ORÍ 7
Àwọn Orílẹ̀-Èdè “Á sì Wá Mọ̀ Pé Èmi Ni Jèhófà”
OHUN TÍ ORÍ YÌÍ DÁ LÉ: Ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́ látinú àjọṣe tó wà láàárín Ísírẹ́lì àtàwọn orílẹ̀-èdè tó pẹ̀gàn orúkọ Jèhófà
1, 2. (a) Báwo ni Ísírẹ́lì ṣe dà bí àgùntàn tó dá wà láàárín àwọn ìkookò? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ orí yìí.) (b) Kí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtàwọn ọba wọn máa ń fàyè gbà?
Ọ̀PỌ̀ ọdún ni Ísírẹ́lì fi dà bí àgùntàn tó dá wà láàárín àwọn ìkookò. Àwọn ọmọ Ámónì, àwọn ọmọ Móábù àtàwọn ọmọ Édómù ń gbógun ti Ísírẹ́lì ní apá ìlà oòrùn ààlà rẹ̀. Àwọn Filísínì tó wà lápá ìwọ̀ oòrùn kò yéé bá Ísírẹ́lì ṣọ̀tá. Ìlú Tírè tí nǹkan ti rọ̀ṣọ̀mù tó sì jẹ́ ojúkò ọrọ̀ ajé wà lápá àríwá. Orílẹ̀-èdè Íjíbítì àtijọ́ tí Fáráò tó fira ẹ̀ ṣe ọlọ́run ti ń ṣàkóso ló sì bá Ísírẹ́lì pààlà lápá gúúsù.
2 Jèhófà máa ń dáàbò bo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n bá gbára lé e, ó sì máa ń gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn. Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtàwọn ọba wọn jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká sọ wọ́n di oníwà ìbàjẹ́. Àpẹẹrẹ kan ni Ọba Áhábù tí kò lè dá ìpinnu ṣe. Òun àti Jèhóṣáfátì ọba Júdà gbé láyé lákòókò kan náà, ó sì jọba lórí ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì. Ọmọ ọba Sídónì tó ń ṣàkóso ìlú Tírè tí nǹkan ti rọ̀ṣọ̀mù ló fi ṣe aya. Jésíbẹ́lì lorúkọ obìnrin náà, ó gbé ìjọsìn Báálì lárugẹ ní Ísírẹ́lì, ó sì mú kí ọkọ rẹ̀ ṣe àwọn nǹkan tó sọ ìjọsìn mímọ́ di aláìmọ́ lọ́nà tó lékenkà.—1 Ọba 16:30-33; 18:4, 19.
3, 4. (a) Àwọn wo ni Ìsíkíẹ́lì yí àfiyèsí rẹ̀ sí? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn?
3 Jèhófà ti kìlọ̀ fáwọn èèyàn rẹ̀ nípa àbájáde ìwà àìṣòótọ́ wọn. Àmọ́ sùúrù rẹ̀ ti wá dópin. (Jer. 21:7, 10; Ìsík. 5:7-9) Lọ́dún 609 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn ọmọ ogun Bábílónì pa dà sí Ilẹ̀ Ìlérí lẹ́ẹ̀kẹta. Ó ti ń lọ sí ọdún mẹ́wàá báyìí tí wọ́n ti gbéjà ko ilẹ̀ náà gbẹ̀yìn. Àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, ṣe ni wọ́n á ya ògiri Jerúsálẹ́mù lulẹ̀, wọ́n á sì pa àwọn tó ṣọ̀tẹ̀ sí Nebukadinésárì run. Bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í dó ti Jerúsálẹ́mù, tí àwọn nǹkan tó burú jáì tí Ìsíkíẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ dórí bíńtín, wòlíì náà yí àfiyèsí rẹ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè tó yí Ilẹ̀ Ìlérí ká.
Àwọn orílẹ̀-èdè tó pẹ̀gàn orúkọ Jèhófà ò ní lọ láìjìyà
4 Nínú ìran tí Jèhófà fi han Ìsíkíẹ́lì, ó jẹ́ kó mọ̀ pé àwọn ọ̀tá Júdà máa yọ̀ tí Jerúsálẹ́mù bá pa run, wọ́n á sì tún ni àwọn tó yè bọ́ lára. Àmọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tó pẹ̀gàn orúkọ Jèhófà, tí wọ́n ṣenúnibíni sí àwọn èèyàn rẹ̀ tàbí tí wọ́n sọ àwọn èèyàn rẹ̀ dìbàjẹ́ kò ní lọ láìjìyà. Àwọn ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú àjọṣe Ísírẹ́lì àtàwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyẹn? Báwo sì lohun tí Ìsíkíẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn orílẹ̀-èdè yẹn ṣe fi wá lọ́kàn balẹ̀ lónìí?
