Sáàmù
Sí olùdarí; lórí Muti-lábénì.* Orin Dáfídì.
א [Áléfì]
ב [Bétì]
3 Nígbà tí àwọn ọ̀tá mi bá sá pa dà,+
Wọ́n á ṣubú, wọ́n á sì ṣègbé kúrò níwájú rẹ.
4 Nítorí pé o gbèjà mi lórí ẹ̀tọ́ mi;
O jókòó sórí ìtẹ́ rẹ, o sì ń fi òdodo ṣe ìdájọ́.+
ג [Gímélì]
5 O ti bá àwọn orílẹ̀-èdè wí,+ o sì ti pa àwọn ẹni burúkú run,
O ti nu orúkọ wọn kúrò títí láé àti láéláé.
ה [Híì]
ו [Wọ́ọ̀]
ז [Sáyìn]
11 Ẹ kọ orin ìyìn sí Jèhófà, ẹni tó ń gbé ní Síónì;
Ẹ jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ àwọn ohun tí ó ṣe.+
ח [Hétì]
13 Ṣojú rere sí mi, Jèhófà; wo ìyà tí àwọn tó kórìíra mi fi ń jẹ mí,
Ìwọ tó gbé mi dìde láti àwọn ẹnubodè ikú,+
14 Kí n lè máa kéde àwọn iṣẹ́ rẹ tí ó yẹ fún ìyìn ní àwọn ẹnubodè ọmọbìnrin Síónì,+
Kí àwọn iṣẹ́ ìgbàlà rẹ sì lè máa mú inú mi dùn.+
ט [Tétì]
15 Àwọn orílẹ̀-èdè ti rì sínú kòtò tí wọ́n gbẹ́;
Ẹsẹ̀ wọn ti kó sínú àwọ̀n tí àwọn fúnra wọn dẹ pa mọ́.+
16 Àwọn ìdájọ́ tí Jèhófà ń mú ṣẹ ń jẹ́ kí a mọ̀ ọ́n.+
Iṣẹ́ ọwọ́ ẹni burúkú ti dẹkùn mú òun fúnra rẹ̀.+
Hígáíónì.* (Sélà)
י [Yódì]
17 Àwọn èèyàn burúkú á sá pa dà, wọ́n á sì forí lé Isà Òkú,*
Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tó gbàgbé Ọlọ́run.
18 Àmọ́, a kò ní gbàgbé àwọn aláìní títí lọ;+
Bẹ́ẹ̀ ni ìrètí àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ kò ní já sí asán láé.+
כ [Káfì]
19 Dìde, Jèhófà! Má ṣe jẹ́ kí ẹni kíkú borí.
Jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè gba ìdájọ́ níwájú rẹ.+
20 Dẹ́rù bà wọ́n, Jèhófà,+
Jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè mọ̀ pé ẹni kíkú lásán ni wọ́n. (Sélà)