ORÍ 67
“Èèyàn Kankan Ò Sọ̀rọ̀ Báyìí Rí”
WỌ́N RÁN ÀWỌN ÒṢÌṢẸ́ LỌ MÚ JÉSÙ
NIKODÉMÙ GBÈJÀ JÉSÙ
Jésù ṣì wà níbi tí wọ́n ti ṣe Àjọyọ̀ Àwọn Àgọ́ Ìjọsìn (tàbí Àjọyọ̀ Àtíbàbà) ni Jerúsálẹ́mù. Inú rẹ̀ dùn bó ṣe ń rí i tí “ọ̀pọ̀ nínú àwọn èèyàn náà gbà á gbọ́.” Àmọ́ ṣe làwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù ń bínú ní tiwọn. Torí náà, wọ́n rán àwọn òṣìṣẹ́, tó dà bí ọlọ́pàá pé kí wọ́n lọ mú un wá. (Jòhánù 7:31, 32) Síbẹ̀, Jésù ò torí ìyẹn sá pa mọ́.
Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni Jésù ń kọ́ àwọ́n èèyàn ní gbangba ní Jerúsálẹ́mù. Ó sọ fún wọn pé: “Màá ṣì wà pẹ̀lú yín fúngbà díẹ̀ sí i, kí n tó lọ sọ́dọ̀ Ẹni tó rán mi. Ẹ máa wá mi, àmọ́ ẹ ò ní rí mi, ẹ ò sì ní lè wá sí ibi tí mo wà.” (Jòhánù 7:33, 34) Ọ̀rọ̀ Jésù ò yé àwọn Júù náà, ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ láàárín ara wọn pé: “Ibo ni ọkùnrin yìí fẹ́ lọ, tí a ò fi ní rí i? Kì í ṣe ọ̀dọ̀ àwọn Júù tó fọ́n ká sáàárín àwọn Gíríìkì ló fẹ́ lọ, kó sì máa kọ́ àwọn Gíríìkì, àbí ohun tó fẹ́ ṣe nìyẹn ni? Kí ló ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé, ‘Ẹ máa wá mi, àmọ́ ẹ ò ní rí mi, ẹ ò sì ní lè wá sí ibi tí mo wà’?” (Jòhánù 7:35, 36) Wọn ò mọ̀ pé ọ̀rọ̀ bó ṣe máa lọ sọ́run lẹ́yìn tó bá jíǹde ló ń sọ. Òótọ́ sì ni, kò sí báwọn ọ̀tá yìí ṣe máa tẹ̀ lé Jésù lọ sí ọ̀run.
Ó ti tó ọjọ́ méje báyìí tí àjọyọ̀ yìí ti bẹ̀rẹ̀. Nígbà tí wọ́n bá ń ṣe àjọyọ̀ yìí, àlùfáà á máa pọn omi nínú odò Sílóámù láràárọ̀ láti ọjọ́ kìíní, á wá máa dà á sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ nínú tẹ́ńpìlì. Ó ṣeé ṣe kí Jésù fẹ́ káwọn èèyàn máa rántí ohun tí àlùfáà máa ń ṣe yẹn nígbà tó sọ fún wọn pé: “Tí òùngbẹ bá ń gbẹ ẹnikẹ́ni, kó wá sọ́dọ̀ mi, kó sì mu. Ẹnikẹ́ni tó bá ní ìgbàgbọ́ nínú mi, bí ìwé mímọ́ ṣe sọ pé: ‘Láti inú rẹ̀ lọ́hùn-ún, omi ìyè máa ṣàn jáde.’”—Jòhánù 7:37, 38.
Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ nígbà tí Ọlọ́run bá fẹ̀mí yan àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kí wọ́n lè láǹfààní láti lọ sí ọ̀run ni Jésù ń sọ, ohun tó sì ṣẹlẹ̀ nìyẹn lẹ́yìn tí Jésù kú. Àtọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún yẹn ni omi tó ń fúnni ní ìyè ti ń ṣàn jáde bí àwọn ọmọ ẹ̀yìn ṣe ń kéde òtítọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn èèyàn.