Àwọn Mọ̀lẹ́bí Tó Fi Ísírẹ́lì Ṣe “Ẹlẹ́yà”
5, 6. Báwo làwọn ọmọ Ámónì ṣe jẹ́ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì?
5 Mọ̀lẹ́bí ni Ámónì, Móábù àti Édómù jẹ́ sí Ísírẹ́lì. Àmọ́ kàkà kí àwọn orílẹ̀-èdè yìí ro ti pé wọ́n jọ jẹ́ mọ̀lẹ́bí àti ìtàn ìdílé wọn, ṣe ni wọ́n ń bá àwọn èèyàn Ọlọ́run ṣọ̀tá ṣáá, wọ́n sì fi wọ́n ṣe “ẹlẹ́yà.”—Ìsík. 25:6.
6 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Àwọn Ọmọ Ámónì. Wọ́n jẹ́ àtọmọdọ́mọ Lọ́ọ̀tì tó jẹ́ mọ̀lẹ́bí Ábúráhámù. Ọmọbìnrin kékeré tí Lọ́ọ̀tì bí ló bí wọn. (Jẹ́n. 19:38) Èdè wọn àti èdè Hébérù wọnú ara gan-an, ó sì ṣeé ṣe kí àwọn èèyàn Ọlọ́run lóye ohun tí wọ́n bá ń sọ. Torí pé ẹbí ni wọ́n, Jèhófà sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n má gbógun ja àwọn ọmọ Ámónì. (Diu. 2:19) Síbẹ̀, nígbà ayé àwọn Onídàájọ́, àwọn ọmọ Ámọ́nì lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ Ẹ́gílónì ọba Móábù láti ni Ísírẹ́lì lára. (Oníd. 3:12-15, 27-30) Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Ámónì gbéjà ko Ísírẹ́lì nígbà tí Sọ́ọ̀lù ń jọba. (1 Sám. 11:1-4) Nígbà ayé Ọba Jèhóṣáfátì, wọ́n tún lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ Móábù láti gbógun ja Ilẹ̀ Ìlérí.—2 Kíró. 20:1, 2.
7. Kí ni àwọn ọmọ Móábù ṣe sí àwọn mọ̀lẹ́bí wọn tí wọ́n jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ísírẹ́lì?
7 Àwọn Ọmọ Móábù pẹ̀lú jẹ́ àtọmọdọ́mọ Lọ́ọ̀tì nípasẹ̀ ọmọbìnrin rẹ̀ àgbà. (Jẹ́n. 19:36, 37) Jèhófà sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n má ṣe bá àwọn ọmọ Móábù jagun. (Diu. 2:9) Àmọ́ àwọn ọmọ Móábù ò fi irú inú rere kan náà hàn sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Dípò kí wọ́n ṣèrànwọ́ fáwọn mọ̀lẹ́bí wọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bọ́ lóko ẹrú ní Íjíbítì, ṣe ni wọ́n ń wá bí wọn ò ṣe ní jẹ́ kí wọ́n wọ Ilẹ̀ Ìlérí. Bálákì ọba Móábù háyà Báláámù kó lè gégùn-ún fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, Báláámù sì kọ́ Bálákì ní ohun tó máa ṣe láti mú kí àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì ṣèṣekúṣe, kí wọ́n sì bọ̀rìṣà. (Nọ́ń. 22:1-8; 25:1-9; Ìfi. 2:14) Ọ̀pọ̀ ọdún ni àwọn ọmọ Móábù fi ni àwọn mọ̀lẹ́bí wọn lára, títí dìgbà ayé Ìsíkíẹ́lì.—2 Ọba 24:1, 2.
8. Kí nìdí tí Jèhófà fi pe Édómù àti Ísírẹ́lì ní arákùnrin, àmọ́ kí ni Édómù ṣe?
8 Àtọmọdọ́mọ Ísọ̀ tí òun àti Jékọ́bù jọ jẹ́ ìbejì ni Àwọn Ọmọ Édómù. Àjọṣe tímọ́tímọ́ wà láàárín Ísírẹ́lì àti Édómù débi pé Jèhófà pe àwọn méjèèjì ní arákùnrin. (Diu. 2:1-5; 23:7, 8) Síbẹ̀, Édómù gbógun ti Ísírẹ́lì látìgbà tí wọ́n ti kúrò ní Íjíbítì títí dìgbà tí Jerúsálẹ́mù pa run lọ́dún 607 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni. (Nọ́ń. 20:14, 18; Ìsík. 25:12) Yàtọ̀ sí pé inú àwọn ọmọ Édómù ń dùn nígbà tí Ísírẹ́lì ń jìyà, tí wọ́n sì rọ àwọn ará Bábílónì pé kí wọ́n pa Jerúsálẹ́mù run, wọ́n tún dínà mọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kí wọ́n má bàa ríbi sá lọ, wọ́n sì tún fi wọ́n lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́.—Sm. 137:7; Ọbad. 11, 14.
