Jẹ́nẹ́sísì
47 Jósẹ́fù wá lọ sọ fún Fáráò+ pé: “Bàbá mi àti àwọn arákùnrin mi, agbo ẹran wọn, ọ̀wọ́ ẹran wọn àti gbogbo ohun ìní wọn ti dé láti ilẹ̀ Kénáánì, wọ́n sì ti wà ní ilẹ̀ Góṣénì.”+ 2 Ó mú márùn-ún lára àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ bá Fáráò.+
3 Fáráò bi àwọn arákùnrin Jósẹ́fù pé: “Iṣẹ́ wo lẹ̀ ń ṣe?” Wọ́n fèsì pé: “Olùṣọ́ àgùntàn ni àwa ìránṣẹ́ rẹ, àwa àti àwọn baba ńlá+ wa.” 4 Wọ́n sọ fún Fáráò pé: “A wá gbé ilẹ̀+ yìí bí àjèjì torí kò sí ibi tí agbo ẹran àwa ìránṣẹ́ rẹ yóò ti máa jẹko, torí ìyàn náà mú gidigidi ní ilẹ̀ Kénáánì.+ Torí náà, jọ̀ọ́, jẹ́ kí àwa ìránṣẹ́ rẹ máa gbé ilẹ̀ Góṣénì.”+ 5 Ni Fáráò bá sọ fún Jósẹ́fù pé: “Bàbá rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ ti wá bá ọ níbí. 6 Ilẹ̀ Íjíbítì wà ní ìkáwọ́ rẹ. Jẹ́ kí bàbá rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ máa gbé ibi tó dáa jù ní ilẹ̀+ yìí. Kí wọ́n máa gbé nílẹ̀ Góṣénì. Tí o bá sì mọ àwọn tó dáńgájíá nínú wọn, jẹ́ kí wọ́n máa bójú tó ẹran ọ̀sìn mi.”
7 Jósẹ́fù wá mú Jékọ́bù bàbá rẹ̀ wọlé lọ bá Fáráò, Jékọ́bù sì súre fún Fáráò. 8 Fáráò bi Jékọ́bù pé: “Ẹni ọdún mélòó ni ọ́?” 9 Jékọ́bù sọ fún Fáráò pé: “Àádóje (130) ọdún ni mo fi ń lọ káàkiri.* Ọdún tí mo ti lò láyé kéré, ó sì kún fún wàhálà,+ kò gùn tó ọdún tí àwọn baba ńlá mi lò láyé nígbà tí wọ́n ń lọ káàkiri.”*+ 10 Lẹ́yìn náà, Jékọ́bù súre fún Fáráò, ó sì kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.
11 Jósẹ́fù wá mú kí bàbá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ máa gbé ilẹ̀ náà, ó sì fún wọn ní ohun ìní nílẹ̀ Íjíbítì, níbi tó dáa jù ní ilẹ̀ náà, ní ilẹ̀ Rámésésì,+ bí Fáráò ṣe pàṣẹ. 12 Jósẹ́fù sì ń pèsè oúnjẹ* fún bàbá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ àti gbogbo agbo ilé bàbá rẹ̀, bí àwọn ọmọ wọn ṣe pọ̀ tó.
13 Kò sí oúnjẹ* ní gbogbo ilẹ̀ náà torí ìyàn náà mú gidigidi, ìyàn+ náà mú kí oúnjẹ tán pátápátá ní ilẹ̀ Íjíbítì àti Kénáánì. 14 Jósẹ́fù sì ń gba gbogbo owó tó wà nílẹ̀ Íjíbítì àti Kénáánì tí àwọn èèyàn fi ra+ ọkà, Jósẹ́fù sì ń kó owó náà wá sínú ilé Fáráò. 15 Nígbà tó yá, wọ́n náwó tán ní ilẹ̀ Íjíbítì àti Kénáánì, gbogbo àwọn ará Íjíbítì sì ń wá sọ́dọ̀ Jósẹ́fù, wọ́n ń sọ pé: “Fún wa ní oúnjẹ! Ṣé ó yẹ ká kú níṣojú rẹ torí pé owó ti tán lọ́wọ́ wa?” 16 Jósẹ́fù wá sọ pé: “Tí owó yín bá ti tán, ẹ mú ẹran ọ̀sìn yín wá, màá gbà á lọ́wọ́ yín, màá sì fi fún yín ní oúnjẹ.” 17 Torí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í mú ẹran ọ̀sìn wọn wá fún Jósẹ́fù. Jósẹ́fù ń gba ẹṣin, agbo ẹran, ọ̀wọ́ ẹran àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn, ó sì ń fún àwọn èèyàn náà ní oúnjẹ. Ó ń fún wọn ní oúnjẹ dípò gbogbo ẹran ọ̀sìn wọn tó gbà lọ́dún yẹn.
