Diutarónómì
15 “Ní òpin ọdún méje-méje, kí o máa ṣe ìtúsílẹ̀.+ 2 Bí ìtúsílẹ̀ náà ṣe máa rí nìyí: Kí gbogbo ẹni tí ọmọnìkejì rẹ̀ jẹ ní gbèsè má ṣe gbà á pa dà. Kó má sọ pé kí ọmọnìkejì rẹ̀ tàbí arákùnrin rẹ̀ san án pa dà, torí pé a máa kéde rẹ̀ pé ó jẹ́ ìtúsílẹ̀ fún Jèhófà.+ 3 O lè gbà á pa dà lọ́wọ́ àjèjì,+ àmọ́ kí o fagi lé gbèsè yòówù kí arákùnrin rẹ jẹ ọ́. 4 Ṣùgbọ́n, ẹnikẹ́ni nínú yín ò gbọ́dọ̀ tòṣì, torí ó dájú pé Jèhófà máa bù kún ọ+ ní ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ pé kí o jogún, 5 àfi tí o bá ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run rẹ délẹ̀délẹ̀ nìkan, tí o sì rí i pé ò ń pa gbogbo àṣẹ yìí tí mò ń fún ọ lónìí mọ́.+ 6 Torí Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa bù kún ọ bó ṣe ṣèlérí fún ọ, o sì máa yá ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ní nǹkan,* àmọ́ kò ní sóhun tí á mú kí o yá nǹkan;+ o sì máa jọba lé ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àmọ́ wọn ò ní jọba lé ọ lórí.+
7 “Tí ọ̀kan lára àwọn arákùnrin rẹ bá di aláìní láàárín rẹ nínú ọ̀kan lára àwọn ìlú rẹ ní ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ, o ò gbọ́dọ̀ mú kí ọkàn rẹ le tàbí kí o háwọ́ sí arákùnrin rẹ tó jẹ́ aláìní.+ 8 Ṣe ni kí o lawọ́ sí i,+ kí o sì rí i dájú pé o yá a ní* ohunkóhun tó bá nílò tàbí tó ń jẹ ẹ́ níyà. 9 Rí i pé o ò gbin èrò ibi yìí sọ́kàn pé, ‘Ọdún keje, ọdún ìtúsílẹ̀, ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé,’+ kí o wá ṣahun sí arákùnrin rẹ tó jẹ́ aláìní, kí o má sì fún un ní nǹkan kan. Tó bá fi ẹjọ́ rẹ sun Jèhófà, ó ti di ẹ̀ṣẹ̀ sí ọ lọ́rùn nìyẹn.+ 10 Kí o lawọ́ sí i dáadáa,+ kí o* má sì ráhùn tí o bá ń fún un, torí èyí á mú kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bù kún ọ nínú gbogbo ohun tí o bá ń ṣe àtàwọn ohun tí o bá dáwọ́ lé.+ 11 Torí pé ìgbà gbogbo ni àwọn òtòṣì á máa wà ní ilẹ̀ rẹ.+ Ìdí nìyẹn tí mo fi ń pàṣẹ fún ọ pé, ‘Kí o lawọ́ dáadáa sí arákùnrin rẹ tí ìyà ń jẹ tó sì tòṣì ní ilẹ̀ rẹ.’+
12 “Tí wọ́n bá ta ọ̀kan lára àwọn èèyàn rẹ fún ọ, tó jẹ́ Hébérù, ì báà jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin, tó sì ti fi ọdún mẹ́fà sìn ọ́, kí o dá a sílẹ̀ ní ọdún keje.+ 13 Tí o bá sì ti dá a sílẹ̀, má ṣe jẹ́ kó lọ lọ́wọ́ òfo. 14 Kí o lawọ́ sí i, kí o fún un látinú agbo ẹran rẹ, látinú ibi ìpakà rẹ àti látinú ibi tí o ti ń fún òróró àti wáìnì. Bí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ṣe bù kún ọ gẹ́lẹ́ ni kí o ṣe fún un. 15 Rántí pé o di ẹrú ní ilẹ̀ Íjíbítì, Jèhófà Ọlọ́run rẹ sì rà ọ́ pa dà. Ìdí nìyẹn tí mo fi ń pa àṣẹ yìí fún ọ lónìí.
16 “Àmọ́ tó bá sọ fún ọ pé, ‘Mi ò ní kúrò lọ́dọ̀ rẹ!’ torí pé ó nífẹ̀ẹ́ ìwọ àti agbo ilé rẹ, tó sì jẹ́ pé inú rẹ̀ máa ń dùn nígbà tó wà lọ́dọ̀ rẹ,+ 17 kí o mú òòlu,* kí o sì fi dá etí rẹ̀ lu mọ́ ara ilẹ̀kùn, ó sì máa di ẹrú rẹ títí láé. Bẹ́ẹ̀ náà ni kí o ṣe fún ẹrúbìnrin rẹ. 18 Má kà á sí ìnira tí o bá dá a sílẹ̀, tó sì kúrò lọ́dọ̀ rẹ, torí pé ìlọ́po méjì iṣẹ́ tí alágbàṣe máa ṣe fún ọ ló ṣe ní ọdún mẹ́fà tó fi sìn ọ́, Jèhófà Ọlọ́run rẹ sì ti bù kún ọ nínú gbogbo ohun tí o ṣe.
19 “Gbogbo àkọ́bí tó jẹ́ akọ nínú ọ̀wọ́ ẹran rẹ àti nínú agbo ẹran rẹ ni kí o yà sọ́tọ̀ fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ.+ O ò gbọ́dọ̀ fi àkọ́bí nínú ọ̀wọ́ ẹran* rẹ ṣe iṣẹ́ kankan, o ò sì gbọ́dọ̀ rẹ́ irun àkọ́bí nínú agbo ẹran rẹ. 20 Iwájú Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni kí ìwọ àti agbo ilé rẹ ti máa jẹ ẹ́ lọ́dọọdún ní ibi tí Jèhófà máa yàn.+ 21 Àmọ́ tó bá ní àbùkù lára, bóyá ó jẹ́ arọ, afọ́jú tàbí tó ní oríṣi àbùkù míì tó le gan-an, o ò gbọ́dọ̀ fi rúbọ sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ.+ 22 Inú àwọn ìlú* rẹ ni kí o ti jẹ ẹ́, aláìmọ́ àti ẹni tó mọ́ lè jẹ ẹ́, bí ẹni tó ń jẹ egbin tàbí àgbọ̀nrín.+ 23 Àmọ́ o ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀;+ ṣe ni kí o dà á jáde sórí ilẹ̀ bí omi.+