9, 10. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Ámónì, Móábù àti Édómù? (b) Àwọn àpẹẹrẹ wo ló fi hàn pé kì í ṣe gbogbo àwọn aráàlú yẹn ló gbógun ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì?
9 Jèhófà sọ pé òun á fìyà jẹ àwọn mọ̀lẹ́bí Ísírẹ́lì nítorí ohun tí wọ́n ṣe sáwọn èèyàn Rẹ̀. Ó ní: “Màá mú kí ọwọ́ àwọn ará Ìlà Oòrùn tẹ . . . àwọn ọmọ Ámónì, yóò sì di ohun ìní wọn, kí a má bàa rántí àwọn ọmọ Ámónì mọ́ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.” Ó tún sọ pé: “Èmi yóò ṣèdájọ́ ní Móábù, wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.” (Ìsík. 25:10, 11) Ní nǹkan bí ọdún márùn-ún lẹ́yìn tí Jerúsálẹ́mù pa run, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ nígbà tí àwọn ará Bábílónì ṣẹ́gun Ámónì àti Móábù. Ní ti Édómù, Jèhófà sọ pé òun máa “pa àwọn èèyàn àti ẹran ọ̀sìn ibẹ̀,” òun á sì “sọ ọ́ di ahoro.” (Ìsík. 25:13) Bí Jèhófà ṣe sọ tẹ́lẹ̀, a ò gbúròó Ámónì, Móábù àti Édómù mọ́.—Jer. 9:25, 26; 48:42; 49:17, 18.
10 Àmọ́ kì í ṣe gbogbo àwọn aráàlú yẹn ló gbógun ti àwọn èèyàn Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, Sélékì ọmọ Ámónì àti Ítímà ọmọ Móábù wà lára àwọn jagunjagun Ọba Dáfídì tó lákíkanjú. (1 Kíró. 11:26, 39, 46; 12:1) Bákan náà, Rúùtù tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Móábù wá sin Jèhófà tọkàntọkàn.—Rúùtù 1:4, 16, 17.
Tá a bá juwọ́ sílẹ̀ pẹ́nrẹ́n, ó lè ṣàkóbá fún wa
11. Kí la rí kọ́ látinú àjọṣe Ísírẹ́lì àti orílẹ̀-èdè Ámónì, Móábù àti Édómù?
11 Àwọn ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nítorí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n bá ṣe wọléwọ̀de? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dẹra nù, àwọn àṣà ìsìn èké bẹ̀rẹ̀ sí í yọ́ wọlé látọ̀dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí wọn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn Báálì Péórì ti ilẹ̀ Móábù àti Mólékì ọlọ́run àwọn ọmọ Ámónì. (Nọ́ń. 25:1-3; 1 Ọba 11:7) Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ sí wa. Àwọn mọ̀lẹ́bí wa tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè máa fúngun mọ́ wa láti ṣe ohun tí Jèhófà ò fẹ́. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè má lóye ìdí tí a kì í fi í ṣe Ọdún Àjíǹde, tí a kì í fún ara wa lẹ́bùn nígbà Ọdún Kérésìmesì àti ìdí tí a ò fi ní lọ́wọ́ sí àwọn ayẹyẹ tí kò bá Bíbélì mu tí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń ṣe. Tí wọn ò bá tiẹ̀ ní èrò tó burú lọ́kàn, wọ́n lè mú ká fọwọ́ rọ́ ohun tá a gbà gbọ́ tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan bó tiẹ̀ jẹ́ fúngbà díẹ̀. Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì nígbà náà pé ká má ṣe juwọ́ sílẹ̀ nírú ipò bẹ́ẹ̀! Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ísírẹ́lì yìí ti jẹ́ ká rí i pé tá a bá juwọ́ sílẹ̀ pẹ́nrẹ́n, ó lè ṣàkóbá fún àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà.
12, 13. Àtakò wo ló ṣeé ṣe ká dojú kọ, àmọ́ kí ló ṣeé ṣe kó jẹ́ àbájáde rẹ̀ tá a bá jẹ́ adúróṣinṣin?
