Sáàmù
Sí olùdarí; kí a yí i sí “Egbin Àfẹ̀mọ́jú.”* Orin Dáfídì.
22 Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, kí ló dé tí o fi kọ̀ mí sílẹ̀?+
Kí nìdí tí o fi jìnnà sí mi láti gbà mí sílẹ̀,
Tí o sì jìnnà sí igbe ìrora mi?+
2 Ọlọ́run mi, mò ń ké pè ọ́ ní ọ̀sán, àmọ́ o ò dáhùn;+
Kódà ní òru, mi ò dákẹ́.
8 “Ó fi ara rẹ̀ lé Jèhófà lọ́wọ́. Kí Ó gbà á sílẹ̀ báyìí!
Kí Ó gbà á là, ṣebí ó fẹ́ràn Rẹ̀ gan-an!”+
9 Ìwọ ni Ó gbé mi jáde láti inú ìyá mi,+
Ìwọ ni O mú kí ọkàn mi balẹ̀ ní àyà ìyá mi.
10 Ọwọ́ rẹ ni mo wà* látìgbà tí wọ́n ti bí mi;
Ìwọ ni Ọlọ́run mi láti inú ìyá mi wá.
14 A tú mi jáde bí omi;
Gbogbo egungun mi ti yẹ̀.
15 Okun mi ti tán, mo dà bí èéfọ́ ìkòkò;+
Ahọ́n mi lẹ̀ mọ́ ẹran ìdí eyín mi;+
O sì mú mi wálẹ̀ sínú ekuru kí n lè kú.+
17 Mo lè ka gbogbo egungun mi.+
Wọ́n ń wò mí, wọ́n sì tẹjú mọ́ mi.
19 Àmọ́ ìwọ, Jèhófà, má jìnnà sí mi.+
Ìwọ ni okun mi; tètè wá ràn mí lọ́wọ́.+
20 Gbà mí* lọ́wọ́ idà,
Gba ẹ̀mí mi tó ṣeyebíye* lọ́wọ́ èékánná* ajá;+
21 Gbà mí kúrò lẹ́nu kìnnìún + àti lọ́wọ́ ìwo akọ màlúù igbó;
Dá mi lóhùn, kí o sì gbà mí sílẹ̀.
23 Ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù Jèhófà, ẹ yìn ín!
Gbogbo ẹ̀yin ọmọ* Jékọ́bù, ẹ yìn ín lógo!+
Ẹ máa bẹ̀rù rẹ̀, gbogbo ẹ̀yin ọmọ* Ísírẹ́lì.
24 Nítorí kò gbójú fo ìyà tó ń jẹ ẹni tí ara ń ni, kò sì ṣàìka ìpọ́njú rẹ̀ sí;+
Kò gbé ojú rẹ̀ pa mọ́ fún un.+
Nígbà tó ké pè é fún ìrànlọ́wọ́, ó gbọ́.+
25 Màá yìn ọ́ láàárín ìjọ ńlá;+
Màá san àwọn ẹ̀jẹ́ mi níwájú àwọn tó bẹ̀rù rẹ.
Kí wọ́n gbádùn ayé* títí láé.
27 Gbogbo ayé á rántí, wọ́n á sì yíjú sọ́dọ̀ Jèhófà.
Gbogbo ìdílé àwọn orílẹ̀-èdè á tẹrí ba níwájú rẹ.+
28 Nítorí pé ti Jèhófà ni ìjọba;+
Ó ń ṣàkóso àwọn orílẹ̀-èdè.
29 Gbogbo àwọn tó láásìkí* nínú ayé á jẹ, wọ́n á sì tẹrí ba;
Gbogbo àwọn tó ń lọ sínú erùpẹ̀ yóò wólẹ̀ níwájú rẹ̀;
Kò sí ìkankan lára wọn tó lè dá ẹ̀mí* rẹ̀ sí.
30 Àwọn àtọmọdọ́mọ wọn* yóò máa sìn ín;
Ìran tó ń bọ̀ yóò gbọ́ nípa Jèhófà.
31 Wọ́n á wá, wọ́n á sì sọ nípa òdodo rẹ̀.
Wọ́n á sọ fún àwọn ọmọ tí a máa bí nípa ohun tó ṣe.