ọ́, ẹ rọ́ àlá yín fún mi.”
9 Olórí agbọ́tí sì rọ́ àlá tó lá fún Jósẹ́fù, ó ní: “Mo rí igi àjàrà kan lójú àlá. 10 Ẹ̀ka mẹ́ta wà lórí igi àjàrà náà. Bí ọ̀mùnú rẹ̀ ṣe ń yọ, ó yọ òdòdó, òṣùṣù èso àjàrà rẹ̀ sì pọ́n. 11 Ife Fáráò wà lọ́wọ́ mi, mo mú àwọn èso àjàrà náà, mo fún un sínú ife Fáráò, mo sì gbé ife náà fún Fáráò.” 12 Jósẹ́fù wá sọ fún un pé: “Ìtúmọ̀ rẹ̀ nìyí: Ẹ̀ka mẹ́ta náà dúró fún ọjọ́ mẹ́ta. 13 Lọ́jọ́ mẹ́ta òní, Fáráò máa mú ọ jáde,* ó máa dá ọ pa dà sẹ́nu iṣẹ́+ rẹ, wàá sì máa gbé ife fún Fáráò bí o ti ń ṣe tẹ́lẹ̀ nígbà tí o jẹ́ agbọ́tí+ rẹ̀. 14 Àmọ́ kí o rántí mi tí nǹkan bá ti ṣẹnuure fún ọ. Jọ̀ọ́, fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí mi, kí o sì sọ̀rọ̀ mi fún Fáráò, kí n lè kúrò níbí. 15 Ṣe ni wọ́n jí mi gbé kúrò ní ilẹ̀ àwọn Hébérù,+ mi ò sì ṣe ohunkóhun níbí tó fi yẹ kí wọ́n jù mí sí ẹ̀wọ̀n.”*+
16 Nígbà tí olórí alásè rí i pé ìtúmọ̀ tí Jósẹ́fù ṣe dára, ó sọ fún un pé: “Èmi náà lá àlá. Apẹ̀rẹ̀ mẹ́ta tó ní búrẹ́dì funfun wà lórí mi nínú àlá náà. 17 Oríṣiríṣi oúnjẹ tí wọ́n yan tó jẹ́ ti Fáráò wà nínú apẹ̀rẹ̀ tó wà lókè pátápátá, àwọn ẹyẹ sì ń jẹ ẹ́ nínú apẹ̀rẹ̀ tó wà lórí mi.” 18 Jósẹ́fù wá sọ pé: “Ìtúmọ̀ rẹ̀ nìyí: Apẹ̀rẹ̀ mẹ́ta náà dúró fún ọjọ́ mẹ́ta. 19 Lọ́jọ́ mẹ́ta òní, Fáráò yóò bẹ́ orí rẹ,* yóò gbé ọ kọ́ sórí òpó igi, àwọn ẹyẹ yóò sì jẹ ẹran ara rẹ.”+
20 Ọjọ́ kẹta wá jẹ́ ọjọ́ ìbí+ Fáráò, ó sì se àsè fún gbogbo ìránṣẹ́ rẹ̀, ó wá mú olórí agbọ́tí àti olórí alásè jáde* níṣojú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. 21 Ó dá olórí agbọ́tí pa dà sí ipò tó wà tẹ́lẹ̀, ó sì ń gbé ife fún Fáráò. 22 Àmọ́, ó gbé olórí alásè kọ́, bí Jósẹ́fù ṣe túmọ̀ àlá wọn fún wọn.+ 23 Ṣùgbọ́n olórí agbọ́tí náà ò rántí Jósẹ́fù; ó ti gbàgbé rẹ̀.+