12 A tún lè rí ẹ̀kọ́ míì kọ́ látinú ohun tí Ámónì, Móábù àti Édómù ṣe fún Ísírẹ́lì. Àwọn mọ̀lẹ́bí wa tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè ṣenúnibíni sí wa. Jésù sọ pé láwọn ìgbà míì, iṣẹ́ ìwàásù wa lè “fa ìpínyà, ọkùnrin sí bàbá rẹ̀, ọmọbìnrin sí ìyá rẹ̀ àti ìyàwó sí ìyá ọkọ rẹ̀.” (Mát. 10:35, 36) Jèhófà sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n má ṣe bá àwọn mọ̀lẹ́bí wọn jà, torí náà, a kì í bá àwọn mọ̀lẹ́bí wa tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí jà. Àmọ́ kò yẹ kí ẹnu yà wá tí àtakò bá dé.—2 Tím. 3:12.
13 Tí àwọn mọ̀lẹ́bí wa ò bá tiẹ̀ ta ko ìjọsìn wa sí Jèhófà ní tààràtà, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí wọ́n lágbára lórí wa ju Jèhófà lọ. Kí nìdí? Ìdí ni pé Jèhófà ló yẹ kó gba ipò kìíní nígbèésí ayé wa. (Ka Mátíù 10:37.) Yàtọ̀ síyẹn, tá a bá jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, ó ṣeé ṣe ká rí lára àwọn mọ̀lẹ́bí wa tó máa dara pọ̀ mọ́ wá nínú ìjọsìn mímọ́ bíi ti Sélékì, Ítímà àti Rúùtù. (1 Tím. 4:16) Nígbà náà, inú àwọn pẹ̀lú máa dùn láti jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà, wọ́n á sì rí i pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wọn àti pé ó ń dáàbò bò wọ́n.
Jèhófà ‘Jẹ Àwọn Ọ̀tá Rẹ̀ Níyà’
14, 15. Irú ìwà wo ni àwọn Filísínì hù sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì?
14 Àwọn Filísínì ti ṣí kúrò ní erékùṣù Kírétè lọ sí ilẹ̀ tí Jèhófà ṣèlérí pé òun máa fún Ábúráhámù àti àtọmọdọ́mọ rẹ̀ nígbà tó yá. Àwọn nǹkan kan pa Ábúráhámù, Ísákì àti àwọn èèyàn náà pọ̀. (Jẹ́n. 21:29-32; 26:1) Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi máa wọ Ilẹ̀ Ìlérí, àwọn Filísínì ti di alágbára gan-an, àkòtagìrì sì làwọn ọmọ ogun wọn. Òrìṣà bíi Baali-sébúbù àti Dágónì ni wọ́n ń bọ. (1 Sám. 5:1-4; 2 Ọba 1:2, 3) Nígbà míì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń bá wọn jọ́sìn àwọn òrìṣà yìí.—Oníd. 10:6.
15 Nítorí ìwà àìṣòótọ́ tí Ísírẹ́lì hù, Jèhófà gbà kí àwọn Filísínì lo agbára lórí àwọn èèyàn rẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún. (Oníd. 10:7, 8; Ìsík. 25:15) Wọ́n ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lára gan-an, wọn ò gbà kí wọ́n ṣe ohun tí wọ́n fẹ́,a wọ́n sì pa ọ̀pọ̀ lára wọn. (1 Sám. 4:10) Àmọ́, Jèhófà máa ń gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ tí wọ́n bá ronú pìwà dà, tí wọ́n sì pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó yan àwọn èèyàn bíi Sámúsìn, Sọ́ọ̀lù àti Dáfídì láti dá àwọn èèyàn Rẹ̀ nídè. (Oníd. 13:5, 24; 1 Sám. 9:15-17; 18:6, 7) Bí Ìsíkíẹ́lì ṣe sọ tẹ́lẹ̀, Jèhófà ‘jẹ àwọn Filísínì níyà’ nígbà tí àwọn ará Bábílónì gbógun ja ilẹ̀ wọn, tí àwọn Gíríìkì sì tún gbógun tì wọ́n lẹ́yìn náà.—Ìsík. 25:15-17.
16, 17. Àwọn ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú ohun tó wáyé láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtàwọn Filísínì?