Àwọn kan lára àwọn tó ń tẹ́tí sọ́rọ̀ Jésù sọ pé: “Wòlíì náà nìyí lóòótọ́.” Ó dájú pé àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ̀rọ̀ nípa wòlíì tó tóbi ju Mósè ni wọ́n ń tọ́ka sí. Àwọn míì sọ pé: “Kristi náà nìyí.” Àmọ́ àwọn míì sọ pé: “Gálílì kọ́ ni Kristi ti máa jáde wá, àbí ibẹ̀ ni? Ṣebí ìwé mímọ́ sọ pé látinú ọmọ Dáfídì ni Kristi ti máa wá, ó sì máa wá láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, abúlé tí Dáfídì wà tẹ́lẹ̀?”—Jòhánù 7:40-42.
Ọ̀rọ̀ yìí fa ìyapa láàárín àwọn èèyàn náà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan ṣì ń wá bí wọ́n á ṣe mú Jésù, àwọn òṣìṣẹ́ yìí ò jẹ́ fọwọ́ kàn án. Nígbà táwọn òṣìṣẹ́ náà pa dà dé láìmú Jésù, àwọn àlùfáà àtàwọn Farisí bi wọ́n pé: “Kí ló dé tí ẹ ò mú un wá?” Wọ́n dáhùn pé: “Èèyàn kankan ò sọ̀rọ̀ báyìí rí.” Inú wá bí àwọn aṣáájú ìsìn náà, wọ́n sì fìkanra sọ fún wọn pé: “Àbí wọ́n ti tan ẹ̀yin náà jẹ ni? Kò sí ìkankan nínú àwọn alákòóso tàbí àwọn Farisí tó gbà á gbọ́, àbí ó wà? Àmọ́ ẹni ègún làwọn èèyàn yìí tí wọn ò mọ Òfin.”—Jòhánù 7:45-49.
Lọ́tẹ̀ yìí, Farisí kan tó ń jẹ́ Nikodémù tó sì tún jẹ́ ọ̀kan lára ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn gbìyànjú láti gbèjà Jésù. Ó ṣe tán, ó ti lọ sọ́dọ̀ Jésù lóru ní nǹkan bí ọdún méjì ààbọ̀ sẹ́yìn, ó sì ti fi hàn nígbà yẹn pé òun nígbàgbọ́ nínú rẹ̀. Torí náà, Nikodémù bi wọ́n pé: “Òfin wa kì í ṣèdájọ́ èèyàn láìjẹ́ pé ó kọ́kọ́ gbọ́ tẹnu rẹ̀, kó sì mọ ohun tó ń ṣe, àbí ó máa ń ṣe bẹ́ẹ̀?” Báwo ni wọ́n ṣe dáhùn? Wọ́n ní: “Kì í ṣe Gálílì ni ìwọ náà ti wá, àbí ibẹ̀ ni? Wádìí, kí o sì rí i pé a ò ní mú wòlíì kankan wá láti Gálílì.”—Jòhánù 7:51, 52.
Lóòótọ́, Ìwé Mímọ́ ò sọ ní tààràtà pé wòlíì kan máa wá láti Gálílì. Síbẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ́ka sí i pé Kristi máa wá látibẹ̀, torí ó sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn èèyàn máa rí “ìmọ́lẹ̀ tó mọ́lẹ̀ yòò” ní “Gálílì àwọn orílẹ̀-èdè.” (Àìsáyà 9:1, 2; Mátíù 4:13-17) Bákan náà, àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí wọ́n ṣe máa bí Jésù ṣẹ torí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ni wọ́n bí i sí, àtọmọdọ́mọ Dáfídì sì ni. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe káwọn kan lára àwọn Farisí mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí, ó jọ pé àwọn gan-an ló ń tan oríṣiríṣi ọ̀rọ̀ òdì kálẹ̀ nípa Jésù.