Àìsáyà
39 Ní àkókò yẹn, ọba Bábílónì, ìyẹn Merodaki-báládánì ọmọ Báládánì, fi àwọn lẹ́tà àti ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí Hẹsikáyà,+ torí ó gbọ́ pé Hẹsikáyà ṣàìsàn, ara rẹ̀ sì ti yá.+ 2 Hẹsikáyà kí wọn káàbọ̀ tayọ̀tayọ̀,* ó sì fi ohun tó wà nínú ilé ìṣúra rẹ̀ hàn wọ́n,+ ìyẹn fàdákà, wúrà, òróró básámù àti àwọn òróró míì tó ṣeyebíye, pẹ̀lú gbogbo ilé tó ń kó ohun ìjà sí àti gbogbo ohun tó wà nínú àwọn ibi ìṣúra rẹ̀. Kò sí nǹkan tí Hẹsikáyà kò fi hàn wọ́n nínú ilé* rẹ̀ àti ní gbogbo agbègbè tó wà lábẹ́ àkóso rẹ̀.
3 Lẹ́yìn náà, wòlíì Àìsáyà wá sọ́dọ̀ Ọba Hẹsikáyà, ó sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kí ni àwọn ọkùnrin yìí sọ, ibo ni wọ́n sì ti wá?” Torí náà, Hẹsikáyà sọ pé: “Ibi tó jìnnà ni wọ́n ti wá, láti Bábílónì.”+ 4 Ó tún béèrè pé: “Kí ni wọ́n rí nínú ilé* rẹ?” Hẹsikáyà fèsì pé: “Gbogbo ohun tó wà nínú ilé* mi ni wọ́n rí. Kò sí nǹkan kan tó wà nínú àwọn ibi ìṣúra mi tí mi ò fi hàn wọ́n.”
5 Àìsáyà wá sọ fún Hẹsikáyà pé: “Gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, 6 ‘Wò ó! Ọjọ́ ń bọ̀ tí wọ́n máa kó gbogbo ohun tó wà nínú ilé* rẹ àti gbogbo ohun tí àwọn baba ńlá rẹ ti kó jọ títí di òní yìí lọ sí Bábílónì. Kò ní ku nǹkan kan,’+ ni Jèhófà wí.+ 7 ‘Wọ́n á mú àwọn kan lára àwọn ọmọ tí o máa bí, wọ́n á sì di òṣìṣẹ́ ààfin ní ààfin ọba Bábílónì.’”+
8 Ni Hẹsikáyà bá sọ fún Àìsáyà pé: “Ọ̀rọ̀ Jèhófà tí o sọ dáa.” Ó wá fi kún un pé: “Torí àlàáfíà àti ìfọkànbalẹ̀* máa wà lásìkò* tèmi.”+