16 Àwọn ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú ohun tó wáyé láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtàwọn Filísínì? Àwa èèyàn Jèhófà òde òní ti fojú winá àtakò látọ̀dọ̀ àwọn kan lára àwọn orílẹ̀-èdè tó lágbára jù lọ tó ń ni àwọn èèyàn lára. Àmọ́ ọ̀rọ̀ wa ò rí bíi tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì torí pé a ò fi Jèhófà sílẹ̀ rárá. Síbẹ̀, ó lè fẹ́ dà bíi pé ọwọ́ àwọn ọ̀tá ìjọsìn mímọ́ lékè nígbà míì. Bí àpẹẹrẹ, ní ìbẹ̀rẹ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún ogún, ìjọba ilẹ̀ Amẹ́ríkà gbìyànjú láti fòpin sí iṣẹ́ àwa èèyàn Jèhófà, wọ́n dájọ́ pé kí wọ́n fi àwọn tó ń múpò iwájú nínú ètò Jèhófà sẹ́wọ̀n fún ọ̀pọ̀ ọdún. Nígbà ogun àgbáyé kejì, ẹgbẹ́ òṣèlú Násì ní orílẹ̀-èdè Jámánì gbìyànjú láti pa àwọn èèyàn Ọlọ́run rẹ́ ráúráú, wọ́n fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ lára wa sẹ́wọ̀n, wọ́n sì pa àwọn tó pọ̀ gan-an. Lẹ́yìn ogun yẹn, ọ̀pọ̀ ọdún ni ìjọba Soviet Union fi gbéjà ko àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n fi àwọn ará wa sáwọn àgọ́ tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ àṣekúdórógbó, wọ́n sì kó àwọn míì lọ sígbèkùn láwọn ibi tó jìnnà gan-an nílẹ̀ náà.
17 Àwọn ìjọba ṣì lè máa fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa, wọ́n lè ju àwa èèyàn Ọlọ́run sẹ́wọ̀n tàbí kí wọ́n tiẹ̀ pa lára wa. Ǹjẹ́ ó yẹ kí àwọn nǹkan yìí mú kẹ́rù bà wá tàbí kó mú kí ìgbàgbọ́ wa jó rẹ̀yìn? Ká má rí i! Jèhófà máa dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ tó jẹ́ adúróṣinṣin. (Ka Mátíù 10:28-31.) A ti rí bí àwọn ìjọba apàṣẹwàá tí wọ́n lágbára ṣe pa rẹ́, àmọ́ tí àwa èèyàn Jèhófà ń gbèrú sí i. Láìpẹ́, ohun tó fara jọ èyí tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn Filísínì máa ṣẹlẹ̀ sí gbogbo ìjọba èèyàn, bí wọ́n fẹ́, bí wọ́n kọ̀, wọ́n á gbà pé Jèhófà ni aláṣẹ. Bíi tàwọn Filísínì, a ò ní gbúròó wọn mọ́ láé!
‘Ọrọ̀ Tó Pọ̀ Rẹpẹtẹ’ Kò Lè Dáàbò Boni Títí Lọ
18. Àwọn nǹkan wo ló jẹ́ kí ìlú Tírè lókìkí?
18 Ojúkò ọrọ̀ ajé ni ìlú Tírèb àtijọ́. Ibẹ̀ ni olú ìlú ọ̀kan lára àwọn ilẹ̀ ọba tí ọrọ̀ ajé wọn búrẹ́kẹ́ jù lọ láyé ìgbà yẹn. Àwọn ọkọ̀ òkun rẹ̀ máa ń kó ọjà gba orí Òkun Mẹditaréníà lọ sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlú tó wà lápá ìwọ̀ oòrùn. Wọ́n tún máa ń kó ọjà láti Tírè gba orí ilẹ̀ lọ sáwọn ìlú tó jìnnà réré lápá ìlà oòrùn. Ọ̀pọ̀ ọdún ni ìlú yìí fi to ọrọ̀ jọ pelemọ látara àwọn ìlú tó jìnnà réré tó bá dòwò pọ̀. Owó táwọn oníṣòwò àtàwọn ọlọ́jà rẹ̀ ní pọ̀ gan-an débi pé wọ́n gbà pé ìjòyè làwọn jẹ́ láwùjọ.—Àìsá. 23:8.
19, 20. Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín àwọn tó ń gbé ìlú Tírè àtàwọn ará Gíbíónì?
19 Nígbà tí Ọba Dáfídì àti Sólómọ́nì ṣàkóso, Ísírẹ́lì bá àwọn aráàlú Tírè dòwò pọ̀ dáadáa, wọ́n kó àwọn oníṣẹ́ ọnà àtàwọn ohun ìkọ́lé wá nígbà tí wọ́n ń kọ́ ààfin Dáfídì àti nígbà tí Sólómọ́nì ń kọ́ tẹ́ńpìlì. (2 Kíró. 2:1, 3, 7-16) Àwọn ará Tírè mọ ìgbà tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì sin Jèhófà tọkàntọkàn, tí Jèhófà sì bù kún wọn. (1 Ọba 3:10-12; 10:4-9) Ẹ wo àǹfààní tí ọ̀pọ̀ àwọn aráàlú Tírè ní láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìjọsìn mímọ́, kí wọ́n mọ Jèhófà, kí wọ́n sì rí àǹfààní tó wà nínú kéèyàn jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́!
