Òwe
26 Bíi yìnyín nígbà ẹ̀ẹ̀rùn àti òjò nígbà ìkórè,
Bẹ́ẹ̀ ni ògo kò yẹ òmùgọ̀.+
2 Bí ẹyẹ kì í ṣeé fò láìnídìí, tí alápàáǹdẹ̀dẹ̀ kì í sì í ṣàdédé fò,
Bẹ́ẹ̀ ni ègún kì í dédé wá láìsí ìdí kan pàtó.*
4 Má ṣe fún òmùgọ̀ lésì gẹ́gẹ́ bí ìwà ẹ̀gọ̀ rẹ̀,
Kí o má bàa fi ara rẹ sí ipò rẹ̀.*
5 Fún òmùgọ̀ lésì gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ̀,
Kó má bàa rò pé òun gbọ́n.+
6 Bí ẹni tó dá ara rẹ̀ lẹ́sẹ̀, tó sì ṣe ara rẹ̀ léṣe*
Ni ẹni tó fa ọ̀ràn lé òmùgọ̀ lọ́wọ́.
8 Bí ẹni ń so òkúta mọ́ kànnàkànnà
Ni téèyàn bá ń fi ògo fún òmùgọ̀.+
9 Bíi koríko ẹlẹ́gùn-ún tó dé ọwọ́ ọ̀mùtí,
Bẹ́ẹ̀ ni òwe rí lẹ́nu àwọn òmùgọ̀.
10 Bíi tafàtafà tó ń ṣe ohun tó bá ṣáà ti rí léṣe,*
Ni ẹni tó gbéṣẹ́ fún òmùgọ̀ tàbí àwọn tó ń kọjá lọ.
11 Bí ajá tó pa dà sídìí èébì rẹ̀,
Bẹ́ẹ̀ ni òmùgọ̀ ṣe ń tún ìwà ẹ̀gọ̀ rẹ̀ hù.+
12 Ṣe o ti rí ẹni tó rò pé òun gbọ́n?+
Ìrètí wà fún òmùgọ̀ jù ú lọ.
13 Ọ̀lẹ ń sọ pé: “Ọmọ kìnnìún wà lójú ọ̀nà,
Kìnnìún wà ní gbàgede ìlú!”+
16 Ọ̀lẹ rò pé òun gbọ́n
Ju àwọn méje tó lè fèsì tó mọ́gbọ́n dání.
18 Bíi wèrè tó ń ta ohun ọṣẹ́ oníná, ọfà àti ikú*
19 Ni ẹni tó tan ọmọnìkejì rẹ̀ jẹ, tó wá sọ pé, “Eré ni mò ń ṣe!”+
20 Níbi tí kò bá sí igi, iná á kú,
Níbi tí kò bá sì sí abanijẹ́, ìjà á tán.+
21 Bí èédú ṣe wà fún ẹyin iná, tí igi sì wà fún iná,
Bẹ́ẹ̀ ni alárìíyànjiyàn ṣe máa ń dá ìjà sílẹ̀.+
24 Ẹni tó kórìíra ẹlòmíì máa ń fi ọ̀rọ̀ ẹnu bò ó mọ́lẹ̀,
Àmọ́ ẹ̀tàn ló fi sínú.
25 Bó tilẹ̀ ń sọ ohun rere, má gbà á gbọ́,
Nítorí ohun ìríra méje ló wà lọ́kàn rẹ̀.*
26 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó fi ẹ̀tàn bo ìkórìíra rẹ̀ mọ́lẹ̀,
A ó tú ìwà burúkú rẹ̀ síta nínú ìjọ.
27 Ẹni tó gbẹ́ kòtò yóò já sínú rẹ̀,
Ẹni tó bá sì yí òkúta kúrò, òkúta náà yóò pa dà sórí rẹ̀.+
28 Ẹni tó ní ahọ́n èké kórìíra àwọn tó fi ń bà jẹ́,
Ẹnu tó ń pọ́nni sì ń fa ìparun.+