Àìsáyà
9 Àmọ́, ìṣúdùdù náà kò ní rí bí ìgbà tí ìdààmú bá ilẹ̀ náà, bí ìgbà àtijọ́ tí wọ́n hùwà àbùkù sí ilẹ̀ Sébúlúnì àti ilẹ̀ Náfútálì.+ Àmọ́ tó bá yá, Ó máa mú kí a bọlá fún un, ní ọ̀nà ibi òkun, ní agbègbè Jọ́dánì, Gálílì àwọn orílẹ̀-èdè.
2 Àwọn èèyàn tó ń rìn nínú òkùnkùn
Ti rí ìmọ́lẹ̀ tó mọ́lẹ̀ yòò.
Ní ti àwọn tó ń gbé ilẹ̀ tó ṣókùnkùn biribiri,
Ìmọ́lẹ̀ ti tàn sórí wọn.+
3 O ti sọ orílẹ̀-èdè náà di púpọ̀;
O ti mú kó máa yọ̀ gidigidi.
Wọ́n ń yọ̀ níwájú rẹ
Bí àwọn èèyàn ṣe ń yọ̀ nígbà ìkórè,
Bí àwọn tó ń fayọ̀ pín ẹrù ogun.
4 Torí o ti fọ́ àjàgà ẹrù wọn sí wẹ́wẹ́,
Ọ̀pá tó wà ní èjìká wọn, ọ̀pá ẹni tó ń kó wọn ṣiṣẹ́,
Bíi ti ọjọ́ Mídíánì.+
5 Gbogbo bàtà tó ń kilẹ̀ bó ṣe ń lọ
Àti gbogbo aṣọ tí wọ́n rì bọnú ẹ̀jẹ̀
Ló máa di ohun tí wọ́n fi ń dá iná.
Orúkọ rẹ̀ á máa jẹ́ Àgbàyanu Agbani-nímọ̀ràn,+ Ọlọ́run Alágbára,+ Baba Ayérayé, Ọmọ Aládé Àlàáfíà.
7 Àkóso* rẹ̀ á máa gbilẹ̀ títí lọ,
Àlàáfíà kò sì ní lópin,+
Lórí ìtẹ́ Dáfídì+ àti lórí ìjọba rẹ̀,
Kó lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in,+ kó sì gbé e ró,
Nípasẹ̀ ìdájọ́+ tí ó tọ́ àti òdodo,+
Láti ìsinsìnyí lọ àti títí láé.
Ìtara Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun máa ṣe èyí.
9 Gbogbo èèyàn sì máa mọ̀ ọ́n,
Éfúrémù àti àwọn tó ń gbé ní Samáríà,
Tí wọ́n ń fi ìgbéraga àti àfojúdi ọkàn sọ pé:
Wọ́n ti gé àwọn igi síkámórè lulẹ̀,
Àmọ́ á máa fi àwọn igi kédárì rọ́pò wọn.”
11 Jèhófà máa gbé àwọn elénìní Résínì dìde sí i,
Ó sì máa ru àwọn ọ̀tá rẹ̀ sókè láti jagun,
12 Síríà láti ìlà oòrùn àti àwọn Filísínì láti ìwọ̀ oòrùn,*+
Wọ́n máa la ẹnu wọn, wọ́n á sì jẹ Ísírẹ́lì run.+
Pẹ̀lú gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò tíì yí pa dà,
Àmọ́ ó ṣì na ọwọ́ rẹ̀ jáde láti lù wọ́n.+
15 Àgbà ọkùnrin àti ẹni tí àwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún gidigidi ni orí,
Wòlíì tó ń fúnni ní ìtọ́ni èké sì ni ìrù.+
16 Àwọn tó ń darí àwọn èèyàn yìí ń mú kí wọ́n rìn gbéregbère,
Nǹkan sì ti dà rú mọ́ àwọn tó ń tẹ̀ lé wọn lójú.
17 Ìdí nìyẹn tí inú Jèhófà ò fi ní dùn sí àwọn ọ̀dọ́kùnrin wọn,
Kò sì ní ṣàánú àwọn ọmọ aláìníbaba* àti àwọn opó wọn
Torí apẹ̀yìndà àti aṣebi ni gbogbo wọn,+
Gbogbo ẹnu sì ń sọ ọ̀rọ̀ òpònú.
Pẹ̀lú gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò tíì yí pa dà,
Àmọ́ ó ṣì na ọwọ́ rẹ̀ jáde láti lù wọ́n.+
18 Torí pé ìwà burúkú máa ń jó bí iná,
Ó ń jó àwọn igi ẹlẹ́gùn-ún àti èpò run.
Ó máa dáná sí igbó tó díjú,
Èéfín wọn tó ṣú sì máa ròkè lálá.
Ẹnì kankan ò ní dá ẹ̀mí arákùnrin rẹ̀ pàápàá sí.
20 Ẹnì kan máa gé nǹkan lulẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún,
Àmọ́ ebi á ṣì máa pa á;
Ẹnì kan sì máa jẹun ní ọwọ́ òsì,
Àmọ́ kò ní yó.
Wọ́n máa para pọ̀ gbéjà ko Júdà.+
Pẹ̀lú gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò tíì yí pa dà,
Àmọ́ ó ṣì na ọwọ́ rẹ̀ jáde láti lù wọ́n.+