20 Dípò kí àwọn aráàlú Tírè lo àǹfààní yẹn láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, ọrọ̀ ni wọ́n ń lé lójú méjèèjì. Wọn ò tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn ará Gíbíónì tó jẹ́ ìlú tó lágbára nílẹ̀ Kénáánì, àwọn nǹkan àgbàyanu tí Jèhófà ṣe ni àwọn aráàlú yìí gbọ́ tí wọ́n sì wá di ìránṣẹ́ rẹ̀. (Jóṣ. 9:2, 3, 22–10:2) Kódà, àwọn tó ń gbé ìlú Tírè ṣàtakò sí àwọn èèyàn Ọlọ́run, wọ́n tiẹ̀ tún ta àwọn kan sóko ẹrú.—Sm. 83:2, 7; Jóẹ́lì 3:4, 6; Émọ́sì 1:9.
Ká má ṣe máa wo ọrọ̀ bí ògiri tó ń dáàbò boni
21, 22. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Tírè, kí ló sì fà á?
21 Jèhófà gbẹnu Ìsíkíẹ́lì sọ fún àwọn alátakò náà pé: “Màá bá ọ jà, ìwọ Tírè, màá sì gbé ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè dìde sí ọ, bí òkun ṣe ń gbé ìgbì rẹ̀ dìde. Wọ́n á run ògiri Tírè, wọ́n á wó àwọn ilé gogoro rẹ̀, màá ha iyẹ̀pẹ̀ rẹ̀ kúrò, màá sì sọ ọ́ di àpáta lásán tó ń dán.” (Ìsík. 26:1-5) Ọrọ̀ tí àwọn tó ń gbé ìlú Tírè kó jọ ni wọ́n gbà pé ó máa dáàbò bo àwọn. Lójú wọn, ṣe ni ọrọ̀ wọn dà bí ògiri tó dáàbò bo ìlú wọn tó wà lórí ilẹ̀ tí omi yí ká, èyí tí gíga rẹ̀ jẹ́ àádọ́jọ (150) ẹsẹ̀ bàtà. Ì bá dáa ká ní wọ́n fiyè sí ìkìlọ̀ Sólómọ́nì pé: “Ohun ìní ọlọ́rọ̀ ni ìlú olódi rẹ̀; lọ́kàn rẹ̀, ó dà bí ògiri tó ń dáàbò boni.”—Òwe 18:11.
22 Nígbà tí àwọn ará Bábílónì àtàwọn Gíríìkì mú àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì ṣẹ, àwọn tó ń gbé ìlú Tírè wá rí i pé ọrọ̀ àti ògiri ìlú wọn tí wọ́n rò pé ó dáàbò bo àwọn ò já mọ́ nǹkan kan. Lẹ́yìn tí wọ́n pa Jerúsálẹ́mù run, ọdún mẹ́tàlá (13) ni àwọn ará Bábílónì fi gbógun ti ìlú Tírè. (Ìsík. 29:17, 18) Nígbà tó fi máa di ọdún 332 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Alẹkisáńdà Ńlá mú apá pàtàkì kan ṣẹ lára àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì.c Àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kó àwọn àwókù ìlú Tírè ti orí ilẹ̀ jọ, wọ́n sì da àwọn òkúta, àwọn iṣẹ́ ọnà tí wọ́n fi igi ṣe àti iyẹ̀pẹ̀ rẹ̀ sínú omi, wọ́n sì fi ṣe ọ̀nà tí wọ́n gbà wọ ìlú Tírè orí omi. (Ìsík. 26:4, 12) Alẹkisáńdà wó ògiri ìlú náà lulẹ̀, ó kó àwọn nǹkan tó wà níbẹ̀, ó pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ ogun àtàwọn aráàlú, ó sì ta ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn sóko ẹrú. Tipátipá ni àwọn tó ń gbé Tírè fi mọ Jèhófà, wọ́n wá kẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tó nira pé ‘ọrọ̀ tó pọ̀ rẹpẹtẹ’ kò lè dáàbò boni títí lọ.—Ìsík. 27:33, 34.
