Ìsíkíẹ́lì
25 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 2 “Ọmọ èèyàn, yíjú sọ́dọ̀ àwọn ọmọ Ámónì,+ kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sórí wọn.+ 3 Kí o sọ nípa àwọn ọmọ Ámónì pé, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ. Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Torí ẹ sọ pé ‘Àháà!’ nígbà tí wọ́n sọ ibi mímọ́ mi di aláìmọ́, nígbà tí wọ́n sọ ilẹ̀ Ísírẹ́lì di ahoro àti nígbà tí ilé Júdà lọ sí ìgbèkùn, 4 torí náà, èmi yóò mú kí ọwọ́ àwọn ará Ìlà Oòrùn tẹ̀ ọ́, wàá sì di ohun ìní wọn. Wọ́n á kọ́ àwọn ibùdó* wọn sínú rẹ, wọ́n á sì pàgọ́ wọn sáàárín rẹ. Wọ́n á jẹ èso rẹ, wọ́n á sì mu wàrà rẹ. 5 Èmi yóò sọ Rábà+ di ibi tí àwọn ràkúnmí á ti máa jẹko, èmi yóò sì sọ ilẹ̀ àwọn ọmọ Ámónì di ibi ìsinmi agbo ẹran; ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.”’”
6 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí, ‘Torí ẹ pàtẹ́wọ́,+ tí ẹ fẹsẹ̀ kilẹ̀, tí ẹ* sì ń yọ̀ bí ẹ ṣe ń fi ilẹ̀ Ísírẹ́lì ṣe irú ẹlẹ́yà yìí,+ 7 torí náà, èmi yóò na ọwọ́ mi láti fìyà jẹ yín, kí n lè mú kí àwọn orílẹ̀-èdè kó ẹrù yín lọ. Màá pa yín rẹ́ láàárín àwọn èèyàn, màá sì pa yín run ní àwọn ilẹ̀ náà.+ Màá pa yín rẹ́, ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’
8 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Torí Móábù+ àti Séírì + sọ pé: “Wò ó! Ilé Júdà dà bíi gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù,” 9 èmi yóò mú kó rọrùn láti gbógun ti àwọn ìlú tó wà ní ẹ̀gbẹ́* Móábù, ní ààlà rẹ̀. Àwọn ló rẹwà* jù ní ilẹ̀ náà, Bẹti-jẹ́ṣímótì, Baali-méónì, títí dé Kiriátáímù.+ 10 Màá mú kí ọwọ́ àwọn ará Ìlà Oòrùn+ tẹ òun àti àwọn ọmọ Ámónì, yóò sì di ohun ìní wọn, kí a má bàa rántí àwọn ọmọ Ámónì mọ́ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.+ 11 Èmi yóò ṣèdájọ́ ní Móábù,+ wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’
12 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Édómù ti gbẹ̀san lára ilé Júdà, wọ́n sì ti jẹ̀bi gidigidi torí ẹ̀san tí wọ́n gbà;+ 13 torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Màá tún na ọwọ́ mi láti fìyà jẹ Édómù, èmi yóò pa àwọn èèyàn àti ẹran ọ̀sìn ibẹ̀, èmi yóò sì sọ ọ́ di ahoro.+ Idà ni yóò pa wọ́n láti Témánì títí dé Dédánì.+ 14 ‘Màá lo àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì láti gbẹ̀san lára Édómù.+ Wọ́n á mú ìbínú mi àti ìrunú mi wá sórí Édómù, kí wọ́n lè mọ̀ pé èmi ló ń gbẹ̀san lára wọn,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”’
15 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Èrò ìkà tó wà lọ́kàn àwọn Filísínì* ti mú kí wọ́n máa wá bí wọ́n á ṣe gbẹ̀san kí wọ́n sì pani run, torí wọn ò yéé kórìíra.+ 16 Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Màá na ọwọ́ mi láti fìyà jẹ àwọn Filísínì,+ màá pa àwọn Kérétì rẹ́,+ màá sì run àwọn tó ṣẹ́ kù nínú àwọn tó ń gbé ní etí òkun.+ 17 Màá gbẹ̀san lára wọn lọ́nà tó lé kenkà, màá fi ìbínú jẹ wọ́n níyà, wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà nígbà tí mo bá gbẹ̀san lára wọn.”’”