18 Nígbà tí ọdún yẹn parí, wọ́n wá bá a ní ọdún tó tẹ̀ lé e, wọ́n ń sọ fún un pé: “Ká má parọ́ fún olúwa mi, a ti kó owó wa àti ẹran ọ̀sìn wa fún olúwa mi. A ò ní nǹkan kan mọ́ tí a lè fún olúwa mi àyàfi ara wa àti ilẹ̀ wa. 19 Ṣé ó yẹ kí àwa àti ilẹ̀ wa kú níṣojú rẹ ni? Ra àwa àti ilẹ̀ wa, kí o fi fún wa lóúnjẹ, àwa yóò di ẹrú Fáráò, ilẹ̀ wa yóò sì di tirẹ̀. Fún wa ní irúgbìn ká lè wà láàyè, ká má bàa kú, kí ilẹ̀ wa má sì di ahoro.” 20 Jósẹ́fù wá bá Fáráò ra gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Íjíbítì, torí gbogbo ará Íjíbítì ló ta ilẹ̀ wọn, torí pé ìyàn náà mú gidigidi; ilẹ̀ náà sì wá di ti Fáráò.
21 Ó wá kó àwọn èèyàn náà lọ sínú àwọn ìlú, láti ìkángun ilẹ̀ Íjíbítì kan sí ìkejì.+ 22 Ilẹ̀ àwọn àlùfáà nìkan ni kò rà,+ torí Fáráò ló ń fún àwọn àlùfáà ní oúnjẹ. Oúnjẹ tí Fáráò ń fún wọn ni wọ́n gbára lé. Ìdí nìyẹn tí wọn ò fi ta ilẹ̀ wọn. 23 Jósẹ́fù sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Ẹ wò ó, mo ti ra ẹ̀yin àti ilẹ̀ yín fún Fáráò lónìí. Ẹ gba irúgbìn, kí ẹ sì gbìn ín sí ilẹ̀ náà. 24 Nígbà tí ẹ bá kórè, kí ẹ fún Fáráò+ ní ìdá kan nínú márùn-ún, kí ẹ fi ìdá mẹ́rin yòókù ṣe irúgbìn tí ẹ máa gbìn sínú oko àti oúnjẹ tí ẹ̀yin àti ilé yín àti àwọn ọmọ yín máa jẹ.” 25 Torí náà, wọ́n sọ pé: “O ti dá ẹ̀mí wa sí.+ Jẹ́ ká rí ojú rere olúwa mi, àwa yóò sì di ẹrú Fáráò.”+ 26 Jósẹ́fù wá sọ ọ́ di òfin pé ìdá kan nínú márùn-ún gbọ́dọ̀ jẹ́ ti Fáráò, òfin yìí ni wọ́n ń tẹ̀ lé títí di òní nílẹ̀ Íjíbítì. Ilẹ̀ àwọn àlùfáà nìkan ni kò di ti Fáráò.+
27 Ísírẹ́lì wá ń gbé ní ilẹ̀ Íjíbítì, ní Góṣénì,+ wọ́n tẹ̀ dó síbẹ̀, wọ́n bímọ, wọ́n sì ń pọ̀ gan-an.+ 28 Jékọ́bù gbé ilẹ̀ Íjíbítì fún ọdún mẹ́tàdínlógún (17), ọjọ́ ayé Jékọ́bù sì wá jẹ́ ọdún mẹ́tàdínláàádọ́jọ (147).+
29 Nígbà tí àkókò tí Ísírẹ́lì máa kú+ sún mọ́ tòsí, ó pe Jósẹ́fù ọmọ rẹ̀, ó sì sọ pé: “Tí mo bá rí ojúure rẹ, jọ̀ọ́ fi ọwọ́ rẹ sábẹ́ itan mi, kí o fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí mi, kí o sì jẹ́ olóòótọ́ sí mi. Jọ̀ọ́, má sin mí sí Íjíbítì.+ 30 Tí mo bá kú,* kí o gbé mi kúrò ní Íjíbítì, kí o sì lọ sin mí sí sàréè àwọn baba ńlá+ mi.” Jósẹ́fù fèsì pé: “Màá ṣe ohun tí o sọ.” 31 Ísírẹ́lì wá sọ pé: “Búra fún mi.” Ó sì búra fún un.+ Ísírẹ́lì sì tẹrí ba níbi ìgbèrí ibùsùn+ rẹ̀.