23. Kí lohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ń gbé ìlú Tírè kọ́ wa?
23 Ẹ̀kọ́ wo lá lè rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ń gbé Tírè? A ò ní jẹ́ kí “agbára ìtannijẹ ọrọ̀” mú ká gbẹ́kẹ̀ lé àwọn nǹkan tara, ká wá máa wò ó bí ògiri tó ń dáàbò boni. (Mát. 13:22) A ò lè “sin Ọlọ́run àti Ọrọ̀.” (Ka Mátíù 6:24.) Àwọn tó ń fi gbogbo ọkàn sin Jèhófà nìkan ló lè ní ìfọ̀kànbalẹ̀ tòótọ́. (Mát. 6:31-33; Jòh. 10:27-29) Gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ nípa òpin ètò àwọn nǹkan yìí máa ṣẹ pátápátá bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìlú Tírè ṣe ṣẹ. Nígbà yẹn, tipátipá làwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé ọrọ̀ máa mọ Jèhófà nígbà tó bá pa ètò ọrọ̀ ajé ayé yìí run nínú èyí tí àwọn èèyàn ti ya olójúkòkòrò, tí wọn ò sì mọ̀ ju tara wọn nìkan.
“Pòròpórò Lásán” ni Ìjọba Ayé
24-26. (a) Kí nìdí tí Jèhófà fi pe Íjíbítì ní “pòròpórò lásán?” (b) Kí ni Ọba Sedekáyà ṣe tó fi hàn pé ó kọ etí dídi sí ìkìlọ̀ Jèhófà, kí sì ni àbájáde rẹ̀?
24 Ṣáájú ìgbà ayé Jósẹ́fù títí dìgbà tí àwọn ará Bábílónì gbógun ja Jerúsálẹ́mù, Íjíbítì rọ́wọ́ mú gan-an lágbo òṣèlú ní agbègbè Ilẹ̀ Ìlérí. Lójú àwọn èèyàn, Íjíbítì lè dà bí igi tó ti wà tipẹ́, tó sì ti ta gbòǹgbò torí pé ọjọ́ pẹ́ tí orílẹ̀-èdè náà ti wà. Àmọ́ Íjíbítì kò já mọ́ nǹkan kan rárá lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jèhófà, agbára rẹ̀ ò sì ju ti “pòròpórò lásán.”—Ìsík. 29:6.
25 Ọba Sedekáyà apẹ̀yìndà ò mọ̀ pé bọ́rọ̀ Íjíbítì ṣe rí nìyẹn. Jèhófà lo wòlíì Jeremáyà láti rọ Sedekáyà pé kó fi ara ẹ̀ sábẹ́ ọba Bábílónì. (Jer. 27:12) Sedekáyà tiẹ̀ fi orúkọ Jèhófà búra pé òun ò ní ṣọ̀tẹ̀ sí Nebukadinésárì. Àmọ́ nígbà tó yá, kò ṣe ohun tí Jèhófà sọ, ó da májẹ̀mú tó bá Nebukadinésárì dá, ó sì ké gbàjarè sí Íjíbítì pé kí wọ́n wá bá òun gbógun ja àwọn ará Bábílónì. (2 Kíró. 36:13; Ìsík. 17:12-20) Àmọ́ ṣe ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n gbára lé ilẹ̀ Íjíbítì torí agbára rẹ̀ kó ara wọn sínú ewu tó lékenkà. (Ìsík. 29:7) Agbára tí ilẹ̀ Íjíbítì ní lè fẹ́ dà bíi ti “ẹran ńlá inú àwọn odò.” (Ìsík. 29:3, 4) Síbẹ̀, Jèhófà sọ pé bí ìgbà tọ́wọ́ ọlọ́dẹ tẹ àwọn ọ̀nì odò Náílì ló máa rí nígbà tí òun bá mú Íjíbítì. Ó máa fi ìwọ̀ kọ́ ẹnu rẹ̀, ó sì máa fà á lọ kó lè pa á run. Ohun tó ṣe gẹ́lẹ́ nìyẹn nígbà tó mú kí àwọn ará Bábílónì ṣẹ́gun ilẹ̀ àtijọ́ náà.—Ìsík. 29:9-12, 19.
26 Kí ló wá ṣẹlẹ̀ sí Sedekáyà aláìṣòótọ́? Torí pé “ìjòyè burúkú” yìí ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà, Ìsíkíẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa rọ̀ ọ́ lóyè, ìjọba rẹ̀ sì máa pa run. Àmọ́ Ìsíkíẹ́lì tún sọ nǹkan tó fi hàn pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. (Ìsík. 21:25-27) Jèhófà mú kó sọ tẹ́lẹ̀ pé ọba kan tó wá láti ìdílé ọba, tó sì “lẹ́tọ̀ọ́ sí i lọ́nà òfin” máa gorí ìtẹ́. Nínú orí tó tẹ̀ lé e nínú ìwé yìí, àá mọ ẹni tí ọba náà jẹ́.
