Ìsíkíẹ́lì
34 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 2 “Ọmọ èèyàn, sọ àsọtẹ́lẹ̀ sórí àwọn olùṣọ́ àgùntàn Ísírẹ́lì. Sọ tẹ́lẹ̀, kí o sì sọ fún àwọn olùṣọ́ àgùntàn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Ẹ gbé, ẹ̀yin olùṣọ́ àgùntàn Ísírẹ́lì,+ tí ẹ̀ ń bọ́ ara yín! Ǹjẹ́ kì í ṣe agbo ẹran ló yẹ kí ẹ̀yin olùṣọ́ àgùntàn máa bọ́?+ 3 Ẹ̀ ń jẹ ọ̀rá, ẹ̀ ń wọ aṣọ tí wọ́n fi irun àgùntàn ṣe, ẹ sì ń pa àwọn ẹran tó sanra jù lọ,+ àmọ́ ẹ ò bọ́ agbo ẹran.+ 4 Ẹ ò tọ́jú èyí tó rẹ̀ kó lè lágbára, ẹ ò tọ́jú èyí tó ń ṣàìsàn kí ara rẹ̀ lè yá, ẹ ò fi aṣọ wé èyí tó fara pa, ẹ ò lọ mú àwọn tó rìn lọ pa dà wálé, ẹ ò sì wá èyí tó sọ nù;+ kàkà bẹ́ẹ̀, ọwọ́ líle ni ẹ fi ń dà wọ́n, ẹ sì hùwà ìkà sí wọn.+ 5 Wọ́n wá fọ́n ká torí kò sí olùṣọ́ àgùntàn;+ wọ́n fọ́n ká, wọ́n sì di oúnjẹ fún gbogbo ẹran inú igbó. 6 Àwọn àgùntàn mi ń rìn kiri lórí gbogbo òkè ńlá àti lórí gbogbo òkè kéékèèké; àwọn àgùntàn mi fọ́n ká sí gbogbo ayé, kò sì sí ẹni tó ń wá wọn kiri tàbí tó ń béèrè ibi tí wọ́n wà.
7 “‘“Torí náà, ẹ̀yin olùṣọ́ àgùntàn, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà: 8 ‘“Bí mo ti ń bẹ láàyè,” ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, “torí pé àwọn àgùntàn mi ti di ẹran tí wọ́n fẹ́ pa, tí wọ́n sì ti di oúnjẹ fún gbogbo ẹran inú igbó, torí pé kò sí olùṣọ́ àgùntàn kankan, tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn mi kò sì wá àwọn àgùntàn mi; àmọ́ tí wọ́n ń bọ́ ara wọn, tí wọn ò sì bọ́ àwọn àgùntàn mi,”’ 9 torí náà, ẹ̀yin olùṣọ́ àgùntàn, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà. 10 Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Èmi yóò bá àwọn olùṣọ́ àgùntàn náà jà, màá mú kí wọ́n jíhìn ohun tí wọ́n ṣe sí àwọn àgùntàn mi,* mi ò ní jẹ́ kí wọ́n bọ́* àwọn àgùntàn mi mọ́,+ àwọn olùṣọ́ àgùntàn náà kò sì ní bọ́ ara wọn mọ́. Màá gba àwọn àgùntàn mi sílẹ̀ ní ẹnu wọn, wọn ò sì ní rí wọn jẹ mọ́.’”
11 “‘Torí ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Wò ó, èmi fúnra mi yóò wá àwọn àgùntàn mi, màá sì bójú tó wọn.+ 12 Èmi yóò bójú tó àwọn àgùntàn mi bí olùṣọ́ àgùntàn tó rí àwọn àgùntàn rẹ̀ tó fọ́n ká, tó sì ń fún wọn ní oúnjẹ.+ Èmi yóò gbà wọ́n sílẹ̀ kúrò ní gbogbo ibi tí wọ́n fọ́n ká sí ní ọjọ́ ìkùukùu* àti ìṣúdùdù tó kàmàmà.+ 13 Èmi yóò mú wọn jáde láàárín àwọn èèyàn, màá sì kó wọn jọ láti àwọn ilẹ̀. Èmi yóò mú wọn wá sórí ilẹ̀ wọn, màá sì bọ́ wọn lórí àwọn òkè Ísírẹ́lì,+ lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi tó ń ṣàn àti lẹ́gbẹ̀ẹ́ gbogbo ibi tí wọ́n ń gbé ní ilẹ̀ náà. 14 Èmi yóò bọ́ wọn ní ibi ìjẹko tó dáa, ilẹ̀ tí wọ́n á sì ti máa jẹko yóò wà lórí àwọn òkè gíga Ísírẹ́lì.+ Wọ́n á dùbúlẹ̀ síbẹ̀, níbi ìjẹko tó dáa,+ orí ilẹ̀ tó sì dáa jù lórí àwọn òkè Ísírẹ́lì ni wọ́n á ti máa jẹ ewéko.”
