Ìsíkíẹ́lì
10 Bí mo ṣe ń wò, mo rí ohun tó rí bí òkúta sàfáyà lókè ohun tó tẹ́ pẹrẹsẹ lórí àwọn kérúbù náà, ó sì dà bí ìtẹ́.+ 2 Ó wá sọ fún ọkùnrin tó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀*+ náà pé: “Wọ àárín àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà,+ lábẹ́ àwọn kérúbù, kó ẹyin iná tó ń jó + láàárín àwọn kérúbù náà sí ọwọ́ rẹ méjèèjì, kí o sì fọ́n ọn ká sórí ìlú náà.”+ Mo wá rí i tó wọlé.
3 Àwọn kérúbù náà dúró ní apá ọ̀tún ilé náà nígbà tí ọkùnrin náà wọlé, ìkùukùu* sì kún àgbàlá inú. 4 Ògo Jèhófà+ gbéra láti orí àwọn kérúbù wá sí ẹnu ọ̀nà ilé náà, ìkùukùu sì bẹ̀rẹ̀ sí í kún inú ilé náà díẹ̀díẹ̀,+ ògo Jèhófà sì mọ́lẹ̀ yòò ní gbogbo àgbàlá náà. 5 Ìró ìyẹ́ apá àwọn kérúbù náà sì dé àgbàlá ìta, ó dún bí ìgbà tí Ọlọ́run Olódùmarè bá ń sọ̀rọ̀.+
6 Lẹ́yìn náà, ó pàṣẹ fún ọkùnrin tó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ pé: “Mú iná láàárín àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà, láàárín àwọn kérúbù,” ó sì wọlé, ó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ àgbá kẹ̀kẹ́ náà. 7 Ọ̀kan lára àwọn kérúbù náà wá na ọwọ́ rẹ̀ jáde síbi iná tó wà láàárín wọn.+ Ó mú díẹ̀ lára rẹ̀, ó sì kó o sí ọwọ́ méjèèjì ọkùnrin tó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀.+ Ọkùnrin náà gbà á, ó sì jáde lọ. 8 Àwọn kérúbù náà ní ohun tó dà bí ọwọ́ èèyàn lábẹ́ ìyẹ́ wọn.+
9 Bí mo ṣe ń wò, mo rí àgbá kẹ̀kẹ́ mẹ́rin lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn kérúbù náà, àgbá kẹ̀kẹ́ kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ kérúbù kọ̀ọ̀kan, àwọn àgbá náà ń dán bí òkúta kírísóláítì.+ 10 Àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin jọra, wọ́n rí bí ìgbà tí àgbá kẹ̀kẹ́ kan wà nínú àgbá kẹ̀kẹ́ míì. 11 Tí wọ́n bá ń lọ, wọ́n lè lọ sí ibikíbi ní ọ̀nà mẹ́rẹ̀ẹ̀rin láìṣẹ́rí pa dà, torí ibi tí orí bá kọjú sí ni wọ́n máa ń lọ láìṣẹ́rí pa dà. 12 Gbogbo ara wọn, ẹ̀yìn wọn, ọwọ́ wọn, ìyẹ́ apá wọn àti àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà, àgbá kẹ̀kẹ́ àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, ní ojú káàkiri ara wọn.+ 13 Ní ti àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà, mo gbọ́ ohùn kan tó sọ fún wọn pé, “Ẹ gbéra, ẹ̀yin àgbá kẹ̀kẹ́!”
14 Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn* ní ojú mẹ́rin. Ojú àkọ́kọ́ jẹ́ ojú kérúbù, ojú kejì jẹ́ ojú èèyàn, ojú kẹta jẹ́ ojú kìnnìún, ojú kẹrin sì jẹ́ ojú idì.+
15 Àwọn kérúbù náà á sì dìde, àwọn ni ẹ̀dá alààyè* tí mo rí ní odò Kébárì,+ 16 tí àwọn kérúbù náà bá sì gbéra, àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà á gbéra pẹ̀lú wọn; tí wọ́n bá sì na ìyẹ́ apá wọn kí wọ́n lè lọ sókè, àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà kì í yí tàbí kí wọ́n kúrò lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn.+ 17 Tí wọ́n bá dúró, àwọn àgbá náà á dúró; tí wọ́n bá sì gbéra, àwọn àgbá náà á gbéra pẹ̀lú wọn, torí ẹ̀mí tó ń darí àwọn ẹ̀dá alààyè náà* wà nínú àwọn àgbá náà.
18 Ògo Jèhófà+ wá kúrò ní ẹnu ọ̀nà ilé náà, ó sì dúró lórí àwọn kérúbù náà.+ 19 Bí mo ṣe ń wò, àwọn kérúbù náà wá na ìyẹ́ apá wọn, wọ́n sì gbéra nílẹ̀. Àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn nígbà tí wọ́n gbéra. Wọ́n dúró ní ẹnubodè ìlà oòrùn ní ilé Jèhófà, ògo Ọlọ́run Ísírẹ́lì sì wà lórí wọn.+
20 Àwọn ni ẹ̀dá alààyè* tí mo rí lábẹ́ ìtẹ́ Ọlọ́run Ísírẹ́lì ní odò Kébárì,+ mo wá mọ̀ pé kérúbù ni wọ́n. 21 Àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ní ojú mẹ́rin, ìyẹ́ apá mẹ́rin, ohun tó sì dà bí ọwọ́ èèyàn wà lábẹ́ ìyẹ́ apá wọn.+ 22 Ojú wọn sì dà bí àwọn ojú tí mo rí lẹ́bàá odò Kébárì.+ Iwájú tààrà ni kálukú wọn ń lọ.+