27. Kí la rí kọ́ látinú àjọṣe orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àti Íjíbítì?
27 Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú àjọṣe Ísírẹ́lì àti Íjíbítì? Kò yẹ káwa èèyàn Jèhófà lónìí gbára lé àwọn ìjọba ayé, kò yẹ ká máa ronú pé irú ìjọba bẹ́ẹ̀ máa fini lọ́kàn balẹ̀. A gbọ́dọ̀ rí i pé a “kì í ṣe apá kan ayé” nínú èrò ọkàn wa pàápàá. (Jòh. 15:19; Jém. 4:4) Ó lè fẹ́ dà bíi pé ìjọba ayé lágbára, àmọ́ bí ilẹ̀ Íjíbítì àtijọ́ ni wọ́n rí, pòròpórò lásán ni wọ́n. Ẹ ò rí i pé kò ní bọ́gbọ́n mu tá a bá lọ gbẹ́kẹ̀ lé ọmọ aráyé tó lè kú nígbàkigbà dípò ká gbẹ́kẹ̀ lé Olódùmarè, Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run!—Ka Sáàmù 146:3-6.
Àwọn Orílẹ̀-Èdè ‘Á Wá Mọ̀’
28-30. Ìyàtọ̀ wo ló wà nínú bí àwọn orílẹ̀-èdè á ṣe ‘wá mọ’ Jèhófà àti bí àwa ṣe mọ Jèhófà?
28 Nínú ìwé Ìsíkíẹ́lì, ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jèhófà sọ pé àwọn orílẹ̀-èdè “á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.” (Ìsík. 25:17) Ó dájú pé ohun tí Jèhófà sọ gẹ́lẹ́ ló ṣẹlẹ̀ nígbà tó mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ sórí àwọn ọ̀tá tó ń gbógun ti àwọn èèyàn rẹ̀ nígbà àtijọ́. Àmọ́ ìmúṣẹ tó jù bẹ́ẹ̀ lọ á ṣì wáyé lásìkò wa yìí. Lọ́nà wo?
29 Bíi tàwọn èèyàn Ọlọ́run nígbà àtijọ́, àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wa kà ń wò wá bíi pé a ò ní igi lẹ́yìn ọgbà, bí àgùntàn tó dá wà la rí lójú wọn. (Ìsík. 38:10-13) Bá a ṣe máa rí i nínú Orí 17 àti 18 ìwé yìí, àwọn orílẹ̀-èdè máa tó fi ìbínú tó le gan-an gbéjà ko àwa èèyàn Ọlọ́run. Àmọ́ tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n á gbà pé agbára ju agbára lọ. Wọ́n á wá mọ̀ tipátipá pé Jèhófà ni Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run nígbà tó bá ń pa wọ́n run nínú ogun Amágẹ́dọ́nì.—Ìfi. 16:16; 19:17-21.
30 Àmọ́ Jèhófà máa dáàbò bo àwa ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì máa bù kún wa. Kí nìdí? Ìdí ni pé a ti fi hàn báyìí pé a mọ Jèhófà torí òun la gbẹ́kẹ̀ lé, à ń ṣègbọràn sí i, a sì ń fún un ní ìjọsìn mímọ́ tó tọ́ sí i.—Ka Ìsíkíẹ́lì 28:26.
a Bí àpẹẹrẹ, àwọn Filísínì ò gbà kí àwọn oníṣẹ́ irin ṣiṣẹ́ kankan ní Ísírẹ́lì. Ọ̀dọ̀ àwọn Filísínì ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń lọ tí wọ́n bá fẹ́ pọ́n àwọn nǹkan tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ lóko, owó iṣẹ́ tí wọ́n sì máa ń gbà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń tó owó iṣẹ́ ọjọ́ mélòó kan.—1 Sám. 13:19-22.
b Ó jọ pé orí àpáta ńlá kan tó yọ sókè láàárín agbami tí kò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà sí etíkun ni wọ́n kọ́ ìlú Tírè àtijọ́ sí, ó sì tó nǹkan bí àádọ́ta (50) kìlómítà sí apá àríwá Òkè Kámẹ́lì. Nígbà tó yá, wọ́n kọ́ lára ìlú náà sórí ilẹ̀. Orúkọ tí wọ́n ń pe ìlú náà lédè Hébérù ni Súrì, tó túmọ̀ sí “Àpáta.”
c Àìsáyà, Jeremáyà, Jóẹ́lì, Émọ́sì àti Sekaráyà pẹ̀lú sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìlú Tírè, gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ yìí pátá ló sì ṣẹ.—Àìsá. 23:1-8; Jer. 25:15, 22, 27; Jóẹ́lì 3:4; Émọ́sì 1:10; Sek. 9:3, 4.