15 “‘“Èmi fúnra mi yóò bọ́ àwọn àgùntàn mi,+ èmi fúnra mi yóò sì mú kí wọ́n dùbúlẹ̀,”+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí. 16 “Màá wá èyí tó sọ nù,+ màá mú èyí tó rìn lọ pa dà wálé, màá fi aṣọ wé èyí tó fara pa, màá sì tọ́jú èyí tó rẹ̀ kó lè lágbára; àmọ́ èmi yóò pa èyí tó sanra àti èyí tó lágbára. Èmi yóò dá a lẹ́jọ́.”
17 “‘Ní tiyín, ẹ̀yin àgùntàn mi, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Mo máa tó ṣèdájọ́ láàárín àgùntàn kan àti àgùntàn mìíràn, láàárín àwọn àgbò àti àwọn òbúkọ.+ 18 Ṣé bí ẹ ṣe ń jẹ̀ ní ibi ìjẹko tó dáa jù kò tó yín? Ṣé ó tún yẹ kí ẹ fi ẹsẹ̀ tẹ àwọn ewéko yòókù mọ́lẹ̀ ní ibi ìjẹko yín? Lẹ́yìn tí ẹ sì ti mu omi tó mọ́ jù, ṣé ó wá yẹ kí ẹ fi ẹsẹ̀ yín da omi náà rú? 19 Ṣé kí àwọn àgùntàn mi wá máa jẹ ewéko tí ẹ ti fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀, kí wọ́n sì máa mu omi tí ẹ ti fi ẹsẹ̀ dà rú?”
20 “‘Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ fún wọn nìyí: “Wò ó, èmi fúnra mi yóò ṣèdájọ́ láàárín àgùntàn tó sanra àti èyí tó rù, 21 torí ẹ̀ ń fi ẹ̀gbẹ́ àti èjìká yín tì wọ́n, ẹ sì ń fi ìwo yín kan gbogbo àwọn tó ń ṣàìsàn, títí ẹ fi tú wọn káàkiri. 22 Èmi yóò gba àwọn àgùntàn mi là, wọn ò sì ní dọdẹ wọn mọ́;+ èmi yóò sì ṣèdájọ́ láàárín àgùntàn àti àgùntàn. 23 Èmi yóò yan olùṣọ́ àgùntàn kan fún wọn,+ Dáfídì ìránṣẹ́ mi,+ yóò sì máa bọ́ wọn. Òun fúnra rẹ̀ máa bọ́ wọn, ó sì máa di olùṣọ́ àgùntàn wọn.+ 24 Èmi Jèhófà yóò di Ọlọ́run wọn,+ Dáfídì ìránṣẹ́ mi yóò sì di ìjòyè láàárín wọn.+ Èmi Jèhófà ti sọ̀rọ̀.
25 “‘“Èmi yóò bá wọn dá májẹ̀mú àlàáfíà,+ èmi yóò sì pa àwọn ẹranko ẹhànnà run ní ilẹ̀ náà,+ kí wọ́n lè máa gbé láìséwu nínú aginjù, kí wọ́n sì sùn nínú igbó.+ 26 Èmi yóò mú kí wọ́n di ìbùkún, màá mú kí ibi tó yí òkè mi ká náà di ìbùkún,+ màá sì mú kí òjò rọ̀ ní àkókò tó yẹ. Ìbùkún á rọ̀ bí òjò.+ 27 Àwọn igi oko yóò so èso, ilẹ̀ yóò mú èso jáde,+ wọn yóò sì máa gbé láìséwu lórí ilẹ̀ náà. Wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà tí mo bá ṣẹ́ àwọn ọ̀pá àjàgà wọn,+ tí mo sì gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tó fi wọ́n ṣẹrú. 28 Àwọn orílẹ̀-èdè ò ní dọdẹ wọn mọ́, àwọn ẹran inú igbó ò ní pa wọ́n jẹ, ààbò yóò sì wà lórí wọn, ẹnì kankan ò sì ní dẹ́rù bà wọ́n.+
29 “‘“Èmi yóò fún wọn ní oko tó lókìkí,* ìyàn ò ní pa wọ́n mọ́ ní ilẹ̀ náà,+ àwọn orílẹ̀-èdè ò sì ní fi wọ́n ṣẹlẹ́yà mọ́.+ 30 ‘Wọn yóò wá mọ̀ pé èmi Jèhófà Ọlọ́run wọn wà pẹ̀lú wọn àti pé èèyàn mi ni wọ́n, ìyẹn ilé Ísírẹ́lì,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”’
31 “‘Ní tiyín, ẹ̀yin àgùntàn mi,+ ẹ̀yin àgùntàn tí mò ń bójú tó, èèyàn lẹ jẹ́, èmi sì ni Ọlọ́run yín,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”